Sísẹ́ Ọlọrun Ní Ọrúndún Ogún
“Àwọn ènìyàn gbà pẹ̀lú èrò náà pé kò sí Ọlọrun wọ́n sì ń dá ṣètò ìgbésí-ayé araawọn, yálà ó yọrí sí rere tàbí búburú, wọn kò sì ronú nípa Ọlọrun rárá.”
—Ìwé One Hundred Years of Debate Over God—The Sources of Modern Atheism.
BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ máa ń dùn ún wò, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ igi ràbàtà kan ni a kì í kà sí bàbàrà. Wíwà rẹ̀ kò tún jẹ́ titun mọ́; gíga rẹ̀ kò sì tún ní múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ mọ́.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbé ìjiyàn púpọ̀ dìde ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, sísẹ́ wíwà Ọlọrun kò múnigbọ̀nrìrì kò sì tún daniláàmú mọ́ lónìí. Sànmánì ìfàyègbà ti yọ̀ǹda kí àìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun máa bá a nìṣó ní ìrọwọ́rọsẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun.
Kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn sẹ́ Ọlọrun jálẹ̀jálẹ̀; ní òdìkejì sí ìyẹn, ìyọrísí ìwádìí èrò láti àwọn orílẹ̀-èdè 11 jákèjádò àwọn ilẹ̀ America, Europe, àti Asia fihàn pé, ní ìpíndọ́gba, iye tí ó fi díẹ̀ dínkù sí ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun ti gbòdekan—àní láàárín ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà pàápàá. Báwo ni èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?
Sísẹ́ Ọlá-Àṣẹ Ọlọrun
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé, “Nígbà mìíràn àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun wulẹ̀ lè tọ́kasí kíkọ̀ tàbí ṣíṣàì ka Ọlọrun sí lọ́nà tí ìwàhíhù.” Fún ìdí yìí, The New Shorter Oxford English Dictionary pèsè ìtumọ̀ kejì tí ó tẹ̀lé e yìí fún “àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun”: “Ẹnì kan tí ó sẹ́ Ọlọrun lọ́nà ti ìwàhíhù; ẹnì kan tí kò gbà pé Ọlọrun wà.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Bẹ́ẹ̀ni, àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun lè wémọ́ sísẹ́ yálà wíwà Ọlọrun tàbí ọlá-àṣẹ rẹ̀ tàbí méjèèjì. Bibeli sọ̀rọ̀ bá ẹ̀mí àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun yìí nínú Titu 1:16 pé: “Wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n mọ Ọlọrun, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa àwọn ìṣesí wọn.”—The New English Bible; fiwé Orin Dafidi 14:1.
Irú kíkọ ọlá-àṣẹ Ọlọrun ní àkọ̀jálẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a lè tọpasẹ̀ rẹ̀ padà sọ́dọ̀ tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́. Efa gbà pé Ọlọrun wà; síbẹ̀, ó fẹ́ láti ‘dàbí Ọlọrun, ní mímọ rere àti búburú.’ Ohun tí ó túmọ̀ sí ni pé kí ó lè ‘jẹ́ ọ̀gá araarẹ̀’ kí ó sì ṣẹ̀dá àkójọ òfin ìwàhíhù tirẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Adamu darapọ̀ mọ́ Efa nínú kíkọ̀ tí ó kọ ọlá-àṣẹ Ọlọrun.—Genesisi 3:5, 6.
Ìṣarasíhùwà yìí ha gbòdekan lónìí bí? Bẹ́ẹ̀ni. Àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun lọ́nà ọgbọ́n àyínìke ni a ń fihàn nínú ìwákiri fún òmìnira. Ìwé náà One Hundred Years of Debate Over God—The Sources of Modern Atheism ṣàlàyé pé: “Ó ti sú àwọn ènìyàn láti máa gbé lábẹ́ àbójútó Ọlọrun lónìí. Ó . . . tẹ́ wọn lọ́rùn láti gbé lómìnira.” Àkójọ òfin ìwàhíhù ti Bibeli ni wọ́n kọ̀sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò gbéṣẹ́, tí kò sì jẹ́ gidi. Lọ́nà púpọ̀ ni ìrònú àwọn ènìyàn fi dàbí ti Farao ilẹ̀ Egipti tí ó fi ìṣàyàgbàǹgbà polongo pé: “Ta ni OLUWA, tí èmi ó fi gba ohùn rẹ̀ gbọ́ . . . ? Èmi kò mọ OLUWA náà.” Ó kọ ọlá-àṣẹ Jehofa.—Eksodu 5:2.
Sísẹ́ tí Kristẹndọm Sẹ́ Ọlọrun
Sísẹ́ Ọlọrun tí ó múni gbọ̀nrìrì jùlọ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm, tí wọ́n ti fi àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó jẹ́ àtọwọ́dá ènìyàn dípò àwọn òtítọ́ mímọ́ gaara ti inú Bibeli. (Fiwé Matteu 15:9.) Ní àfikún sí i, wọ́n ti ṣètìlẹ́yìn fún ogun tí ó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ jùlọ ti ọ̀rúndún ogún, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ àṣẹ inú Bibeli láti fi ojúlówó ìfẹ́ hàn.—Johannu 13:35.
Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tún ti sẹ́ Ọlọrun nípa dídẹ̀yìn wọn kọ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwàhíhù rẹ̀—fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìpẹ̀jọ́ lòdìsí àwọn àlùfáà tí ń bá àwọn ọmọdé lòpọ̀ ti jẹ́rìí sí i. Ipò Kristẹndọm jọ ti Israeli ìgbàanì àti Juda. A sọ fún wòlíì Esekieli pé, “Ilẹ̀ náà sì kún fún ẹ̀jẹ̀, ìlú sì kún fún ìyí-ẹjọ́-po, nítorí wọ́n wí pé, Oluwa ti kọ ayé sílẹ̀, Oluwa kò ríran.” (Esekieli 9:9; fiwé Isaiah 29:15.) Abájọ nígbà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi kọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm sílẹ̀ pátápátá! Ṣùgbọ́n wọ́n ha gbọ́dọ̀ kọ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun sílẹ̀ bí?
Àwọn Ìdí tí Ó Lẹ́sẹ̀nílẹ̀ fún Àìgbàgbọ́ Nínú Wíwà Ọlọrun Kẹ̀?
Yálà wọ́n ti kíyèsí àgàbàgebè ìsìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó dájú pé kò ṣeéṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun láti mú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun báramu pẹ̀lú ìjìyà tí ń bẹ nínú ayé. Simone de Beauvoir sọ nígbà kan rí pé: “Ó rọrùn jùlọ fún mi láti ronú nípa ayé kan tí kò ní ẹlẹ́dàá ju láti ronú nípa ẹlẹ́dàá kan ti a di ẹrù gbogbo ìtakora ayé lé lórí.”
Àwọn àìṣèdájọ́ òdodo inú ayé—títíkan ìwọ̀nyí tí àwọn àgàbàgebè onísìn súnnásí—ha fi ẹ̀rí hàn pé kò sí Ọlọrun bí? Rò ó wò ná: Bí a bá fi ọ̀bẹ kan halẹ̀ mọ́, tàbí fi ṣèpalára fún aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan, tàbí tí a tilẹ̀ fi pa á, èyí ha fi ẹ̀rí hàn pé ọ̀bẹ náà kò ní ẹni tí ó ṣé e bí? Kìí ha ṣe pé ó wulẹ̀ fihàn pé ohun èèlò náà ní a lò lọ́nà tí ó lòdì? Bákan náà, ọ̀pọ̀ lára ẹ̀dùn-ọkàn àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn ń ṣi agbára-ìṣe tí Ọlọrun fifún wọn àti ilẹ̀-ayé fúnraarẹ̀ lò.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan nímọ̀lára pé kò bọ́gbọ́nmu láti gbàgbọ́ nínú Ọlọrun, níwọ̀n bí a kò ti lè rí i. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́, ìgbì ohùn, àti àwọn òórùn ń kọ́? A kò lè rí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, síbẹ̀ a mọ̀ pé wọ́n wà. Ẹ̀dọ̀fóró, etí, àti imú wa mú kí a mọ èyí. Dájúdájú, a gbàgbọ́ nínú ohun tí a kò lè rí bí a bá ti ní ẹ̀rí lọ́wọ́.
Lẹ́yìn tí ó ti ronú nípa àwọn ẹ̀rí tí ó ṣeé fojúrí—títíkan àwọn electron, proton, èròjà akéréjojú, omiró amino, àti ọpọlọ tí ó díjú—onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun àdánidá Irving William Knobloch ni a sún láti sọ pé: “Mo gbàgbọ́ nínú Ọlọrun nítorí pé ní tèmi wíwà Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ni àlàyé bíbọ́gbọ́nmu kanṣoṣo fún bí àwọn nǹkan ti ṣe wà.” (Fiwé Orin Dafidi 104:24.) Bákan náà, onímọ̀ nípa ìṣiṣẹ́ ara ẹ̀dá alàyè Marlin Books Kreider sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lásán, àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan tí ó fi ìgbésí-ayé rẹ̀ jin ìkẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìwádìí jinlẹ̀, èmi kò ní iyèméjì rárá nípa wíwà Ọlọrun.”
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí nìkan kọ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ physics Henry Margenau ti sọ, “bí o bá ṣàgbéyẹ̀wò àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ní ìmọ̀ jùlọ, díẹ̀ ni àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun tí ìwọ yóò rí láàárín wọn.” Kò yẹ kí ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tàbí ìkùnà ìsìn fi ipá mú wa láti pa ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá tì. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ìdí tí kò fi gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀.
Ìyàtọ̀ tí Ń Bẹ Nínú Ìsìn Tòótọ́
Ní 1803, ààrẹ United States Thomas Jefferson kọ̀wé pé: “Níti tòótọ́, àwọn ìwà-ìbàjẹ́ inú ìsìn Kristian ni èmi takò; ṣùgbọ́n kì í ṣe ojúlówó ìlànà ẹ̀kọ́ Jesu fúnraarẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, ìyàtọ̀ kan wà láàárín Kristẹndọm àti ìsìn Kristian. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà ìgbàgbọ́ Kristẹndọm ni a gbékarí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn. Ní ìyàtọ̀, orí Bibeli nìkanṣoṣo ni ìsìn Kristian tòótọ́ gbé àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ kà. Nípa báyìí, Paulu kọ̀wé sí àwọn ará Kolosse ti ọ̀rúndún kìn-ín-ní pé ó yẹ kí wọ́n ní “ìmọ̀ pípéye,” “ọgbọ́n,” àti “ìfinúmòye ti ẹ̀mí.”—Kolosse 1:9, 10, NW.
Èyí ni ohun tí a níláti retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúlówó Kristian, nítorí tí Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.”—Matteu 28:19, 20, NW.
Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń mú àṣẹ yìí ṣẹ ní àwọn ilẹ̀ 231 yíká ayé. Wọ́n ti túmọ̀ Bibeli sí èdè 12 wọ́n sì ti tẹ ẹ̀dà tí ó fi púpọ̀ rékọjá 74,000,000. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nípasẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé, wọ́n ń ran àwọn ènìyàn tí iye wọn rékọjá 4,500,000 lọ́wọ́ ní báyìí láti ‘pa gbogbo ohun tí Jesu paláṣẹ mọ́.’
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ yìí ń ní àwọn ìyọrísí tí ó rìn jìnnà. Ó ń mú ìlàlóye tòótọ́ wá, nítorí pé a kò gbé e karí èrò ènìyàn, bíkòṣe ọgbọ́n Ọlọrun. (Owe 4:18) Síwájú sí i, ó ń ran àwọn ènìyàn láti orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà-ìran gbogbo lọ́wọ́ láti ṣe nǹkan tí “Àjọ Ìgbòkègbodò Ìlàlóye” ènìyàn kò lè ṣe àṣeparí rẹ̀ láé—láti gbé ‘àkópọ̀-ìwà titun wọ̀’ tí ń mú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti mú ojúlówó ìfẹ́ dàgbà fún araawọn.—Kolosse 3:9, 10, NW.
Ìsìn tòótọ́ ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun ní ọ̀rúndún ogún wa. Kò sẹ́ Ọlọrun—yálà wíwà rẹ̀ tàbí ọlá-àṣẹ rẹ̀. A késí ọ láti fi ojú araàrẹ rí èyí nípa ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ọ̀kan lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
FÍFÚN GBÒǸGBÒ ÀÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ WÍWÀ ỌLỌRUN LÓKUN
Ní agbedeméjì ọ̀rúndún kejìdínlógún, ọlọ́gbọ́n èrò-orí náà Denis Diderot ni a fún ní àṣẹ láti túmọ̀ ìwé gbédègbéyọ̀ tí ó jẹ́ ìdìpọ̀ kanṣoṣo láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí French. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe rékọjá ohun tí ẹni tí ó gbé iṣẹ́ fún un retí pé kí ó ṣe. Diderot lo nǹkan bí ẹ̀wádún mẹ́ta fún ṣíṣàkójọ ìwé Encyclopédie rẹ̀, ìwé tí ó ní ìdìpọ̀ 28 tí ó sì ṣojú fún ẹ̀mí tí ó gbilẹ̀ nínú sànmánì náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé Encyclopédie náà ní ìsọfúnni púpọ̀ tí ó gbéṣẹ́ nínú, ọgbọ́n ènìyàn ni àfiyèsí rẹ̀ dá lé lórí. Gẹ́gẹ́ bí àkójọ ìwé náà Great Ages of Man ti wí, “ó gbójú-gbóyà láti wàásù ìlànà àṣerégèé [tí àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí] pé ènìyàn lè mú ìpín rẹ̀ sunwọ̀n sí i bí ó bá fi ìrònú rọ́pò ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí ń tọ́ ọ sọ́nà.” Ó rọrùn láti rí i pé kò mẹ́nukan Ọlọrun. Ìwé náà The Modern Heritage sọ pé, “Nípa irú kókó ẹ̀kọ́ tí wọ́n yàn, àwọn olóòtú náà mú kí ó ṣe kedere pé ìsìn kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn mọ̀.” Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé, ṣọ́ọ̀ṣì gbìyànjú láti tẹ ìwé Encyclopédie náà rì. Aṣojú àgbà fún ìjọba lórí ọ̀ràn òfin jẹ́rìí lòdì sí i gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lè dojú òṣèlú, ìwàrere, àti ìsìn dé.
Láìka àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí, ìwé Encyclopédie Diderot ni àwọn ènìyàn bíi 4,000 béèrè fún—iye kan tí ń mú háà ṣeni, bí a bá ro ti iye owó gọbọi tí ó gbé lérí. Kìkì àkókò nìkan ni yóò jẹ ṣáájú kí iná àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun tí ń rú túú lábẹ́lẹ̀ yìí tó rúyọ láti di sísẹ́ Ọlọrun látòkè-délẹ̀.