ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/1 ojú ìwé 2-5
  • Gbòǹgbò Àìgbàgbọ́ Nínú Wíwà Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbòǹgbò Àìgbàgbọ́ Nínú Wíwà Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ríróye Gbòǹgbò Náà
  • A Fún Irúgbìn Náà
  • Ẹ̀mí-Tàbítàbí Rúyọ
  • Àìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Dé Ògógóró Rẹ̀
  • Sísẹ́ Ọlọrun Ní Ọrúndún Ogún
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ṣó Ṣeé Ṣe Láti Nígbàgbọ́ Nínú Ẹlẹ́dàá?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Isin Ha Pọndandan Nitootọ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/1 ojú ìwé 2-5

Gbòǹgbò Àìgbàgbọ́ Nínú Wíwà Ọlọrun

AŃ GBÉ nínú plánẹ́ẹ̀tì kan tí ó kún fún yánpọnyánrin; wíwo àkọlé iwájú ìwé agbéròyìnjáde kan fìrí ti tó láti fìdí ẹ̀rí yẹn múlẹ̀ lójoojúmọ́. Ipò ìgbékútà tí ayé wa wà ti mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn gbé ìbéèrè dìde nípa wíwà Ọlọrun. Àwọn kan, ní jíjẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun, tilẹ̀ sẹ́ wíwà rẹ̀. Ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ nípa rẹ bí?

Ìgbàgbọ́ tàbí àìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ojú-ìwòye rẹ nípa ọjọ́-ọ̀la. Láìsí Ọlọrun, lílàájá ìran ẹ̀dá ènìyàn di ọwọ́ aráyé látòkèdélẹ̀​—⁠èrò kan tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì, bí a bá ṣàgbéyẹ̀wò agbára tí ènìyàn ní láti pa ara rẹ̀ run. Bí ìwọ bá gbàgbọ́ nítòótọ́ pé Ọlọrun wà, nígbà náà ó ṣeéṣe kí o gbà pé ìwàláàyè lórí plánẹ́ẹ̀tì yìí ní ète kan nítòótọ́​—⁠ète kan tí a óò ní ìrírí ìmúṣẹ rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni a ń rí àwọn tí wọ́n sẹ́ wíwà Ọlọrun, kìkì nínú àwọn ọ̀rúndún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nìkan ni a ti rí i pé òkìkí àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun ti kàn káàkiri. Ìwọ ha mọ ìdí tí ó fi rí bẹ́ẹ̀ bí?

Ríróye Gbòǹgbò Náà

Igi títóbi ràbàtà kan máa ń dùn-⁠ún wò. Síbẹ̀, kìkì àwọn ewé, ẹ̀ka, àti ìtí rẹ̀ lásán ni ojú lè rí. Gbòǹgbò rẹ̀​—⁠orísun ìwàláàyè igi náà⁠—​wà nínú abẹ́-ilẹ̀ lọ́hùn-⁠ún.

Bákan náà gan-⁠an ni ó rí pẹ̀lú àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí igi gíga fíofío kan, sísẹ́ wíwà Ọlọrun ti tóbi ràbàtà ní ìwọ̀n àti ìrísí nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kọkàndínlógún. Ìwàláàyè àti àgbáyé ha lè wà láìsí Okùnfà Àkọ́kọ́ kan tí agbára rẹ̀ ju ti ẹ̀dá lọ bí? Ìjọsìn irú Ẹlẹ́dàá bẹ́ẹ̀ ha jẹ́ ìfi àkókò ṣòfò bí? Ìdáhùn tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí ti ìgbà náà wá ròkè lálá ó sì já geere. Friedrich Nietzsche polongo pé: “Níwọ̀n bí a kò ti nílò àkójọ òfin ìwàhíhù mọ́, a kò nílò ìsìn mọ́ pẹ̀lú.” Ludwig Feuerbach tẹnumọ́ ọn pé: “Àlá ọkàn ènìyàn ni ìsìn jẹ́.” Karl Marx, tí àwọn ìwé rẹ̀ yóò ṣì lo agbára ìdarí pàtàkì nínú àwọn ẹ̀wádún tí ń bọ̀, sọ láìṣojo pé: “Mo fẹ́ kí ọkàn ní òmìnira púpọ̀ sí i kúrò nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìsìn.”

Èyí wú ogunlọ́gọ̀ ènìyàn lórí. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí wọ́n róye rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ àwọn ewé, ẹ̀ka, àti ìtì àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun. Àwọn gbòǹgbò náà ti fìdí múlẹ̀ wọ́n sì ti ń hù jáde tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ọ̀rúndún kọkàndínlógún tó bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, àwọn ìsìn Kristẹndọm ni ó ṣe agbátẹrù ìdàgbàsókè àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun lóde-òní! Báwo ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀? Nítorí ìwà-ìbàjẹ́ wọn, àwọn ètò ìdásílẹ̀ ìsìn wọ̀nyí fa ìtànjẹ àti àtakò ńláǹlà.

A Fún Irúgbìn Náà

Ní àwọn Sànmánì Agbedeméjì, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ní agbára ìdarí tí ń tẹnilóríba lé àwọn ọmọ-abẹ́ rẹ̀ lórí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Ó dàbí ẹni pé ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso kò gbéṣẹ́ tó láti bójútó àìní àwọn ènìyàn nípa tẹ̀mí. Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso tí ipò oyè wọn gbé pẹ́ẹ́lí jù, ní pàtàkì àwọn bíṣọ́ọ̀bù, ni a yàn láti àárín àwọn ọ̀tọ̀kùlú wọ́n sì ka ipò-oyè wọn sí orísun kanṣoṣo tí a ti lè rí iyì àti agbára.”

Àwọn kan, bí i John Calvin àti Martin Luther, gbìyànjú láti ṣàtúnṣe ṣọ́ọ̀ṣì náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀nà tí wọ́n gbé e gbà kò fìgbà gbogbo rí bí i ti Kristi; ojú-ìwòye tèmi lọ̀gá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni ó jẹ́ àmì Ìṣàtúnṣe náà. (Fiwé Matteu 26:52.) Àwọn ìgbéjàkò kan rorò débi pé ní ọ̀rúndún mẹ́ta lẹ́yìn náà Thomas Jefferson, ààrẹ United States kẹta, kọ̀wé pé: “Yóò túbọ̀ rọrùn láti rí ìdáríjì gbà fún àìgba ọlọrun kankan gbọ́, jù láti hùwà àìlọ́wọ̀ sí i nípasẹ̀ àwọn ànímọ́ rírorò ti Calvin lọ.”a

Ó ṣe kedere pé, Ìṣàtúnṣe náà kò mú ìjọsìn mímọ́ gaara padàbọ̀sípò. Síbẹ̀, ó dín agbára Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki kù. Vatican kò tún jẹgàba lé ìgbàgbọ́ ìsìn lórí mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn darapọ̀ mọ́ ẹ̀ya-ìsìn Protẹstanti tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dásílẹ̀. Àwọn mìíràn, tí ìsìn ti jákulẹ̀, sọ ọkàn ènìyàn di ohun tí wọ́n ń  jọ́sìn. Ìṣarasíhùwà gbogbo-lèrò jẹyọ, ní yíyọ̀ǹda fún ọ̀kan-⁠ò-jọ̀kan èrò nípa Ọlọrun.

Ẹ̀mí-Tàbítàbí Rúyọ

Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kejìdínlógún, èrò-àrògún ni àwọn ènìyàn ń gbéga gẹ́gẹ́ bí oògùn gbogboǹṣe fún àwọn ìṣòro aráyé. Ọlọ́gbọ́n èrò-orí ará Germany náà Immanuel Kant tẹnumọ́ ọn pé ìtẹ̀síwájú ènìyàn ni a ti bẹ́gidí nítorí gbígbé tí ó gbáralé ìṣèlú àti ìsìn fún ìtọ́sọ́nà. Ó rọni pé: “Ẹ gbójú-gbóyà láti mọ àmọ̀dájú! Ẹ ní ìgboyà tí ó pọ̀ tó láti lo òye yín!”

Ìṣarasíhùwà yìí ni àmì ìdámọ̀ fún Àjọ Ìgbòkègbodò Ìlàlóye, tí a tún mọ̀ sí Sànmánì Ìrònú. Sáà tí ó wà jálẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún yìí, ni wíwá ìmọ̀ kiri lọ́nà àṣerégèé sàmì sí. Ìwé Milestones of History sọ pé: “Ẹ̀mí-tàbítàbí ni ó rọ́pò ìgbàgbọ́ gbà-láìjanpata. Gbogbo ìgbàgbọ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ògbólógbòó ni a gbé ìbéèrè dìde sí.”

‘Ìgbàgbọ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ògbólógbòó’ kan tí ó kù kí ó wá sábẹ́ àyẹ̀wò fínnífínní ni ìsìn. Ìwé náà The Universal History of the World sọ pé: “Àwọn ènìyàn yí ojú-ìwòye wọn nípa ìsìn padà. Ìlérí nípa èrè ní ọ̀run kò tẹ́ wọn lọ́rùn mọ́; wọ́n ń fi dandangbọ̀n béèrè fún ìgbésí-ayé tí ó sàn jù lórí ilẹ̀-ayé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìgbàgbọ́ wọn nínú agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ nù.” Níti tòótọ́, ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí ti Àjọ Ìgbòkègbodò Ìlàlóye ń yọṣùtì sí ìsìn. Ní pàtàkì, wọ́n dẹ́bi fún àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki tí agbára ń pa lébi fún mímú kí àwọn ènìyàn wà ní ipò àìmọ̀kan.

Bí ìsìn kò ti tẹ́ wọn lọ́rùn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí wọ̀nyí di elérò ọ̀rọ̀-ẹ̀dá-kò-kan-Ọlọ́run; wọ́n gbàgbọ́ nínú Ọlọrun ṣùgbọ́n wọ́n tẹnumọ́ ọn pé kò lọ́kàn-ìfẹ́ kankan nínú ènìyàn.b Àwọn díẹ̀ di aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun tí kì í fi ọ̀rọ̀ bọpo-bọyọ̀, àwọn bí ọlọ́gbọ́n èrò-orí náà Paul Henri Thiry Holbach, tí ó jẹ́wọ́ pé ìsìn ni “orísun ìyapa, ìsínwín, àti ìwà-ọ̀daràn.” Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Kristẹndọm sú àwọn púpọ̀ síi wọ́n sì ṣàjọpín ìrònú Holbach.

Ẹ wo bí ó ti jẹ́ òdìkejì ohun tí a retí tó pé Kristẹndọm ni ó gún ìdàgbàsókè àìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun ní kẹ́ṣẹ́! Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀kọ́-ìsìn Michael J. Buckley kọ̀wé pé: “Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì ni erùpẹ̀ náà nínú èyí tí àìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun ti hù jáde. Òye ìwàhíhù àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ni àwọn ìsìn tí wọ́n ní ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ kan náà ṣẹ̀ sí tí wọ́n sì kó ìríra bá gidigidi. Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ẹ̀ya-ìsìn ti ba ilẹ̀ Europe jẹ́, wọ́n ti dọ́gbọ́n hùmọ̀ ìpànìyàn ní ìpakúpa, wọ́n ti fi dandangbọ̀n béèrè pé kí ìsìn ṣàtakò tàbí dojú ìjọba dé, wọ́n ti gbìdánwò láti dẹ́yẹ sí àwọn ọba-aládé tàbí kí wọ́n rọ̀ wọ́n lóyè.”

Àìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Dé Ògógóró Rẹ̀

Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, sísẹ́ Ọlọrun ni a kò fibò mọ́, ó sì ń gbilẹ̀. Kò ni àwọn ọlọ́gbọ́n èrò-orí àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lára rárá láti polongo ojú-ìwòye wọn. Aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun kan tí kìí fi ọ̀rọ̀ bọpo-bọyọ̀ polongo pé: “Ọ̀tá wa ni Ọlọrun jẹ́. Ìkórìíra Ọlọrun ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n. Bí aráyé yóò bá ní ìtẹ̀síwájú tòótọ́, ó níláti jẹ́ lórí ìpìlẹ̀ àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣípòpadà ọlọ́gbọ́n àyínìke kan wáyé ní ọ̀rúndún ogún. Síṣẹ́ wíwà Ọlọrun dí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́; oríṣi irú àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun mìíràn bẹ̀rẹ̀ síí gbilẹ̀, tí ó sì ń nípalórí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn gba Ọlọrun gbọ́ pàápàá.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ẹ̀ya-ìsìn Protẹstanti tí wọ́n ti ara Ìṣàtúnṣe náà wá kò jáwọ́ nínú ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Wo àwọn ìtẹ̀jáde Jí! ti August 22, 1989, ojú-ìwé 16 sí 20, àti September 8, 1989, ojú-ìwé 23 sí 27.

b Àwọn elérò ọ̀rọ̀-ẹ̀dá-kò-kan-Ọlọ́run jẹ́wọ́ pé, bí i ti ẹnì kan tí ń ṣe agogo, Ọlọrun fi ìṣẹ̀dá rẹ̀ sẹ́nu iṣẹ́ ó sì wá dẹ̀yìn kọ gbogbo rẹ̀ pátá, ní dídá àgunlá àguntẹ̀tẹ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà The Modern Heritage ti sọ, àwọn elérò ọ̀rọ̀-ẹ̀dá-kò-kan-Ọlọrun “gbàgbọ́ pé àìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun jẹ́ ìṣìnà kan tí ó ti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí kò ní ìrètí wá ṣùgbọ́n pé ìgbékalẹ̀ ọlọ́lá-àṣẹ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki àti àìṣe é yípadà àti ojú-ìwòye tèmi lọ̀gá ti àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tilẹ̀ tún múni banújẹ́ jù.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Karl Marx

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ludwig Feuerbach

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Friedrich Nietzsche

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

ÈPO Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ilẹ̀-ayé: Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da láti ọwọ́ British Library; Nietzsche: Copyright British Museum (tún wo ojú-ìwé 3); Calvin: Musée Historique de la Réformation, Genève (Fọ́tò F. Martin); Marx: Fọ́tò U.S. National Archives (tún wo ojú-ìwé 3); Planẹẹti, irin-iṣẹ́,àwọn ajagun ìsìn, ẹ̀rọ tí ń fa kẹ̀kẹ́: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck; Feuerbach: The Bettmann Archive (tún wo ojú-ìwé 3)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́