Isin Ha Pọndandan Nitootọ Bi?
ISIN ha ṣe pataki fun ọ bi? Iwọ, ha jẹ́ mẹmba awujọ isin tabi ṣọọṣi kan bi? Bi ó ba rí bẹẹ, iwọ ni ọpọ ohun ti ó jọra pẹlu awọn eniyan ti wọn ti walaaye sẹhin ni 1844, ọdun na nigba ti ọmọran ara Germany naa Karl Marx kọwe pe: “Isin . . . jẹ́ oògùn apanilọ́bọlọ̀ fun awọn eniyan.” Ni awọn ọjọ wọnni ó fẹrẹẹ jẹ́ pe gbogbo eniyan ni ó nlọ si ṣọọṣi ti isin sì ni agbara idari lilagbara lori gbogbo ẹgbẹ awujọ. Lonii, iyẹn ti yipada lọna lilekenka, ti isin sì nko apa ti ó kere tabi ki ó má tilẹ sí rara ninu igbesi-aye ọgọrọọrun lọna araadọta-ọkẹ awọn eniyan. Bi iwọ ba nlọ si ṣọọṣi, ó ṣeeṣe ki ó jẹ pe ẹgbẹ tirẹ ni o kere julọ ni adugbo rẹ.
Ki ni ó fa iyipada naa? Fun ohun kan, Karl Marx mu imọ-ọran aṣodi si isin kan jade ti ó di eyi ti ó lagbara idari gan-an. Lọna ti ó han gbangba ni Marx ka isin sí ohun idena kan sí itẹsiwaju eniyan. Oun sọ pe awọn aini araye ni a lè kúnjú wọn lọna ti ó dara julọ nipa ifẹ ọrọ̀ alumọni, imọ-ọran kan ti kò fi aye eyikeyii silẹ fun Ọlọrun tabi fun isin atọwọdọwọ. Eyi mu ki ó ṣalaye pe: “Ohun akọkọ ti ó pọndandan fun ayọ awọn eniyan ni imukuro isin.”
Imọ-ọran Marx nipa ifẹ ọrọ̀ alumọni ni ara Germany onigbagbọ ninu ijọba afẹnifẹre naa Friedrich Engels ati aṣiwaju Kọmunist ara Russia naa Vladimir Lenin tubọ mu dagba. A wá mọ ọn gẹgẹ bi ẹkọ Marx-oun-Lenin. Titi di ẹnu aipẹ yii, eyi ti ó ju idamẹta araye gbé labẹ awọn akoso oṣelu ti wọn tẹle imọ-ọran alaigbọlọrun gbọ yii de iwọn pupọ tabi diẹ. Ọpọ ọkunrin ati obinrin ṣì nṣe bẹẹ sibẹsibẹ.
Idagbasoke Ìdágunlá Si Isin
Ṣugbọn itankalẹ imọ-ọran akoso Kọmunisti kii ṣe kiki ohun ti ó din agbara idari isin lori araye kù. Idagbasoke ninu pápá imọ ijinlẹ pẹlu kó apakan. Fun apẹẹrẹ, ìmúgbayì àbá ero-ori ẹfoluṣọn mu ki ọpọlọpọ gbé ibeere dide sí wíwà Ẹlẹdaa kan. Awọn koko miiran sì tun wà.
Iwe Encyclopædia Britannica mẹnukan “iṣawari awọn àlàyé onimọ ijinlẹ fun awọn ohun àrà ti a ti sọtẹlẹ pe okunfa wọn rekọja agbara ẹ̀dá” ati “imukuro agbara idari awọn isin afidimulẹ kuro ni ayika igbokegbodo iru bii imọ ijinlẹ egboogi, imọ nipa ọna ikọnilẹkọọ ati pápá ẹkọ ihumọ.” Awọn idagbasoke bi iwọnyi ti jalẹ si idagbasoke idagunla si isin. Ki ni idagunla si isin? A tumọ rẹ bi “oju iwoye nipa igbesi-aye . . . ti a gbekari ironu naa pe isin ati awọn igbeyẹwo lori isin ni a nilati gbojufoda tabi ki a mọọmọ mu un kuro.” Idagunla si isin ní agbara idari ni awọn ilẹ Kọmunist ati awọn ti kii ṣe ti Kọmunist.
Ṣugbọn idagunla si isin ati ẹkọ Marx-oun-Lenin kò wà ní awọn nikan ninu didin agbara idari isin kù. Awọn ṣọọṣi Kristẹndọmu nilati ṣajọpin ẹ̀bi naa. Eeṣe? Nitori pe fun ọpọ ọrundun wọn ti ṣi aṣẹ wọn lò. Wọn sì ti kọni ni awọn ẹkọ ti a gbekari aṣa atọwọdọwọ ati imọ-ọran eniyan ti kò ba iwe mimọ mu kaka ti iba fi jẹ́ lori Bibeli. Nipa bayii, ọpọ ninu agbo wọn ti tubọ di alailagbara nipa tẹmi lati koju ikọlu idagunla si isin.
Siwaju sii, awọn ṣọọṣi funraawọn fun apa ti ó pọ̀ julọ juwọsilẹ fun idagunla si isin nigbẹhingbẹhin. Ni ọrundun kọkandinlogun, awọn ọmọwe onisin ninu Kristẹndọmu wá pẹlu iru ariwisi gigaju kan, ti o pa ijotiitọ Bibeli run gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti a mísí fun ọpọlọpọ. Awọn ṣọọṣi, ti o ni ninu Ṣọọṣi Roman Katoliki, tẹwọgba àbá ero-ori ẹfoluṣọn. Bẹẹni, sibẹsibẹ wọn sọ pe awọn gbagbọ ninu iṣẹda. Ṣugbọn wọn faye gba ṣiṣeeṣe naa pe ara eniyan jẹyọ jade, nigba ti o jẹ pe kiki ọkàn ni a dá lati ọwọ Ọlọrun. Laaarin awọn ọdun 1960, isin Protẹstanti mú ẹkọ isin kan jade ti ó polongo “iku Ọlọrun.” Ọpọ alufaa Protẹstanti tẹwọgba ọna igbesi-aye onifẹẹ ọrọ̀ alumọọni. Wọn fọwọsi ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo ati ibẹya kan naa lòpọ̀ paapaa. Diẹ lara awọn ẹlẹkọọ isin Katoliki mu ẹkọ isin isọnidominira dagba, ni dída ẹkọ isin Katoliki pọ pẹlu ẹkọ Marx oniyiipada àfọ̀tẹ̀ṣe.
Ilọsilẹ Idagunla Si Isin
Nipa bayii, idagunla si isin wá jẹgàba, paapaa julọ ni awọn ọdun 1960, ati titi di nǹkan bii aarin awọn ọdun 1970. Lẹhin naa awọn nǹkan bẹrẹ sii yipada lẹẹkansii. Isin, bi o tilẹ jẹ pe, fun apa ti ó pọ julọ, kii ṣe awọn ṣọọṣi jàǹkànjàǹkàn ti nbẹ loju ọpọn, dabi eyi ti npadasipo. Yika gbogbo aye, apa ipari awọn ọdun 1970 ati 1980 ṣẹlẹrii ilọsoke ninu iye awọn awujọ isin titun.
Ki ni ó fa imusọji isin lẹẹkansii? Onimọ ijinlẹ nipa ajọṣepọ ẹgbẹ-oun-ọgba ara France naa Gilles Kepel sọ pe “awọn ọmọ ṣọọṣi ti a dá ni ẹkọ alaijẹ mọ́ isin . . . dì í mu pe aṣa ti ko jẹ mọ isin ti ṣamọna wọn si ipo kan tí itẹsiwaju ko ti ṣeeṣe ati pe nipa fifi itẹnumọ polongo ominira wọn kuro lọdọ Ọlọrun, awọn eniyan nkarugbin ohun ti wọn ti funrugbin nipasẹ igberaga ati asan wọn, ti ó ni ninu, ìyapòkíì, ikọsilẹ, àrùn AIDS, ilokulo oogun, [ati] ifọwọ ara ẹni pa ara ẹni.”
Ilọsilẹ ninu idagunla si isin ti tubọ jere agbara titun sii lati igba iwolulẹ ẹkọ Marx-oun-Lenin ti ó han gbangba lẹnu aipẹ yii. Fun ọpọ eniyan imọ-ọran alaigbọlọrungbọ yii ti di isin gidi kan. Nigba naa, finu woye ṣìbáṣìbo awọn wọnni ti wọn ti fi igbẹkẹle wọn sinu rẹ! Irohin kan ti a fi ranṣẹ si Washington Post lati Moscow fa ọrọ oludari Ile-ẹkọ Giga Ẹgbẹ Oṣelu Kọmunisti tẹlẹri yọ ẹni ti o wi pe: “Orilẹ-ede kan gbarale kii ṣe iṣunna owo rẹ̀ ati awọn eto idasilẹ rẹ nikan, ṣugbọn pẹlu lori arosọ atọwọdọwọ ati awọn baba olupilẹ rẹ. Ó jẹ́ ohun ti nmuni banujẹ fun awujọ eyikeyii lati ṣe awari pe arosọ wọn titobi julọ ni a kò gbekari otitọ ṣugbọn lori igbekeeyide ati àlá asan. Ṣugbọn ohun ti a nniriiri rẹ̀ nisinsinyi niyẹn ninu ọran ti Lenin ati iyipada àfọ̀tẹ̀ṣe.”
Ni sisọrọ nipa ayé eleto Kọmunisti ati elétò iṣowo bombata, onimọ ẹkọ nipa ibaṣepọ ẹgbẹ-oun-ọgba ati ọmọran ara Faranse naa Edgar Morin gba pe: “Kii ṣe kiki pe a ti ri iwolulẹ ọjọ-ọla dídán yanranyanran ti awujọ ti ó dagunla si isin ti a nawọ rẹ̀ jade si ẹgbẹ oṣiṣẹ nikan ni ṣugbọn a tun ti ri iwolulẹ itẹsiwaju lọna ti ẹ̀dá ti ó sì daju hánún-hánún, ninu eyi ti a ti ro pe o yẹ ki imọ ijinlẹ, ironu, ati iṣakoso dẹmọ funraarẹ tẹsiwaju. . . . Itẹsiwaju eyikeyii ni a kò mu daniloju nisinsinyi. Ọjọ ọla ti a fojusọna fun ti wolulẹ.” Bayii ni imọlara asán ọpọlọpọ ti wọn fi igbagbọ wọn sinu awọn isapa eniyan lati da ayé ti ó sunwọn sii kan laisi Ọlọrun ti rí.
Ọkan-ifẹ Ti A Sọ Dọtun Ninu Isin
Imọlara ìjádìí ọgbọn itanjẹ yii yika ayé ti nmu ki ọpọlọpọ awọn eniyan olotiitọ ọkàn mọ aini naa fun iha tẹ̀mí ninu igbesi-aye wọn. Wọn rí aini naa fun isin. Ṣugbọn awọn ni awọn ṣọọṣi jàǹkànjàǹkàn kò tẹlọrun pẹlu, ti awọn kan sì ṣiyemeji sí awọn isin ti wọn ṣẹṣẹ jẹyọ—titikan awọn isin awo ti nṣiṣẹ iwosan, awọn awujọ mẹmiimẹmii, ẹgbẹ imulẹ, ati awọn awujọ olujọsin Satani paapaa. Awọn onigbonara ẹhanna isin tun nfarahan lẹẹkansii pẹlu. Bẹẹni, nitori naa, isin npadasipo dé aye kan. Ṣugbọn iru ipadasipo isin bẹẹ ha jẹ́ ohun daradara kan fun iran eniyan bi? Niti tootọ, njẹ isin eyikeyii niti gidi ha mu awọn aini tẹmi araye ṣẹ bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Isin jẹ́ ìmí-ẹ̀dùn ẹ̀dá ti a tẹ̀ loriba, imọlara aye alailaanu kan, ati apẹẹrẹ pipe ti ipo ti kò mú ọkàn yágágá. Ó jẹ́ oògùn apanilọ́bọlọ̀ fun awọn eniyan”
[Credit Line]
Fọto: New York Times, Berlin—33225115
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Vladimir Lenin (loke) ati Karl Marx ri isin gẹgẹ bi ohun idena kan si itẹsiwaju eniyan
[Credit Line]
Musée d’Histoire Contemperaine—BDIC (Universitiés de Paris)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ero ẹkọ Marx-oun-Lenin ti gbé ifojusọna giga dide ninu ọkan-aya araadọta-ọkẹ eniyan
[Credit Line]
Musée d’Histoire Contemperaine—BDIC (Universitiés de Paris)
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Fọto ẹhin iwe: Garo Nalbandian