Àǹfààní Wo Ni Ìsìn Ń Ṣeni?
“MO LÈ jẹ́ èèyàn dáadáa bí mi ò tiẹ̀ ṣẹ̀sìn kankan!” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nírú èrò yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, tí wọ́n lójú àánú, tí wọ́n sì ṣeé gbára lé ni kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù kò pọ̀ rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn níbẹ̀ sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́.a Àní nǹkan bí èèyàn kan péré nínú márùn-ún ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Látìn Amẹ́ríkà.
Bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn, ìwọ náà lè máa rò pé ẹ̀sìn ò fi bẹ́ẹ̀ ran èèyàn lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé rere. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìyẹn nígbà ayé àwọn òbí rẹ àgbà, àwọn èèyàn lẹ́mìí ìsìn ju ìgbà tiwa yìí lọ. Kí ló fà á táwọn èèyàn níbi gbogbo kò fi nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn mọ́? Ǹjẹ́ ìwà èèyàn lè dáa láìjẹ́ pé ò ń ṣẹ̀sìn kan? Ǹjẹ́ ẹ̀sìn kan tiẹ̀ wà tó lè ṣeni láǹfààní?
Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Pa Ẹ̀sìn Tì
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lèyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ fi gbà gbọ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Wọ́n máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láti rí ojú rere Ọlọ́run, yálà nípa ààtò ìsìn táwọn àlùfáà ń ṣe tàbí nípa ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn olórí ẹ̀sìn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ló mọ̀ pé ẹ̀tàn pọ̀ nínú ẹ̀sìn. Wọ́n mọ ipa tí ẹ̀sìn ti kó nínú ogun, wọ́n sì mọ ìwà pálapàla táwọn àlùfáà ń hù. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìsìn fúnra rẹ̀ kò burú. Ohun táwọn mìíràn nífẹ̀ẹ́ sí ni bí àwọn àlùfáà ṣe máa ń sọ̀rọ̀ bí ẹni mímọ́, ọ̀nà ìgbàjọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì, àtàwọn orin ṣọ́ọ̀ṣì. Kódà, àwọn kan gbà pé ó dára bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì dẹ́ru ba àwọn èèyàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ náà kò sí nínú Bíbélì. Àmọ́, nígbà tó yá, àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó wá yí ojú tọ́pọ̀ èèyàn fi ń wo ìsìn padà.
Ọ̀kan lára rẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́wọ́ gbà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Àwọn kan gbà pé ńṣe ni gbogbo nǹkan ṣàdédé wà, pé Ọlọ́run kọ́ ló dá wọn. Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ni kò lè mú un dáni lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìwàláàyè ti wá. (Sáàmù 36:9) Yàtọ̀ síyẹn, bí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti ń tẹ̀ síwájú, àwọn ohun kàǹkà-kàǹkà táwọn èèyàn gbé ṣe nínú ìmọ̀ ìṣègùn, ètò ìrìnnà àti ètò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ti mú káwọn èèyàn gbà pé kò sí ìṣòro èyíkéyìí tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè yanjú. Síwájú sí i, àwọn kan gbà pé àwọn onímọ̀ nípa àjọgbé ẹ̀dà àtàwọn afìṣemọ̀rònú ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó dára ju ti ìsìn lọ. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì pàápàá kò mú un dá àwọn èèyàn lójú pé títẹ̀lé òfin Ọlọ́run ni ọ̀nà tó dára jù lọ.—Jákọ́bù 1:25.
Ohun tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì wá ṣe ni pé wọ́n yí ìwàásù wọn padà. Àwọn àlùfáà àtàwọn oníwàásù kò kọ́ni mọ́ pé Ọlọ́run lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ọ̀pọ̀ wọn ń kọni ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa fúnra rẹ̀ pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Nítorí káwọn olórí ẹ̀sìn kan lè gbayì, wọ́n sọ pé Ọlọ́run á tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn èèyàn láìbìkítà nípa irú ìgbésí ayé tí wọ́n lè máa gbé. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí.”—2 Tímótì 4:3.
Dípò kí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ fa àwọn èèyàn mọ́ra, ńṣe ló ń lé wọn sá. Wọ́n ń rò ó lọ́kàn pé: ‘Bí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì kò bá fi hàn pé Ọlọ́run lágbára láti dá àwọn nǹkan kó sì tún fún wa lófin, kí ni mò ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fún? Kí nìdí tí màá fi máa da ara mi láàmú láti máa fi ẹ̀sìn kọ́ àwọn ọmọ mi?’ Àwọn èèyàn tí wọ́n ń sapá láti máa gbé ìgbé ayé tó dára ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ìsìn bí ohun tí kò wúlò. Wọn ò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, ìsìn kò sì jẹ́ nǹkan kan lójú wọn mọ́. Kí ló ṣẹlẹ̀, tí ohun tó yẹ kó ṣeni láǹfààní fi wá di ohun tí kò wúlò mọ́? Bíbélì sọ ohun tó fà á gan-an.
Wọ́n Fi Ẹ̀sìn Ṣe Iṣẹ́ Ibi
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ìjímìjí pé àwọn kan yóò fi ẹ̀sìn ṣe iṣẹ́ ibi. Ó sọ pé: “Àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Ọ̀kan lára àwọn tó sọ “ohun àyídáyidà” ni ọ̀gbẹ́ni Augustine tó jẹ́ ògbógi nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà nípa ṣíṣàlàyé fún wọn látinú Ìwé Mímọ́. Àmọ́, Augustine ṣe àyídáyidà ohun tí Jésù sọ ní Lúùkù 14:23 pé: “Ṣe é ní ọ̀ranyàn fún wọn láti wọlé wá.” Augustine ní ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ni pé kò sóhun tó burú nínú ká máa fipá yí àwọ̀n èèyàn lọ́kàn padà. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 28:23, 24) Ọ̀gbẹ́ni Augustine lo ìsìn láti darí àwọn èèyàn síbi tó wù ú.
Sátánì tó jẹ́ áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ ló ń mú káwọn èèyàn ṣi ìsìn lò tó sì ń sọ ọ́ dìdàkudà. Òun ló mú kí àwọn onísìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbìyànjú láti sọ ìjọ Kristẹni dìdàkudà. Bíbélì sọ nípa àwọn onísìn náà pé: “Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa ara wọn dà di àpọ́sítélì Kristi. Kò sì ṣeni ní kàyéfì, nítorí Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo.”—2 Kọ́ríńtì 11:13-15.
Sátánì ṣì ń lo àwọn ìsìn tí wọ́n ń ṣe bíi pé ìsìn Kristẹni tòótọ́ làwọn, pé ìwà àwọn dára àti pé àwọn ń lani lóye. Ìdí tí Sátánì sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni láti mú káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ dípò ohun tí Ọlọ́run sọ. (Lúùkù 4:5-7) Bóyá o ti kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ àlùfáà lónìí ló ń lo ìsìn láti fi gbé ara wọn ga nípa fífún ara wọn ní oyè kàǹkà-kàǹkà, wọ́n sì tún ń lò ó láti fi gba owó lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn. Àwọn ìjọba pẹ̀lú ti lo ìsìn láti yí àwọn ará ìlú lérò padà, èyí tó mú káwọn ará ìlú máa fi ara wọn rúbọ nínú ogun.
Èṣù ń lo ìsìn gan-an ju bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rò lọ. O lè máa rò pé àwọn agbawèrèmẹ́sìn bíi mélòó kan ni Sátánì ń lò. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, . . . ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Bíbélì tún sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Ìṣípayá 12:9; 1 Jòhánù 5:19) Ṣé inú Ọlọ́run á dùn sí ìsìn táwọn olórí ìsìn àtàwọn olórí ìṣèlú fi ń kó àwọn èèyàn sẹ́yìn ara wọn?
“Kí ni Èyí Jámọ́ fún Mi?”
Bí inú rẹ kò bá dùn sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, mọ̀ dájú pé inú Ọlọ́run Olódùmarè pàápàá kò dùn sí i rárá. Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ sọ pé àwọn bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú, ohun kan náà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ nìyẹn. Àmọ́ àwọn àwùjọ méjèèjì ló jẹ́ aláìṣòótọ́. Ìbáwí mímúná tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló máa fún àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ nígbà tiwa yìí. Jèhófà sọ pé: “Wọn kò fiyè sí ọ̀rọ̀ tèmi gan-an; àti òfin mi wọ́n ń kọ̀ ọ́ ṣáá pẹ̀lú. Kí ni èyí jámọ́ fún mi pé ẹ ń mú oje igi tùràrí pàápàá láti Ṣébà? . . . Àwọn ẹbọ yín gan-an kò sì mú inú mi dùn.” (Jeremáyà 6:19, 20) Ọlọ́run kì í tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn alágàbàgebè. Ọlọ́run kò ní inú dídùn sí ààtò ìsìn wọn àti àdúrà wọn. Ó sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ọkàn mi kórìíra . . . àwọn àkókò àjọyọ̀ yín. Wọ́n ti di ẹrù ìnira fún mi; rírù wọ́n ti sú mi. Nígbà tí ẹ bá sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ yín, èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín. Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀.”—Aísáyà 1:14, 15.
Ǹjẹ́ àwọn àjọ̀dún táwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe dùn mọ́ Jèhófà nínú, èyí tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe fún Kristi, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé àwọn ọlọ́run èké ló wà fún? Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn àlùfáà tí wọ́n sọ àwọn ẹ̀kọ́ Kristi dìdàkudà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn èyíkéyìí tí kò tẹ̀ lé òfin rẹ̀? Mọ̀ dájú pé inú Ọlọ́run kò dùn sáwọn ààtò tí wọ́n ń ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì lónìí bí inú rẹ̀ kò ṣe dùn sáwọn ẹbọ tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń rú láyé ọjọ́un. Ó sọ nípa àwọn ẹbọ náà pé: “Kí ni èyí jámọ́ fún mi?”
Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ṣì ń fojú tó dá gan-an wo ìjọsìn tòótọ́ táwọn olóòótọ́ ọkàn ń ṣe. Inú Ọlọ́run máa ń dùn nígbà tí ẹnì kan bá dúpẹ́ fún gbogbo ohun tó ń rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Málákì 3:16, 17) Nítorí náà, ǹjẹ́ o rò pé o lè jẹ́ èèyàn tó dáa láìjọ́sìn Ọlọ́run? Ṣé ẹni tí kò ṣe nǹkan kan fáwọn òbí rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lè pe ara rẹ̀ léèyàn rere? Ǹjẹ́ ẹni tí kò jọ́sìn Ọlọ́run lè jẹ́ èèyàn rere? Ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tí ìwàláàyè ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a óò rí i bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń bọlá fún Ọlọ́run tó sì tún ń ṣe àwa èèyàn láǹfààní.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Àwọn ọdún 1960 . . . làwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ sí í di ẹni tí kò lẹ́mìí ìsìn mọ́.”—Ìwé The Decline of Christendom in Western Europe, 1750-2000.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ǹjẹ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ǹjẹ́ ó yẹ ká bá ẹni tó sọ pé òun ń ṣojú fún Ọlọ́run nídìí irú nǹkan bí èyí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo irú àjọ̀dún yìí?
[Credit Line]
AP Photo/Georgy Abdaladze