ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/1 ojú ìwé 8-12
  • Ipò Pàtàkì Tí Ó Yẹ Ìjọsìn Jehofa Nínú Ìgbésí-Ayé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipò Pàtàkì Tí Ó Yẹ Ìjọsìn Jehofa Nínú Ìgbésí-Ayé Wa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Orílẹ̀-Èdè Israeli Ṣe Jọ́sìn Jehofa
  • Ìtara fún Ìjọsìn Tòótọ́ ní Ọ̀rúndún Kìn-⁠ín-ní
  • A Gbé Ìjọsìn Jehofa Ga Lónìí
  • Ìjọsìn Tòótọ́ Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Jọ́sìn Jèhófà Nínú Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/1 ojú ìwé 8-12

Ipò Pàtàkì Tí Ó Yẹ Ìjọsìn Jehofa Nínú Ìgbésí-Ayé Wa

“Ní ojoojúmọ́ ni èmi ó máa fi ìbùkún fún ọ; èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ láé àti láéláé.”​—⁠ORIN DAFIDI 145:⁠2.

1. Níti ìjọsìn, kí ni Jehofa ń béèrè pé kí a ṣe?

“ÈMI Jehofa Ọlọrun rẹ jẹ́ Ọlọrun tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Eksodu 20:5, NW) Mose gbọ́ ìpolongo yẹn láti ẹnu Jehofa, òun sì tún un sọ lẹ́yìn náà nígbà tí ó ń bá orílẹ̀-èdè Israeli sọ̀rọ̀. (Deuteronomi 5:9) Kò sí iyèméjì nínú ọkàn Mose pé Jehofa Ọlọrun retí pé kí àwọn ìránṣẹ́ Òun jọ́sìn Òun lọ́nà tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.

2, 3. (a) Kí ni ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọ Israeli lọ́kàn pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́bàá Òkè Sinai jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a óò gbéyẹ̀wò nípa ìjọsìn àwọn ọmọ Israeli àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lónìí?

2 Níbi tí wọ́n dó sí lẹ́bàá Òkè Sinai, àwọn ọmọ Israeli àti “ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó dàpọ̀ mọ́ wọn” tí wọ́n tẹ̀lé wọn kúrò ní Egipti ṣe ẹlẹ́rìí ohun àrà-ọ̀tọ̀ kan. (Eksodu 12:38) Kò jọra rárá pẹ̀lú ìjọsìn àwọn ọlọrun Egipti, tí a ti fi àwọn àgbálù, tàbí ìyọnu mẹ́wàá tẹ́lógo nísinsìnyí. Bí Jehofa ti fi wíwà rẹ̀ níbẹ̀ hàn fún Mose, àwọn ohun mérìíyìírí tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ṣẹlẹ̀: ààrá, mànàmáná, àti ohùn ipè tí ó rinlẹ̀ dòdò tí ó mú kí gbogbo ibùdó náà mìtìtì. Iná àti èéfín tẹ̀lé e bí gbogbo òkè-ńlá náà ti ń mì tìtì. (Eksodu 19:​6-⁠20; Heberu 12:​18-⁠21) Bí ọmọ Israeli èyíkéyìí bá nílò ẹ̀rí síwájú sí i láti gbà pé ohun tí ń ṣẹlẹ̀ jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀, ìyẹn máa tó wáyé. Kò pẹ́ kò jìnnà, Mose sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè-ńlá náà lẹ́yìn tí ó ti gba ẹ̀dà kejì àwọn òfin Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tí a mísí náà ti sọ, “awọ ojú [Mose] ń dán; [àwọn ènìyàn náà] sì bẹ̀rù láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Ìrírí mánigbàgbé kan, tí ó kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn ni èyí jẹ́ nítòótọ́!​—⁠Eksodu 34:⁠30.

3 Fún irú orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ ti Ọlọrun, kò sí iyèméjì kankan nípa ipò tí ìjọsìn Jehofa gbà. Òun ni Olùdáǹdè wọn. Ọwọ́ rẹ̀ ni ìwàláàyè wọn sinmi lé. Òun tún ni Olùfúnni-ní-Òfin wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ha fi ìjọsìn Jehofa sí ipò kìn-⁠ín-ní bí? Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun lóde-òní sì tún ń kọ́? Ipò wo ni ìjọsìn Jehofa dìmú nínú ìgbésí-ayé wọn?​—⁠Romu 15:⁠4.

Bí Orílẹ̀-Èdè Israeli Ṣe Jọ́sìn Jehofa

4. Báwo ni ìṣètò àgọ́ àwọn ọmọ Israeli ṣe rí nígbà tí wọ́n fi gbé nínú aginjù, kí sì ni ó wà ní àárín àgọ́ náà?

4 Kí á sọ pé o wo àwọn ọmọ Israeli látòkèèrè níbi tí wọ́n dó sí nínú aginjù, kí ni ìwọ ìbá rí? Ọ̀pọ̀ àwọn àgọ́, tí a pa lọ́nà gígúnrégé nínú èyí tí ó ṣeéṣe kí àádọ́jọ ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ máa gbé, tí a sì pín sí ọ̀wọ́-ọ̀wọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àgbájọ ẹ̀yà mẹ́ta sí ìhà àríwá, gúúsù, ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀ oòrùn. Bí o bá túbọ̀ wò ó fínnífínní, ìwọ yóò tún ti kíyèsí àgbájọ mìíràn tí ó túbọ̀ súnmọ́ àárín ibùdó náà. Àwọn àpapọ̀ àgbájọ àgọ́ mẹ́rin tí wọ́n túbọ̀ kéré yìí ni ibi tí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi ń gbé. Ní àárín gbùngbùn àgọ́ náà gan an, ní agbègbè kan tí a fi ògiri aláṣọ gé mọ́ apá ọ̀hún, ni ohun ìgbékalẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ kan wà. Èyí ni “àgọ́ àjọ,” tàbí àgọ́-ìsìn, tí àwọn ọmọ Israeli “ọlọ́gbọ́n-inú” ti níláti kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ìkọ́lé Jehofa.​—⁠Numeri 1:52, 53; 2:3, 10, 17, 18, 25; Eksodu 35:⁠10.

5. Ète wo ni àgọ́-ìsìn ṣiṣẹ́ fún ní Israeli?

5 Ní gbogbo nǹkan bí 40 ibi tí wọ́n pàgọ́ sí nígbà ìrìn-àjò wọn ní aginjù, ni àwọn ọmọ Israeli ti ń pa àgọ́-ìsìn náà, ó sì di ọ̀gangan ibi tí wọ́n darí àfiyèsí sí nígbà ibùdó wọn. (Numeri, orí 33) Ó bá a mu gẹ́ẹ́ nígbà náà pé Bibeli ṣàpèjúwe Jehofa gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń gbé láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àárín gbùngbùn àgọ́ wọn. Ògo rẹ̀ kún inú àgọ́-ìsìn náà. (Eksodu 29:43-⁠46; 40:34; Numeri 5:⁠3; 11:20; 16:3) Ìwé náà Our Living Bible ṣàlàyé pé: “Ibi ìjọsìn tí ó ṣeé gbé rìn yìí ní ìjẹ́pàtàkì tí ó ga jùlọ, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ibùdó ìpéjọpọ̀ níti ìsìn fún àwọn ẹ̀yà náà. Ó tipa báyìí mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan ní àwọn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi rìn gbéregbère káàkiri nínú aginjù tí ó sì mú kí ìgbésẹ̀ àjùmọ̀gbé ṣeéṣe.” Ju ìyẹn lọ, àgọ́ìsìn náà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí lemọ́lemọ́ pé ìjọsìn tí àwọn ọmọ Israeli ń ṣe fún Ẹlẹ́dàá wọn jẹ́ ohun pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé wọn.

6, 7. Ohun ìgbékalẹ̀ wo fún ìjọsìn ni ó rọ́pò àgọ́-ìsìn, ọ̀nà wo ni ó sì gbà ṣiṣẹ́ fún àwọn ọmọ Israeli?

6 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israeli ti dé Ilẹ̀ Ìlérí, àgọ́-ìsìn náà ń bá a lọ láti jẹ́ ọ̀gangan ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn àwọn ọmọ Israeli. (Joṣua 18:⁠1; 1 Samueli 1:3) Nígbà tí ó ṣe, Ọba Dafidi gbèrò láti kọ́ ohun ìgbékalẹ̀ wíwà títílọ kan. Èyí ni a mọ̀ sí tẹ́ḿpìlì náà, tí Solomoni ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ lẹ́yìn náà. (2 Samueli 7:​1-⁠10) Nígbà ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ àwọsánmà ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti fihàn pé Jehofa fọwọ́sí ilé náà. Solomoni gbàdúrà pé, “Nítòótọ́ èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ láti máa gbé inú rẹ̀, ibùjókòó kan fún ọ láti máa gbé inú rẹ̀ títíláé.” (1 Ọba 8:12, 13; 2 Kronika 6:2) Tẹ́ḿpìlì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ náà ni ó wá di ọ̀gangan ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn orílẹ̀-èdè náà nísinsìnyí.

7 Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún, àwọn ọmọkùnrin Israeli a máa lọ sí Jerusalemu láti pésẹ̀ síbi àwọn ayẹyẹ onídùnnú ní tẹ́ḿpìlì gẹ́gẹ́ bí ìmọrírì wọn fún ìbùkún Ọlọrun. Lọ́nà yíyẹ, àwọn ìtúnpàdépọ̀ wọ̀nyí ni a ń pè ní “àjọ OLUWA,” èyí tí ń pe àfiyèsí sí ìjọsìn Ọlọrun. (Lefitiku 23:​2, 4) Àwọn obìnrin olùfọkànsìn máa ń lọ pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà mìíràn nínú ìdílé.​—⁠1 Samueli 1:​3-⁠7; Luku 2:​41-⁠44.

8. Báwo ni Orin Dafidi 84:​1-⁠12 ṣe jẹ́rìí sí ìjẹ́pàtàkì ìjọsìn Jehofa?

8 Lọ́nà jíjágeere ni onipsalmu tí a mísí náà gbà jẹ́wọ́ bí wọ́n ti ka ìjọsìn sí ohun tí ó ṣe pàtàkì tó nínú ìgbésí-ayé wọn. Àwọn ọmọkùnrin Kora kọrin pé: “Àgọ́ rẹ wọnnì ti ní ẹwà tó, Oluwa àwọn ọmọ-ogun!” Ó dájú pé kì í ṣe ilé ńlá kan lásán ni wọ́n ń kókìkíyìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin Jehofa Ọlọrun, ní pípolongo pé: “Àyà mi àti ara mi ń kígbe sí Ọlọrun alààyè.” Iṣẹ́-ìsìn àwọn ọmọ Lefi mú ayọ̀ ńlá wá fún wọn. Wọ́n polongo pé: “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ: wọn ó máa yìn ọ́ síbẹ̀.” Ní tòótọ́, gbogbo Israeli lè kọrin pé: “Ìbùkún ni fún ènìyàn náà, ipá ẹni tí ó wà nínú rẹ: ní ọkàn ẹni tí ọ̀nà rẹ wà. . . . Wọ́n ń lọ láti ipá dé ipá, ní Sioni ni àwọn yọ níwájú Ọlọrun.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìn-àjò ọmọ Israeli kan lọ sí Jerusalemu lè jẹ́ èyí tí ó gùn tí ó sì ń múni káàárẹ̀, ipá rẹ̀ ní a ń sọ dọ̀tun bí ó bá ti ń dé inú olú-ìlú náà. Ọkàn-àyà rẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú bí ó ti ń kókìkí àǹfààní rẹ̀ láti jọ́sìn Jehofa: “Nítorí pé ọjọ́ kan nínú àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ. Mo fẹ́ kí ń kúkú máa ṣe adènà ní ilé Ọlọrun mi, jù láti máa gbé àgọ́ ìwà búburú. . . . Oluwa àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún olúwarẹ̀ náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.” Irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ fi ipò àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ Israeli fifún ìjọsìn Jehofa hàn.​—⁠Orin Dafidi 84:​1-⁠12.

9. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Israeli nígbà tí ó kùnà láti fi ìjọsìn Jehofa sí ipò tí ó ṣe pàtàkì?

9 Ó baninínújẹ́ pé, orílẹ̀-èdè Israeli kùnà láti fi ìjọsìn tòótọ́ sí ipò ṣíṣe pàtàkì. Wọ́n yọ̀ǹda kí ìfọkànsìn fún àwọn ọlọrun èké tẹ ìtara wọn fún Jehofa rì. Nítorí náà, Jehofa fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, ní yíyọ̀ǹda kí a kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni. Nígbà tí a dá wọn padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn lẹ́yìn 70 ọdún, Jehofa pèsè ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ń runisókè fún orílẹ̀-èdè Israeli láti ẹnu àwọn wòlíì olùṣòtítọ́ bíi Hagai, Sekariah, àti Malaki. Esra àlùfáà àti Gómìnà Nehemiah ru àwọn ènìyàn Ọlọrun sókè láti tún tẹ́ḿpìlì náà kọ́ kí wọ́n sì mú ìjọsìn tòótọ́ padàbọ̀sípò níbẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ti ń kọjá lọ, ìjọsìn tòótọ́ tún padà di ohun tí wọn kò fi ọwọ́ dan-⁠in-dan-⁠in mú mọ́ ní orílẹ̀-èdè náà.

Ìtara fún Ìjọsìn Tòótọ́ ní Ọ̀rúndún Kìn-⁠ín-ní

10, 11. Ipò wo ni àwọn olùṣòtítọ́ fi ìjọsìn Jehofa sí nínú ìgbésí-ayé wọn nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀-ayé?

10 Nígbà tí àkókò tí Jehofa ti yànkalẹ̀ pé, Messia farahàn. Àwọn olùṣòtítọ́ ènìyàn ń wo ojú Jehofa fún ìgbàlà. (Luku 2:25; 3:15) Ní kedere ni Ìhìnrere Luku ṣàpèjúwe Anna ẹni ọdún 84 tí ó jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí opó kan “a kì í fẹ́kù ní tẹmpili nígbà kankan, tí ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ lóru ati lọ́sàn-án pẹlu ààwẹ̀ ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.”​—⁠Luku 2:37, NW.

11 Jesu wí pé, “Oúnjẹ mi ni fún mi lati ṣe ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi ati lati parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Johannu 4:34, NW) Rántí bí Jesu ṣe hùwàpadà nígbà tí ó gbéjàko àwọn olùpààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpìlì. Ó sojú tábìlì wọn àti bẹ́ǹṣì awọn wọnnì tí ń ta àdàbà dé. Marku ròyìn pé: “[Jesu] kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé nǹkan-èlò la tẹmpili kọjá, ṣugbọn ó tẹramọ́ kíkọ́ni ati wíwí pé: ‘A kò ha kọ ọ́ pé, “Ilé àdúrà ni a óò máa pe ilé mi fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè”? Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di hòrò awọn ọlọ́ṣà.’” (Marku 11:​15-⁠17, NW) Bẹ́ẹ̀ni, Jesu kò tilẹ̀ yọ̀ǹda fún ẹnikẹ́ni láti gbẹ̀bùrú la àárín àgbàlá tẹ́ḿpìlì kọjá nígbà tí wọ́n bá ń gbé àwọn ohun èèlò kọjá lọ sí apá mìíràn nínú ìlú-ńlá náà. Ìgbésẹ̀ Jesu fi ìdí ìmọ̀ràn tí ó kọ́kọ́ fúnni múlẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa ati òdodo [Ọlọrun].” (Matteu 6:33, NW) Jesu fi àpẹẹrẹ àgbàyanu lélẹ̀ fún wa níti fífún Jehofa ní ìfọkànsìn rẹ̀ tí ó yà sọ́tọ̀ gedegbe. Ó fi ohun tí ó wàásù rẹ̀ sílò níti tòótọ́.​—⁠1 Peteru 2:⁠21.

12. Báwo ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ṣe fi ipò àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ìjọsìn Jehofa sí hàn?

12 Jesu tún fi àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti tẹ̀lé nípa ọ̀nà tí ó gbà mú iṣẹ́ tí a fi rán an ṣẹ láti tú àwọn tí a nilára sílẹ̀, àti láti gba àwọn Júù olùṣòtítọ́ kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn àṣà ìsìn èké. (Luku 4:18) Ní ìṣègbọràn sí àṣẹ Jesu láti sọni di ọmọ-ẹ̀yìn kí a sì batisí wọn, àwọn Kristian ìjímìjí fi àìṣojo polongo ìfẹ́-inú Jehofa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Oluwa wọn ti a jí dìde. Ipò àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ìjọsìn Rẹ̀ sí dùn mọ́ Jehofa nínú gidigidi. Nípa báyìí, lọ́nà ìyanu ni áńgẹ́lì Ọlọrun fúnraarẹ̀ dá aposteli Peteru àti Johannu sílẹ̀ kúrò nínú àhámọ́ tí ó sì fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n, ati pé, nígbà tí ẹ bá ti dúró ninu tẹmpili, ẹ máa bá a nìṣó ní sísọ gbogbo awọn àsọjáde nipa ìyè yii fún awọn ènìyàn.” Bí a ti sọ okun wọn dọ̀tun, wọ́n ṣègbọràn. Lójoojúmọ́, ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Jerusalemu àti láti ilé dé ilé “wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni ati pípolongo ìhìnrere nipa Kristi naa, Jesu.”​—⁠Iṣe 1:⁠8; 4:29, 30; 5:20, 42, NW; Matteu 28:​19, 20.

13, 14. (a) Láti ìgbà àwọn Kristian ìjímìjí, kí ni Satani ti gbìdánwò láti ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun? (b) Kí ni àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ti ń bá a nìṣó láti máa ṣe?

13 Bí àtakò sí ìwàásù wọn ti ń ga sí i, Ọlọrun darí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ láti kọ ìmọ̀ràn tí ó bọ́ sí àkókò. Kété lẹ́yìn 60 C.E. Peteru kọ̀wé pé: “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé [Jehofa], nitori ó ń bìkítà fún yín. Ẹ pa awọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyèsára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ. Ṣugbọn ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-⁠in ninu ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé awọn ohun kan naa ní ọ̀nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí ninu gbogbo ẹgbẹ́ awọn arákùnrin yín ninu ayé.” Kò sí iyèméjì pé àwọn Kristian ìjímìjí rí ìmúdánilójú lẹ́ẹ̀kan sí i nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Wọ́n mọ̀ pé lẹ́yìn tí àwọn bá ti jìyà fún àkókò díẹ̀, Ọlọrun yóò parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn. (1 Peteru 5:​7-⁠10, NW) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Júù wọ̀nyẹn, àwọn Kristian tòótọ́ ṣe ìgbéga ìjọsìn Jehofa tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí dé ìwọn àyè gíga.​—⁠Kolosse 1:⁠23.

14 Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti sọtẹ́lẹ̀, ìpẹ̀yìndà, kíkúrò nínú ìjọsìn tòótọ́, ṣẹlẹ̀. (Iṣe 20:29, 30; 2 Tessalonika 2:3) Àwọn ìjẹ́wọ́ ní gbangba láti àwọn ẹ̀wádún tí ó parí ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní ṣe ìkójọ pelemọ ẹ̀rí nípa èyí. (1 Johannu 2:​18, 19) Satani ṣàṣeyọrí ní fífúnrúgbìn àwọn Kristian aláfarawé sí àárín àwọn ojúlówó, ní mímú kí ó ṣòro láti fi ìyàtọ̀ sí àárín “awọn èpò” àti àwọn Kristian tí wọ́n dàbí àlìkámà. Bí ó tilẹ̀ ri bẹ́ẹ̀, láti àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá wá, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan díẹ̀ ń fi ìjọsìn Ọlọrun sí ipò àkọ́kọ́, àní ní fifi ẹ̀mí wọn wewu pàápàá. Ṣùgbọ́n Ọlọrun kò tún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kójọ láti gbé ìjọsìn tòótọ́ ga títí di àwọn ẹ̀wádún tí ó parí “awọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè.”​—⁠Matteu 13:​24-30, 36-⁠43, NW; Luku 21:24, NW.

A Gbé Ìjọsìn Jehofa Ga Lónìí

15. Láti ọdún 1919 wá, ìmúṣẹ wo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah 2:​2-⁠4 àti Mika 4:​1-⁠4 ti ní?

15 Ní ọdún 1919, Jehofa fi agbára fún àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró láti tẹ́wọ́gba iṣẹ́ aláìṣojo ti ìgbétásì ìjẹ́rìí kárí-ayé èyí tí ó ti gbé ìjọsìn Ọlọrun òtítọ́ ga. Pẹ̀lú ìrọ́wọlé “awọn àgùtàn mìíràn” ìṣàpẹẹrẹ láti ọdún 1935 wá, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń wọ́ tìrítìrí nípa tẹ̀mí kọjá lọ sí “òkè ilé Oluwa” ti ń ga síwájú àti síwájú sí i. Ní ọdún iṣẹ́-ìsìn 1993, 4,709,889 àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa fi ìyìn fún un nípa kíkésí àwọn ẹlòmíràn láti darapọ̀ nínú ìjọsìn rẹ̀ tí a gbéga. Ẹ sì wo bí ìyàtọ̀ tí èyí mú wá ṣe yàtọ̀ sí ipò ìrẹ̀sílẹ̀ nípa tẹ̀mí ti “àwọn òkè kéékèèké” ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé, pàápàá jùlọ ní Kristẹndọm!​—⁠Johannu 10:16, NW; Isaiah 2:​2-⁠4; Mika 4:​1-⁠4.

16. Kí ni ó yẹ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ṣe lójú ìwòye ohun tí a sọtẹ́lẹ̀ nínú Isaiah 2:​10-⁠22?

16 Àwọn tí ń ṣe ìjọsìn èké ń wo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti katidra wọn àti àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọn pàápàá gẹ́gẹ́ bí ‘ẹni gíga,’ ní pípè wọ́n ní àwọn orúkọ-oyè kàǹkà-kàǹkà àti fífi ọlá fún wọn. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí ohun tí Isaiah sọtẹ́lẹ̀: “A óò rẹ ìwo gíga ènìyàn sílẹ̀, a óò sì tẹ orí ìgbéraga ènìyàn ba, Oluwa nìkan ṣoṣo ni a óò gbé ga ní ọjọ́ náà.” Nígbà wo ní èyí yóò jẹ́? Lákòókò ìpọ́njú ńlá tí ń yára kánkán bọ̀ wá yìí ni, nígbà tí ‘àwọn òrìṣà yóò parun pátápátá.’ Ní ojú-ìwòye ìsúnmọ́lé àkókò tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ yẹn, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gbọ́dọ̀ fi ìrònú jinlẹ̀ ṣàyẹ̀wò ipò tí wọ́n fi ìjọsìn Jehofa sí nínú ìgbésí-ayé wọn.​—⁠Isaiah 2:​10-⁠22.

17. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lónìí ṣe ń fi ipò àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ìjọsìn Jehofa sí hàn?

17 Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí-ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a mọ̀ dáradára fún ìtara wọn nínú wíwàásù Ìjọba náà. Ìjọsìn wọn, kìí wulẹ̀ ṣe ìsìn gbà-má-pa-mí-jẹ tí ó wà fún kìkì nǹkan bíi wákàtí kan lọ́sẹ̀. Bẹ́ẹ̀kọ́, gbogbo apá ìgbésí-ayé wọn pátá ni ó rọ̀ mọ́ ọn. (Orin Dafidi 145:2) Níti tòótọ́, ní ọdún tí ó kọjá iye tí ó ju 620,000 àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò àwọn àlámọ̀rí wọn láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian fún àkókò kíkún. Ó sì dájú pé àwọn yòókù kò fi ojú tín-⁠ín-rín ìjọsìn Jehofa. Ó ń farahàn lọ́nà títayọ nínú àwọn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ojoojúmọ́ àti ìwàásù ìtagbangba wọn, àní bí àwọn ojúṣe wọn nínú ìdílé bá tilẹ̀ béèrè pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.

18, 19. Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ ìṣírí tí o ti lè rí gbà láti inú kíkà nípa ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí.

18 Ìtàn ìgbésí-ayé àwọn Ẹlẹ́rìí tí a ń tẹ̀ jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà pèsè ìjìnlẹ̀ òye nípa àwọn ọ̀nà tí onírúurú àwọn arákùnrin àti arábìnrin ti gbà láti fi ìjọsìn Jehofa sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé wọn. Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tí ó ya ìgbésí-ayé araarẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa ní ọmọ ọdún mẹ́fà gbé iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nnárì kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi góńgó rẹ̀. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ arákùnrin àti arábìnrin, góńgó wo ni ẹ lè yàn tí yóò ràn yín lọ́wọ́ láti fi ìjọsìn Jehofa sí ipò àkọ́kọ́ jùlọ nínú ìgbésí-ayé yín?​—⁠Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Lilepa Gongo Kan Tí Mo Ti Gbékalẹ̀ Ní Ọmọ Ọdun Mẹfa,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti March 1, 1992, ojú-ìwé 26 sí 30.

19 Arábìnrin àgbàlagbà kan tí ó jẹ́ opó pèsè àpẹẹrẹ àtàtà mìíràn níti fífi ìjọsìn Jehofa sí ipò pàtàkì tí ó yẹ fún un. Ó jèrè ìṣírí ńláǹlà láti lo ìfaradà láti ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí òun ti ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Wọ́n jẹ́ “ìdílé” rẹ̀. (Marku 3:​31-⁠35, NW) Bí o bá bá araàrẹ nínú irú ipò kan náà, ìwọ yóò ha tẹ́wọ́gba ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà nínú ìjọ bí? (Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí bí Arábìnrin Winifred Remmie ṣe sọ̀rọ̀ nípa araarẹ̀ nínú “Mo Dahunpada ni Akoko Ìkórè,” tí a tẹ̀jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti July 1, 1992, ojú-ìwé 21 sí 23.) Ẹ̀yin ìránṣẹ́ alákòókò kíkún, ẹ fihàn pé nítòótọ́ ni ìjọsìn Jehofa wà ní ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé yín nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣiṣẹ́sìn níbi tí a bá yàn yín sí, ní fífi pẹ̀lú ìmúratán juwọ́sílẹ̀ fún àwọn ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso Ọlọrun. (Jọ̀wọ́ kíyèsí àpẹẹrẹ Arákùnrin Roy Ryan, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ọ́ nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Rírọ̀ Timọtimọ Mọ́ Eto-Ajọ Ọlọrun,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti December 1, 1991, ojú-ìwé 24 sí 27.) Ẹ rántí pé nígbà tí a bá fi ìjọsìn Jehofa sí ipò àkọ́kọ́, àwa yóò ní ìdánilójú náà pé òun yóò bójútó wa. Kò yẹ kí a máa ṣàníyàn nípa ibi tí àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé yóò gbà wá. Ìrírí Arábìnrin Olive àti Sonia Springate ṣàpèjúwe èyí.​—⁠Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “A Ti Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti February 1, 1994, ojú-ìwé 20 sí 25.

20. Àwọn ìbéèrè ṣíṣekókó wo ni a níláti bí araawa nísinsìnyí?

20 Nítorí náà, lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, kò ha yẹ kí a béèrè àwọn ìbéèrè díẹ̀ tí ń múni fi òye ronú lọ́wọ́ araawa? Ipò wo ni ìjọsìn Jehofa dìmú nínú ìgbésí-ayé mi? Mo ha ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ mi láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun dé ibi tí agbára mi gbé e dé bí? Ní àwọn agbègbè wo nínú ìgbésí-ayé ni mo ti lè ṣe ìmúsunwọ̀n sí i? Fífi ìrònújinlẹ̀ gbé ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yẹ̀wò yóò nawọ́ àǹfààní náà sí wa láti ronú lórí bí a ṣe ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wa ní ìbámu pẹ̀lú yíyàn tí a fi sí ipò kìn-⁠ín-ní nínú ìgbésí-ayé wa​—⁠ìjọsìn Jehofa Oluwa Ọba-Aláṣẹ, Bàbá wa onífẹ̀ẹ́.​—⁠Oniwasu 12:13; 2 Korinti 13:⁠5.

Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò

◻ Níti ìjọsìn, kí ni Jehofa ń béèrè pé kí a ṣe?

◻ Kí ni àgọ́-ìsìn náà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí fún?

◻ Ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní C.E., àwọn wo ni wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ àrà-ọ̀tọ̀ ti ìtara fún ìjọsìn tòótọ́, báwo sì ni wọ́n ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

◻ Láti ọdún 1919 wá, ní ọ̀nà wo ni a ti gbà gbé ìjọsìn Jehofa ga?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́