Ohun Ìṣúra Tí Kò Ṣeé Díyelé Tí A Níláti Ṣàjọpín
GẸ́GẸ́ BÍ GLORIA MALASPINA ṢE SỌ Ọ́
Nígbà tí èbúté òkun Sicily ń parẹ́ mọ́ wa lójú, èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí pa àfiyèsí wa pọ̀ sórí ibi tí a ń rè, erékùṣù Mediterranean ti Melita. Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà arùmọ̀lára sókè tí ó jẹ́! Bí ọkọ̀-òkun náà tí ń la òkun kọjá, a ronú nípa ìrírí aposteli Paulu ní Melita ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní.—IṢE 28:1-10.
ỌDÚN 1953 ni, Melita kò sì tíì fọwọ́sí ìgbòkègbodò ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lábẹ́ òfin nígbà yẹn. Ní ọdún tí ó ṣáájú, a ti kẹ́kọ̀ọ́yege ní Watchtower Bible School of Gilead a sì ti yàn wá sí Itali. Lẹ́yìn àkókò kúkúrú ti kíkẹ́kọ̀ọ́ èdè Italian, a ń háragàgà láti rí ohun tí ó ń dúró dè wá ní Melita.
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti mọ bí èmi, tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe di míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ àjèjì bí? Jẹ́ kí n ṣàlàyé.
Àpẹẹrẹ Arunisókè Tí Màmá Fi Lélẹ̀
Ní 1926, nígbà tí ìdílé wa ń gbé ní Fort Frances, Ontario, Canada, màmá mi gba ìwé-pẹlẹbẹ náà Millions Now Living Will Never Die lọ́wọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan (bí a ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì nígbà yẹn). Ó kà á pẹ̀lú ọkàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀, ó darapọ̀ pẹ̀lú àwọn àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ọ̀sẹ̀ yẹn gan-an, níbi tí a ti lo ìwé-ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà. Màmá jẹ́ olùfi ìtara ka Bibeli, ó sì tẹ́wọ́gba ìhìn-iṣẹ́ nípa Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣúra náà tí ó ti ń wá. (Matteu 6:33; 13:44) Láìka àtakò rírorò láti ọ̀dọ̀ Bàbá sí, àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn ọmọdébìnrin wẹẹrẹ mẹ́ta láti bójútó, ó mú ìdúró rẹ̀ fún ohun tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.
Ìgbàgbọ́ tí kì-í-yẹ̀ tí Màmá ní láàárín 20 ọdún tí ó tẹ̀lé e mú kí èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjèèjì, Thelma àti Viola, wà lójúfò sí ìrètí àgbàyanu ti ìyè ayérayé nínú ayé titun ti òdodo. (2 Peteru 3:13) Ó dojúkọ ọ̀pọ̀ àdánwò lílekoko, ṣùgbọ́n a kò fi ìgbà kan rí ṣiyèméjì nípa bí ipa-ọ̀nà tí ó yàn ṣe tọ̀nà tó.
Ní 1931, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá péré, a ṣí lọ sí oko kan ní ìhà-àríwá Minnesota, U.S.A. Níbẹ̀ ni a ti pàdánù àǹfààní ìkẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣùgbọ́n a kò pàdánù gbígba ìtọ́ni Bibeli láti ọ̀dọ̀ Màmá. Iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ tí ó farajìn fún gẹ́gẹ́ bí olùpín-ìwé-ìsìn-kiri, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ru mí sókè láti fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ ọn nínú iṣẹ́ yẹn. Ní 1938 èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjèèjì fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wa hàn fún Jehofa nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní àpéjọ kan ní Duluth, Minnesota.
Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́yege ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní 1938, Màmá fún mi ní ìṣírí láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa òye-iṣẹ́ ọ́fíìsì kí n baà lè ṣètìlẹ́yìn fún araàmi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà kan (orúkọ titun náà fún àwọn olùpín-ìwé-ìsìn-kiri). Èyí jásí ìmọ̀ràn rere, ní pàtàkì níwọ̀n bí Bàbá ti pinnu láti bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ tí ó sì fi wá sílẹ̀ láti máa bójútó araawa.
Ṣíṣàjọpín Ohun Ìṣúra Wa Ní Àkókò Kíkún
Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín mo ṣí lọ sí California, àti ní 1947, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní San Francisco. Nígbà tí mo ń kópa nínú iṣẹ́ àṣeṣaájú àpéjọpọ̀ fún Àpéjọ “Ìmúgbòòrò Gbogbo Orílẹ̀-Èdè” ní Los Angeles, mo bá Francis Malaspina pàdé. Góńgó tí tọ̀tún-tòsì wa ní fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì yọrí sí ìbẹ̀rẹ̀ ipò-ìbátan onífẹ̀ẹ́ kan. A ṣe ìgbéyàwó ni 1949.
Ní September 1951, a pe èmi àti Francis sí kíláàsì kejìdínlógún ti Gilead. Ní ọjọ ìkẹ́kọ̀ọ́yege, February 10, 1952, lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ jíjinlẹ̀ fún oṣù márùn-ún, ààrẹ ilé-ẹ̀kọ́ náà, Nathan H. Knorr pe àwọn orílẹ̀-èdè tí a óò rán wa lọ ní ìtòtẹ̀léra lọ́nà a b d. Nígbà tí ó wí pé, “Itali, Arákùnrin àti Arábìnrin Malaspina,” a tilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí rin ìrìn-àjò náà nínú ọkàn wa!
Ní ọ̀sẹ̀ mélòókan lẹ́yìn náà, a wọ ọkọ̀-òkun ní New York láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ mẹ́wàá ní orí omi lọ sí Genoa, Itali. Giovanni DeCecca àti Max Larson, tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ ti Brooklyn, wà níbẹ̀ ní èbútékọ̀ láti kí wa pé ó dìgbà kan ná. Ní Genoa àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n ti mọ̀ nípa àwọn ìṣòro wíwọlé sí orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n wá pàdé wa.
Bí gbogbo ohun tí ó yí wa ká ti ń mú kí ìmọ̀lára wa ru sókè, a wọ ọkọ̀ ojú-irin lọ sí Bologna. Ohun tí a rò pé àwa yóò rí nígbà tí a bá débẹ̀ ni ìlú-ńlá kan ti àwọn bọ́m̀bù tí a jù nígbà Ogun Àgbáyé II ṣì bàjẹ́ síbẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ohun mìíràn tí ó fanimọ́ra tún wà níbẹ̀, irú bí òórùn kọfí yíyan tí ń dáni lọ́rùn tí ń gba inú atẹ́gùn òwúrọ̀ kan àti òórùn ọbẹ̀ àjẹpọ́nnulá títasánsán tí a ti sè sílẹ̀ fún àìmọye oríṣiríṣi oúnjẹ.
Lílé Góńgó kan Bá
A bẹ̀rẹ̀ sí jáde fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ pẹ̀lú ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ tí a ti há sórí, a sì ń sọ ọ́ léraléra títí tí wọ́n a fi gba ìhìn-iṣẹ́ náà tàbí tí wọ́n a fi pa ìlẹ̀kùn dé. Ìfẹ́-ọkàn náà láti sọ ti ẹnu wa sún wa láti kọ́ èdè náà taápọn-taápọn. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, a yàn wá sí ibùgbé titun fún àwọn míṣọ́nnárì ní Naples.
Ìlú-ńlá tí ó tóbi yìí ni a mọ̀ fún ìrísí àwòyanu rẹ̀. A gbádùn iṣẹ́-ìsìn wa níbẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn oṣù mẹ́rin mìíràn, a yan ọkọ mi sẹ́nu iṣẹ́ àyíká, tàbí arìnrìn-àjò, láti máa ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ìjọ láti Romu dé Sicily. Nígbà tí ó ṣe, a ṣe ìbẹ̀wò sí Melita àti Libia ní Àríwá Africa pẹ̀lú.
Ìrìn-àjò ọkọ̀ ojú-irin láti Naples dé Sicily ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn jẹ́ ìdánwò ìfaradà níti ara-ìyára. Fún wákàtí mẹ́fà sí mẹ́jọ nígbà mìíràn, a óò wọ ọkọ̀ ojú-irin tí ó kún fọ́fọ́ a óò sì dúró sí àárín àwọn ìjókòó ti ó kún fún èrò. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fún wa ní àǹfààní dídára láti mọ àwọn ènìyàn tí wọ́n yí wa ká. Lọ́pọ̀ ìgbà ìdẹ̀ ńlá kan tí ọtí ìbílẹ̀ wà nínú rẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìjókòó fún ẹni tí ó ni ín, ẹni tí yóò máa mu ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ láti fi pòùngbẹ lákòókò ìrìn-àjò gígùn náà. Àwọn èrò-ọkọ̀ tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-ọ̀rẹ́ sábà máa ń fẹ́ láti ṣàjọpín búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹran wọn pẹ̀lú wa, ìwà-ọ̀làwọ́ ọlọ́yàyà, onífẹ̀ẹ́ àlejò ṣíṣe, tí a mọrírì.
Ní Sicily àwọn arákùnrin máa ń wá láti pàdé wa wọ́n a sì gbé àwọn àpò wa gun òkè-ńlá tí a óò pọ́n fún wákàtí mẹ́ta àti ààbọ̀ kí a tó dé ìjọ tí ó wà lókè. Ìkíni káàbọ̀ ọlọ́yàyà ti àwọn Kristian arákùnrin wa mú kí a gbàgbé àárẹ̀ wa. Nígbà mìíràn a máa ń gun àwọn jẹ̀kí tí ẹsẹ̀ wọn lókun, ṣùgbọ́n a kì í wo ọ̀gbun tí ń bẹ nísàlẹ̀ níbi tí a lè ṣubú sí bí ẹsẹ̀ jẹ̀kí náà bá tàsé. Ìdúróṣinṣin àwọn arákùnrin wa fún òtítọ́ Bibeli láìka àwọn ìnira wọn sí fún wa lókun, ìfẹ́ tí a sì fihàn sí wa mú kí a kún fún ọpẹ́ láti wà pẹ̀lú wọn.
Melita àti Libia
Bí ìrántí àwọn arákùnrin wa ní Sicily ti kún ọkàn wa fọ́fọ́, a wọkọ̀-òkun lọ sí Melita. Aposteli Paulu ti bá àwọn ènìyàn onínúure pàdé níhìn-ín, bẹ́ẹ̀ sì ni àwa náà pẹ̀lú. Ìjì kan ní ibi Ìyawọlẹ̀ St. Paul mú kí a rántí ewu tí àwọn ọkọ̀-òkun kékeré náà dojúkọ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní. (Iṣe 27:39-28:10) Síbẹ̀ Libia ṣì wà níwájú. Báwo ni nǹkan yóò ṣe rí ní ilẹ̀ Africa tí a ti fòfinde iṣẹ́ wa yìí?
Lẹ́ẹ̀kan síi a ní ìrírí àṣà kan tí ó yàtọ̀ pátápátá. Ìrísí àti ìró inú ìlú-ńlà Tripoli gba àfiyèsí mi bí a ṣe ń gba àárín àwọn òpópónà tí ó kún fún ọwọ̀n ní agbègbè àárín ìgboro kọjá. Àwọn ọkùnrin lo irun ìbakasíẹ tí a hun láti dàábòbo araawọn kúrò lọ́wọ́ ooru tí ń jóni lára ti Aṣálẹ̀ Sahara ní ọ̀sán àti kúrò lọ́wọ́ òtútù ní òru. A kọ́ láti lóye kí a sì bọ̀wọ̀ fún ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà mú ara wọn bá ipò ojú-ọjọ́ mu níbi tí wọ́n ń gbé.
Ìtara ọlọgbọ́n ti àwọn ará kọ́ wa ní ohun púpọ̀ nípa gbígbáralé Jehofa pátápátá àti títẹ̀lé ìtọ́ni àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìmọ̀ jù wá lọ nípa wíwàásù lábẹ́ irú àyíká ipò bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristian arákùnrin wa wá láti orílẹ̀-èdè púpọ̀; síbẹ̀ wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan nínú iṣẹ́-ìsìn wọn sí Jehofa.
Iṣẹ́ Àyànfúnni Titun Kan
Nítorí àtakò sí iṣẹ́ ìwàásù wa, a níláti fi Itali sílẹ̀, ṣùgbọ́n a fayọ̀ gba iṣẹ́ àyànfúnni titun ti wíwàásù ní Brazil ní 1957. Èmi àti Francis mú ara wa bá ìgbésí-ayé àti àwọn àṣà mu, àti lẹ́yìn oṣù mẹ́jọ, a késí Francis láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyíká. A rin ìrìn-àjò nínú bọ́ọ̀sì, ọkọ̀ òfuurufú, a sì fi ẹsẹ̀ rìn. Rírin ìrìn-àjò nínú orílẹ̀-èdè gbàràmù tí ó rẹwà yìí, dàbí kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrísí ojú-ilẹ̀.
Àyíká wa àkọ́kọ́ ní àwọn ìjọ mẹ́wàá nínú ìlú-ńlá ti São Paulo nínú, àti ní àfikún sí àwọn ìlú kékeré mẹ́wàá ní ìgbèríko àti ní agbègbè etíkun gúúsù ti ìpínlẹ̀ São Paulo. Kò sí ìjọ kankan ní àwọn ìlú wọ̀nyẹn nígbà náà. A máa ń wá ibi kan láti gbé, lẹ́yìn tí a bá sì ti fìdíkalẹ̀, a óò bẹ̀rẹ̀ sí mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà tọ àwọn ènìyàn lọ láti ilé-dé-ilé. A tún ń fi ìwé ìkésíni pe àwọn ènìyàn láti wá wo ọ̀kan lára àwọn fíìmù Watch Tower Society tí ń kọ́nilẹ́kọ̀ọ́.
Gbígbé fíìmù, ohun atànmọ́lẹ̀ sí fíìmù, ẹ̀rọ tí ń díwọ̀n iná mànàmáná, àwọn àkójọ fáìlì, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé ìkésíni, àti òǹtẹ̀ tí a fi ń lu ọ̀gangan ibi tí a óò ti fi fíìmù náà hàn sórí ìwé ìkésíni kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Ní ìfiwéra, àpò ìkáṣọ wa kékeré kì í ṣe ẹrù rárá. A níláti gbé ohun atànmọ́lẹ̀ sí fíìmù náà sórí itan wa kí ó má baà mì kí ó sì fọ́ nígbà ìrìn-àjò lórí ọ̀nà gbágungbàgun náà.
Lẹ́yìn tí a bá ti rí ibì kan tí a óò ti fi fíìmù náà hàn, a óò lọ láti ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà a óò sì fi ìwé ìkésíni sílẹ̀ fún fífi fíìmù náà hàn. Nígbà mìíràn a ń gba àṣẹ láti fi fíìmù náà hàn nínú ilé àrójẹ tàbí ní hòtẹ́ẹ̀lì. Nígbà mìíràn a ń ta aṣọ ìtẹ́bẹ́ẹ̀dì sí àárín àwọn òpó méjì ní gbangba ìta. Àwọn àwùjọ olùgbọ́ onímọrírì náà, tí ọ̀pọ̀ lára wọn kò tí ì rí àwòràn tí ń rìn rí, yóò dúró wọn yóò sì tẹ́tísílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí Francis ṣe ń ka àlàyé náà. Lẹ́yìn náà, a óò wá pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì ni a ń wọ̀ kí a tó lè dé àwọn abúlé. Díẹ̀ lára àwọn odò náà kò ní afára, nítorí èyí a óò gbé bọ́ọ̀sì náà gun àdìpọ̀ igi tí ó lè léfòó lójú omi a óò sì tù ú kọjá sí ìhà kejì. A máa ń rọ̀ wá láti jáde kúrò nínú bọ́ọ̀sì náà, bí a bá sì rí i pé bọ́ọ̀sì náà ń yọ̀ lọ sí inú odò, kí a fò sí ìhà kejì àdìpọ̀ igi náà láti lè yẹra fún rírì sínú odò. Ọpẹ́ ni pé, odò náà kò gba bọ́ọ̀sì kankan mọ́ wa lọ́wọ́—ọpẹ́ ni, ní pàtàkì níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé àwọn ẹja piranha tí ń jẹ ẹran ara wà nínú odò náà!
Lẹ́yìn lílọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ní New York ní 1958, a padà sí Brazil, níbi tí a tún ti padà sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò lẹ́yìn ìgbà díẹ̀. Iṣẹ́ àgbègbè wa gbé wa dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Uruguay ní gúúsù, Paraguay ní ìwọ̀-oòrùn, ìpínlẹ̀ Pernambuco ní àríwá, àti Òkun Atlantic ní ìhà ìlà-oòrun Brazil.
Àdádó Àwọn Adẹ́tẹ̀
Ní agbedeméjì àwọn ọdún 1960, a gba ìkésíni láti fi ọ̀kan lára àwọn fíìmù Society hàn ní àdádó àwọn adẹ́tẹ̀. Mo níláti jẹ́wọ́ pé ẹ̀rù bà mí lọ́nà kan ṣáá. A kò ní ìmọ̀ ohun púpọ̀ nípa àrùn ẹ̀tẹ̀, bíkòṣe ohun tí a ti kà nípa rẹ̀ nínú Bibeli. Bí a ṣe wọ àyíká náà, tí a kùn ní ọ̀dà funfun, a darí wa sí gbọ̀ngàn ńlá kan. Wọ́n ti ta okùn láti fi pààlà sí apákan ní àárín fún wa àti ohun-èlò wa.
Ẹni 40 ọdún oníṣẹ́ iná mànàmáná tí ń ràn wá lọ́wọ́ jẹ́ olùgbé àdádó náà. Gbogbo ọwọ́ àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mìíràn ti re, èyí sì sọ ìrísí rẹ̀ di èyí tí ó burẹ́wà. Ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí, ṣùgbọ́n ìwà ọ̀yàyà rẹ̀ àti òye rẹ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ rẹ̀ fi mí lára balẹ̀. Bí a ṣe parí àwọn ìmúrasílẹ̀ tí ó pọndandan ni a bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. Lára àwọn ẹgbẹ̀rún olùpọ́njú tí ń gbé inú ilé náà, iye tí ó ju igba lọ pésẹ̀. Bí wọ́n ti ń tiro wọlé, a ṣàkíyèsí ipele tí ó yàtọ̀ tí àìsàn tí ń fìyà jẹ wọ́n náà ní. Ẹ wo irú ìrírí bíbaninínújẹ́, tí ń múni káàánú tí èyí jẹ́!
A ronú nípa ohun tí Jesu wí fún adẹ́tẹ̀ náà tí ó rọ̀ ọ́ pé, “Oluwa, bí iwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, iwọ lè mú kí emi mọ́.” Ní fífọwọ́kan ọkùnrin náà, Jesu mú un lọ́kàn le pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí iwọ mọ́.” (Matteu 8:2, 3, NW) Lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà parí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún wíwá tí a wá, ara wọ́n tí ó díbàjẹ́ jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú fún ìyà ńláǹlà tí aráyé ń jẹ. Lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti kẹ́kọ̀ọ́ síi.
Ní 1967 a padà sí United States láti bójútó àwọn ìṣòro ìlera mímúná. Bí a ṣe ń bá a nìṣó láti máa bá ìwọ̀nyí yí, a tún ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kan síi láti ṣe iṣẹ́ àyíká. Fún 20 ọdún tí ó tẹ̀lé e, mo nípìn-ín pẹ̀lú Francis nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní United States. Láàárín àkókò yìí ó tún kọ́ni ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjísẹ́ Ìjọba.
Ẹ wo irú orísun ìṣírí tí ó jẹ́ fún mi láti ní ọkọ onífẹ̀ẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ olùṣòtítọ́ tí ń bójútó iṣẹ́ àyànfúnni èyíkéyìí tí a bá fún un! A jùmọ̀ ní àǹfààní láti nípìn-ín nínú ṣíṣàjọpín ohun ìṣúra ti òtítọ́ Bibeli ní àwọn apá kọ́ńtínẹ̀ǹtì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
Ohun Ìṣúra náà Mú Wa Dúró
Nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1950, Màmá fẹ́ David Easter, arákùnrin olùṣòtítọ́ tí ó ṣe ìrìbọmi ní 1924. Wọ́n ṣiṣẹ́sìn papọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín apá tí ó kẹ́yìn nínú ìgbésí-ayé Màmá, àrùn Ọdẹ-Orí Abọ́jọ́-Ogbó-Rìn bẹ̀rẹ̀ sí jẹ jáde. Ó béèrè ìtọ́jú púpọ̀ níwọ̀n bí àrùn náà ti dín agbára ìrònú rẹ̀ kù. Àwọn arábìnrin mi àti David tẹ́rígba ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo náà ti bíbójútó o, níwọ̀n bí wọn kò ti fẹ́ kí a fi àkànṣe àǹfààní iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún tí a ní sílẹ̀. Àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ Màmá títí dé ojú ikú ní 1987 ṣe púpọ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ láti wéwèé ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé wa, ìrètí èrè ti ọ̀run tí Màmá fọkàn ṣìkẹ́ sì tù wá nínú.
Nígbà tí ó fi máa di 1989, mo wòye pé agbára Francis kò rí bí ti tẹ́lẹ̀ mọ́. A kò mọ̀ pé àrùn àtọ̀sí ajá, àrùn kan tí wọ́n mọ̀-bí-ẹní-mowó ní àwọn apá ibi púpọ̀ nínú ayé, ti ń ní ipa tí ó léwu lé e lórí. Ní 1990, ọ̀tá tí kò dẹ̀yìn yìí borí rẹ̀, mo sì pàdánù alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi olùfẹ́ ẹni tí mo ti bá ṣàjọpín ohun tí ó ju 40 ọdún nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa.
Mímú ara-ẹni bá ipò mu jẹ́ apákan ìgbésí-ayé. Àwọn kan rọrùn, àwọn kan sì nira. Ṣùgbọ́n Jehofa, Olùfúnni ní ohun ìṣúra tí kò ṣeé díyelé ti òtítọ́ Bibeli, mú mi dúró nípasẹ̀ ètò-àjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìṣírí ìdílé mi. Mo ṣì ń ní ìtẹ́lọ́rùn bí mo ti ń fojúsọ́nà fún gbogbo àwọn ìlérí Jehofa tí kì í yẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Nígbà tí èmi àti ọkọ mi jẹ́ míṣọ́nnárì ní Itali