ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 1/1 ojú ìwé 31
  • Jehofa Ní Agbára Ju Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Ní Agbára Ju Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Lọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tí Ń Yin Jehofa Lógo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 1/1 ojú ìwé 31

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Jehofa Ní Agbára Ju Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Lọ

ÈṢÙ àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ti ń gbìyànjú tipẹ́tipẹ́ láti ké wíwàásù ìhìnrere náà nígbèrí nípasẹ̀ àwọn ìsìn èké àti ìbẹ́mìílò. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa èrò ibi tí Satani ní, nínú 2 Korinti 4:4 (NW) níbi tí ó ti sọ pé “ọlọrun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii ti fọ́ èrò-inú awọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ títàn ìhìnrere ológo nipa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọrun, má baà mọ́lẹ̀ wọlé.”

Ṣùgbọ́n Jehofa Ọlọrun ní agbára ju Satani lọ. Kò sí ohun tí àwọn ọ̀tá Jehofa lè ṣe láti ṣe ìdíwọ́ fún mímú ìfẹ́-inú rẹ̀ àtọ̀runwá ṣẹ, tí ó jẹ́ láti “gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (1 Timoteu 2:4, NW) Àwọn ìròyìn tí ó tẹ̀lé e yìí láti ẹnu àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní Australia tẹnumọ́ èyí.

◻ Lẹ́yìn 20 ọdún tí ó ti takété sí ìsìn, adélébọ̀ kan tún bẹ̀rẹ̀ síi ka Bibeli. Ìfẹ́-ọkàn tí ó tún sọjí nínú Bibeli yìí mú kí ó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìbéèrè, nítorí náà ó gbàdúrà sí Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́ láti rì àwọn ìdáhùn náà. Ó fẹ́ láti wá òtítọ́, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé pípadà sí ìsìn rẹ̀ àtijọ́ kì yóò yanjú ìṣòro rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ìwákiri rẹ̀ nípa ṣíṣe ìbẹ̀wò sí ilé-ìtàwé-àlòkù tí ó sì béèrè bí wọ́n bá ní àwọn ìwé èyíkéyìí tí ó jẹmọ́ ìsìn.

Ẹni tí ó ni ilé-ìtàwé náà rántí pé òun ní ìwé kan tí ó jẹmọ́ ìsìn, kì í ṣe nínú ilé ìtàwé náà, ṣùgbọ́n ní ilé. Orúkọ ìwé náà ni Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Obìnrin náà fi ìháragàgà ka ìwé náà ó sì rí ìdáhùn sí púpọ̀ lára àwọn ìbéèrè rẹ̀ nípa Bibeli. Lẹ́yìn wíwá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ìwé tẹlifóònù, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó kàn sí wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bibeli.

◻ Ọ̀dọ́mọbìnrin kan bẹ ìwé ìròyìn àdúgbò kan lọ́wẹ̀ láti polówó ìfúnpá. Ìpolówó ọjà náà tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí ‘ìfúnpá àtayébáyé tí ń jẹ́ bí idán.’ Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣàkíyèsí ìpolówó ọjà náà. Ó pinnu láti késí nọ́ḿbà tí a fúnni lórí tẹlifóònù ó sì bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ nípa orísun agbára ìfúnpá náà. Ìjíròrò lórí ojú-ìwòye Bibeli nípa ìgbòkègbodò ẹ̀mí-èṣù tẹ̀lé e. Ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ni ìfúnpá náà ṣípayá pé ọjọ́ kan ṣáájú ọjọ́ náà, òun ti gbàdúrà sí Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ìṣòro òun pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí-èṣù. Ẹlẹ́rìí náà ṣètò fún ìjíròrò mìíràn lórí tẹlifóònù.

Nígbà tí ó tẹ̀ ẹ́ láago, ọ̀dọ́mọbìnrin náà kò sí nílé. Màmá rẹ̀ dáhùn tẹlifóònù náà ó sì wí pé: “Èmi kò mọ ohun tí o bá ọmọbìnrin mi sọ, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìyanu ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ jẹ́!” Ó sọ pé lẹ́yìn títẹ̀ ẹ́ láago lákọ̀ọ́kọ́, ọmọbìnrin òun kó gbogbo àwọn àwòrán àti ìwé tí ó níí ṣe pẹ̀lú Satani jùnù ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ka Bibeli.

Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n ṣètò fún ìbẹ̀wò ara-ẹni sọ́dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin náà. Ó tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lójú-ẹsẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí náà nípa wíwá sí àwọn ìpàdé Kristian. Lẹ́ẹ̀kan síi, Jehofa ṣẹ́gun àwọn ẹ̀mí-èṣù nípa mímú kí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bibeli máa tàn-yòò síwájú síi.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́