Èéṣe Tí Ó Fi Tó Àkókò Láti Ṣe Ìpinnu?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹrìndínlógún B.C.E., Ọlọrun yan àwọn ọmọ Israeli gẹ́gẹ́ bí “ìṣúra . . . ju gbogbo ènìyàn lọ: . . . orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Eksodu 19:5, 6) Kò pẹ́ tí wọ́n fi pàdánù ìjẹ́mímọ́ wọn, ìmọ́gaara ìsìn wọn, tí wọ́n sì jẹ́ kí ìbọ̀rìṣà àti àṣà ìwà ìbàjẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó múlé gbè wọ́n kó èérí bá wọn. Wọ́n tipa báyìí fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn ọlọ́rùn líle.” (Deuteronomi 9:6, 13; 10:16; 1 Korinti 10:7-11) Ní àkókò tí ó ju ọ̀ọ́dúnrún ọdún lọ lẹ́yìn ikú Joṣua, Jehofa gbé àwọn onídàájọ́ dìde, àwọn olùṣòtítọ́ afinimọ̀nà tí ó ti yẹ kí wọ́n ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Israeli padà sínú ìjọsìn tòótọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn náà “kò dẹ́kun ìṣe wọn, àti ìwà-agídí wọn.”—Awọn Onidajọ 2:17-19.
Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọrun gbé àwọn ọba àti wòlíì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ dìde láti sún àwọn ènìyàn náà gbégbèésẹ̀ láti padà sínú ìjọsìn tòótọ́. Wòlíì Asariah fún Ọba Asa àti àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà pẹ̀lú rẹ̀ ní ìṣírí láti wá Jehofa: “Bí ẹ̀yin bá sì ṣàfẹ́rí rẹ̀, ẹ̀yin óò rí i; ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ ọ́, òun ó sì kọ̀ yín.” Asa ṣe àtúnṣe ìsìn nínú ìjọba Juda. (2 Kronika 15:1-16) Lẹ́yìnwá ìgbà náà, Ọlọrun níláti tún ìkésíni náà ṣe nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Joeli. (Joeli 2:12, 13) Síbẹ̀ lẹ́yìn náà, Sefaniah gba àwọn olùgbé Juda níyànjú láti “wá Oluwa.” Ọmọdékùnrin Josiah ọba ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìgbétásì àtúnṣe láti fòpin sí ìbọ̀rìṣà àti ìwà-ìbàjẹ́.—Sefaniah 2:3; 2 Kronika 34:3-7.
Láìka irú àwọn abala ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn fún ìrònúpìwàdà sí, ipò àwọn ènìyàn náà níti ìsìn túbọ̀ ń burú síwájú àti síwájú síi. (Jeremiah 2:13; 44:4, 5) Jeremiah fi ètò-ìgbékalẹ̀ ìsìn tí a fi àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà kó èérí bá náà bú, ó ṣàpèjúwe rẹ̀ bí èyí tí kò ṣeé túnṣe: “Ará Etiopia lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà, tàbí ẹkùn lè yí ìlà ara rẹ̀ padà? bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú ìbá lè ṣe rere, ẹ̀yin tí a kọ́ ní ìwà búburú?” (Jeremiah 13:23) Fún ìdí yìí, Ọlọrun fi ìyà ńlá jẹ ìjọba Juda. A pa Jerusalemu àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ run ní 607 B.C.E., a sì kó àwọn tí ó làájá lẹ́rú lọ sí Babiloni, níbi tí wọ́n wà fún 70 ọdún.
Nígbà tí sáà àkókò yẹn wá sí ìparí, Ọlọrun fi àánú hàn. Ó sún Ọba Kirusi láti dá àwọn ọmọ Israeli sílẹ̀, àṣẹ́kù kan nínú wọn sì padà sí Jerusalemu láti tún tẹ́ḿpìlì kọ́. Dípò kí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n láti inú gbogbo èyí, wọ́n tún yapa kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ lẹ́ẹ̀kan síi, ní mímú kí Jehofa Ọlọrun tún ìkésíni rẹ̀ ṣe pé: “Ẹ yípadà sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi ó sì yípadà sí ọ̀dọ̀ yín.”—Malaki 3:7.
Ìdí Tí A Fi Kọ Israeli Sílẹ̀
Báwo ni ipò ìsìn àwọn ọmọ Israeli ti rí ní àkókò Jesu? Àwọn àgàbàgebè aṣáájú ìsìn náà jẹ́ “afọ́jú afinimọ̀nà” tí ń fi “awọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.” ‘Wọ́n ń rékọjá ìlà àṣẹ Ọlọrun nitori òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọn.’ Àwọn ènìyàn náà “ń fi ètè wọn” bọlá fún Ọlọrun, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí i. (Matteu 15:3, 4, 8, 9, 14, NW) Wọn yóò ha tún rí àǹfààní mìíràn láti ronúpìwàdà gbà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Jesu wí pé: “A óò gba ìjọba Ọlọrun kúrò lọ́wọ́ yín a óò sì fi fún orílẹ̀-èdè kan tí yoo máa mú èso rẹ̀ jáde.” Ó sọ síwájú síi pé: “a ti pa ilé yín,” tẹ́ḿpìlì tí ń bẹ ní Jerusalemu, “tì fún yín.” (Matteu 21:43, NW; 23:38, NW) Ìṣìnà wọn ti pọ̀ jù. Wọ́n kọ Jesu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Messia wọ́n sì mú kí a ṣekúpa á, wọ́n sì yan Kesari atẹnilóríba ti Romu gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.—Matteu 27:25; Johannu 19:15.
Àwọn ọmọ Israeli kò fẹ́ láti lóye pé àkókò tí Jesu ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ àkókò ìdájọ́. Jesu sọ fún àwọn aláìṣòtítọ́ olùgbé Jerusalemu pé: ‘Ẹ kò fi òye mọ àkókò tí a óò bẹ̀ yín wò.’—Luku 19:44, NW.
Ní Pentekosti 33 C.E., Ọlọrun gbé orílẹ̀-èdè titun kan, tàbí awọn ènìyàn kalẹ̀, àwọn tí a fi ẹ̀mí yàn, tí wọ́n jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, tí a óò yàn láti inú ẹ̀yà ìran àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá. (Iṣe 10:34, 35; 15:14) Ìrètí èyíkéyìí ha wà pé ètò-ìgbékalẹ̀ ìsìn àwọn Júù ni a óò túnṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn bí? Àwọn ọmọ-ogun Romu pèsè ìdáhùn ní 70 C.E., nígbà tí wọ́n sọ Jerusalemu di àbàtì àlàpà. Ọlọrun ti kọ ètò-ìgbékalẹ̀ ìsìn yẹn sílẹ̀ pátápátá.—Luku 21:5, 6.
Ìpẹ̀yìndà Ńlá ti Kristẹndọm
Àwọn Kristian tí a fi ẹ̀mí yàn tún parapọ̀ di “orílẹ̀-èdè mímọ́, awọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” (1 Peteru 2:9, NW; Galatia 6:16) Ṣùgbọ́n ìjọ Kristian ìjímìjí pàápàá kò tilẹ̀ pa ìmọ́gaara ìsìn rẹ̀ mọ́ fún ìgbà pípẹ́.
Ìwé Mímọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìpẹ̀yìndà ńlá kan, tàbí yíyapa kúrò nínú ìgbàgbọ́ tòótọ́. Àwọn èpò ìṣàpẹẹrẹ inú òwe-àkàwé Jesu, ìyẹn ni, àwọn ayédèrú Kristian, yóò gbìyànjú láti fún àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ náà, tàbí àwọn Kristian tòótọ́, àwọn wọnnì tí a fi ẹ̀mí Ọlọrun yàn pa. Òwe-àkàwé náà ṣí i payá pé gbígbilẹ̀ ìsìn Kristian èké, tí olórí ọ̀tá Ọlọrun, Èṣù, ń gbé lárugẹ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀, “nígbà tí awọn ènìyàn ń sùn.” Èyí wáyé lẹ́yìn ikú àwọn olùṣòtítọ́ aposteli Kristi, lákòókò sáà oorun tẹ̀mí tí ó tẹ̀lé e. (Matteu 13:24-30, 36-43, NW; 2 Tessalonika 2:6-8) Gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli ti sọtẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ ayédèrú Kristian fi ọgbọ́n àyínìke wọ inú agbo wa. (Iṣe 20:29, 30; 1 Timoteu 4:1-3; 2 Timoteu 2:16-18; 2 Peteru 2:1-3) Johannu ni ó kú gbẹ̀yìn lára àwọn aposteli. Ní nǹkan bí ọdún 98 C.E., ó kọ̀wé pé “wákàtí ìkẹyìn,” apá tí ó gbẹ̀yìn nínú sáà àwọn aposteli, ti bẹ̀rẹ̀ nígbà náà.—1 Johannu 2:18, 19, NW.
Gbàrà tí Constantine olú-ọba Romu, ti fi òǹtẹ̀ tẹ ìdàpọ̀mọ́ra agbára ìsìn àti ti ìṣèlú, ni ipò Kristẹndọm nípa tẹ̀mí, ti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti ìwàhíhù ti lọsílẹ̀ lójijì. Ọ̀pọ̀ àwọn òpìtàn gbà pé “ayọ̀-ìṣẹ́gun Ṣọ́ọ̀ṣì ní ọ̀rúndún kẹrin” jẹ́ “ìjábá kan,” bí a bá fi ojú-ìwòye ti Kristian wò ó. ‘Kristẹndọm pàdánù ipò ìwàrere gíga rẹ̀’ tí ó sì tẹ́wọ́gba ọ̀pọ̀ àṣà àti ọgbọ́n-èrò-orí tí ó ti inú ìbọ̀rìṣà wá, àwọn bí “ìjọsìn Maria” àti ìbọlá fún “àwọn ènìyàn mímọ́,” àti èròǹgbà nípa Mẹ́talọ́kan pẹ̀lú.
Lẹ́yìn ayọ̀-ìṣẹ́gun èké rẹ̀, ìlọsẹ́yìn bá ipò Kristẹndọm. Àwọn òfin àti àlàyé ẹ̀kọ́-ìsìn láti ẹnu àwọn popu àti ìgbìmọ̀, mú ètò ìgbékalẹ̀ ìsìn kan tí kò ṣeé túnṣe jáde, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti Ìgbógun Ti Àdámọ̀, Ogun Ìsìn, àti àwọn ogun “mímọ́” láàárín àwọn Katoliki àti Protẹstanti.
Nínú ìwé rẹ̀ A World Lit Only by Fire, William Manchester kọ̀wé pé: “Àwọn popu ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún àti ìkẹrìndínlógún gbé ìgbésí-ayé tí ó dàbíi ti àwọn olú-ọba Romu. Àwọn ni wọ́n lọ́rọ̀ jùlọ nínú ayé, àwọn àti àwọn àlùfáà wọn àgbà sì sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀ nípa títa àwọn oyè ìsìn.” Nígbà ìpẹ̀yìndà ńlá náà, àwọn àwùjọ kékeré tàbí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wá ọ̀nà láti tún ṣàwárí ìsìn Kristian tòótọ́ padà, wọ́n sì ń fi àwọn ànímọ́ bíi ti àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ hàn. Lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fojúwiná ìṣòrò. Ìwé kan náà sọ pé: “Ní àwọn ìgbà mìíràn ó máa ń dàbí ẹni pé àwọn tí wọ́n jẹ́ ènìyàn mímọ́ nítòótọ́ nínú ìsìn Kristian, Protẹstanti àti Katoliki bákan náà, ti di ajẹ́rìíkú tí a fẹ̀sùn èké kan tí a sì sun jóná gúrúgúrú.” Àwọn mìíràn, tí a fẹnu lásán pè ní Alátùn-ún-ṣe àwọn bíi Martin Luther àti John Calvin, gbìyànjú láti dá àwọn ètò-ìgbékalẹ̀ ìsìn tí ó tọ́jọ́ sílẹ̀ èyí tí ó yàtọ̀ sí ti Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ṣùgbọ́n tí ó ṣì ń ṣàjọpín àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀. Àwọn pẹ̀lú fi ara wọn fún àlámọ̀rí ìṣèlú pátápátá.
Níhà ọ̀dọ̀ àwọn Protẹstanti, wọ́n ti sapá láti ṣe ohun tí wọ́n fi ẹnu lásán pè ní ìtúnmúsọjí ìsìn. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, àwọn ìsapá wọ̀nyí jásí ìgbòkègbodò kíkankíkan ti iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùtàn náà fúnra wọn jẹ́wọ́ rẹ̀, ipò tẹ̀mí ti agbo Protẹstanti lónìí kò fúnni ní ìṣírí rárá. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Protẹstanti náà Oscar Cullmann gbà láìpẹ́ yìí pé “yánpọnyánrin ìgbàgbọ́ ń bẹ, láàárín àwọn ṣọ́ọ̀ṣì náà fúnra wọn.”
Àtúnṣe àti àwọn ìgbésẹ̀ lòdìsí àtúnṣe ni a tún ti gbé lárugẹ láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki. Láti ọ̀rúndún kọkànlá sí ìkẹtàlá, lójú ìwà-ìbàjẹ́ tí ó gbilẹ̀ àti ọrọ̀ jaburata tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ní, àwùjọ àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí wọ́n ń tẹ̀lé ẹ̀jẹ́ ipò-òṣì láìyẹsẹ̀ ní a dásílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ń ṣọ́ wọn tọwọ́-tẹsẹ̀ àti pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti wí, ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso ní ṣọ́ọ̀ṣì tẹ̀ wọ́n lóríba. Lẹ́yìn náà ni Ìgbésẹ̀ Lòdìsí Àtúnṣe ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, èyí tí Ìgbìmọ̀ Trent gbé lárugẹ tí a sì dìídì dojú rẹ̀ kọ gbígbéjàko Àtúnṣe Protẹstanti wọlé dé.
Ní apá ìdajì àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún kọkàndínlógún, nígbà ìmúpadàbọ̀sípò ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso ní ṣọ́ọ̀ṣì, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki dúró gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ oníkùmọ̀ àti alátakò ìyípadà ìgbàlódé. Ṣùgbọ́n, a kò lè sọ pé a ṣe àtúnṣe gidi èyíkéyìí láti mú ìsìn Kristian padàbọ̀sípò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ ìsapá láti sọ ọlá-àṣẹ àwùjọ àlùfáà di alágbára láìka ìyípadà nínú ìsìn, ìṣèlú, àti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà sí.
Láìpẹ́ yìí, ní àwọn ọdún 1960, ó dàbí ẹni pé Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki fẹ́ láti lo àjọ Vatican II tí ń ṣojú fún gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọ̀nà ìgbàṣe ìyípadà pátápátá kan. Bí ó ti wù kí ó rí, popu tí ó wà nígbà náà dá àtúnṣe tí ìgbìmọ̀ náà mú wá dúró lójijì láti ṣèdíwọ́ fún ojú-ìwòye àwọn mẹ́ḿbà ẹlẹ́mìí ìtẹ̀sìwájú nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà. Ìpele yìí, tí àwọn kan pè ní ìmúpadàbọ̀sípò láti ọwọ́ Wojtyła, ni àwùjọ Katoliki kan ti túmọ̀ sí “irú oríṣi ojú-ìwòye titun ti Constantine.” Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú ìwé agbéròyìnjáde ti àwọn onísìn Jesuit náà La Civiltà Cattolica, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ìsìn yòókù, ń dojúkọ “ìyípadà tegbòtigaga àti yánpọnyánrin tí ó kárí ayé: ó jẹ́ ìyípadà tegbòtigaga nítorí pé ó wémọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ìgbésí-ayé Kristian; ó kárí ayé nítorí pé ó wémọ́ gbogbo apá-ẹ̀ka ìsìn Kristian.”
Àwọn ìsìn Kristẹndọm kò tíì ṣe àtúnṣe nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì ní àsìkò “ìkórè,” nígbà tí a bá ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ jọ sínú ìjọ mímọ́gaara kanṣoṣo ní a óò tó mú ìsìn Kristian tòótọ́ padàbọ̀sípò. (Matteu 13:30, 39, NW) Àkọsílẹ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ti ìwà-ọ̀daràn àti aṣemáṣe tí a ti ṣe ní orúkọ ìsìn, yálà èyí tí ń jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian tàbí tí kò ṣe bẹ́ẹ̀, gbé ìbéèrè náà dìde pé, Ó ha jẹ́ òtítọ́ gidi láti retí àtúnṣe tòótọ́ láti ọ̀dọ̀ Kristẹndọm?
Àtúnṣe Kò Ha Ṣeé Ṣe Bí?
Ìwé Ìṣípayá, tàbí Apokalipsi, sọ̀rọ̀ nípa aṣẹ́wó ńlá ìṣàpẹẹrẹ kan tí ń jẹ́ orúkọ ohun-ìjìnlẹ̀ náà “Babiloni Ńlá.” (Ìṣípayá 17:1, 5, NW) Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn tí ń ka Bibeli ti wá ọ̀nà láti ṣàlàyé ohun-ìjìnlẹ̀ àmì ìṣàpẹẹrẹ yìí. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ọrọ̀ àti ìwà-ìbàjẹ́ àwùjọ àlùfáà kó nírìíra. Àwọn kan ronú pé Babiloni Ńlá dúró fún ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso ní ṣọ́ọ̀ṣì. Lára wọn ni Jan Hus, àlùfáà Katoliki kan tí ó jẹ́ ará Bohemia tí a dáná sun láàyè ní 1415, àti Aonio Paleario, ọmọ ilẹ̀ Itali tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa àlámọ̀rí ẹ̀dá tí a sorọ̀ tí a sì dánásun ní 1570. Àwọn méjèèjì gbìdánwò láìsí àṣeyọrí láti ṣàtúnṣe Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki pẹ̀lú ìrètí náà pé yóò padà “jèrè iyì rẹ̀ ìjímìjí.”
Ní òdìkejì pátápátá, orí 17 àti 18 nínú ìwé Ìṣípayá fihàn pé Babiloni Ńlá dúró fún ilẹ̀-ọba gbogbo ìsìn èké àgbáyé.a “Aṣẹ́wó ńlá” tí ó ní ẹ̀ka púpọ̀ yìí kò ṣeé mú bọ̀sípò nítorí pé “awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́jọpọ̀ títí dé ọ̀run.” Níti tòótọ́, ní ọ̀rúndún ogún yìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìsìn pátá, kì í ṣe ti Kristẹndọm nìkan, ni ó ń pín nínú ẹ̀bi ogun tí ó ti ń báa lọ láti máa ta ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti ìlọsílẹ̀ bíburú jáì níti ìwàrere èyí tí ń pọ́n aráyé lójú. Nítorí náà, Ọlọrun ti fi àṣẹ sí ìparun “Babiloni.”—Ìṣípayá 18:5, 8, NW.
Ìsinsìnyí Ni Ó Tó Àkókò Láti “Jáde Kúrò Nínú Rẹ̀”
Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣí i payá pé ọjọ́ tiwa bá “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” burúkú yìí mu. (Matteu 24:3, NW) Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti fi òtítọ́-inú sin Ọlọrun kì yóò fẹ́ láti tẹ̀lé àwọn èrò tàbí ẹwùn tirẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ ‘wá Oluwa nígbà tí ó lè rí i,’ bẹ́ẹ̀ni, nísinsìnyí gan-an, nítorí pé “ìpọ́njú ńlá” tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ ti súnmọ́lé. (Isaiah 55:6; Matteu 24:21, NW) Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn ti àwọn ọmọ Israeli, Ọlọrun kò ní fi àyè gba ìwà-ìbàjẹ́ ìsìn kan kìkì nítorí pé ó ń yangàn pé òun lọ́jọ́lórí. Dípò kí wọ́n làkàkà láti tún ọkọ ojú-omi tí ó dájú pé ó níláti rì ṣe, gbogbo àwọn tí ń fẹ́ láti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun àti ìgbàlà gbọ́dọ̀ ṣègbọràn láìjáfara sí àṣẹ onímìísí náà tí ń bẹ nínú Ìṣípayá 18:4 (NW) pé: “Ẹ jáde kúrò ninu [Babiloni Ńlá], ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹlu rẹ̀ ninu awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára awọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”
Ṣùgbọ́n “jáde kúrò” lọ síbo? Níbòmíràn wo ni a tún ti lè rí ìgbàlà? Ewu wíwá ààbò sí ibi tí kò tọ́ kò ha sì tún wà bí? Báwo ni a ṣe lè dá ìsìn kanṣoṣo tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun mọ̀? Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni a ti lè rí kìkì àwọn ìdáhùn tí ó ṣeé gbáralé. (2 Timoteu 3:16, 17) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa késí ọ láti túbọ̀ ṣàyẹ̀wò Bibeli fínnífínní. Yóò lè ṣeé ṣe fún ọ láti lóye àwọn wo ni Ọlọrun ti yàn gẹ́gẹ́ bí “awọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀,” àwọn tí òun yóò dáàbòbò nígbà ọjọ́ ìbínú rẹ̀ tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀.—Iṣe 15:14, NW; Sefaniah 2:3; Ìṣípayá 16:14-16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti mọ Babiloni Ńlá ìṣàpẹẹrẹ náà ní ọ̀nà títọ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, wo orí 33 sí 37 nínú ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, tí a tẹ̀jáde ní 1988 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí ọkọ̀ ojú-omi ìsìn rẹ bá ń rì, kọjá sínú ọkọ̀ ojú-omi ìgbàlà ti ìsìn Kristian tòótọ́