Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Tí Ń Ṣe Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́-Ọlọ́wọ̀
“Wọ́n . . . ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán tòru ninu tẹmpili rẹ̀.”—ÌṢÍPAYÁ 7:15, NW.
1. Orí kókó ìdàgbàsókè nínú òye tẹ̀mí wo ni a dé ní 1935?
NÍ May 31, 1935, ìdùnnú-ayọ̀ ńláǹlà kún inú àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Washington, D.C. Níbẹ̀, fún ìgbà àkọ́kọ́, ògìdìgbó ńlá (tàbí, ogunlọ́gọ̀ ńlá) ti Ìṣípayá 7:9 ni a dá mọ̀ yàtọ̀ ní kedere ní ìbámu pẹ̀lú apá yòókù nínú Bibeli àti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀.
2. Kí ni ó fihàn pé iye ènìyàn tí ń pọ̀ síi ti mọ̀ pé Ọlọrun kò pè wọ́n sí ìyè ti ọ̀run?
2 Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ṣáájú, ní ibi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 10,681 lára àwọn tí wọ́n pésẹ̀ (nǹkan bíi 1 nínú ẹni 6) ni kò ṣàjọpín nínú búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ, 3,688 lára àwọn wọ̀nyí sì jẹ́ ògbóṣáṣá olùpòkìkí Ìjọba Ọlọrun. Èéṣe tí wọ́n fi yẹra fún ṣíṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà? Nítorí pé lórí ìpìlẹ̀ ohun tí wọ́n ti kọ́ nínú Bibeli, wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun kò pè wọ́n sí ìyè ti ọ̀run bíkòṣe pé ní ọ̀nà mìíràn wọ́n lè nípìn-ín nínú àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jehofa ṣe. Nítorí náà ní àpéjọpọ̀ yẹn, nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ béèrè pé: “Kí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀-ayé títíláé jọ̀wọ́ dìde dúró,” kí ni ó ṣẹlẹ̀? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún dìde dúró, ariwo sì ta gèè láti ọ̀dọ̀ àwùjọ.
3. Èéṣe tí dídá àwọn ògìdìgbó ńlá mọ̀ fi fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá wọn ní ìsúnniṣe ọ̀tun, kí sì ni ìmọ̀lára àwọn Ẹlẹ́rìí nípa èyí?
3 Ohun tí àwọn àyànṣaṣojú náà kọ́ ní àpéjọpọ̀ yẹn fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn ní ìsunníṣe ọ̀tun. Wọ́n wá mọrírì pé nísinsìnyí, ṣáájú òpin ètò-ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó, kì í wulẹ̀ ṣe kìkì ẹgbẹ̀rún mélòókan ni a óò fún ní àǹfààní láti wá sínú ìṣètò Jehofa fún pípa ìwàláàyè mọ́ bíkòṣe ògìdìgbó ńlá àwọn ènìyàn, tí wọ́n ní èrò wíwàláàyè títíláé nínú paradise orí ilẹ̀-ayé. Ẹ sì wo irú ìhìn-iṣẹ́ amọ́kànyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn olùfẹ́ òtítọ́ níbẹ̀! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ pé iṣẹ́ ńláǹlà kan wà láti ṣe—iṣẹ́ onídùnnú-ayọ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, John Booth, tí ó di mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, rántí pé: “Àpéjọ yẹn fún wa ní ohun púpọ̀ láti yọ̀ lé lórí.”
4. (a) Báwo ni kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jọ níti gidi ti lọ jìnnà tó láti 1935? (b) Ní ọ̀nà wo ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá gbà ń fúnni ní ẹ̀rí pé ìgbàgbọ́ àwọn jẹ́ èyí tí ó wàláàyè?
4 Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ga sókè lọ́nà tí ń múnijígìrì. Láìka inúnibíni oníwà-ipá tí a ṣe sí wọn lákòókò Ogun Àgbáyé II sí, iye wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po mẹ́ta láàárín ọdún mẹ́wàá. Àwọn akéde 56,153 tí wọ́n ti ń fúnni ní ìjẹ́rìí ní gbangba ní 1935 ga sókè, dé iye tí ó lé ní 4,900,000 olùpòkìkí Ìjọba tí wọ́n wà ní àwọn ilẹ̀ tí ó lé ní 230, ní 1994. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ lára àwọn wọ̀nyí ń fojúsọ́nà pẹ̀lú ìháragàgà láti wà lára àwọn wọnnì tí Jehofa yóò fi ìwàláàyè pípé nínú paradise ilẹ̀-ayé ṣe ojúrere sí. Bí a bá fi wọ́n wé agbo kékeré, wọ́n ti di ogunlọ́gọ̀ ńlá níti tòótọ́. Wọ́n kì í ṣe àwọn ènìyàn tí ń sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀ tí wọn kì í fi í hàn. (Jakọbu 1:22; 2:14-17) Gbogbo wọn ń ṣàjọpín ìhìnrere nípa Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìwọ ha jẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ènìyàn aláyọ̀ yẹn bí? Jíjẹ́ ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí jẹ́ àmì ìdánimọ̀ pàtàkì, ṣùgbọ́n ohun púpọ̀ síi wémọ́ ọn.
“Wọ́n Dúró Níwájú Ìtẹ́”
5. Kí ni òtítọ́ náà pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń ‘dúró níwájú ìtẹ́’ fihàn?
5 Nínú ìran tí a fún aposteli Johannu, ó rí wọn tí “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ ati níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtàn.” (Ìṣípayá 7:9, NW) Dídúró wọn níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, fihàn pé wọ́n ka ipò ọba aláṣẹ Jehofa sí gidigidi. Èyí ní ohun púpọ̀ nínú. Fún àpẹẹrẹ: (1) Wọ́n tẹ́wọ́gba ẹ̀tọ́ tí Jehofa ní láti pinnu ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Genesisi 2:16, 17; Isaiah 5:20, 21) (2) Wọ́n ń tẹ́tísílẹ̀ sí Jehofa bí ó ṣe ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. (Deuteronomi 6:1-3; 2 Peteru 1:19-21) (3) Wọ́n mọrírì ìjẹ́pàtàkì títẹríba fún àwọn wọnnì tí Jehofa ti fi ipò ìṣàbójútó lé lọ́wọ́. (1 Korinti 11:3; Efesu 5:22, 23; 6:1-3; Heberu 13:17) (4) Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n ń sakun taápọn-taápọn láti dáhùnpadà sí ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso Ọlọrun, kì í ṣe pẹ̀lú àfipáṣe, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìmúratán, láti inú ọkàn-àyà. (Owe 3:1; Jakọbu 3:17, 18) Wọ́n wà níwájú ìtẹ́ náà láti ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Jehofa, ẹni tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún gidigidi tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ jinlẹ̀jinlẹ̀. Nínú ọ̀ràn ti ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí, ‘dídúró’ wọn níwájú ìtẹ́ fihàn pé Ẹni náà tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tẹ́wọ́gbà wọ́n. (Fiwé Ìṣípayá 6:16, 17.) Lórí ìpìlẹ̀ wo ni o fi tẹ̀wọ́gbà wọ́n?
Wọ́n “Wọ Aṣọ Ìgúnwà Funfun”
6. (a) Kí ni wíwọ̀ tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà “wọ aṣọ ìgúnwà funfun” túmọ̀ sí? (b) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe jèrè ìdúró òdodo níwájú Jehofa? (d) Dé àyè wo ni ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi tí a ta sílẹ̀ fi nípa ìdarí lórí ìgbésí-ayé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?
6 Àpèjúwe tí aposteli Johannu ṣe nípa ohun tí ó rí sọ pé àwọn mẹ́ḿbà ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí “wọ aṣọ ìgúnwà funfun.” Àwọn aṣọ ìgúnwà funfun wọ̀nyẹn ń ṣàpẹẹrẹ ìdúró mímọ́ tónítóní, ti òdodo wọn níwájú Jehofa. Báwo ni wọ́n ṣe jèrè irú ìdúró bẹ́ẹ̀? A ti ṣàkíyèsí ṣáájú pé nínú ìran Johannu wọ́n dúró “níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtàn.” Wọ́n mọ Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọrun tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Johannu 1:29, NW) Johannu gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn alàgbà, tí ó wà níbi ìtẹ́ Ọlọrun nínú ìran náà ṣàlàyé pé: “Wọ́n sì ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun.” (Ìṣípayá 7:14, 15, NW) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi tí ń ranipadà. Wọn kò fohùnṣọ̀kan níti èrò-orí lásán pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bibeli nípa ìràpadà. Ìmọrírì fún un nípa lórí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú lọ́hùn-ún; nípa bẹ́ẹ̀, ‘ọkàn-àyà ni wọ́n fi’ lo ìgbàgbọ́. (Romu 10:9, 10, NW) Èyí nípa ìdarí jíjinlẹ̀ lórí ohun tí wọ́n ń fi ìgbésí-ayé wọn ṣe. Nínú ìgbàgbọ́, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Kristi, wọ́n fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ yẹn hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi, wọ́n gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbádùn ipò-ìbátan tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà. Ẹ wo irú àǹfààní rere tí èyí jẹ́—ọ̀kan tí a níláti dáàbòbò dáradára!—2 Korinti 5:14, 15.
7, 8. Báwo ni ètò-àjọ Jehofa ti ṣe ran ogunlọ́gọ̀ ńlá náà lọ́wọ́ láti pa aṣọ ìgúnwà wọn mọ́ láìléèérí?
7 Pẹ̀lú àníyàn onífẹ̀ẹ́ fún ire wọn wíwàpẹ́títí, léraléra ni ètò-àjọ Jehofa ń pe àfiyèsí sí àwọn ìṣesí àti ìwà tí ó lè fi èérí yí, tàbí kó àbààwọ́n bá, aṣọ tí a lè fi dá ẹnì kan mọ̀ débi pé, ẹni náà kò ní bá àpèjúwe alásọtẹ́lẹ̀ ti Ìṣípayá 7:9, 10 mu, láìka ohun tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀ lóde sí. (1 Peteru 1:15, 16) Ní títẹnumọ́ ohun tí a ti tẹ̀jáde ṣáájú, ní 1941 àti ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé e, Ilé-Ìṣọ́nà fi hàn léraléra pé yóò jẹ́ ohun tí kò yẹ rárá láti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn àti lẹ́yìn náà, nígbà tí a ko bá sí lẹ́nu iṣẹ́-òjíṣẹ́, kí a máa lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìwà bí àgbèrè tàbí panṣágà. (1 Tessalonika 4:3; Heberu 13:4) Ní 1947 ó tẹnumọ́ ọn pé ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa fún ìgbéyàwó Kristian ṣeé fi sílò ní gbogbo ilẹ̀; láìka ohun tí àṣà ìbílẹ̀ lè tẹ́wọ́gbà sí, àwọn wọnnì tí wọ́n ń bá a nìṣó láti máa kó obìnrin jọ kò lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa.—Matteu 19:4-6; Titu 1:5, 6.
8 Ní 1973, a fihan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa káàkiri àgbáyé pé gbogbo wọn gbọ́dọ̀ takété sí níní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú àwọn àṣà tí kò ṣeé sẹ́ pé ó lè sọni di aláìmọ́, irú bí àṣìlò tábà, láìka ibi yòówù tí wọ́n lè wà sí—kì í ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lẹ́nu iṣẹ́-ìsìn pápá nìkan ṣùgbọ́n lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ pẹ̀lú tàbí ní àwọn ibì kọ́lọ́fín kan tí kò bọ́ sí ojútáyé. (2 Korinti 7:1) Ní 1987 ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, a fún àwọn èwe Kristian ní ìmọ̀ràn lílágbára pé kí wọn baà lè di ìdúró mímọ́ tónítóní mú níwájú Ọlọrun, wọ́n gbọ́dọ̀ dènà gbígbé ìgbésí-ayé méjì. (Orin Dafidi 26:1, 4) Léraléra, Ilé-Ìṣọ́nà ti kìlọ̀ nípa onírúurú apá tí ẹ̀mí ayé pín sí nítorí pé “irú ọ̀nà-ètò ìjọsìn tí ó mọ́ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú-ìwòye Ọlọrun ati Baba wa” ní nínú lati pa ara ẹni mọ́ “láìní èérí kúrò ninu ayé.”—Jakọbu 1:27, NW.
9. Àwọn wo ni yóò dúró gẹ́gẹ́ bí ẹni ìtẹ́wọ́gbà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá náà?
9 Àwọn wọnnì tí ìgbàgbọ́ wọn sún wọn láti gbé ìgbésí-ayé ní ọ̀nà kan tí wọn yóò fi lè wà ní mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí àti níti ìwà-híhù ni yóò ṣì máa “dúró níwájú ìtẹ́” gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí kì í ṣe pé wọ́n wulẹ̀ bẹ̀rẹ̀ gbígbé ìgbésí-ayé Kristian nìkan ni ṣùgbọ́n tí wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin lo ìforítì nínú rẹ̀.—Efesu 4:24.
“Imọ̀ Ọ̀pẹ . . . Ní Ọwọ́ Wọn”
10. Kí ni ìjẹ́pàtàkì imọ̀ ọ̀pẹ tí Johannu rí lọ́wọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?
10 Lára àwọn ohun títayọ tí a rí lára ogunlọ́gọ̀ ńlá náà, gẹ́gẹ́ bí aposteli Johannu ti kíyèsí i, ni pé “imọ̀ ọ̀pẹ . . . ń bẹ ní ọwọ́ wọn.” Báwo ni ìyẹn ti ṣe pàtàkì tó? Kò sí iyèméjì pé àwọn imọ̀ ọ̀pẹ wọ̀nyẹn rán Johannu létí nípa ayẹyẹ àgọ́-àjọ ti àwọn Júù, ayẹyẹ onídùnnú ayọ̀ jùlọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò àwọn Heberu, tí wọ́n máa ń ṣe tẹ̀lé ìkórè ìgbà ẹ̀rùn. Ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, imọ̀ ọ̀pẹ, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka igi mìíràn, ní wọn máa ń lò láti pa àtíbàbà nínú èyí tí wọn yóò gbé lákòókò ayẹyẹ náà. (Lefitiku 23:39, 40; Nehemiah 8:14-18) Àwọn olùjọsìn ní tẹ́ḿpìlì tún máa ń jù wọ́n lákòókò kíkọ orin Haleli (Orin Dafidi 113 sí 118). Ó ṣeé ṣe kí jíju tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń ju imọ̀ ọ̀pẹ ti rán Johannu létí nípa àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà nígbà tí Jesu gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalemu nígbà tí ogunlọ́gọ̀ olùjọsìn ń fi pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ju imọ̀ ọ̀pẹ tí wọ́n sì ń kígbe pé: “Alábùkúnfún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jehofa, àní ọba Israeli!” (Johannu 12:12, 13, NW) Nítorí náà jíju imọ̀ ọ̀pẹ fihàn pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà fi pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ kókìkí Ìjọba Jehofa àti Ọba rẹ̀ tí ó fi òróró yàn.
11. Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun fi ń rí ìdùnnú-ayọ̀ nítòótọ́ nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa?
11 Irú ẹ̀mí onídùnnú-ayọ̀ kan náà ni ogunlọ́gọ̀ ńlá fihàn nísinsìnyí pàápàá bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́sin Jehofa. Èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n kò dojúkọ ipò ìṣòro tàbí pé wọn kò ní ìrírí ìbànújẹ́ tàbí ìrora. Ṣùgbọ́n ìtẹ́lọ́rùn tí ń wá láti inú ṣíṣiṣẹ́sìn àti ṣíṣe ohun tí ó dùn mọ́ Jehofa nínú ń ṣèrànwọ́ láti bo àwọn nǹkan wọnnì mọ́lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, míṣọ́nnárì kan tí ó ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ fún ọdún 45 ní Guatemala sọ nípa ipò tí kò báradé tí ó yí wọn ká, iṣẹ́ alágbára àti ìrìn-àjò tí ó léwu tí ó jẹ́ apákan ìgbésí-ayé bí wọ́n ṣe ń sapá láti mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà dé àwọn abúlé àwọn ará India. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó jẹ́ àkókò kan tí a láyọ̀ jùlọ nínú ìgbésí-ayé wa.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń nímọ̀lára ipa tí ọjọ́ ogbó àti àìlera ń ní lórí rẹ̀, lára àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ sínú ìwé àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ rẹ̀ ni pé: “Ó jẹ́ ìgbésí-ayé rere, tí ó sì ní èrè.” Káàkiri ilẹ̀-ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìmọ̀lára kan náà nípa iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn.
“Iṣẹ́-Ìsìn Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ . . . Tọ̀sán Tòru”
12. Yálà lọ́sàn-án tàbí lóru, kí ni Jehofa ń kíyèsí níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé?
12 Àwọn olùjọsìn onídùnnú-ayọ̀ wọ̀nyí ń ṣe “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀” fún Jehofa “tọ̀sán tòru.” (Ìṣípayá 7:15, NW) Káàkiri àgbáyé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ yìí. Nígbà tí ilẹ̀ bá ti ṣú ní àwọn ilẹ̀ kan tí àwọn ènìyàn sì ti sùn níbẹ̀, oòrun ń ta ní àwọn ilẹ̀ mìíràn ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì dí fún jíjẹ́rìí. Bí àgbáyé ti ń yípo, léraléra, tọ̀sán tòru, wọ́n ń kọ orin ìyìn sí Jehofa. (Orin Dafidi 86:9) Ṣùgbọ́n iṣẹ́-ìsìn tọ̀sán tòru tí a tọ́ka sí ní Ìṣípayá 7:15 túbọ̀ jẹ́ ti ara-ẹni.
13. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi ohun tí ó túmọ̀ sí láti ṣiṣẹ́sìn “tọ̀sán tòru” hàn?
13 Àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n parapọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tọ̀sán tòru. Èyí ha túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ni a lè wò gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ bí? Òtítọ́ ni pé láìka ohunkóhun tí wọ́n ń ṣe sí, wọ́n kọ́ láti máa ṣe é ní ọ̀nà tí yóò bọlá fún Jehofa. (1 Korinti 10:31; Kolosse 3:23) Bí ó ti wù kí ó rí, “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀” níí ṣe pẹ̀lú kìkì ohun tí ó bá kan ìjọsìn ẹni sí Ọlọrun ní tààràtà. Lílọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò kan “tọ̀sán tòru” dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ṣíṣe é lemọ́lemọ́ àti ṣíṣe é déédéé, bákan náà sì ni fífi ìsapá onítara ṣe é.—Fiwé Joṣua 1:8; Luku 2:37; Iṣe 20:31; 2 Tessalonika 3:8.
14. Kí ni yóò mú kí iṣẹ́-ìsìn pápá wa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan bá àpèjúwe iṣẹ́-ìsìn “tọ̀sán tòru” mu?
14 Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́sìn nínú àgbàlá ilẹ̀-ayé ti tẹ́ḿpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jehofa, àwọn wọnnì tí wọ́n parapọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá ń sakun láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá déédéé àti láti máa ṣe e lemọ́lemọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi ṣe góńgó wọn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn mìíràn ń lo ara wọn tokunra-tokunra gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà ọwọ́ àwọn wọ̀nyí máa ń dí fún jíjẹ́rìí ní òpópónà àti ní àwọn ilé-ìtajà ní òwúrọ̀ kùtù. Láti lè mú ara wọn bá ipò àwọn olùfìfẹ́hàn mu, àwọn Ẹlẹ́rìí kan máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní òru. Wọ́n ń jẹ́rìí nígbà tí wọ́n bá ń rajà, tí wọ́n bá ń rìnrìn-àjò, lákòókò oúnjẹ ọ̀sán, àti nípasẹ̀ tẹlifóònù.
15. Yàtọ̀ sí iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá, kí ni iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa ní nínú?
15 Kíkópa nínú àwọn ìpàdé ìjọ pẹ̀lú jẹ́ apákan iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa; bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ tí ó níí ṣe pẹ̀lú ilé kíkọ́ àti bíbójútó àwọn ibi tí a ń lò fún àpéjọ Kristian. Ó tún kan àwọn ìsapá tí a ń ṣe láti fún àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin wa ní ìṣírí àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́, nípa tẹ̀mí àti nípa tara, láti lè máa bá iṣẹ́-ìsìn wọn sí Jehofa nìṣó. Èyí ní iṣẹ́ àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé-Ìwòsàn nínú. Iṣẹ́-ìsìn Beteli ní onírúurú ẹ̀ka tí ó pín sí, àti iṣẹ́-ìsìn ìyọ̀ǹda ara-ẹni ní àwọn àpéjọpọ̀, ni gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀. Ní tòótọ́, nígbà tí a bá kọ́ ìgbésí-ayé wa yí ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa ká, wọ́n ń kún fún iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ṣe sọ, àwọn ènìyàn Jehofa ń ṣe “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ . . . tọ̀sán tòru,” wọ́n sì ń rí ìdùnnú-ayọ̀ ńláǹlà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.—Iṣe 20:35; 1 Timoteu 1:11.
‘Láti Inú Gbogbo Orílẹ̀-Èdè, Ẹ̀yà, Ènìyàn, àti Ahọ́n’
16. Báwo ni ó ṣe ń jásí òtítọ́ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń jáde wa “lati inú gbogbo orílẹ̀-èdè”?
16 Ogunlọ́gọ̀ ńlá yẹn ń rọ́ wá, láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè. Ọlọrun kì í ṣe ojúsàájú, ìpèsè ìràpadà tí a tipasẹ̀ Jesu Kristi pèsè sì tó láti ṣe gbogbo wọn láǹfààní. Nígbà tí a kọ́kọ́ dá ogunlọ́gọ̀ ńlá mọ̀ ní 1935 ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ aláápọn ní ilẹ̀ 115. Nígbà tí yóò fi di àwọn ọdún 1990, wíwá àwọn ẹni-bí-àgùtàn kiri ti tànkálẹ̀ dé àwọn ilẹ̀ tí ó ju ìyẹn lọ ní ìlọ́po méjì.—Marku 13:10.
17. Kí ni a ti ń ṣe láti ran àwọn ènìyàn láti inú gbogbo ‘ẹ̀yà, ènìyàn, àti ahọ́n’ lọ́wọ́ láti wà lára ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?
17 Láti lè wá àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ogunlọ́gọ̀ ńlá náà rí, kì í ṣe kìkì àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ ti orílẹ̀-èdè níkan ni àwọn Ẹlẹ̀rìí Jehofa ń pe àfiyèsí sí ṣùgbọ́n wọn tún ń pe àfiyèsí sí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ ti ẹ̀yà àti ènìyàn àti èdè tí ń bẹ nínú àwọn orílẹ̀-èdè náà pẹ̀lú. Láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn Ẹlẹ́rìí ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jáde ni iye tí ó lé ni 300 èdè. Èyí ní nínú dídá àwọn àgbájọ olùtúmọ̀ tí wọ́n dáńgájíá lẹ́kọ̀ọ́ àti bíbójútó wọn, pípèsè àwọn ohun-èlò kọ̀m̀pútà tí a lè fi ṣiṣẹ́ lé gbogbo èdè wọ̀nyí lórí, bákan náà sì ni ṣíṣe iṣẹ́ ìtẹ̀wé náà gan-an. Ní kìkì ọdún márùn-ún sẹ́yìn, a ti fi èdè 36, tí àwọn ènìyàn 98,000,000 ń sọ kún àwọn èdè tí a ń tú wọ̀nyí. Ní àfikún síi, àwọn Ẹlẹ́rìí ń sakun láti fúnra wọn bẹ àwọn ènìyàn wọ̀nyí wò láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—Matteu 28:19, 20.
“Lati Inú Ìpọ́njú Ńlá Naa”
18. (a) Nígbà tí ìpọ́njú ńlá náà bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn wo ni a óò dáàbòbò? (b) Ìpolongo aláyọ̀ wo ni a óò ṣe nígbà náà?
18 Nígbà tí àwọn áńgẹ́lì náà bá ju afẹ́fẹ́ apanirun tí a mẹ́nukàn nínú Ìṣípayá 7:1 sílẹ̀, kì í ṣe àwọn ẹni-àmì-òróró tí wọ́n jẹ́ “awọn ẹrú Ọlọrun wa” nìkan ni yóò ní ìrírí ààbò onífẹ̀ẹ́ ti Jehofa ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ó ti darapọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn tòótọ́ pẹ̀lú yóò ní ìrírí rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ fún aposteli Johannu, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá wọ̀nyẹn yóò “jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá naa” gẹ́gẹ́ bí olùlàájá. Ẹ wo irú igbe ìmọrírì àti ìyìn tí wọn yóò ké bí wọ́n ti ń polongo pé: “Ọlọrun wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa ni awa jẹ ní gbèsè fún ìgbàlà”! Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun ní ọ̀run yóò sì pa ohun pọ̀ pẹ̀lú wọn ní pípolongo pé: “Àmín! Ìbùkún ati ògo ati ọgbọ́n ati ìdúpẹ́ ati ọlá ati agbára ati okun ni fún Ọlọrun wa títí láé ati láéláé. Àmín.”—Ìṣípayá 7:10-14, NW.
19. Ìgbòkègbodò onídùnnú-ayọ̀ wo ni àwọn olùlàájá yóò háragàgà láti nípìn-ín nínú rẹ̀?
19 Ẹ wo irú àkókò aláyọ̀ tí ìyẹn yóò jẹ́! Gbogbo àwọn tí wọ́n bá wàláàyè yóò jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun òtítọ́ kanṣoṣo náà! Ìdùnnú-ayọ̀ títóbi jùlọ ti àwọn wọ̀nyí yóò jẹ́ ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Iṣẹ́ púpọ̀ yóò wà láti ṣe—iṣẹ́ onídùnnú-ayọ̀! A níláti sọ aye dí Paradise. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òkú ni a óò jí dìde tí a óò sì kọ́ ní àwọn ọ̀nà Jehofa. Ẹ wo irú àǹfààní onídùnnú-ayọ̀ tí yóò jẹ́ láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀!
Kí Ni O Rí Sọ Sí I?
◻ Ipa wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ 1935 ní lórí iṣẹ́-òjíṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
◻ Kí ni òtítọ́ náà pé a fi ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́” hàn fihàn?
◻ Báwo ni ìmọrírì fún ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn ṣe ń nípa lórí ìgbésí-ayé wa?
◻ Kí ni jíjù tí wọ́n ń ju imọ̀ ọ̀pẹ dúró fún?
◻ Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tọ̀sán tòru?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wọn ń fi ìṣedéédéé, aápọn, àti ìsapá onítara hàn