ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 7-9
Jèhófà Bù Kún Ogunlọ́gọ̀ Èèyàn Tí Ẹnikẹ́ni Kò Lè Kà
Kí nìdí tí Jèhófà fi bù kún ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà?
Wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́ [Jèhófà],” ìyẹn ni pé wọ́n gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé àti Ọ̀run
Wọ́n wọ “aṣọ funfun,” ìyẹn ni pé wọ́n jẹ́ mímọ́, Jèhófà sì kà wọ́n sí olódodo nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi
Wọ́n ń ṣe ‘iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tọ̀sántòru,’ ní ti pé wọn ò ṣíwọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe é tọkàntọkàn
Kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè wà lára ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà?