Báwo Ni O Ṣe Lè Mú Àdúrà Rẹ Sunwọ̀n Síi?
ÀDÚRÀ jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nínú àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun. Àwọn alátakò lè gbẹ́sẹ̀lé Bibeli rẹ tàbí kí wọ́n dí ọ lọ́wọ́ pípàdépọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó lè dí ọ lọ́wọ́ gbígbàdúrà. Àdúrà gbígbà ṣe pàtàkì púpọ̀. Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì tó, nígbà náà, fún wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan láti ṣìkẹ́ kí a sì mú àǹfààní yìí lò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú àdúrà rẹ sunwọ̀n síi?
Bibeli kì í ṣe ìwé àdúrà. Síbẹ̀, a lè ṣàpèjúwe rẹ̀ bí ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ gíga jùlọ tí aráyé ní lórí àdúrà. Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nìkan ní iye tí ó ju 150 àdúrà lọ. Àwọn kan kúrú; àwọn mìíràn sì gùn. Àwọn ọba tàbí àwọn ìgbèkùn, gba àwọn mìíràn ní gbangba tàbí ní ìkọ̀kọ̀, nínú ayọ̀-ìṣẹ́gun tàbí nínú ìpọ́njú. Gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti kọ nínú Orin Dafidi 65:2, “gbogbo ènìyàn” yíjú sí Jehofa, ‘Ẹni tí ń gbọ́ àdúrà.’ Èéṣe tí Ọlọrun fi mí sí àwọn òǹkọ̀wé Bibeli láti ṣe àkọsílẹ̀ àṣàyàn àdúrà tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀?
Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, gbé 2 Timoteu 3:16 yẹ̀wò. Ó sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní.” Nípa báyìí, àwọn àdúrà inú Bibeli wà níbẹ̀ láti ṣamọ̀nà wa, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀, ìlànà, àti ìtàn inú Ìwé Mímọ́ ti ṣe. Báwo ni àwọn àdúrà wọ̀nyí ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
Nípa wíwo àwọn àdúrà inú Ìwé Mímọ́ fínnífínní, a lè dá àwọn tí a gbà ní àwọn ipò tí ó jọ tiwa mọ̀. A lè kọ́ bí ète àti ọ̀nà ìgbékalẹ̀ àdúrà ti yàtọ̀ síra. Ní àfikún síi, a óò ṣàwárí àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn àti ìdúpẹ́ titun a óò sì rí àwọn ọ̀rọ̀ titun fún àwọn ìbéèrè-ẹ̀bẹ̀ àti ìrawọ́-ẹ̀bẹ̀ wa. Ní ṣókí, àwọn àdúrà inú Bibeli lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí àwọn àdúrà tiwa sunwọ̀n síi.
Maria, ẹni tí ó di ìyá Jesu, láìṣe àní-àní jẹ́ ẹnì kan tí ó jàǹfààní láti inú àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú àdúrà kan tí a kọ sínú Bibeli. Ó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìbátan rẹ̀ Elisabẹti lẹ́yìn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti lóyún ọmọkùnrin nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun. Maria sọ̀rọ̀ ìyìn àti ìdúpẹ́ sí Ọlọrun, díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tayọ lọ́lá ní ìjọra pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó wà nínú àdúrà inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Ó jọ bi ẹni pé Maria ti mọ àdúrà tí Hanna, ìyá wòlíì Samueli gbà ní àmọ̀dunjú. Ní èyí tí ó lé ní 1,000 ọdún ṣáájú, Hanna pẹ̀lú ti lóyún ọmọkùnrin kan pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun. Ó ha lè jẹ́ pé Maria ṣàṣàrò lórí àdúrà yìí nítorí pé ó fi ìmọ̀lára tirẹ̀ hàn bí?—1 Samueli 2:1-10; Luku 1:46-55.
Ìwọ ńkọ́? O ha lè rántí àdúrà kan nínú Bibeli tí a gbà lábẹ́ irú ipò tí ó jọ tìrẹ bí? Wíwá irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀, kíkà wọ́n, àti ṣíṣàṣàrò lórí wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọrun sunwọ̀n síi. Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e, a késí ọ láti ṣàyẹ̀wò àdúrà mẹ́ta láti inú Ìwé Mímọ́. A gbà wọ́n lábẹ́ àyíká ipò tí ó yàtọ̀síra, bóyá tí ó lè farajọ tìrẹ.