Àwọn Àdúrà Inú Bibeli Yẹ Ní Wíwò Fínnífínní
OBÌNRIN kan tí ń ṣàníyàn, ọba kan, àti Ọmọkùnrin Ọlọrun tìkára rẹ̀ ni wọ́n gba àwọn àdúrà tí a fẹ́ wò fínnífínní báyìí. Àyíká ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó fa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdúrà yìí. Síbẹ̀, irú àwọn ipò yìí lè nípa lórí wa lónìí. Kí ni a lè kọ́ láti inú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí?
“Bojúwo Ìpọ́njú Ìránṣẹ́bìnrin Rẹ”
O ha ń jìjàkadì pẹ̀lú ìṣòro tí kò dáwọ́ dúró bí? Tàbí àníyàn ha ti dẹ́rùpa ọ́ bí? Nígbà náà ipò rẹ jọra pẹ̀lú ti Hanna ṣáájú kí ó tó bí ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́, Samueli. Kò ní ọmọ, obìnrin mìíràn sì ń kẹ́gàn rẹ̀. Ní tòótọ́, ipò Hanna mú un bínú ó sì dà láàmú débi pé kò jẹun. (1 Samueli 1:2-8, 15, 16) Ó bẹ Jehofa ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí jáde:
“Oluwa àwọn ọmọ-ogun, bí ìwọ nítòótọ́ bá bojúwo ìpọ́njú ìránṣẹ́bìnrin rẹ, tí o sì rántí mi, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́bìnrin rẹ, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá fi ọmọkùnrin kan fún ìránṣẹ́bìnrin rẹ, nígbà náà ni èmi óò fi í fún Oluwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kì yóò sì kàn án lórí.”—1 Samueli 1:11.
Kíyèsíi pé Hanna kò sọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀ nǹkan. Ó bẹ Jehofa fún ohun kan pàtó (fún ọmọkùnrin kan) ó sì ti èyí lẹ́yìn pẹ̀lú ìpinnu kan pàtó (láti fi í fún Ọlọrun). Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa?
Nígbà tí o bá wà nínú ipò tí kò báradé, jẹ́ kí àdúrà rẹ ṣe pàtó. Ohun yòówù kí ìṣòro rẹ lè jẹ́—yálà ìṣòro ìdílé ni, ti ìdánìkanwà, tàbí ti àìlera—gbàdúrà sí Jehofa nípa rẹ̀. Ṣàlàyé fún un bí ìṣòro náà ti rí gan-an kí o sì sọ ìmọ̀lára rẹ. Opó kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Louise sọ pé: “Ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ ni mo máa ń kó gbogbo ìṣòro mi lé Jehofa. Nígbà mìíràn ìṣòro náà máa ń pọ̀, ṣùgbọ́n mo máa ń mẹ́nuba ìkọ̀ọ̀kan wọn ní kedere.”
Bíbá Jehofa sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó ṣe pàtó ń mú ọ̀pọ̀ àǹfààní lọ́wọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí ìṣòro wa ti rí, tí yóò sì jẹ́ kí ó dàbí èyí tí kò ṣòro púpọ̀. Ṣíṣe pàtó nínú àwọn àdúrà wa ń nà wá lọ́rùn kúrò nínú àníyàn. Kí a tó dáhùn àdúrà rẹ̀ pàápàá, ọkàn Hanna balẹ̀, “kò sì fa ojú ro mọ́.” (1 Samueli 1:18) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣíṣe pàtó ń jẹ́ kí a wà lójúfò sí ìdáhùn àwọn àdúrà wa. Bernhard, Kristian kan ní Germany, sọ pé: “Bí mo bá ti ṣe pàtó tó nínú ọ̀nà ìgbàdúrà mi, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdáhùn rẹ̀ yóò ti ṣe kedere tó.”
“Ọmọ Kékeré Ni Mí”
Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan lè ní ìmọ̀lára àníyàn tí ó yàtọ̀ bí ó bá gba iṣẹ́ àyànfúnni tí ó lérò pé òun kò tóótun láti ṣe. Ẹrù iṣẹ́ tí Jehofa fifún ọ ha máa ń bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà mìíràn bí? Àbí àwọn ènìyàn kan ha kà ọ́ sí ẹni tí kò tóótun fún àwọn iṣẹ́ àyànfúnni rẹ bí? Solomoni ọ̀dọ́ wà ní irú ipò náà nígbà tí a yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba Israeli. Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n yọrí ọlá faramọ́ kí ẹlòmíràn wà lórí àléfà. (1 Ọba 1:5-7, 41-46; 2:13-22) Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀, Solomoni bẹ̀bẹ̀ ohun kan nínú àdúrà rẹ̀:
“Oluwa Ọlọrun mi, ìwọ ti fi ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba . . . ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé. . . . Fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ, láti mọ ìyàtọ̀ rere àti búburú.”—1 Ọba 3:7-9.
Solomoni gbé àdúrà rẹ̀ karí ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jehofa, àǹfààní tí a fún un, àti agbára rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ àyànfúnni náà. Ní ọ̀nà kan náà, nígbàkigbà tí a bá fún wa ní ẹrù iṣẹ́ tí a lérò pé ó ju agbára wa lọ, a níláti bẹ Ọlọrun kí ó lè mú wa gbaradì láti ṣe iṣẹ́ náà. Gbé àwọn ìrírí tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí yẹ̀wò:
Eugene ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a ní kí n bójútó ẹrù iṣẹ́ tí ó pọ̀ síi ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Watch Tower Society, mo nímọ̀lára àìtóótun pátápátá. Àwọn mìíràn wà tí wọ́n tóótun jù mí lọ tí wọ́n sì ní ìrírí púpọ̀. N kò rí oorun sùn tó ní alẹ́ ọjọ́ méjì àkọ́kọ́, mo sì lo àkókò tí ó pọ̀ ní gbígbàdúrà, èyí tí ó fún mi ní okun àti ìdánilójú tí ó pọndandan.”
Roy ni a ní kí ó sọ ọ̀rọ̀ ìsìnkú lẹ́yìn ikú òjijì àti oníbànújẹ́ ti ọ̀dọ́mọkùnrin ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí ó gbajúmọ̀. Ó dájú pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn yóò wá síbẹ̀. Kí ni Roy ṣe? “N kò tí ì gbàdúrà danin-danin tó báyìí rí fún okun àti fún agbára láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ́ láti sọ àwọn èrò tí ń gbéniró kí n sì fúnni ní ìtùnú.”
Bí Ẹlẹ́dàá ti ‘ń ṣe àwọn nǹkan kánkán’ tí ètò-àjọ rẹ̀ sì ń gbèrú síi, àbájáde tí a lè retí ni pé púpọ̀ síi nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni a óò fún ní ẹrù-iṣẹ́. (Isaiah 60:22) Bí a bá ní kí o gba ìpín tí ó pọ̀ síi, ní ìdánilójú pé Jehofa yóò fún ọ ní ìrírí, ìdálẹ́kọ̀ọ́, tàbí agbára èyíkéyìí tí ìwọ kò ní. Tọ Ọlọrun lọ bí Solomoni ti ṣe, Òun yóò sì mú ọ gbaradì láti bójútó iṣẹ́ àyànfúnni náà.
“Kí Gbogbo Wọ́n Lè Jẹ́ Ọ̀kan”
Ipò kẹta tí ń wáyé lónìí ni ti ṣíṣojú fún àwùjọ nínú àdúrà. Nígbà tí a bá pè wá láti ṣojú fún àwọn ènìyàn nínú àdúrà, kí ni a níláti gbàdúrà fún? Gbé àdúrà Jesu tí a kọ sínú Johannu orí 17 yẹ̀wò. Ó gba àdúrà yìí níṣojú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní alẹ́ tí ó lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Irú ìrawọ́-ẹ̀bẹ̀ wo ni ó darí sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ọ̀run?
Jesu tẹnumọ́ góńgó àjùmọ̀ní àti ìrètí tí àwọn wọnnì tí wọ́n pésẹ̀ jọ ní. Ó mẹ́nukan ìṣelógo orúkọ Jehofa Ọlọrun àti sísọ Ìjọba rẹ̀ di mímọ̀. Jesu tẹnumọ́ ìníyelórí ìbátan ipò ara-ẹni pẹ̀lú Bàbá àti Ọmọkùnrin, tí a gbé karí ìmọ̀ Ìwé Mímọ́. Ó sọ̀rọ̀ nípa yíya ara-ẹni sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, èyí tí yóò múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún àtakò. Kristi tún bẹ Bàbá rẹ̀ láti dáàbòbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kí ó sì mú wọn ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́.
Bẹ́ẹ̀ni, Jesu tẹnumọ́ ìṣọ̀kan. (Johannu 17:20, 21) Ṣáájú ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti bá ara wọn jiyàn bí ọmọdé. (Luku 22:24-27) Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àdúrà, Kristi kò wá bí yóò ti dá ẹ̀bi fún wọn ṣùgbọ́n bí yóò ti mú wọn ṣọ̀kan. Ní ọ̀nà kan náà àwọn àdúrà ìdílé àti ti ìjọ gbọ́dọ̀ gbé ìfẹ́ ró kí ó sì wá ojútùú sí bíborí aáwọ̀ láàárín ẹnìkọ̀ọ̀kan. Àwọn tí a ń ṣojú fún ni a gbọ́dọ̀ fà papọ̀ ní ìṣọ̀kan.—Orin Dafidi 133:1-3.
Ìṣọ̀kan yìí ni a fi hàn nígbà tí àwọn tí ń tẹ́tísílẹ̀ bá sọ pé, “Àmín,” tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí,” ní ìparí. Kí èyí ba lè ṣeé ṣe, ó níláti yé wọn kí wọ́n sì faramọ́ gbogbo ohun tí a sọ. Nígbà náà, kì yóò bá a mu láti mẹ́nukan kókó kan nínú àdúrà tí àwọn kan tí wọ́n pésẹ̀ kò mọ̀ nípa rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, alàgbà kan tí ó ń ṣíwájú ìjọ nínú àdúrà lè béèrè fún ìbùkún Jehofa lórí arákùnrin tàbí arábìnrin kan nípa tẹ̀mí tí ara rẹ̀ kò yá gan-an. Ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó bójúmu yóò jẹ́ ohun tí ó dára jù bí ó bá ṣe èyí kìkì bí èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn tí òun ń ṣojú fún bá mọ ẹni náà tí wọ́n sì ti gbọ́ nípa àmódi náà.
Pẹ̀lúpẹ̀lù, kíyèsí i pé Jesu kò to àìní àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ náà níkọ̀ọ̀kan. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kì bá ti túmọ̀ sí mímẹ́nukan àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí tí ó jẹ́ pé kìkì àwọn kan ni wọ́n mọ̀ ọ́n. Àwọn ọ̀rọ̀ ara ẹni jẹ́ kókó tí ó yẹ fún àdúrà ìkọ̀kọ̀, èyí tí a lè ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ àti ní yékéyéké tó bí a bá ti fẹ́ ẹ.
Báwo ni ẹnì kan ṣe lè múra ara rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣojú nínú àdúrà fún àwùjọ àwọn olùjọsìn tí ó pọ̀? Kristian onírìírí kan ṣàlàyé pé: “Mo máa ń ronú ṣáájú nípa ohun tí n óò dúpẹ́ fún, àwọn ìbéèrè ẹ̀bẹ̀ tí àwọn arákùnrin lè ní, àti àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mo lè mẹ́nukàn fún wọn. Èmi yóò to àwọn èrò mi, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn, lẹ́sẹẹsẹ lọ́kàn mi. Ṣáájú kí n tó gbàdúrà ní gbangba, mo máa ń gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́jẹ́, ní bíbéèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti lè ṣojú fún àwọn arákùnrin ní ọ̀nà tí ó mú iyì wá.”
Àyíká ipò yòówù kí tìrẹ jẹ́, ó ṣeé ṣe kí o rí àdúrà kan nínú Bibeli tí ẹnì kan ti gbà ní irú ipò tí ó jọ tìrẹ. Bí àdúrà ti gbòòrò tó nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ ẹ̀rí inúrere-ìfẹ́ Ọlọrun. Kíka àwọn àdúrà wọ̀nyí àti ṣíṣàṣàrò lé wọn lórí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú àwọn àdúrà rẹ sunwọ̀n síi.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
ÀWỌN ÀDÚRÀ TÍ Ó GBA ÀFIYÈSÍ NÍNÚ BIBELI
Àwọn ìránṣẹ́ Jehofa gbàdúrà lábẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyíká ipò. O ha lè rí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó jẹ mọ́ ọ lára àwọn ipò tí ó tẹ̀lé e yìí?
Ìwọ ha nílò ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, bí Elieseri ti ṣe bi?—Genesisi 24:12-14.
Ìwọ ha wà nínú ewu tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀, bíi ti Jakọbu bí?—Genesisi 32:9-12.
Ìwọ ha fẹ́ láti túbọ̀ mọ Ọlọrun síi, bí Mose ti ṣe bí?—Eksodu 33:12-17.
Ìwọ ha dojúkọ àwọn alátakò, bíi ti Elijah bí?—1 Ọba 18:36, 37.
Ìwàásù ha ṣòro fún ọ, bí ó ti rí fún Jeremiah bí?—Jeremiah 20:7-12.
Ìwọ ha níláti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kí o sì tọrọ ìdáríjì, bí Danieli ti ṣe bí?—Danieli 9:3-19.
Ìwọ ha dojúkọ inúnibíni, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ti ṣe bí?—Ìṣe 4:24-31.
Tún wo Matteu 6:9-13; Johannu 17:1-26; Filippi 4:6, 7; Jakọbu 5:16.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
OHUN TÍ A NÍLÁTI GBÀDÚRÀ FÚN NÍGBÀ TÍ A BÁ Ń WỌ̀YÁ-ÌJÀ PẸ̀LÚ ÀṢÀ TÍ Ó TI MỌ́RA
Ìwọ ha ń bá àìlera tí ń ṣẹlẹ̀ léraléra jìjàkadì bí? Báwo ni àwọn àdúrà tí a kọ sílẹ̀ nínú Bibeli ṣe lè ṣàǹfààní? Kẹ́kọ̀ọ́ lára Dafidi, ẹni tí ó gbàdúrà ní onírúurú ìgbà nípa àwọn àìlera òun tìkára rẹ̀.
Dafidi kọrin pé: “Ọlọrun, wádìí mi, kí o sì mọ àyà mi: dán mi wò, kí o sì mọ ìrò-inú mi.” (Orin Dafidi 139:23) Ó jẹ́ ìfẹ́-ọkàn Dafidi pé kí Jehofa Ọlọrun ṣàwárí àwọn ìfẹ́-ọkàn, èrò-ìmọ̀lára, tàbí ìsúnniṣe tí kò tọ́. Ní èdè mìíràn, Dafidi wá ìrànlọ́wọ́ Jehofa nínú yíyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀.
Ṣùgbọ́n àìlera Dafidi borí rẹ̀, ó sì dẹ́ṣẹ̀ gidigidi. Níhìn-ín lẹ́ẹ̀kan síi, àdúrà ràn án lọ́wọ́—ní àkókò yìí láti mú ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun padàbọ̀sípò. Gẹ́gẹ́ bí Orin Dafidi 51:2 ti sọ, Dafidi bẹ̀bẹ̀ pé: “Wẹ̀ mí ní àwẹ̀mọ́ kúrò nínú àìṣedéédéé mi, kí o sì wẹ̀ mí nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.”
Àwa pẹ̀lú lè fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà fún ìrànwọ́ Jehofa láti baà lè dènà àwọn èrò tí kò tọ́. Èyí yóò fún wa lókun láti borí àìlera tí ó ti mọ́ra ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀. Bí àṣà náà bá tún padà wáyé, a níláti tún tọ Jehofa lọ pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá ìjà náà nìṣó.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn àdúrà tí a gbà nítìtorí àwùjọ gbọ́dọ̀ tẹnumọ́ àwọn ìrètí tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ àti àwọn góńgó tẹ̀mí tí a jùmọ̀ ní