Ìwọ Yóò Ha Yin Jehofa Bí?
“ỌLỌRUN, gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìyìn rẹ dé òpin ayé.” Àwọn ọ̀rọ̀ orin alásọtẹ́lẹ̀ tí àwọn ọmọkùnrin Kora kọ nìyí. (Orin Dafidi 48:10) Lónìí, ègbè orin ńláǹlà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń yin Ọlọrun wọ́n sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ nípa wíwàásù ìhìnrere Ìjọba rẹ̀. Nípa ṣíṣe èyí ní 232 ilẹ̀ àti erékùṣù òkun àti ní àwọn èdè tí ó lé ní 300, ní ìtumọ̀ olówuuru wọ́n ń dé “òpin ayé.”
Kí ni ohun náà tí ń sọ ọ di ọ̀ranyàn fún àwọn ènìyàn tí ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀síra níti ìṣẹ̀dálẹ̀, ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, àti èdè láti máa yin Jehofa? Ìdí pàtàkì ni ìmoore wọn fún ìmọ̀ pípéye nípa Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Òtítọ́ tẹ̀mí ti sọ wọ́n dòmìnira kúrò nínú ìgbàgbọ́ ohun asán àti kúrò nínú oko-ẹrú ìgbàgbọ́ ìsìn irú bí ìdálóró ayérayé. (Johannu 8:32) Òtítọ́ náà tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn àgbàyanu ànímọ́ Ọlọrun, irú bí ìfẹ́, agbára, ọgbọ́n, àti ìdájọ́-òdodo tí a fi àánú pẹ̀rọ̀ sí. Yíyọ̀ọ̀da tí Ọlọrun yọ̀ọ̀da Ọmọkùnrin rẹ̀ kanṣoṣo, Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà fún aráyé ń sún àwọn ènìyàn ọlọ́kàn títọ́ láti máa yin Jehofa kí wọ́n sì máa sìn ín.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìṣípayá nínú Bibeli ti sọ, ègbè orin ní ọ̀run ké ní ohùn rara pé: “Jehofa, àní Ọlọrun wa, iwọ ni ó yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbára, nitori pé iwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati nitori ìfẹ́-inú rẹ ni wọ́n ṣe wà tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Irú ìyìn bẹ́ẹ̀ kì í ṣàdédé wá láti inú nínímọ̀lára iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń jẹyọ láti inú ọ̀wọ̀-ńlá fún Jehofa.
Yin Ọlọrun Nípa Pípolongo Ìhìnrere
Nígbà tí ó bá ń yin Jehofa, ẹnì kan ń ṣàfarawé àpẹẹrẹ gígalọ́lá ti Jesu Kristi, olórí olùyin Ọlọrun. Títẹ̀lé ipasẹ̀ Jesu ní nínú lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. (Matteu 4:17, 23; 24:14) Ìgbòkègbodò wíwàásù yìí ti di ìsapá ńláǹlà tí ó kárí-ayé ní yíyin Jehofa.
Iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣe pàtàkì débi pé kedere ni Bibeli so ó pọ̀ mọ́ ìgbàlà. Romu 10:13-15 kà pé: “‘Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jehofa ni a óò gbàlà.’ Bí ó ti wù kí ó rí, bawo ni wọn yoo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe lo ìgbàgbọ́ ninu ẹni tí wọn kò gbọ́ nipa rẹ̀? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe gbọ́ láìsí ẹni kan lati wàásù? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe wàásù láìjẹ́ pé a ti rán wọn jáde? Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ awọn wọnnì tí ń polongo ìhìnrere awọn ohun rere ti dára rèǹtè-rente tó!’”
Ní ọdún tí ó kọjá nìkan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ya iye tí ó lé ní billion kan wákàtí sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ sì wo irú ìyọrísí dáradára tí ó ti inú yíyin Ọlọrun lọ́nà yìí jáde! Nǹkan bíi 314,000 darapọ̀ mọ́ ègbè orin àwọn olùyìn náà nípa fífi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn fún Jehofa hàn nípa ìrìbọmi.
Síbẹ̀, kí ni a lè sọ nípa nǹkan bíi 12,288,917 tí ó pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi ti 1994? Iye tí ó lé ní 7,000,000 ń bẹ lára wọn tí kò tí ì máa yin Jehofa gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ìhìnrere. Ṣùgbọ́n wíwà níbẹ̀ wọn ní ibi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí lè yọrí sí fífi àràádọ́ta ọ̀kẹ́ kún ègbè orin àwọn olùyìn náà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kí ni a lè ṣe láti ran àwọn olùfìfẹ́hàn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti di olùyin Jehofa?
Ìrànlọ́wọ́ Tí Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
Ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn lè ní ìfẹ́-ọkàn láti yin Jehofa ṣùgbọ́n kí wọ́n nímọ̀lára pé àwọn kò lè dójú ìlà ohun tí a béèrè fún. Ó dára kí wọ́n rántí àwọn ọ̀rọ̀ onipsalmu náà pé: “Èmi óò gbé ojú mi sí orí òkè wọnnì, níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá? Ìrànlọ́wọ́ mi ti ọwọ́ Oluwa wá, tí ó dá ọ̀run òun ayé.” (Orin Dafidi 121:1, 2) Ó hàn gbangba pé, onipsalmu náà gbé ojú rẹ̀ sí àwọn òkè Jerusalemu níbi tí tẹ́ḿpìlì Jehofa wà tí ó sì jẹ́ ibùjókòó Ìṣàkóso Ọlọrun. Láti inú èyí ó tọ̀nà láti parí èrò pé ìrànlọ́wọ́ tí a nílò láti yin Ọlọrun àti láti polongo ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà ń wá kìkì láti ọ̀dọ̀ Jehofa àti ètò-àjọ rẹ̀.—Orin Dafidi 3:4; Danieli 6:10.
Lónìí, àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ yin Jehofa lè retí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ ètò-àjọ rẹ̀ ti orí ilẹ̀-ayé. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ nípa dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí ní nínú ju wíwulẹ̀ kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Bibeli lásán lọ. Ó ń ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mú ìmọrírì dàgbà fún ohun tí ó ń kọ́ àti fún ètò-àjọ tí Jehofa ń lò.
Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ń gbìyànjú láti rí i dájú pé òtítọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà wọ inú ọkàn-àyà wọn kì í ṣe orí lásán. Olùkọ́ náà kò sì gbọdọ̀ fàsẹ́yìn ní fífihan akẹ́kọ̀ọ́ náà bí Jehofa ṣe ń lo ètò-àjọ Rẹ̀ láti ṣàṣeparí ète Rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Ìwé pẹlẹbẹ náà Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé àti fídíò náà Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name (Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—Ètò-Àjọ Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Náà) ti pèsè ìrànlọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà láti ṣàṣeparí èyí.
Àwọn ìpàdé Kristian pẹ̀lú ń kó ipa tí ó ṣe kókó nínú ríran àwọn wọnnì tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di olùyin Jehofa lọ́wọ́. Nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a lè késí akẹ́kọ̀ọ́ láti wá sí àwọn ìpàdé Kristian. Bí àkókò ti ń lọ, òun yóò kọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwá sí gbogbo àwọn ìpàdé ìjọ déédéé àti kíkópa nínú wọn. (Heberu 10:24, 25) Àwọn alábòójútó lè pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ó níyelórí gan-an fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di olùyin Jehofa nípa ṣíṣe ìmúrasílẹ̀ àwọn ìpàdé tí ó ń gbéniró nípa tẹ̀mí tí ó sì ṣeé múlò.
Ran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Yin Jehofa
Àwọn ọmọ wà lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di akéde ìhìnrere ní ẹ̀yìn ọ̀la. Àwọn bàbá ní pàtàkì ní ẹrù-iṣẹ́ tí ó bá Bibeli mú láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4) Nígbà tí àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọrun bá kọ́ wọn dáradára, àwọn ọmọ tí wọ́n kéré gan-an pàápàá lè mú ìfẹ́-ọkàn láti yin Jehofa dàgbà.
Ọmọdébìnrin kékeré kan ní Argentina tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ léraléra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ wọn kí òun baà lè tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn òbí rẹ̀ àti àwọn alàgbà fohùnṣọ̀kan láti yọ̀ọ̀da fún un kí ó di akéde aláìṣèrìbọmi. Ó ti ń gbé ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹ́lẹ̀. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún márùn-ún péré ni ọmọdébìnrin kékeré yìí tí kò sì lè kàwé, ó ti há ibi tí àwọn ẹsẹ Bibeli mélòókan wà sórí. Lẹ́yìn tí ó bá ti wá ẹsẹ ìwé mímọ́ kan rí, yóò ní kí onílé náà kà á, lẹ́yìn náà yóò sì ṣàlàyé.
Ó ṣe kedere pé àwọn alàgbà àti àwọn òbí lápapọ̀ lè ṣàṣeparí ohun púpọ̀ nípa fífún àwọn wọnnì tí ń tẹ̀síwájú síhà dídi olùyin Jehofa ní ìṣírí kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.—Owe 3:27.
Ipò-Ìbátan Wíwà Títíláé Pẹ̀lú Jehofa
Síbẹ̀, bí ìwọ fúnra rẹ bá ti ń darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún ìgbà díẹ̀ ńkọ́ ṣùgbọ́n tí o kò tí ì darapọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn? Ó lè ṣàǹfààní láti béèrè àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé e yìí lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Mo ha gbàgbọ́ pé mo ti rí òtítọ́ àti pé Jehofa ni Ọlọrun òtítọ́ kanṣoṣo náà bí? Ó ha dá mi lójú pé Ìjọba Ọlọrun ni ojútùú kanṣoṣo sí ìṣòro aráyé bí? Mo ha ti pa gbogbo ìsìn èké àti àṣà àti ìṣe ayé tí ń bí Jehofa nínú tì bí? Mo ha ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Ọlọrun àti fún àwọn ohun òdodo tí òun ń béèrè fún bí?’ (Orin Dafidi 97:10) Bí o bá lè dáhùn bẹ́ẹ̀ni sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láìlábòsí-ọkàn, kí ní ń dí ọ lọ́wọ́ láti máṣe yin Jehofa?—Fiwé Ìṣe 8:36.
Yíyin Jehofa ní nínú ju wíwàásù ìhìnrere lọ. Bí o bá ti gba ìmọ̀ pípéye sínú, tí o ní ìgbàgbọ́ tòótọ́, tí o sì ń mú ìgbésí-ayé rẹ bá àwọn ohun tí Ọlọrun ń béèrè fún mu, o níláti mú kí ipò-ìbátan ara-ẹni rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun fẹsẹ̀múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Lọ́nà wo? Nípa yíya ara rẹ sí mímọ́ fún un nínú àdúrà lẹ́yìn náà kí o sì fi àpẹẹrẹ èyí hàn nípa ìrìbọmi nínú omi. Ìyè àìnípẹ̀kun kò ṣeé fi tàfàlà. Nítorí náà, gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí lórí ìmọ̀ràn Jesu pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nitori fífẹ̀ ati aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà naa tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni awọn ẹni tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé tóóró ni ẹnubodè naa ati híhá ni ojú ọ̀nà naa tí ó lọ sínú ìyè, ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni awọn ẹni tí ń rí i.”—Matteu 7:13, 14.
Pẹ̀lú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí tí ń súnmọ́ òpin alájàálù rẹ̀, kì í ṣe àkókò nìyí láti máa lọ́tìkọ̀. Gbé ìgbésẹ̀ ojú-ẹsẹ̀ síhà ipò-ìbátan ayérayé pẹ̀lú Jehofa. Níti tòótọ́, àkókò náà nìyí láti dáhùnpadà lọ́nà rere sí ìbéèrè náà pé, Ìwọ yóò ha yin Jehofa bí?