ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/15 ojú ìwé 24-28
  • “Ẹ . . . Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Awọn Farisi ati Awọn Sadusi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ . . . Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Awọn Farisi ati Awọn Sadusi”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìṣọ̀kan Ìsìn
  • Àwọn Farisi
  • Wọ́n Jẹ́ Aṣàyípadà Ìsìn
  • Ìgbẹ́sẹ̀lófin
  • Àwọn Sadusi
  • Àwọn Olùṣenúnibíni sí Jesu àti Àwọn Ọmọlẹ́yìn Rẹ̀
  • Àìní Fún Bíbá A Lọ Láti Máa Wà Lójúfò
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • ‘Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jesu Fi Awọn Alátakò Rẹ̀ Bú
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ó Mú Kí Búrẹ́dì Pọ̀, Ó sì Kìlọ̀ Nípa Ìwúkàrà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/15 ojú ìwé 24-28

“Ẹ . . . Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Awọn Farisi ati Awọn Sadusi”

NÍGBÀ tí Jesu Kristi sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní èyí tí ó lé ní ọ̀rúndún 19 sẹ́yìn, ó ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lójúfò sí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìṣe ìsìn èké tí ó lè panilára. (Matteu 16:6, 12) Àkọsílẹ̀ Marku 8:15 sọ ní pàtó pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà awọn Farisi ati ìwúkàrà Herodu.” Èéṣe tí a fi mẹ́nukan Herodu? Nítorí pé àwọn kan lára àwọn Sadusi jẹ́ alátìlẹ́yìn Herodu, àwùjọ àwọn olóṣèlú kan.

Èéṣe tí irú ìkìlọ̀ àrà-ọ̀tọ̀ báyìí fi pọndandan? Àwọn Farisi àti Sadusi kìí ha íṣe alátakò paraku fún Jesu bí? (Matteu 16:21; Johannu 11:45-50) Bẹ́ẹ̀ni, ohun tí wọ́n jẹ́ nìyẹn. Síbẹ̀, àwọn kan nínú wọn níkẹyìn yóò tẹ́wọ́gba ìsìn Kristian wọn yóò sì gbìyànjú nígbà náà láti kan èrò tiwọn nípá lé ìjọ Kristian lórí.—Ìṣe 15:5.

Ewu náà tún wà pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn fúnra wọn lè farawé àwọn aṣáájú ìsìn lábẹ́ agbára ìdarí àwọn tí a ti tọ́ wọn dàgbà. Nígbà mìíràn, títi inú ipò ìdìdelẹ̀ bẹ́ẹ̀ wá ti yọrí sí ohun tí ń dènà lílóye kókó ohun tí Jesu ń kọ́ wọn.

Kí ló mú àṣà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi léwu tóbẹ́ẹ̀? Wíwo ipò àwọn ìsìn ní ọjọ́ Jesu yóò fún wa ní òye díẹ̀.

Àìṣọ̀kan Ìsìn

Òpìtàn Max Radin kọ̀wé nípa àpapọ̀ àwùjọ àwọn Júù ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní pé: “Ìdádúró lómìnira ìjọ àwọn Júù kúrò lọ́dọ̀ ara wọn jẹ́ òtítọ́ gan-an, wọ́n sì fi dandan lé e pẹ̀lú. . . . Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nígbà tí wọ́n bá tẹnumọ́ ọ̀wọ̀ fún tẹ́ḿpìlì àti ìlú mímọ́ náà gidigidi, ìyọṣùtì tí ó gbóná ni a lè fi hàn sí àwọn aláṣẹ gíga jùlọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ní orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ wọn.”

Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ipò tẹ̀mí tí ó baninínújẹ́ nítòótọ́! Kí ni àwọn ohun tí ó ṣokùnfà èyí? Kì í ṣe gbogbo àwọn Júù ni ó gbé ní Palestine. Àṣà ìbílẹ̀ Griki, nínú èyí tí àwọn àlùfáà kì í tií ṣe olórí àpapọ̀ àwùjọ, ti nípa ìdarí lórí jíjin ọ̀wọ̀ fún ètò tí Jehofa ṣe nípa ipò àlùfáà lẹ́sẹ̀. (Eksodu 28:29; 40:12-15) Àwọn tí a kò sì tún níláti gbójúfò ni àwọn gbáàtúù àti àwọn akọ̀wé tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé.

Àwọn Farisi

Orúkọ náà Farisi, tàbí Peru·shimʹ, ṣeé ṣe kí ó túmọ̀ sí “àwọn tí wọ́n ya ara sọ́tọ̀.” Àwọn Farisi ka ara wọn sí ọmọlẹ́yìn Mose. Wọ́n dá ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, tàbí ẹgbẹ́ awo tiwọn sílẹ̀ (chavu·rahʹ, ní èdè Heberu). Kí ẹnì kan tó lè di ọmọ ẹgbẹ́, ó níláti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú àwọn mẹ́ḿbà mẹ́ta pé òun yóò máa fìṣọ́ra kíyèsí ìmọ́gaara òfin àwọn ọmọ Lefi, òun yóò máa yẹra fún kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ʽam-ha·ʼaʹrets (àwọn ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n jẹ́ púrúǹtù), àti pé òun yóò máa ṣe fínnífínní-dórí-bíńtín níti sísan ìdá mẹ́wàá. Marku 2:16 sọ̀rọ̀ nípa “awọn akọ̀wé òfin ti awọn Farisi.” Ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ yìí jẹ́ àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn olùkọ́ tí wọ́n kọ́ṣẹ́mọṣẹ́, nígbà tí àwọn yòókù jẹ́ àwọn gbáàtúù.—Matteu 23:1-7.

Àwọn Farisi gbàgbọ́ nínú Ọlọrun kan tí ó wà níbi gbogbo. Wọ́n ronú pé níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “Ọlọrun wà níbi gbogbo, a lè sìn Ín nínú tàbí níta Tẹ́ḿpìlì, a kò sì gbọdọ̀ gbàdúrà sí i nípa ẹbọ rírú nìkan. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n gba sinagọgu gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn, ibi ìkẹ́kọ̀ọ́, àti ibi àdúrà, wọ́n sì gbé e ga sí ipò tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn tí ó sì ṣe pàtàkì nínú ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn tí ń bá Tẹ́ḿpìlì náà díje.”—Encyclopaedia Judaica.

Àwọn Farisi kò ní ọ̀wọ̀ fún tẹmpili Jehofa. Èyí ni a lè rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú afinimọ̀nà, tí ó wí pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá fi tẹmpili búra, kò ṣe nǹkankan; ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹmpili búra, ó wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe.’ Ẹ̀yin òmùgọ̀ ati afọ́jú! Èwo, níti tòótọ́, ni ó tóbi jù, wúrà ni tabi tẹmpili tí ó sọ wúrà di mímọ́? Pẹ̀lúpẹ̀lù, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá fi pẹpẹ búra, kò ṣe nǹkankan; ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe.’ Ẹ̀yin afọ́jú! Èwo, níti tòótọ́, ni ó tóbi jù, ẹ̀bùn ni tabi pẹpẹ tí ó sọ ẹ̀bùn di mímọ́? Nitori naa ẹni tí ó bá fi pẹpẹ búra ń fi í búra ati ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀.”—Matteu 23:16-20.

Báwo ni ìrònú àwọn Farisi ṣe lọ́ báyìí? Kí ni wọ́n ń gbójúfòdá? Kíyèsí ohun tí Jesu sọ tẹ̀lé e. “Ẹni tí ó bá sì fi tẹmpili búra ń fi í búra ati ẹni tí ń gbé inú rẹ̀.” (Matteu 23:21) Nípa ẹsẹ yìí, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ E. P. Sanders ṣàkíyèsí pé: “Tẹ́ḿpìlì náà jẹ́ mímọ́ kì í ṣe kìkì nítorí pé Ọlọrun mímọ́ ni a ń jọ́sìn níbẹ̀, bíkòṣe nítorí pé ó wà níbẹ̀.” (Judaism: Practice and Belief, 63 BCE—66 CE) Bí ó ti wù kí ó rí, wíwàníbẹ̀ lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀ Jehofa kì yóò níye lórí tóbẹ́ẹ̀ fún àwọn tí wọ́n rò pé ó wà níbi gbogbo.

Àwọn Farisi tún gbàgbọ́ nínú ìdàpọ̀ kádàrá pẹ̀lú òmìnira ìfẹ́-inú. Ní èdè mìíràn, “ohun gbogbo ni a ti yàn tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ a tún fún ni ní òmìnira yíyàn.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ wọ́n gbàgbọ́ pé Adamu àti Efa ni a ti kádàrá láti dẹ́ṣẹ̀ àti pé ọgbẹ́ kékeré ní ọmọ-ìka ní a ti kádàrá rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Jesu lè ti ní irú èrò tí ó jẹ́ èké yìí lọ́kàn nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìwólulẹ̀ ilé-ìṣọ́ kan tí ó yọrí sí ikú àwọn 18. Ó béèrè pé: “Ṣé ẹ̀yin lérò pé a fi [awọn òjìyà ìpalára náà] hàn ní ajigbèsè ju gbogbo awọn ènìyàn mìíràn tí ń gbé ní Jerusalemu lọ ni?” (Luku 13:4) Gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń jẹ́ òtítọ́ nípa jàm̀bá tí ó pọ̀ jùlọ, èyí jẹ́ àbájáde “ìgbà àti [èèṣì],” kì í ṣe àyànmọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Farisi ti fi kọ́ni. (Oniwasu 9:11) Báwo ni àwọn bẹ́ẹ̀ tí a retí pé kí wọ́n ní ìmọ̀ yóò ṣe mójútó àwọn òfin Ìwé Mímọ́?

Wọ́n Jẹ́ Aṣàyípadà Ìsìn

Àwọn Farisi rinkinkin mọ́ ọn pé àwọn òfin Ìwé Mímọ́ ni àwọn rabi ìran kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ túmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìsọfúnni tí ó dé kẹ́yìn. Nípa báyìí, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pé “wọn kò ní ìṣòro púpọ̀ ní mímú àwọn ẹ̀kọ́ Torah bá àwọn ìsọfúnni wọn tí ó dé kẹ́yìn mu, tàbí ní pípẹ́ àwọn ìsọfúnni wọn sọ tàbí mímẹ́nubà wọ́n nínú àwọn ọ̀rọ̀ Torah.”

Nípa ti Ọjọ́ Ètùtù ọlọ́dọọdún, wọ́n ta àtaré agbára ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ olórí àlùfáà wá sórí ọjọ́ náà fúnra rẹ̀. (Lefitiku 16:30, 33) Nígbà ayẹyẹ Ìrékọjá, wọ́n gbé ìtẹnumọ́ gíga jù karí kíka àwọn ẹ̀kọ́ inú Eksodu ní àkàtúnkà bí wọ́n ti ń mu ọtí wáìnì àti àkàrà aláìwù ju ti àgùtàn Ìrékọjá lọ.

Nígbà tí ó yá, àwọn Farisi di ẹni tí ń lo agbára ìdarí ní tẹmpili. Wọ́n wá ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ gbígbé omi láti odò adágún Siloamu ní alẹ́ ọjọ́ Àjọyọ̀ Ìkówọlé, títa omi náà sílẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, lílu igi willow mọ́ orí pẹpẹ ní òpin àjọyọ̀ náà, àti àdúrà déédéé lójoojúmọ́ tí kò ní ìpìlẹ̀ nínú Òfin.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Jewish Encyclopedia sọ pé: “Èyí tí ó ṣe pàtàkì gan-an” ni “àwọn àyípadà titun tí àwọn Farisi ṣe tí ó níí ṣe pẹ̀lú Ọjọ́ Ìsinmi.” Aya kan ni a retí pé kí ó fayọ̀ tẹ́wọ́gba Ọjọ́ Ìsinmi nípa títan àtùpà. Bí ó bá dàbíi pé àwọn ìgbòkègbodò kan yóò yọrí sí òpò tí kò bá òfin mu, àwọn Farisi yóò fi òfin dè é. Wọ́n tilẹ̀ lọ jìnnà débi ṣíṣòfin ìtọ́jú ìṣègùn wọ́n sì sọ ìbínú wọn jáde lórí iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi. (Matteu 12:9-14; Johannu 5:1-16) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ń ṣàyípadà ìsìn yìí kò fi mọ sórí ṣíṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ètò titun pẹ̀lú èrò láti ṣe ọgbà, tàbí odi, fún dídáàbòbo àwọn òfin Ìwé Mímọ́.

Ìgbẹ́sẹ̀lófin

Àwọn Farisi jẹ́wọ́ níní ọlá-àṣẹ láti dá àwọn òfin Ìwé Mímọ́ dúró tàbí láti fagilé e. Ìrònú wọn ni ó hàn nínú àṣàyàn ọ̀rọ̀ inú Talmud pé: “Ó sàn kí a fa òfin kan tu ju kí a gbàgbé òfin Torah lódindi.” Àpẹẹrẹ kan ni ti dídẹ́kun ṣíṣe Jubeli fún ìdí náà pé bí àkókò yẹn ti ń súnmọ́lé, kò sí ẹni tí yóò fẹ́ láti yá aláìní ní nǹkan nítorí ìbẹ̀rù pé ó lè pàdánù ẹ̀tọ́ rẹ̀.—Lefitiku, orí 25.

Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ni ti gbígbẹ́sẹ̀lé ìgbẹ́jọ́ obìnrin kan tí a fura sí pé ó ṣe panṣaga àti níti ọ̀ràn ìpànìyàn kan tí a kò yanjú, ìlànà ìwẹ̀nùmọ́ ni a patì. (Numeri 5:11-31; Deuteronomi 21:1-9) Díẹ̀ ni ó kù kí àwọn Farisi gbẹ́sẹ̀lé àwọn ohun tí a béèrè fún nínú Ìwé Mímọ́ níti pípèsè fún àwọn òbí ẹni tí wọ́n ṣe aláìní.—Eksodu 20:12; Matteu 15:3-6.

Jesu kìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà awọn Farisi, èyí tí í ṣe àgàbàgebè.” (Luku 12:1) Ìwà àwọn Farisi, pẹ̀lú ìṣẹ wọn tí kò bá ìlànà ìsàkóso Ọlọrun mu, láìṣe àní-àní jẹ́ àgàbàgebè—dájúdájú ohun tí kò yẹ kí a mú wọ inú ìjọ Kristian. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, iṣẹ́ ìtọ́kasí ti àwọn Júù sọ̀rọ̀ àwọn Farisi lọ́nà tí ó dára ju ti àwọn Sadusi lọ. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwùjọ alátakò ìyípadà ìgbàlódé yìí yẹ̀wò.

Àwọn Sadusi

Orúkọ náà Sadusi ni ó ṣeé ṣe kí a mú láti inú Sadoku, àlùfáà àgbà ní àwọn ọjọ́ Solomoni. (1 Ọba 2:35, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Àwọn Sadusi jẹ́ ẹgbẹ́ alátakò ìyípadà ìgbàlódé tí ń ṣojú fún ire tẹ́ḿpìlì àti ipò àlùfáà. Láìdàbí àwọn Farisi, tí wọ́n jẹ́wọ́ níní ọlá-àṣẹ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìfọkànsìn, àwọn Sadusi gbé ẹ̀tọ́ ipò wọn ka ìtàn ìlà ìdílé àti ipò. Wọ́n tako àwọn àyípadà titun tí àwọn Farisi ṣe títí di ìgbà ìparun tẹ́ḿpìlì ní 70 C.E.

Ní àfikún sí kíkọ àyànmọ́ sílẹ̀, àwọn Sadusi kọ̀ láti gba ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tí a kò mẹ́nukàn ní kedere nínú àwọn Ìwé Márùn-ún Mose, àní bí a bá tilẹ̀ sọ ọ́ ní ibòmíràn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Níti tòótọ́, wọ́n “kà á sí ìwà mímọ́ láti ṣawuyewuye lórí” àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. (The Jewish Encyclopedia) Èyí múni rántí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan nígbà tí wọ́n pe Jesu níjà lórí àjíǹde.

Ní lílo àkàwé opó ọlọ́kọ méje, àwọn Sadusi béèrè pé: “Ní àjíǹde, èwo ninu awọn méje náà ni oun yoo jẹ́ aya fún?” Àmọ́ ṣá o, opó wọn tí ó jẹ́ ìméfò lásán tilẹ̀ lè ti ní ọkọ 14 tàbí 21. Jesu ṣàlàyé pé: “Ní àjíǹde awọn ọkùnrin kì í gbéyàwó bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi awọn obìnrin fúnni ninu ìgbéyàwó.”—Matteu 22:23-30.

Ní mímọ̀ nípa kíkọ̀ tí àwọn Sadusi kọ àwọn òǹkọ̀wé mìíràn tí a mísí yàtọ̀ sí Mose, Jesu fi ìjótìítọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ hàn nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ láti inú àwọn Ìwé Márùn-ún Mose. Ó sọ pé: “Ṣugbọn níti awọn òkú, pé a gbé wọn dìde, ṣé ẹ̀yin kò kà ninu ìwé Mose, ninu ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ nipa igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún, bí Ọlọrun ṣe wí fún un pé, ‘Emi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jekọbu’? Oun kì í ṣe Ọlọrun awọn òkú, bíkòṣe ti awọn alààyè.”—Marku 12:26, 27.

Àwọn Olùṣenúnibíni sí Jesu àti Àwọn Ọmọlẹ́yìn Rẹ̀

Àwọn Sadusi ní ìgbàgbọ́ nínú lílo ọgbọ́n ìṣèlú nínú bíbá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lo dípò dídúró de Messia náà—bí wọ́n bá tilẹ̀ gbàgbọ́ nínú bíbọ̀ rẹ̀ rárá. Lábẹ́ àdéhùn pẹ̀lú Romu, àwọn ni ó níláti darí tẹ́ḿpìlì wọn kò sì fẹ́ kí Messia kankan wà níbẹ̀, láti dí àwọn ọ̀ràn lọ́wọ́. Ní wíwo Jesu gẹ́gẹ́ bí ewu fún ipò wọn, wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Farisi láti ṣekúpa á.—Matteu 26:59-66; Johannu 11:45-50.

Bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn òṣèlú, àwọn Sadusi fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ ìdúróṣinṣin wọn sí Romu jáde wọ́n sì kígbe pé: “Awa kò ní ọba kankan bíkòṣe Kesari.” (Johannu 19:6, 12-15) Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jesu, àwọn Sadusi ni wọ́n mú ipò iwájú nínú gbígbìyànjú láti dá ìtànkálẹ̀ ìsìn Kristian dúró. (Ìṣe 4:1-23; 5:17-42; 9:14) Lẹ́yìn ìparun tẹ́ḿpìlì ní 70 C.E., ẹgbẹ́ yìí di àfẹ́kù.

Àìní Fún Bíbá A Lọ Láti Máa Wà Lójúfò

Ẹ wo bí ìkìlọ̀ Jesu ti jẹ́ èyí tí ó bá a mu tó! Bẹ́ẹ̀ni, a níláti “ṣọ́ra fún ìwúkàrà awọn Farisi ati awọn Sadusi.” Ẹnì kan níláti kíyèsí ìṣùpọ̀ èso búburú rẹ̀ nínú àwùjọ àwọn Júù àti Kristẹndọm lónìí.

Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìyàtọ̀ gédégédé, àwọn Kristian alàgbà tí wọ́n tóótun ní iye tí ó ju 75,500 ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yíká ayé ń ‘fiyèsí ara wọn nígbà gbogbo ati sí ẹ̀kọ́ wọn.’ (1 Timoteu 4:16) Wọ́n gba odindi Bibeli bí èyí tí Ọlọrun mísí. (2 Timoteu 3:16) Kàkà kí wọ́n ṣe àyípadà àwọn ìlànà ìgbàṣe ìsìn tiwọn kí wọ́n sì máa gbé e lárugẹ, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìsopọ̀ṣọ̀kan lábẹ́ ìtọ́sọ́nà ètò-àjọ tí a gbé karí Bibeli tí ń lo ìwé ìròyìn yìí gẹ́gẹ́ bí irin-iṣẹ́ pàtàkì rẹ̀ fún ìtọ́ni.—Matteu 24:45-47.

Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yíká ayé ni a ń gbé dìde nípa tẹ̀mí bí wọ́n ti wá ń lóye Bibeli, tí wọ́n ń fi í sílò nínú ìgbésí-ayé wọn, tí wọ́n sì ń fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Láti rí bí a ṣe ń ṣàṣeparí èyí, èéṣe tí o kò ṣèbẹ̀wò sí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó sún mọ́ ọ jùlọ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

JESU GBA TI ÀWỌN OLÙGBỌ́ RẸ̀ RÒ

JESU KRISTI kọ́ni lọ́nà tí ó ṣe kedere, ó sì gba èrò àwọn tí ń tẹ́tísílẹ̀ sí i rò. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó bá Farisi náà Nikodemu sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn dídi ẹni tí a tún “bí.” Nikodemu béèrè pé: “Bawo ni a ṣe lè bí ènìyàn kan nígbà tí ó ti dàgbà? Oun kò lè wọ inú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ ní ìgbà kejì kí a sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?” (Johannu 3:1-5) Èéṣe tí ó fi ya Nikodemu lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn Farisi gbà pé àtúnbí ṣe pàtàkì kí ẹnì kan tó lè yípadà sí ìsìn àwọn Júù, ọ̀rọ̀ àwọn rabi kan sì fi àwọn aláwọ̀ṣe wé “ọmọ kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí”?

Ìwé A Commentary on the New Testament From the Talmud and Hebraica, tí John Lightfoot kọ, fún wa ní ìlàlóye tí ó tẹ̀lé e yìí: “Èrò tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù nípa ìtóótun ọmọ Israeli kan . . . ni ó ṣì wà gbágbágbá nínú ọkàn Farisi yìí” tí ó ṣòro fún láti “mú ẹ̀tanú rẹ̀ àkọ́kọ́ kúrò . . . : ‘Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọmọ Israeli . . . ní ẹ̀tọ́ láti di ẹni tí a gbà wọlé sínú ìjọba ti Messia, ohun tí o ń sọ ha ni pé, ó di dandan fún ẹnikẹ́ni láti wọ inú ìyá rẹ̀ lọ lẹ́ẹ̀kejì, kí ó baà lè di ọmọ Israeli titun bí?’”—Fiwé Matteu 3:9.

Níwọ̀n bí ó ti gba àtúnbí fún àwọn aláwọ̀ṣe, Nikodemu yóò wo irú ọ̀nà-ìṣe bẹ́ẹ̀ bí èyí tí kò ṣeé ṣe fún àwọn Júù àbínibí—pípadà wọ inú lẹ́ẹ̀kan síi bí ẹnì kan ṣe lè sọ ọ́.

Nígbà kan, àwọn tí ó pọ̀ bínú nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa ‘jíjẹ ẹran-ara òun àti mímu ẹ̀jẹ̀ òun.’ (Johannu 6:48-55) Bí ó ti wù kí ó rí, Lightfoot tọ́ka sí i pé “kò sí ohun tí ó wọ́pọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ àwọn Júù ju gbólóhùn náà ti ‘jíjẹ àti mímu’ ní ọ̀nà àfiwé-ẹlẹ́lọ̀ọ́.” Ó tún ṣàkíyèsí pé ìwé Talmud mẹ́nukan “jíjẹ Messia náà.”

Bí èrò àwọn Farisi àti àwọn Sadusi ṣe ní ipa tí ó ṣe gúnmọ́ kan lórí ìrònú àwọn Júù ọ̀rúndún kìn-ín-ní nìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà tí ó tọ́, ní gbogbo ìgbà ni Jesu máa ń gba ìmọ̀ àti ìrírí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ rò. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó abájọ tí ó mú un jẹ́ Olùkọ́ Ńlá náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́