ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 4/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • “Ẹ . . . Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Awọn Farisi ati Awọn Sadusi”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • ‘Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Wọ́n Pe Sànhẹ́dírìn Jọ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 4/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé òótọ́ ni pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tí òun tó jẹ́ Kristẹni sọ fún ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pé: “Farisí ni mí”?

Ká tó lè lóye ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Ìṣe 23:6, a ní láti kọ́kọ́ yiiri àwọn ohun tó sọ ṣáájú ẹsẹ yẹn àtèyí tó sọ lẹ́yìn ẹsẹ yẹn wò.

Àwọn èèyànkéèyàn kan mú Pọ́ọ̀lù ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì lù ú. Lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ̀rọ̀. Ó sọ fún wọn pé òun gba “ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní [Jerúsálẹ́mù] lẹ́bàá ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì, [òun sì gba] ìtọ́ni ní ìbámu pẹ̀lú àìgbagbẹ̀rẹ́ Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì.” Àwọn èèyàn náà kọ́kọ́ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù bó ṣe ń ṣàlàyé ara rẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ dé àárín kan wọ́n fara ya, bí ọ̀gá sójà tó wá mú Pọ́ọ̀lù ṣe mú Pọ́ọ̀lù lọ sí àgọ́ àwọn sójà nìyẹn. Bí wọ́n ṣe fẹ́ fi pàṣán na Pọ́ọ̀lù, ó sọ fún ọ̀gá sójà kan tó wà níbẹ̀ pé: “Ó ha bófin mu pé kí ẹ na ẹni tí ó jẹ́ ará Róòmù, tí a kò sì dá lẹ́bi lọ́rẹ́?”—Ìṣe 21:27–22:29.

Nígbà tó dọjọ́ kejì, ọ̀gá sójà tó mú Pọ́ọ̀lù náà mú un lọ sí ilé ẹjọ́ àwọn Júù, ìyẹn Sànhẹ́dírìn. Pọ́ọ̀lù wojú gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, ó rí i pé àwọn Sadusí àtàwọn Farisí ló para pọ̀ sínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn náà. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí, ọmọ àwọn Farisí. Lórí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni a ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fa arukutu láàárín àwọn Farisí àtàwọn Sadusí, “nítorí àwọn Sadusí wí pé kò sí àjíǹde tàbí áńgẹ́lì tàbí ẹ̀mí, ṣùgbọ́n àwọn Farisí polongo gbogbo ìwọ̀nyí ní gbangba.” Àwọn kan lára àwọn Farisí tó wà níbẹ̀ sì ń fìbínú sọ pé: “Àwa kò rí ohun àìtọ́ kankan nínú ọkùnrin yìí.”—Ìṣe 23:6-10.

Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tí kò fi ẹ̀sìn Kristẹni ṣeré rárá, nítorí náà kò sí bí Pọ́ọ̀lù ṣe lè ṣàlàyé tó pé Farisí gidi lòun tí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn á gbà á gbọ́. Kódà, àwọn Farisí tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà kò ní tẹ́wọ́ gba ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé Farisí gidi lòun tónítọ̀hún ò bá gba gbogbo ẹ̀kọ́ wọn gbọ́. Nípa báyìí, sísọ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Farisí lòun túmọ̀ sí pé ó láwọn nǹkan kan tóun àtàwọn Farisí fi jọra, àwọn Farisí tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ á sì ti mọ̀ pé ohun tó ní lọ́kàn nìyẹn.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé nítorí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá òun lẹ́jọ́, ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun fìyẹn jọ àwọn Farisí. Ìgbàkigbà tí ọ̀rọ̀ àjíǹde bá délẹ̀, àwọn Farisí làwọn èèyàn máa ka Pọ́ọ̀lù mọ́ dípò àwọn Sadusí, nítorí pé àwọn Sadusí ò gbà pé àjíǹde wà.

Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù, lára ohun tó sì gbà gbọ́ tí kò ta ko ohun táwọn Farisí gbà gbọ́ ni ẹ̀kọ́ àjíǹde, àwọn áńgẹ́lì, àtàwọn kókó kan nínú Òfin Mósè. (Fílípì 3:5) Nítorí pé àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí táwọn Farisí gbà gbọ́ bá ti Pọ́ọ̀lù mu ni Pọ́ọ̀lù ṣe pera ẹ̀ ní Farisí, àwọn ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà sì mọ̀ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe ni pé ó lo ọlá pé ó jẹ́ Júù láti lè fi rí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ẹlẹ́tanú yẹn mú.

Ṣùgbọ́n, olórí ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ò ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni pé, jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni Jèhófà fi wà pẹ̀lú rẹ̀. Àní Jésù tiẹ̀ sọ fún Pọ́ọ̀lù lálẹ́ ọjọ́ kejì tó pera ẹ̀ ní Farisí yẹn pé: “Jẹ́ onígboyà gidi gan-an! Nítorí pé bí o ti ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ tún gbọ́dọ̀ jẹ́rìí ní Róòmù.” Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba Pọ́ọ̀lù, ó yẹ ká gbà pé Pọ́ọ̀lù ò ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́.—Ìṣe 23:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́