“Wọ́n Pe Sànhẹ́dírìn Jọ”
ÀLÙFÁÀ àgbà àtàwọn olórí àwọn Júù ti rí sí i pé àwọn aláṣẹ pa Jésù Kristi, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àjíǹde rẹ̀ gba Jerúsálẹ́mù kan. Àlùfáà àgbà àtàwọn olórí àwọn Júù ò wá mọ èyí tí wọn ì bá ṣe mọ́. Kí ni wọ́n máa ṣe báyìí táwọn èèyàn ò fi ní máa sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi? Báwo ni wọ́n ṣe máa pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu mọ́? Kí àlùfáà àgbà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lè mọ ohun tí wọ́n máa ṣe ni wọ́n ṣe “pe Sànhẹ́dírìn jọ,” ìyẹn àwọn adájọ́ nílé ẹjọ́ gíga jù lọ tàwọn Júù.—Ìṣe 5:21.
Nílẹ̀ Ísírẹ́lì ní ọ̀rúdún kìíní, ohun tí Pọ́ńtíù Pílátù ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà bá sọ labẹ gé. Àmọ́ báwo ni àárín ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn àti Pílátù ṣe rí? Ibo ni kálukú wọn láṣẹ lé lórí? Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn? Kí sì ni iṣẹ́ wọn?
Bí Ìgbìmọ̀ Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Lédè Gíríìkì, ohun tí ọ̀rọ̀ tá a tú sí “Sànhẹ́dírìn” túmọ̀ sí ní olówuuru ni “jíjókòó ti nǹkan.” Àpéjọ tàbí ìpàdé ni wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún. Àmọ́ ohun táwọn Júù ń pe ìgbìmọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn tó ń dájọ́ ní kóòtù wọn nìyẹn.
Àwọn tó kọ ìwé Támọ́dì, èyí tí wọ́n kọ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, sọ pé Sànhẹ́dírìn jẹ́ ìgbìmọ̀ kan láyé àtijọ́. Wọ́n gbà pé àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ló máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn látilẹ̀wá àti pé ńṣe ni wọ́n máa ń pàdé pọ̀ láti jíròrò lórí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú òfin àwọn Júù. Wọ́n sì sọ pé àtìgbà tí Mósè ti yan àádọ́rin àgbààgbà kí wọ́n lè máa ràn án lọ́wọ́ láti darí Ísírẹ́lì ni ìgbìmọ̀ yẹn ti wà. (Númérì 11:16, 17) Àmọ́ àwọn òpìtàn ò fara mọ́ ohun táwọn tó kọ ìwé Támọ́dì sọ. Wọ́n ní ìgbà tí ìjọba Páṣíà ń ṣàkóso Ísírẹ́lì ni ìgbìmọ̀ kan tó jọ Sànhẹ́dírìn ti ọ̀rúndún kìíní bẹ̀rẹ̀. Àwọn òpìtàn sì tún sọ pé àjọ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kọ ìwé Támọ́dì pàápàá yàtọ̀ sí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, wọ́n ní àwọn àti ìgbìmọ̀ àwọn rábì tó wà ní ọ̀rúndún kejì sí ìkẹta ni wọ́n jọra. Ìgbà wo wá ni ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn bẹ̀rẹ̀?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó padà sí ilẹ̀ Júdà láti ìgbèkùn Bábílónì lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ní àjọ kan tó ń bójú tó ọ̀ràn ilẹ̀ wọn nígbà náà. Nehemáyà àti Ẹ́sírà mẹ́nu kan àwọn kan tó jẹ́ ọmọ aládé, àwọn àgbà ọkùnrin, àwọn ọ̀tọ̀kùlú àtàwọn ajẹ́lẹ̀ nígbà yẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn wọ̀nyẹn ló wá di ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn nígbà tó yá.—Ẹ́sírà 10:8; Nehemáyà 5:7.
Láàárín àkókò táwọn òǹkọ̀wé Bíbélì parí kíkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí ìgbà tí Mátíù kọ ìwé Ìhìn Rere Mátíù, nǹkan ò fara rọ fáwọn Júù. Lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Alẹkisáńdà Ńlá tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Gíríìsì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso Jùdíà. Lẹ́yìn ikú Alẹkisáńdà, ìjọba méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ yọ látinú ilẹ̀ Gíríìsì ló ṣàkóso Jùdíà. Àwọn alákòóso láti ìdílé ọ̀gágun Tọ́lẹ́mì làkọ́kọ́, àwọn ti ìdílé ọ̀gágun Sẹ̀lẹ́úkọ́sì sì nìkejì. Inú àwọn ìwé tó sọ ìtàn ìgbà táwọn alákòóso láti ìdílé Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ń ṣàkóso Jùdíà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 198 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, la ti kọ́kọ́ rí i pé wọ́n pe àwọn kan ní ìgbìmọ̀ aṣòfin àwọn Júù. Ó ṣeé ṣe kí agbára ìgbìmọ̀ yìí má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, àmọ́ bí àwọn Júù ṣe ní ìgbìmọ̀ yìí, ó jẹ́ kí wọ́n ní èrò pé àwọn fúnra wọn ló ń ṣàkóso ara wọn.
Lọ́dún 167 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Áńtíókọ́sì Kẹrin (Ẹpifánísì) tó wá láti ìdílé Sẹ̀lẹ́úkọ́sì gbìyànjú láti fipá mú àwọn Júù láti máa tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ àwọn Gíríìkì. Ó fi ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ sí òrìṣà Súúsì lórí pẹpẹ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù láti fi sọ tẹ́ńpìlì náà di àìmọ́. Làwọn Júù bá fárígá tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ogun táwọn Mákábì fi gba Jùdíà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdílé Sẹ̀lẹ́úkọ́sì tó ń ṣàkóso wọn, tí wọ́n sì mú kí ìdílé Hasimóníọ̀sì máa ṣàkóso Jùdíà.a Àsìkò yẹn làwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí tí wọ́n kó àwọn aráàlú sòdí láti ja ogun àjàgbara yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í dá sí ọ̀rọ̀ àkóso ìlú táwọn àlùfáà nìkan ń ṣe tẹ́lẹ̀.
Bí ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn tí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe wá ń fìdí múlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nìyẹn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó wá di ìgbìmọ̀ tó ń ṣàkóso Jùdíà tó sì ń dá ẹjọ́ nílé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù níbi tí wọ́n ti ń rí sí ìtumọ̀ òfin.
Bí Ìjọba Róòmù Àtàwọn Júù Ṣe Ń Lo Agbára Wọn
Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní, Jùdíà ti bọ́ sábẹ́ ìjọba Róòmù. Àmọ́, àwọn Júù ní òmìnira dé àyè kan. Ó jẹ́ àṣà ìjọba Róòmù láti máa fún àwọn ilẹ̀ tó bá wà lábẹ́ wọn láyè láti máa ṣàkóso ara wọn. Nítorí náà, àwọn aláṣẹ tó ń ṣojú fún ìjọba Róòmù kì í dá sí àwọn nǹkan tó jẹ́ ojúṣe kóòtù ìbílẹ̀, wọ́n sì máa ń yàgò fún ohun tó lè mú kí àṣà ìbílẹ̀ wọn tó yàtọ̀ sí tàwọn Júù dá wàhálà sílẹ̀. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé kí olúkúlùkù ilẹ̀ tó wà lábẹ́ wọn máa tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ tirẹ̀, kó wá dà bíi pé wọ́n ń ṣàkóso ara wọn. Kìkì pé kí àlàáfíà sáà ti wà, káwọn èèyàn ilẹ̀ wọ̀nyẹn sì bá ìjọba Róòmù fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Yàtọ̀ sí pé kí ìjọba Róòmù yan àlùfáà àgbà, tó máa ń jẹ́ alága ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, tàbí kí wọ́n rọ̀ ọ́ lóyè, àti pé kí wọ́n gba owó orí, àwọn aṣojú wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ àwọn Júù àfi tí ohun tí wọ́n ń ṣe bá fẹ́ jin agbára tàbí ìlọsíwájú ìjọba Róòmù lẹ́sẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìgbẹ́jọ́ Jésù fi hàn pé ó jọ pé ìjọba Róòmù nìkan ló láṣẹ lórí ọ̀rọ̀ tó bá la ikú lọ.—Jòhánù 18:31.
Èyí fi hàn pé ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ló ń bójú tó èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọ̀ràn abẹ́lé orílẹ̀-èdè àwọn Júù. Ìgbìmọ̀ yìí ní àwọn agbófinró tó máa ń mú àwọn arúfin. (Jòhánù 7:32) Àwọn kóòtù kéékèèké máa ń ṣèdájọ́ àwọn ìwà ọ̀daràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti ẹ̀sùn láàárín àwọn aráàlú láìsí pé ìjọba Róòmù ń dá sí i. Bí àwọn kóòtù kéékèèké ò bá lè yanjú ẹjọ́ kan, wọn yóò gbé ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. Ohun tí ìgbìmọ̀ yẹn bá sì ti sọ labẹ gé.
Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn gbọ́dọ̀ rí i pé àlàáfíà wà lórílẹ̀-èdè náà kí wọ́n sì bá ìjọba Róòmù fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tí wọn ò bá fẹ́ kí wọ́n gba ipò yẹn lọ́wọ́ wọn. Àmọ́ tí àwọn aláṣẹ tó ń ṣojú fún ìjọba Róòmù bá fura pé ẹ̀ṣẹ̀ kan jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣèlú, wọn yóò dá sí i, wọn yóò sì ṣe ohun tó bá tọ́ lójú wọn. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n mú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—Ìṣe 21:31-40.
Àwọn Tó Máa Ń Wà Nínú Ìgbìmọ̀ Yẹn
Àwọn mọ́kànléláàádọ́rin [71] ló wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. Àwọn ni àlùfáà àgbà àtàwọn àádọ́rin èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso Jùdíà, àwọn àlùfáà sàràkí-sàràkí (tó sábà máa ń jẹ́ àwọn Sadusí), àwọn ọ̀tọ̀kùlú láwùjọ àtàwọn akọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ lágbo àwọn Farisí ni wọ́n máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn. Àwọn àlùfáà sàràkí-sàràkí yìí àtàwọn ọ̀tọ̀kùlú láwùjọ tó ń tì wọ́n lẹ́yìn ló lẹ́nu ọ̀rọ̀ jù nínú ìgbìmọ̀ náà.b Àwọn Sadusí máa ń wonkoko mọ́ àṣà àti ìṣe àtẹ̀yìnwá, àmọ́ àwọn Farisí, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ àwọn tẹ́nu wọn tólẹ̀ láwùjọ, máa ń fẹ́ ṣe ohun tó bóde mu ní tiwọn. Òpìtàn náà Josephus sọ pé àwọn Sadusí kì í sábà fẹ́ ṣe ohun táwọn Farisí bá fẹ́ kí wọ́n ṣe. Mímọ̀ tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àárín ẹgbẹ́ méjèèjì ò gún yìí àti pé ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ síra ló mú kó sọ ohun tó sọ nígbà tó ń jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn láyé ọjọ́un.—Ìṣe 23:6-9.
Tá a bá wo bó ṣe jẹ́ pé àwọn sàràkí-sàràkí èèyàn ló máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yìí, ó dà bíi pé ẹni tó bá ti di ara ìgbìmọ̀ yẹn kì í kúrò nípò yẹn àti pé àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ló ń yan ẹlòmíì sínú ìgbìmọ̀ náà nígbà tí àyè kan bá ṣí sílẹ̀. Ìwé Míṣínà sọ pé àwọn tó lè di ara ìgbìmọ̀ yẹn ni “àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí àlùfáà lè fẹ́ ọmọ wọn,” ìyẹn àwọn tí wọ́n ní àkọsílẹ̀ ìtàn ìdílé tó fi hàn pé Júù pọ́ńbélé ni wọ́n. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó ètò ìdájọ́ ilẹ̀ Jùdíà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni tó ti nírìírí dáadáa ní kóòtù kékeré ni wọ́n ń yàn sínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn.
Ibi Tí Àkóso àti Àṣẹ Wọn Dé
Àwọn Júù ò kóyán ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn kéré, àwọn adájọ́ kóòtù kéékèèké sì gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìdájọ́ tí wọ́n bá ṣe tí wọn ò bá fẹ́ kí ikú pa àwọn. Olórí iṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà ni láti rí i pé ẹni tó kúnjú òṣùwọ̀n ló ń di àlùfáà, wọ́n sì tún ń rí sí ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìlú Jerúsálẹ́mù, tẹ́ńpìlì ibẹ̀ àti ètò ìjọsìn nínú tẹ́ńpìlì yẹn. Láìfọ̀rọ̀ gùn, ilẹ̀ Jùdíà nìkan ni ìgbìmọ̀ náà láṣẹ lé lórí. Àmọ́ nítorí pé ìgbìmọ̀ yẹn làwọn Júù gbà pé ó lè sọ ohun tó jẹ́ ìtumọ̀ Òfin Mósè, ìgbìmọ̀ yẹn ló máa ń pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí ò tọ́ fáwọn Júù jákèjádò ayé ìgbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, àlùfáà àgbà àti ìgbìmọ̀ rẹ̀ ló sọ fún àwọn aṣáájú sínágọ́gù ìlú Damásíkù pé kí wọ́n ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ kó lè rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi mú lóǹdè wá. (Ìṣe 9:1, 2; 22:4, 5; 26:12) Bákan náà, ó jọ pé àwọn Júù tó bá wá ṣe àjọyọ̀ ní Jerúsálẹ́mù máa ń délé sọ ohun tí ìgbìmọ̀ náà bá pa láṣẹ.
Ìwé Míṣínà sọ pé ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn nìkan ló láṣẹ lórí ọ̀ràn tó bá kan gbogbo orílẹ̀-èdè wọn, àwọn ló láṣẹ láti fìyà jẹ adájọ́ tó bá ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ ìgbìmọ̀ náà àti láti ṣèdájọ́ ẹni tó bá jẹ́ wòlíì èké. Iwájú ìgbìmọ̀ yìí ni wọ́n mú Jésù àti Sítéfánù wá láti wá jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n fi kàn wọ́n, ibẹ̀ ni wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù wá lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ dojú orílẹ̀-èdè wọn dé, ibẹ̀ ni wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù lọ lórí ẹ̀sùn pé ó sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́.—Máàkù 14:64; Ìṣe 4:15-17; 6:11; 23:1; 24:6.
Ẹjọ́ Tí Wọ́n Dá fún Jésù Àtàwọn Ọmọlẹ́yìn Rẹ̀
Ojoojúmọ́ ni ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn máa ń péjọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọn láti ìgbà ẹbọ òwúrọ̀ títí dìgbà ọrẹ ẹbọ àṣálẹ́, àyàfi ọjọ́ Sábáàtì àtàwọn ọjọ́ mímọ́ yòókù. Ojúmọmọ nìkan ni wọ́n máa ń gbọ́ ẹjọ́. Tí ìdájọ́ ẹnì kan bá máa la ikú lọ, wọn kì í kéde ìdájọ́ yẹn lọ́jọ́ yẹn, ó dọjọ́ kejì. Ìdí nìyẹn tí wọn kì í gbọ́ irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ní Sábáàtì ku ọ̀la tàbí àjọyọ̀ ku ọ̀la. Wọ́n máa ń kìlọ̀ gan-an fáwọn tó bá fẹ́ jẹ́rìí pé kí wọ́n má ṣe jẹ́rìí èké tó lè yọrí sí ikú aláìṣẹ̀. Nítorí náà, fífi tí wọ́n fi òru gbọ́ ẹjọ́ Jésù nílé Káyáfà lọ́jọ́ tí Sábáàtì ku ọ̀la, tí wọ́n sì dájọ́ ikú fún un lóru yẹn kan náà kò bófin mu rárá. Èyí tó tiẹ̀ tún burú jù ni pé àwọn adájọ́ yẹn gan-an ló tún wá ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n wá jẹ́rìí, àwọn náà ló sì rọ Pílátù títí tó fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù.—Mátíù 26:57-59; Jòhánù 11:47-53; 19:31.
Ìwé Támọ́dì sọ pé tó bá ṣeé ṣe kí ẹjọ́ ẹnì kan la ikú lọ, ńṣe làwọn adájọ́ máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ẹjọ́ ọ̀hún dáadáa, tí wọ́n á máa wo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ẹ̀mí onítọ̀hún má lọ sí i. Àmọ́ ìgbìmọ̀ náà ò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà ìgbẹ́jọ́ Jésù àti Sítéfánù rárá. Àní Sítéfánù fẹ́rẹ̀ẹ́ má tíì rojọ́ tán táwọn jàǹdùkú fi ṣùrù bò ó tí wọ́n sì lọ sọ ọ́ lókùúta pa. Ká ní kì í ṣe tàwọn aṣojú ìjọba Róòmù tó dá sí ọ̀rọ̀ ti Pọ́ọ̀lù náà ni, àfàìmọ̀ kó má jẹ́ pé irú ikú tóun náà ì bá kú nìyẹn. Àní àwọn adájọ́ inú ìgbìmọ̀ yìí tiẹ̀ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.—Ìṣe 6:12; 7:58; 23:6-15.
Àmọ́ ṣá, ó jọ pé olóòótọ́ èèyàn làwọn mélòó kan lára ìgbìmọ̀ náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara ìgbìmọ̀ náà ni ọ̀dọ́kùnrin olùṣàkóso tó bá Jésù sọ̀rọ̀ yẹn. Òótọ́ ni pé ọrọ̀ tó ní kò jẹ́ kó lè tẹ̀ lé Jésù, síbẹ̀ ó dà bíi pé ó jẹ́ ẹni tí ìwà rẹ̀ dára nítorí Jésù sọ fún un pé kó wá di ọmọlẹ́yìn òun.—Mátíù 19:16-22; Lúùkù 18:18, 22.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Nikodémù, “olùṣàkóso kan fún àwọn Júù,” ń bẹ̀rù ohun táwọn adájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ máa sọ tó fi jẹ́ kí ilẹ̀ ṣú kó tó wá sọ́dọ̀ Jésù. Síbẹ̀ Nikodémù gbèjà Jésù níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, nítorí ó bi wọ́n pé: “Òfin wa kì í ṣèdájọ́ ènìyàn láìjẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, kí ó sì wá mọ nǹkan tí ó ń ṣe, àbí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀?” Lẹ́yìn náà, Nikodémù tún pèsè “àdìpọ̀ òjíá àti àwọn álóè” kí wọ́n fi múra òkú Jésù sílẹ̀ kí wọ́n tó sin ín.—Jòhánù 3:1, 2; 7:51, 52; 19:39.
Jósẹ́fù ará Arimatíà, tóun náà wà nínú ìgbìmọ̀ yìí, fi ìgboyà tọrọ òkú Jésù lọ́wọ́ Pílátù, ó sì lọ sin ín sínú ibojì tuntun tó ṣe fún ara rẹ̀. Jósẹ́fù yìí “ń dúró de ìjọba Ọlọ́run,” àmọ́ ìbẹ̀rù àwọn Júù ò jẹ́ kó lè fi hàn ní gbangba pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù lòun. Àmọ́, Jósẹ́fù tún ṣe ohun tó dára ní ti pé kò fara mọ́ ètekéte ìgbìmọ̀ náà láti rí i pé wọ́n pa Jésù.—Máàkù 15:43-46; Mátíù 27:57-60; Lúùkù 23:50-53; Jòhánù 19:38.
Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ ara ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn bá àwọn adájọ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ yòókù sọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n pé kí wọ́n má yọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́nu mọ́. Ó ní: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.” (Ìṣe 5:34-39) Kí nìdí tí ìgbìmọ̀ náà ò fi gbà pé Ọlọ́run ń bẹ lẹ́yìn Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Kàkà kí wọ́n ṣe sàdáńkátà Jésù fún iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe, wọ́n sọ pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.” (Jòhánù 11:47, 48) Àìfẹ́ pàdánù ipò wọn gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ ló mú kí ìgbìmọ̀ tó ń dájọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga jù lọ àwọn Júù yìí ṣègbè nínú ìdájọ́ wọn o. Bákan náà, dípò kínú àwọn aṣáájú ìsìn náà máa dùn nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń mú àwọn èèyàn lára dá, ńṣe ni wọ́n “kún fún owú.” (Ìṣe 5:17) Ńṣe ló yẹ kí àwọn adájọ́ yìí jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run àti onídàájọ́ òdodo, àmọ́ ìwà ìbàjẹ́ àti àìṣòótọ́ ló gba ọ̀pọ̀ jù lọ wọn lọ́kàn.—Ẹ́kísódù 18:21; Diutarónómì 16:18-20.
Ìdájọ́ Ọlọ́run
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ti pa òfin Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì kọ Mèsáyà, Jèhófà pẹ̀lú kọ̀ wọ́n nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó ní wọn kì í ṣe àyànfẹ́ òun mọ́. Lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, wọ́n sì fòpin sí ìjọba àwọn Júù àti ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn alára lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Jésù Kristi tí Jèhófà fi jẹ Adájọ́ ni yóò pinnu bóyá èyíkéyìí lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ti ọ̀rúndún kìíní yóò ní àjíǹde, òun ni yóò sì pinnu ẹni tó ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ lára wọn. (Máàkù 3:29; Jòhánù 5:22) Àmọ́ kí ó dá wa lójú pé ìdájọ́ òdodo ni Jésù yóò ṣe tó bá fẹ́ ṣèdájọ́ wọn.—Aísáyà 11:3-5.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti lè mọ̀ sí i nípa àwọn Mákábì àti ìdílé Hasimóníọ̀sì, wo Ilé Ìṣọ́ November 15, 1998, ojú ìwé 21 sí 24, àti ti June 15, 2001, ojú ìwé 27 sí 30.
b Nígbà tí Bíbélì bá lo gbólóhùn náà “àwọn olórí àlùfáà,” àwọn tó ń tọ́ka sí ni, àwọn àlùfáà àgbà àná, ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn tó wá látinú ìdílé tí ipò ńlá tọ́ sí lágbo àwọn àlùfáà.—Mátíù 21:23.