Ohun Rere Wo Ni Ó Lè Ti Inú Jíjíròrò Nípa Ìsìn Jáde?
ÀWỌN òbí máa ń fi ìháragàgà dúró de ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ wọn yóò sọ. Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ àwọn wóróhùn tí pípè rẹ̀ kò jágaara, bóyá “Màmá” tàbí “Tàtá,” wọ́n máa ń kún fún ayọ̀. Kíákíá wọn yóò sọ èyí fún àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò. Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí ọmọ bá sọ jẹ́ ìròyìn ayọ̀ tí ń mú ìdùnnú wá.
Ọmọ kékeré kan máa ń hùwàpadà sí àwọn ìró tí ó gbọ́, ohun tí ó rí, àti òórùn tí ó gbọ́. Àmọ́ ṣáá o, ìhùwàpadà máa ń yàtọ̀. Ṣùgbọ́n bóyá, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìkókó kan kọ̀ láti hùwàpadà sí gbogbo àwọn ìsúnniṣe wọ̀nyí, lọ́nà tí ó tọ́ àwọn òbí yóò dààmú pé a ti ké ìdàgbàsókè ọmọ wọn nígbèrí.
Àwọn ọmọ máa ń hùwàpadà lọ́nà tí ó dára jùlọ sí àwọn tí wọ́n bá mọ̀. Nígbà tí ìyá bá gbá ọmọ mọ́ra, ó sábà máa ń yọrí sí kí ọmọ náà bú sẹ́rìn-ín. Síbẹ̀, bí ìbátan kan tí ó wá ṣèbẹ̀wò bá fọwọ́kàn án ó lè bú sí ẹkún, àní kí ó má tilẹ̀ gbà kí ẹni náà gbé òun. Èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìbátan tí wọ́n ní irú ìrírí báyìí kì í sọ̀rètínù. Bí ọmọ ti ń mojú wọn síi, inú wọn máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń di ojúlùmọ̀ ọmọ náà, tí ọmọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín.
Ní ọ̀nà kan náà, púpọ̀ lára àwọn àgbàlagbà ń lọ́ra láti sọ̀rọ̀ nípa èrò-ìgbàgbọ́ ìsìn wọn ní gbangba pẹ̀lú ẹnì kan tí wọn kò mọ̀ dunjú. Ó lè má yé wọn ìdí tí àlejò kan yóò fi fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ara ẹni—ìsìn. Àbájáde rẹ̀ ni pé wọn máa ń jẹ́ kí ohun ìdínà kan wà láàárín wọn àti àwọn tí wọ́n fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá. Ó ṣetán, wọ́n tilẹ̀ kọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó jẹ́, ìwà tí a dá mọ́ ìran-aráyé, ìfẹ́-ọkàn láti jọ́sìn.
Nítòótọ́, a níláti ní ọkàn-ìfẹ́ sí kíkọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa, bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀pọ̀ sì lè fi wá sí ipò kan tí a ti lè kẹ́kọ̀ọ́. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé tipẹ́tipẹ́ ni a ti mọ Ọlọrun mọ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní gbangba. Ẹ jẹ́ kí a wo bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.
‘Tẹ́tísílẹ̀ Kí O sì Kẹ́kọ̀ọ́’
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí Ọlọrun kọ́kọ́ ní pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ pẹ̀lú Adamu nínú ọgbà Edeni. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Adamu àti Efa ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n yàn láti farapamọ́ nígbà tí Ọlọrun pè wọ́n, nígbà tí ó fẹ́ láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ síwájú síi pẹ̀lú wọn. (Genesisi 3:8-13) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bibeli ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
Ọlọrun bá Noa jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nípa ìparun tí ń bọ̀ sórí ayé oníwà búburú ọjọ́ rẹ̀, nítorí ìdí èyí Noa di “oníwàásù òdodo.” (2 Peteru 2:5) Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ Ọlọrun fún ìran rẹ̀, kì í ṣe pé Noa fi ìgbàgbọ́ nínú ìbáṣepọ̀ Ọlọrun pẹ̀lú ènìyàn hàn nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún fi ara rẹ̀ hàn ní gbangba pé òun wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa. Ìhùwàpadà wo ni Noa ṣàkíyèsí? Ó ṣeni láàánú pé, èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ojúgbà rẹ̀ “kò sì fiyèsí i títí ìkún-omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Matteu 24:37-39) Ṣùgbọ́n a láyọ̀ pé, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Noa méje tẹ́tísílẹ̀, wọ́n ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni Ọlọrun, wọ́n sì la Àkúnya-Omi àgbáyé náà já. Láti ọ̀dọ̀ wọn ni gbogbo ẹ̀dá-ènìyàn lónìí ti wá.
Lẹ́yìn náà, Ọlọrun bá orílẹ̀-èdè kan lápapọ̀ sọ̀rọ̀, Israeli ìgbàanì. Nípasẹ̀ Mose, Ọlọrun fún wọn ní Òfin Mẹ́wàá àti nǹkan bíi 600 òfin mìíràn tí ó dè wọ́n. Jehofa retí pé kí àwọn ọmọ Israeli ṣègbọràn sí gbogbo wọn. Mose fún wọn ní ìtọ́ni pé ní ọdún méjeméje, nígbà Àjọ Àgọ́, Òfin Ọlọrun ni a gbọ́dọ̀ kà ketekete. Ó fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Kó àwọn ènìyàn náà jọ, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àlejò rẹ tí ń bẹ nínú ibodè rẹ.” Fún ète wo? “Kí wọn kí ó lè gbọ́, àti kí wọn kí ó lè kọ́ àti máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, àti kí wọn kí ó máa kíyèsí àti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí.” Gbogbo wọn níláti tẹ́tísílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́. Ronú bí wọn yóò ti gbádùn jíjíròrò ohun tí wọ́n gbọ́ tó!—Deuteronomi 31:10-12.
Ní èyí tí ó ju ọ̀rúndún márùn-ún lẹ́yìn náà, Jehoṣafati ọba Juda ṣètò àwọn ọmọ-ọba àti àwọn ọmọ Lefi nínú ìgbétáásì láti mú ìjọsìn mímọ́ gaara Jehofa sọjí. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí rin ìrìn-àjò jákèjádò àwọn ìlú-ńlá Juda wọ́n sì ń kọ́ àwọn tí ń gbé níbẹ̀ ní àwọn òfin Jehofa. Nípa mímú kí á sọ èyí ní gbangba, ọba náà fi ẹ̀rí ìgboyà rẹ̀ fún ìjọsìn tòótọ́ hàn. Nípa ti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀, wọ́n níláti tẹ́tísílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́.—2 Kronika 17:1-6, 9.
Jíjẹ́rìí Nípa Ìjíròrò
Ọlọrun rán Ọmọkùnrin òun fúnra rẹ̀, Jesu, wá sí ayé láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí Agbẹnusọ Òun. (Johannu 1:14) Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta ti ń ṣẹlẹ́rìí ìyípadà ológo Jesu níwájú wọn, wọ́n gbọ́ ohùn Ọlọrun fúnra rẹ̀ tí ń polongo wí pé: “Èyí ni Ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti fi ojúrere tẹ́wọ́gbà; ẹ fetísílẹ̀ sí i.” (Matteu 17:5) Wọ́n ṣègbọràn láì jampata.
Lọ́nà kan náà, Jesu pàṣẹ fún àwọn aposteli rẹ̀ láti polongo àwọn ète Ọlọrun fún àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ku nǹkan bíi oṣù mẹ́fà kí ó parí, Jesu sọ ọ́ di mímọ̀ pé iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba àwọn ọ̀run gbòòrò débi pé a óò nílò àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ síi. Ó kọ́ 70 nínú wọn bí wọ́n ṣe lè jíròrò nípa Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú àwọn àlejò ó sì rán wọn jáde láti tan ìròyìn náà kálẹ̀ ní gbangba. (Luku 10:1, 2, 9) Kété ṣáájú kí ó tó padà lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run, Jesu rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti lo ìdánúṣe wọn láti bá àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn-iṣẹ́ yìí, ó tilẹ̀ pàṣẹ fún wọn pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.” (Matteu 28:19, 20) Kárí ayé, àwọn Kristian tòótọ́ lónìí ń mú iṣẹ́-àṣẹ yìí ṣẹ nípa jíjíròrò ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn. Àwọn ìjíròrò wọ̀nyí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa Ẹlẹ́dàá náà, Jehofa.—Matteu 24:14.
Ìjíròrò Alálàáfíà, Tí Ń Gbéniró
Ní irú ọ̀nà wo ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu níláti gbà jíròrò èrò-ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Wọn kò níláti mú àwọn alátakò bínú, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò níláti bá àwọn alátakò jiyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti wá àwọn tí yóò tẹ́wọ́gba ìhìnrere rí lẹ́yìn náà kí wọ́n sì pèsè ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ láti gbè é lẹ́sẹ̀. Níti tòótọ́, Ọlọrun ṣàkíyèsí ìhùwàpadà àwọn tí ó ṣalábàápàdé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Ọmọkùnrin rẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbà yín gbà mí pẹlu, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni naa pẹlu tí ó rán mi jáde.” (Matteu 10:40) Ẹ wo irú ìyọsùtì tí èyí jẹ́ nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ojúgbà Jesu kọ ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀!
Kristian aposteli Paulu gbani nímọ̀ràn pé: “Kò yẹ kí ẹrú Oluwa máa jà.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun lati kọ́ni, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí ó máa fún awọn wọnnì tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹlu ìwàtútù; pé bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà tí ń ṣamọ̀nà sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (2 Timoteu 2:24, 25) Ọ̀nà tí Paulu gbà pòkìkí ìhìnrere fún àwọn ará Ateni, Griki, fún wa ní àpẹẹrẹ àtàtà. Ó fọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn Júù nínú sinagọgu wọn. Lójoojúmọ́ ní ibi-ọjà ó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “awọn wọnnì tí ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n wà ní àrọ́wọ́tó.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò sí iyèméjì pé, àwọn kan wulẹ̀ fẹ́ láti tẹ́tísí àwọn èrò titun, Paulu sọ̀rọ̀ ní tààràtà àti lọ́nà tí ó fi inúrere hàn. Ó jíròrò ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun pẹ̀lú àwọn tí ń tẹ́tísílẹ̀ sí i, ó sì rọ̀ wọ́n láti ronúpìwàdà. Ìhùwàpadà wọn rí bákan náà pẹ̀lú ti àwọn ènìyàn lónìí. “Awọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹlẹ́yà, nígbà tí awọn mìíràn wí pé: ‘Dájúdájú awa yoo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nipa èyí àní ní ìgbà mìíràn.’” Paulu kò rinkinkin mọ́ fífa ìjíròrò náà gùn. Níwọ̀n bí ó ti sọ ìhìn-iṣẹ́ náà, ó “jáde kúrò ní àárín wọn.”—Ìṣe 17:16-34.
Lẹ́yìn náà, Paulu sọ fún àwọn mẹ́ḿbà ìjọ Kristian ní Efesu pé òun ‘kò fà sẹ́yìn kúrò ninu sísọ èyíkéyìí lára awọn ohun tí ó lérè nínú tabi kúrò ninu kíkọ́ni ní gbangba ati lati ilé dé ilé.’ Síwájú síi, ó ti, ‘jẹ́rìí kúnnákúnná fún awọn Júù ati awọn Griki nipa ìrònúpìwàdà sí Ọlọrun ati ìgbàgbọ́ ninu Jesu Kristi.’—Ìṣe 20:20, 21.
Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ṣípayá bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun olùṣòtítọ́ ní àsìkò Bibeli ṣe jíròrò nípa ìsìn. Nítorí náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi tìgbọràn tìgbọràn jíròrò nípa ìsìn pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn.
Ìjíròrò Tí Ń So Èso Púpọ̀
‘Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.’ ‘Tẹ́tí sí àwọn òfin rẹ̀.’ Ẹ wo bí irú ìgbaniníyànjú yìí ti pọ̀ tó nínú Bibeli! O lè dáhùnpadà sí irú àwọn ìdarísọ́nà Bibeli wọ̀nyí nígbà mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá tún bá ọ sọ̀rọ̀. Tẹ́tí sí ìhìn-iṣẹ́ tí wọ́n mú wá fún ọ láti inú Bibeli. Ìhìn-iṣẹ́ yìí kì í ṣe ti ìṣèlú ṣùgbọ́n ó ń ṣalágbàwí ìṣàkóso àtọ̀runwá nípasẹ̀ Ọlọrun, Ìjọba rẹ̀. Èyí ni ọ̀nà tí Ọlọrun yóò fi mú àwọn ohun tí ń fa ìforígbárí òde-òní kúrò. (Danieli 2:44) Lẹ́yìn náà ìṣàkóso yìí nípasẹ̀ Ọlọrun láti ọ̀run yóò ṣètò kí á yí gbogbo ilẹ̀-ayé padà sí paradise tí ó dàbí ọgbà Edeni.
Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tẹ́lẹ̀rí kan ti máa ń fìgbà gbogbo kọ̀ láti tẹ́tí sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà tí wọ́n bá bá a sọ̀rọ̀ nípa Bibeli. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìwà-ọ̀daràn tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi tí ó níláti dojúkọ, ìgbésí ayé mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Nítorí náà ó sọ fún Ẹlẹ́rìí tí ó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn náà pé òun yóò ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀rí fún àwọn ìhìn-iṣẹ́ Bibeli. Ìjíròrò déédéé tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́pàá náà ń kó kúrò ní ilé tí ó ń gbé ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fi ayọ̀-ìdùnnú wá a ní gbogbo ibi titun tí ó ń gbé láti máa bá ìjíròrò náà tẹ̀síwájú. Ní òpin gbogbo rẹ̀ òṣìṣẹ́ náà jẹ́wọ́ pé: “Ẹ̀rí tí mo ń wá wà níbẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ní gbogbo ìgbà. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn kò bá lo ìforítì ní bíbá mi sọ̀rọ̀, ǹ bá ṣì wà níta níbẹ̀ tí n óò máa ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìgbésí-ayé túmọ̀ sí. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, mo ti kọ́ òtítọ́ náà, èmi yóò sì lo ìgbésí-aye mi tí ó kù láti wá àwọn mìíràn tí ń wá Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣe.”
Àwọn olùgbọ́ tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ nítòótọ́ fẹ́ láti mọ̀ síi. Lọ́nà tí ó tọ́ wọ́n ń retí láti rí ìdí fún àwọn èrò-ìgbàgbọ́ tí a gbékalẹ̀. (1 Peteru 3:15) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré ti máa ń da ìbéèrè bo àwọn òbí rẹ̀ tí ó sì ń retí kí wọ́n dáhùn, ó yẹ kí o retí nítòótọ́ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí fún ọ ní àwọn ìdáhùn tí ó mọ́yánlórí. Ìwọ lè ní ìdánilójú pé wọn yóò láyọ̀ láti padà wá láti jíròrò ìhìn-iṣẹ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ síwájú síi.
Bóyá o ti mọ díẹ̀ nípa Bibeli tẹ́lẹ̀. O lè wá mọ̀ pé ohun tí Ọlọrun ń retí láti ọ̀dọ̀ rẹ yóò ní nínú àwọn ìyípadà kan nínú ọ̀nà tí o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ. Máṣe lọ́tìkọ̀ láti yẹ̀ ẹ́ wò nítorí ìbẹ̀rù pé ohun tí Ọlọrun ń béèrè yóò ná ọ ní ohun tí ó pọ̀ jù. Wọn yóò kàn mú ayọ̀ tòótọ́ wá ni. Ìwọ yóò mọrírì èyí bí o ti ń tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbé ẹni tí Jehofa jẹ́ yẹ̀wò, ohun tí ó retí láti ọ̀dọ̀ rẹ, àti ohun tí ó ń fún ọ. Béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí pé kí wọ́n fi ohun tí Bibeli sọ nípa èyí hàn ọ́. Yẹ ohun tí wọ́n sọ wò nínú ẹ̀dà Bibeli tìrẹ. Ní kíkẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi kọ́ni gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ nípa ìsìn lọ́gbọ́n nínú, láìṣe àní-àní ìwọ yóò fẹ́ láti túbọ̀ wá ìsọfúnni nípa ọ̀pọ̀ ohun tí ó dára síi tí wọ́n lè ṣalábàápín pẹ̀lú rẹ láti inú Ìwé Mímọ́.—Owe 27:17.
A késí ọ, láti ṣàkíyèsí àwọn Ẹlẹ́rìí ní ibi ìpàdé wọn ládùúgbò, ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti gbọ́ àwọn ìjíròrò tí ń ṣàǹfààní nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìwọ yóò rí i bí àwọn tí ó pésẹ̀ ti ń gbádùn bíbá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ète Ọlọrun. Gba àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ òtítọ́ nípa ohun tí ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́ fún wa lónìí. Dáhùnpadà sí ìkésíni Ọlọrun láti jíròrò nípa ìjọsìn tòótọ́ kí o sì rí ojú rere rẹ̀, àní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Paradise.—Malaki 3:16; Johannu 17:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Noa sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa ète Ọlọrun
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gẹ́gẹ́ bí Paulu ti ṣe ní Ateni ìgbàanì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bibeli