Ìwàláàyè Titun Yóò Wà fún Àwọn Babańlá Wa
ǸJẸ́ Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kọ́ wa pé gbogbo ènìyàn máa ń lọ wọ́ọ́rọ́wọ́ láti máa bá ìwàláàyè nìṣó ní ilẹ̀-ọba ẹ̀mí lẹ́yìn ikú bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, kò sọ bẹ́ẹ̀. Bibeli pèsè ìrètí àgbàyanu ti ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ ronú pé ó gbà ṣe é.
Ronú nípa ohun tí Bibeli sọ nípa babańlá wa àkọ́kọ́, Adamu. Jehofa “fi erùpẹ̀ ilẹ̀” mọ ọ́n. (Genesisi 2:7) Adamu ní àǹfààní láti wàláàyè títí láé nínú ayọ̀ lórí ilẹ̀-ayé. (Genesisi 2:16, 17) Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, ìyọrí sí rẹ̀ sì ni ikú.
Níbo ni Adamu lọ nígbà tí ó kú? Ọlọrun sọ fún un pé: “Ìwọ óò . . . padà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ ṣá ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.”—Genesisi 3:19.
Níbo ni Adamu wà ṣáájú kí Jehofa tó dá a láti inú erùpẹ̀? Kò sí níbikíbi. Òun kò sí níbì kankan. Nítorí náà nígbà tí Jehofa sọ pé Adamu yóò “padà sí ilẹ̀,” òun yóò wulẹ̀ ti ní in lọ́kàn pé Adamu yóò tún jẹ́ aláìlẹ́mìí lẹ́ẹ̀kan síi, gẹ́gẹ́ bí erùpẹ̀. Adamu kò ‘rékọjá’ lọ sọ́dọ̀ àwọn bàbá olùpilẹ̀ṣẹ̀ ayé àwọn ẹ̀mí babańlá. Bẹ́ẹ̀ ni òun kò kọjá lọ sí yálà ìwàláàyè ìgbádùn ní ọrun tàbí ti ìjìyà ayérayé ní ibi ìdálóró. Ìyípadà kanṣoṣo tí ó ṣe ni láti ìwàláàyè lọ sí ipò àìwàláàyè, láti ipò wíwà lọ sí ti àìsí.
Kí ni nípa ìyókù ìran-aráyé? Ǹjẹ́ àwọn ìrandíran Adamu pẹ̀lú kò sí mọ́ lẹ́yìn ikú bí? Bibeli dáhùn pé: “Níbì kannáà ni gbogbo wọn [àti àwọn ẹ̀dá-ènìyàn àti àwọn ẹranko] ń lọ; láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn sì tún padà di erùpẹ̀.”—Oniwasu 3:19, 20.
Ipò Àwọn Òkú
Bẹ́ẹ̀ni, àwọn òkú kò lẹ́mìí mọ́, wọn kò lè gbọ́ràn, ríran, sọ̀rọ̀, tàbí ronú. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli sọ pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Ìfẹ́ wọn, . . . àti ìríra wọn, àti ìlara wọn, ó parun nísinsìnyí.” Bibeli tún sọ pé: “Kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà-òkú níbi tí ìwọ ń rè.”—Oniwasu 9:5, 6, 10.
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti wí, nígbà tí àwọn ènìyàn wà láàyè, wọ́n mọ̀ nípa ikú. Bí ó tí wù kí ó rí, nígbà tí ikú bá dé, wọn kò mọ ohunkóhun mọ́. Wọn kì í dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú ara wọn, kí wọ́n máa wo ohun tí a ń ṣe sí i. Nínú ipò àìsí kò sí ìgbádùn tàbí ìrora, ìdùnnú-ayọ tàbí ìbànújẹ́. Àwọn tí wọ́n ti kú kò mọ̀ pé àkókò ń kọjá. Ipò tiwọn jẹ́ ti aláìmọ ohunkóhun mọ́ tí ó jinlẹ̀ ju ti oorun-kóorun lọ.
Jobu, ìránṣẹ́ Ọlọrun ní àkókò ìgbàanì, mọ̀ pé àwọn ènìyàn kì í báa lọ láti máa wàláàyè lẹ́yìn ikú. Ó tún lóye pé láìjẹ́ pé Ọlọrun bá dásí i, kì yóò sí ìrètí pípadà wàláàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Jobu wí pe: “Ènìyàn kú, a sì ṣàn danu; àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́, òun ha dà? [Òun] dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́.” (Jobu 14:10, 12) Dájúdájú Jobu kò retí pé nígbà tí òun bá kú òun yóò darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá òun ní ayé àwọn ẹ̀mí.
Ìrètí Àjíǹde
Níwọ̀n ìgbà tí àwọn alààyè kò máa báa lọ láti wàláàyè nígbà ikú, ìbéèrè pàtàkì náà ni èyí tí Jobu gbé dìde nígbà tí ó béèrè pé: “Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?” Jobu fúnra rẹ̀ fúnni ní ìdáhùn yìí pé: “Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi [àsìkò nínú sàárè] ni èmi óò dúró dè, títí àmúdọ̀tun mi yóò fi dé. Ìwọ [Jehofa] ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn, ìwọ óò sì ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Jobu 14:14, 15.
Ní èdè mìíràn ẹ̀wẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jobu yóò lọ sí ipò àìsí mọ́, Ọlọrun kì yóò gbàgbé rẹ̀. Jobu ní ìgbàgbọ́ pé àkókò kan yóò dé nígbà tí Jehofa Ọlọrun yóò ‘pe’ òun padà sí ìwàláàyè nípasẹ̀ àjíǹde.
Jesu Kristi, Ọmọkùnrin Ọlọrun, fi hàn pé ìrètí Jobu nínú àjíǹde jẹ́ òtítọ́ gidi. Jesu fi ẹ̀rí hàn pé àwọn òkú ni a lè jí dìde. Báwo? Nípa ṣíṣe é tí òun ṣe é! Òun kò sí níbẹ̀ láti jí Jobu dìde, ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé dájúdájú Jesu jí ọmọkùnrin opó kan láti ìlú-ńlá Naini dìde. Bákan náà Jesu jí ọmọ ọlọ́dún 12 kan dìde ọmọbìnrin ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jairu. Ó sì tún jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lasaru dìde, ẹni tí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin.—Luku 7:11-15; 8:41, 42, 49-56; Johannu 11:38-44.
Ní àfikún sí ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí, Jesu sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde tí ó galọ́lá ní ọjọ́-iwájú. Ó sọ pé: “Wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yóò sì jáde wá.” (Johannu 5:28, 29) Lẹ́yìn náà, aposteli Paulu, ẹni tí Jehofa lò láti jí ọ̀dọ́kùnrin kan dìde, pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ọjọ́-iwájú. Ó sọ pé: “Mo . . . ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.”—Ìṣe 20:7-12; 24:15.
Àwọn ìtọ́kasí Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí sí àjíǹde ọjọ́-iwájú kò ní í ṣe pẹ̀lú ìwàláàyè tí ń bá a nìṣó nínú ilẹ̀-ọba ẹ̀mí. Wọ́n tọ́ka sí àkókò náà nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òkú yóò padà sí ìwàláàyè nínú ara ìyára níhìn-ín gan-an lórí ilẹ̀-ayé. Àwọn wọ̀nyí tí a jí dìde kì yóò jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò rántí ìwàláàyè wọn ti tẹ́lẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. A kì yóò tún wọn bí gẹ́gẹ́ bí ìkókó. Dípò bẹ́ẹ̀, wọn yóò jẹ́ ẹni náà gan-an tí wọ́n jẹ́ nígbà tí wọ́n kú, tí wọ́n sì ní iyè-ìrántí àti àdìn ànímọ́ kan náà. Wọn yóò dá ara wọn mọ̀ àwọn mìíràn yóò sì dá wọn mọ̀. Ẹ wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí yóò jẹ́ bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe tún darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wọn! Ẹ sì wo bí yóò tí móríyá tó láti bá àwọn babańlá wa pàdé!
Àjíǹde sí Ìwàláàyè ní Ọ̀run
Jesu kò ha sọ pé àwọn kan yóò lọ sí ọ̀run bí? Bẹ́ẹ̀ni, ó sọ bẹ́ẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó pa á, ó sọ pé: “Ninu ilé Baba mi ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ. . . . Mo ń bá ọ̀nà mi lọ lati pèsè ibi kan sílẹ̀ fún yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ tí mo sì pèsè ibi kan sílẹ̀ fún yín, emi tún ń bọ̀ wá emi yoo sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi dájúdájú, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹlu lè wà níbẹ̀.” (Johannu 14:2, 3) Jesu ń bá àwọn aposteli rẹ̀ olóòótọ́ sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn rere yóò lọ sí ọ̀run.
Jesu fi hàn pé àwọn wọnnì tí a jí dìde sí ọ̀run gbọ́dọ̀ kún ojú ìlà ohun àbéèrè fún tí ó ju wíwulẹ̀ gbé ìgbésí-ayé tí ó dára lọ. Ohun àbéèrè fún kan ni láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa àti àwọn ète rẹ̀. (Johannu 17:3) Àwọn ohun àbéèrè fún mìíràn ni láti lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi àti láti ṣègbọràn sí Ọlọrun. (Johannu 3:16; 1 Johannu 5:3) Síbẹ̀ ohun àbéèrè fún mìíràn ni láti ‘tún ènìyàn bí’ gẹ́gẹ́ bíi Kristian kan tí ó ṣèrìbọmi tí a fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun bí. (Johannu 1:12, 13; 3:3-6) Ohun àbéèrè fún síwájú síi fún ìwàláàyè ní ọ̀run ni láti lo ìforítì bí Jesu ti ṣe, kí a sì fi ẹ̀rí jíjẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun hàn àní títí dé ojú ikú.—Luku 22:29; Ìṣípayá 2:10.
Ìdí wà fún irú àwọn ohun àbéèrè fún tí ó ga báyìí. Àwọn wọnnì tí a jí dìde sí ọ̀run ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe. Jehofa mọ̀ pé ìṣàkóso ẹ̀dá-ènìyàn kò lè ṣàṣeyọrí láé nínú bíbójútó àwọn àlámọ̀rí lórí ilẹ̀-ayé. Nítorí náà ó ṣètò fún ìṣàkóso ti ọ̀run, tàbí Ìjọba, tí yóò ṣàkóso lórí ìran-aráyé. (Matteu 6:9, 10) Jesu yóò jẹ́ Ọba Ìjọba náà. (Danieli 7:13, 14) Àwọn kan tí a ti yàn láti orí ilẹ̀-ayé tí a sì ti jí dìde sí ọ̀run yóò ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn wọ̀nyí tí a jí dìde yóò di “ìjọba kan ati àlùfáà fún Ọlọrun wa, wọn yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀-ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:10.
Àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ yóò ha kún ojú ìlà àwọn ohun àbéèrè fún fún àjíǹde ti ọ̀run bì? Bẹ́ẹ̀kọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ẹ̀bi wọn, èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn tí wọ́n ń sùn nínú ikú ni kò tóótun. Ọ̀pọ̀ ni kò ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jehofa àti àwọn ète rẹ̀. Wọ́n gbé ayé wọ́n sì kú láìní ìmọ̀ kankan nípa Jesu Kristi tàbí nípa Ìjọba Ọlọrun.
Jesu pe àwọn wọnnì tí yóò lọ sí ọ̀run ní “agbo kékeré.” (Luku 12:32) Lẹ́yìn náà a ṣí i payá pé iye àwọn wọnnì “tí a ti rà láti ilẹ̀-ayé wá” láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run yóò jẹ́ 144,000. (Ìṣípayá 14:1-3; 20:6) Nígbà tí 144,000 jẹ́ iye tí ó pọ̀ tó láti gba “ọ̀pọ̀ ibùjókòó” tí Jesu tọ́ka sí, ó kéré ní ìfiwéra pẹ̀lú ọ̀pọ̀ billion àwọn ènìyàn tí ó ti ọ̀dọ̀ Adamu wá.—Johannu 14:2.
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Ṣáájú Àjíǹde Orí Ilẹ̀-Ayé
Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí a ti ń jíròrò. Ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli, àwọn wọnnì tí wọ́n kú kò sí láàyè mọ́ nínú ikú títí di ìgbà tí Jehofa Ọlọrun bá jí wọn dìde. Àwọn kan ni a jí dìde sí ìwàláàyè ní ọ̀run, níbi tí wọn yóò ti ṣàkóso pẹ̀lú Jesu Kristi nínú ìṣàkóso Ìjọba. Àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jù ni a óò jí dìde sórí ilẹ̀-ayé, láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba náà.
Lápákan nípasẹ̀ àjíǹde ti orí ilẹ̀-ayé, Jehofa yóò mú ète rẹ̀ fún ilẹ̀-ayé ṣẹ. Jehofa dá a “kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Isaiah 45:18) Ó yẹ kí ó jẹ́ ilé ìran-aráyé láé fáàbàdà. Nítorí ìdí èyí, onipsalmu náà kọrin pé: “Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa; ṣùgbọ́n ayè ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Orin Dafidi 115:16.
Ṣáájú kí àjíǹde sí ìwàláàyè lórí ilẹ̀-ayé tó bẹ̀rẹ̀, àwọn ìyípadà ńláǹlà gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí o gbàgbọ́ pé kì í ṣe ète Ọlọrun fún ilẹ̀-ayé láti kún fún ogun, ìbàyíkájẹ́, ìwà-ọ̀daràn, àti ìwà-ipá. Àwọn ènìyàn tí kò ní ọ̀wọ̀ fún Ọlọrun àti àwọn òfin òdodo rẹ̀ ni ó fa àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Nítorí náà, Ìjọba Ọlọrun yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bàjẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́”—ìgbésẹ̀ pàtàkì kan ní mímú ète rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé ṣẹ. (Ìṣípayá 11:18) Ìjọba náà yóò pa gbogbo àwọn olùṣe búburú run, yóò sì fi àwọn olódodo sílẹ̀ láti gbé lórí ilẹ̀-ayé títí láé.—Orin Dafidi 37:9, 29.
Paradise Lórí Ilẹ̀-Ayé
Àwọn wọnnì tí a óò jí dìde sórí ilẹ̀-ayé tí a ti fọ̀ mọ́ yóò jẹ́ onínú tútù, àwọn tí ó bìkítà tí ń ṣe ohun tí ó tọ́. (Fiwé Matteu 5:5.) Lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Ìjọba Ọlọrun, wọn yóò gbé ìgbésí-ayé aláyọ̀ láìséwu. Bibeli fúnni ní àgbàyanu àpẹẹrẹ àkọ́wò ti àwọn ipò nǹkan tí yóò gbalé-gbòde pé: “[Ọlọrun] yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Bẹ́ẹ̀ni, ayé ni a óò yí padà dí paradise. (Luku 23:43) Ronú nípa ohun tí èyí yóò túmọ̀ sí! Ilé-ìwòsàn àti ilé ìtọ́jú aláìsàn yóò di ohun àtijọ́. Nínú Paradise, àwọn wọnnì tí ọjọ́-ogbó ti sọ di kẹ́gẹkẹ̀gẹ nísinsìnyí yóò lágbára wọn yóò sì ní ìlera lẹ́ẹ̀kan síi. (Jobu 33:25; Isaiah 35:5, 6) Kì yóò sí àwọn ilé ààtò ìsìnkú, àwọn ibi ìsìnkú, àti àwọn òkúta ìrántí òkú mọ́. Nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, Jehofa yóò “gbé ikú mì láéláé.” (Isaiah 25:8) Irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ dájúdájú lè túmọ̀ sí ìwàláàyè titun fún wa àti fún àwọn babańlá wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn wọnnì tí a jí dìde sórí ilẹ̀-ayé yóò jẹ́ ọmọ-abẹ́ Ìjọba náà