Ìlérí Ayé kan Láìsí Ìwà Ìbàjẹ́
ÌWÀ ìbàjẹ́ ti wọnú gbogbo ipele ẹgbẹ́ àwùjọ. Ìbáà jẹ́ nínú ìṣàkóso, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, eré ìdárayá, ìsìn, tàbí ìṣòwò, ó dàbí ẹni pé ọwọ́ kò lè ká ìwà ìbàjẹ́ mọ́.
Láti orílẹ̀-èdè kan sí èkejì, àwọn ìròyìn tí ń múni soríkọ́ nípa ìwà ìbàjẹ́ tí ń tini lójú ń fara hàn nínú ìwé ìròyìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n ti pinnu láti ṣiṣẹ́sìn fún ire àǹfààní àwọn ènìyàn ni a ti táṣìírí wọn pé wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn fún ire àǹfààní ti ara wọn nípa gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti owó-ẹ̀yìn. Ìwà ọ̀daràn tí a pè ní ti àwọn òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì wọ́pọ̀. Àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ síi tí wọ́n wà ní ipò gíga nínú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ọrọ̀-ajé jẹ̀bi ríré òfin tí ó de ìwà ọ̀daràn àti ìlànà ìwàhíhù kọjá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn ojoojúmọ́.
Àníyàn tí ń pọ̀ síi wà lórí ohun tí ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà ilẹ̀ Europe kan ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “‘ìwà ìbàjẹ́ lílékenkà’—ìwà kan nínú èyí tí àwọn lọ́gàá lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba, àwọn mínísítà àti, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti máa ń béèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti owó ẹ̀yìn ṣáájú kí wọ́n tó fọwọ́ sí ríra àwọn nǹkan pàtàkì àti dídáwọ́lé iṣẹ́ ìdàgbàsókè.” Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì The Economist sọ pé ní orílẹ̀-èdè kan “ìwádìí tí àwọn ọlọ́pàá ṣe fún ọdún méjì àti fífàṣẹ ọba múni tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójoojúmọ́ kò tí ì ṣèdíwọ́ fún àwọn tí ìwà ìbàjẹ́ ti wọ̀ lẹ́wù.”
Nítorí ìwà ìbàjẹ́ tí ó ti tànkálẹ̀ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lónìí nímọ̀lára pé kò sí ẹnikẹ́ni tí àwọn lè gbẹ́kẹ̀lé. Wọ́n ń sọ èrò ìmọ̀lára òǹkọ̀wé Bibeli náà Dafidi, ní àsọtúnsọ nígbà tí ó sọ pé: “Gbogbo wọn ni ó sì jùmọ̀ yà sí apákan, wọ́n sì di eléèérí pátápátá; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò sí ẹnì kan.”—Orin Dafidi 14:3.
Báwo ni o ṣe ń kojú ìjótìítọ́ ìwà ìbàjẹ́ tí ń tànkálẹ̀? Àwọn ènìyàn púpọ̀ jùlọ lónìí wulẹ̀ ń ṣá a tì. Ṣùgbọ́n bí o bá tilẹ̀ ṣá ìwà ìbàjẹ́ tì, yóò ṣì pa ọ́ lára. Lọ́nà wo?
Ìwà Ìbàjẹ́ Ń Nípa Lórí Rẹ
Ìwà ìbàjẹ́ ńlá àti kékeré ń mú kí owó ìgbọ́bùkátà ga síi, ó ń dín ìjójúlówó àwọn ohun tí a ń mú jáde kù, ó sì ń yọrí sí iṣẹ́ tí kò pọ̀ tó àti owó-ọ̀yà tí ó lọ sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ìwà ọ̀daràn bíi kíkówó jẹ àti yíyíwèé ń náni ní ó kéré tán ìlọ́po mẹ́wàá àpapọ̀ iye tí ìfọ́lé, ìdigunjalè, àti olè jíjà ń náni. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica (1992) sọ pé “ipa ti ìwà ọ̀daràn àwọn ilé-iṣẹ́ ń ní ní United States ni a ti fojú díwọ̀n sí $200,000,000,000 ní ọdún kan—ìlọ́po mẹ́ta iye tí ìwà ọ̀daràn tí a ṣètò ń náni.” Orísun yìí ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má tètè rí àwọn ipa tí ń ní, “irú ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ ń ní ipa ńláǹlà lórí ààbò àwọn òṣìṣẹ́, àwọn aláràlò, àti àyíká.”
Àwọn àbájáde tí ń kó wàhálà báni ti ìwà ìbàjẹ́ rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Solomoni pé: “Mo padà, mo sì ro ìnilára gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn; mo sì wo omijé àwọn tí a ń nilára, wọn kò sì ní olùtùnú; àti lọ́wọ́ aninilára wọn ni ipá wà; ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú.”—Oniwasu 4:1.
Nígbà náà, àwa ha níláti jọ̀wọ́ ara wa fún ìwà ìbàjẹ́ bí? Ohun tí kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀ ha ni bí? Ayé kan láìsí ìwà ìbàjẹ́ ha jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ bí? Ó dùnmọ́ni pé, kì í ṣe bẹ́ẹ̀! Bibeli kọ́ wa pé àìṣèdájọ́-òdodo àti ìwà àìlófin ni a óò mú kúrò láìpẹ́.
Ohun Tí Bibeli Sọ fún Wa
Bibeli sọ fún wa pé ìwà ìbàjẹ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì alágbára kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun tí ó sì sún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ láti darapọ̀ mọ́ òun. (Genesisi 3:1-6) Ohun rere kan kò ti inú ipa-ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, láti ọjọ́ tí Adamu àti Efa ti ṣẹ̀ sí Jehofa Ọlọrun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jìyà àbájáde búburú ti ìwà ìbàjẹ́. Ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ padà sẹ́yìn díẹ̀díẹ̀, tí ó sì yọrí sí ikú tí kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀. (Genesisi 3:16-19) Láti ìgbà náà, ọ̀rọ̀ ìtàn kún fún àwọn àpẹẹrẹ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ìtànjẹ, àti ìwé yíyí. Síbẹ̀, ó dàbí ẹni pé àwọn ọ̀dádá tí ó pọ̀ jùlọ máa ń mú un jẹ.
Láìdàbí àwọn ọ̀daràn lásán, àwọn ọ̀gá àgbà àti olóṣèlú oníwà ìbàjẹ́ kì í sábà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí san ìsanpadà fún èrè tí wọ́n fi èrú kó jọ. Nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀, owó-ẹ̀yìn, àti rìbá jẹ́ ohun tí a ń yọ́ ṣe, ó sábà máa ń ṣòro láti táṣìírí ìwà ìbàjẹ́ ńlá. Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé ayé kan láìsí ìwà ìbàjẹ́ jẹ́ àlá kan tí kò lè ṣẹ.
Ìdásílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ yóò wá láti ọwọ́ Ẹlẹ́dàá ènìyàn, Jehofa Ọlọrun. Dídásí ọ̀ràn látọ̀runwá ni ojútùú kanṣoṣo náà. Èéṣe? Nítorí pé ọ̀tá aráyé tí a kò lè fojúrí, Satani Èṣù, ń bá a nìṣó láti ṣi aráyé lọ́nà. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á ní 1 Johannu 5:19, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” Kí ni ohun mìíràn tí ó lè ṣàlàyé ìpeléke ìwà ìbàjẹ́—ọ̀pọ̀ èyí tí a ṣe ní àṣegbé?
Kò sí ìsapá ẹ̀dá ènìyàn kankan tí ó lè borí Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀. Kìkì dídásí ọ̀ràn látọ̀runwá ni ó lè mú “òmìnira ológo ti awọn ọmọ Ọlọrun” dá aráyé onígbọràn lójú. (Romu 8:21) Jehofa ṣèlérí pé láìpẹ́ a óò ká Satani lọ́wọ́ kò kí ó má baà lè tan aráyé jẹ mọ́. (Ìṣípayá 20:3) Nísinsìnyí ná, bí a bá ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé nínú ayé titun Ọlọrun tí yóò dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́, a gbọ́dọ̀ kọ àwọn ọ̀nà ìbàjẹ́ ayé yìí.
Àwọn Ènìyàn Lè Yípadà
Ní ọjọ́ Jesu Kristi, àwọn wọnnì tí wọ́n ṣi agbára wọn lò tí wọ́n sì tẹ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lórí ba wà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn agbowó-orí lókìkí burúkú nítorí ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń hù. Èyí jẹ́ láìka òfin Ọlọrun tí ó ṣe kedere sí pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ àwọn tí ó ríran kedere lójú ó sì lè yí ọ̀rọ̀ àwọn olódodo padà.” (Eksodu 23:8, NW) Sakeu, olórí agbowó-orí, gbà pé òun lọ́ni lọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ ẹ̀sùn èké. Ṣùgbọ́n dípò gbígbé ìṣàtúnṣe ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà lọ́nà gbígbòòrò lárugẹ, Jesu rọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ronúpìwàdà kí wọ́n sì pa àwọn ọ̀nà ìwà ìbàjẹ́ wọn tì. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, àwọn bí Matteu àti Sakeu tí a mọ̀ sí oníwà ìbàjẹ́ agbowó-orí pa ìgbésí-ayé wọn tẹ́lẹ̀rí tì.—Matteu 4:17; 9:9-13; Luku 19:1-10.
Àwọn wọnnì tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìwà àbòsí lónìí bákan náà lè kọ ìwà ìbàjẹ́ sílẹ̀ nípa gbígbé “àkópọ̀ ìwà titun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tòótọ́ ati ìdúróṣinṣin.” (Efesu 4:24) Ó lè má rọrùn láti máa san owó-orí láìlábòsí tàbí láti dẹ́kun lílọ́wọ́ nínú àwọn ètò kan tí ó lè gbé ìbéèrè dìde. Síbẹ̀, àwọn àǹfààní rẹ̀ yẹ fún ìsapá èyíkéyìí tí a bá lè sà.
Níwọ̀n bí ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí kò ti darí wọn mọ́, àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa ire aásìkí àwọn ẹlòmíràn ń gbádùn àlàáfíà inú-lọ́hùn-ún. Kò sí ìbẹ̀rù bóyá a lè gbá wọn mú nínú ìwà àìtọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ẹ̀rí-ọkàn rere. Wọ́n tẹ̀lé àpẹẹrẹ wòlíì Danieli ti inú Bibeli. Àkọsílẹ̀ Bibeli sọ pé àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́ onípò gíga ń fìgbà gbogbo wá ẹ̀sùn kan sí Danieli lẹ́sẹ̀. “Ṣùgbọ́n wọn kò lè rí ẹfẹ́kẹ́fẹ̀ẹ́ tàbí ẹ̀ṣẹ̀kẹ́sẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; níwọ̀n bí òun ti jẹ́ olódodo ènìyàn tóbẹ́ẹ̀ tí a kò sì rí ìṣìnà tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.”—Danieli 6:5.
Ìlérí Jehofa
Jehofa ṣèlérí pé “bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi nígbà ọgọ́rùn-ún, tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, ṣùgbọ́n nítòótọ́, èmi mọ̀ pé yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀: ṣùgbọ́n kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gùn tí ó dàbí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọrun.”—Oniwasu 8:12, 13.
Ẹ wo bí yóò ti tunilára tó nígbà tí ìwà ìbàjẹ́ kò bá fa àìláyọ̀ mọ́! Ẹ wo irú ìbùkún tí yóò jẹ́ láti gbé títí láé nínú ayé kan níbi tí kò sí ìwà ìbàjẹ́! Èyí kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun èyí tí Ọlọrun, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí ṣáájú awọn àkókò pípẹ́ títí.” (Titu 1:2) Bí o bá kórìíra ìwà ìbàjẹ́ tí o sì nífẹ̀ẹ́ òdodo, dájúdájú ó ṣeé ṣe kí o rí ìmúṣẹ ìlérí Ọlọrun nípa ayé kan láìsí ìwà ìbàjẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìwà ìbàjẹ́ wọ́pọ̀ ní àwùjọ ìjọba àti ti òkòwò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìwà ìbàjẹ́ sábà máa ń nípa lórí ìbálò pẹ̀lú àwọn aṣojú ìjọba