ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 44
  • Ṣé Ìwà Ìbàjẹ́ Tí Àwọn Ìjọba Ń Hù Máa Dópin?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìwà Ìbàjẹ́ Tí Àwọn Ìjọba Ń Hù Máa Dópin?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ìbàjẹ́
  • Ìjọba tí kò ní hùwà ìbàjẹ́
  • Ìjọba Ọlọ́run—Ìjọba Tó Máa Fòpin Sí Ìwà Ìbàjẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìlérí Ayé kan Láìsí Ìwà Ìbàjẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Fífi Idà Ẹ̀mí Gbógun Ti Ìwà Ìbàjẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìwà Ìbàjẹ́ Inú Ìjọba Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 44
Àwọn ọkùnrin méjì ń bọ ara wọn lọ́wọ́ níwájú ọ́fíìsì ìjọba. Ọ̀kan nínú wọn ń fún ìkejì ní àpò tí owó kún inú ẹ̀.

Ṣé Ìwà Ìbàjẹ́ Tí Àwọn Ìjọba Ń Hù Máa Dópin?

Kárí ayé làwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti ń hùwà ìbàjẹ́, ìyẹn sì ti fa ìṣòro tó pọ̀ gan-an.a Bí àpẹẹrẹ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kárí ayé ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n kó owó tó yẹ kí wọ́n fi ran àwọn aráàlú lọ́wọ́ lásìkò yẹn sápò ara wọn. Ìwà ìbàjẹ́ yìí ò jẹ́ káwọn èèyàn rí ìtọ́jú tó yẹ, ìyẹn sì mú kí nǹkan nira gan-an fáwọn èèyàn, kódà ẹ̀mí àwọn kan lọ sí i.

Ìṣòro tó kárí ayé ni ìwà ìbàjẹ́ táwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ń hù. David Cameron tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olórí ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí orílẹ̀-èdè kan láyé yìí táwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kì í tíì hùwà ìbàjẹ́.”

Àmọ́, ó dá wa lójú pé láìpẹ́ gbogbo ìwà ìbàjẹ́ yìí máa dópin. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ wo ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe.

Ìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ìbàjẹ́

Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé: “Èmi Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti àìṣòdodo.”b (Àìsáyà 61:8) Ọlọ́run ń rí bí ìwà ìbàjẹ́ táwọn kan ń hù ṣe ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn jìyà. (Òwe 14:31) Ó ṣèlérí pé: “Nítorí ìnira àwọn tí ìyà ń jẹ, . . . màá dìde láti gbé ìgbésẹ̀.”​—Sáàmù 12:5.

Kí ni Ọlọ́run máa ṣe? Dípò tí Ọlọ́run fi máa tún àwọn ìjọba yìí ṣe, ṣe ló máa fi ìjọba tiẹ̀ rọ́pò wọn, Bíbélì pe ìjọba yìí ní “Ìjọba Ọlọ́run.” (Máàkù 1:14, 15; Mátíù 6:10) Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, . . . Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ọlọ́run máa tipa bẹ́ẹ̀ fòpin sí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ tá à ń rí lónìí.

Ìjọba tí kò ní hùwà ìbàjẹ́

Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní sí ìwà ìbàjẹ́ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí yìí.

  1. 1. Agbára. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè ni Ìjọba náà ti gba agbára.​—Ìfihàn 11:15.

    Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Owó táwọn aráàlú bá ń san ni ìjọba èèyàn fi ń bójú tó àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan máa ń lo àǹfààní yẹn láti jí owó, láti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí kí wọ́n hu àwọn ìwà ìbàjẹ́ míì. Àmọ́, Ìjọba Ọlọ́run ò nílò owó látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn torí pé Ọlọ́run Olódùmarè fúnra ẹ̀ ló ń ti Ìjọba náà lẹ́yìn. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó bá wà lábẹ́ Ìjọba náà máa ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò.​—Sáàmù 145:16.

  2. 2. Alákòóso. Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà.​—Dáníẹ́lì 7:13, 14.

    Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Kò sí bí alákòóso kan nínú ayé ṣe lè ní ire àwọn èèyàn lọ́kàn tó, àwọn kan ṣì máa fẹ́ kó ṣe ohun tí kò tọ́. (Oníwàásù 7:20) Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò rí bẹ́ẹ̀ torí ó fi hàn nígbà tó wà láyé pé òun kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Mátíù 4:8-11) Bákan náà, ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ dénú, ìfẹ́ yìí ló sì ń mú kó máa ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe.​—Sáàmù 72:12-14.

  3. 3. Òfin. Àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run pé, wọ́n tiẹ̀ ń tuni lára.​—Sáàmù 19:7, 8.

    Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Lọ́pọ̀ ìgbà, òfin táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ máa ń lọ́jú pọ̀, ó máa ń nira, ó sì máa ń jẹ́ káwọn kan lè hùwà ìbàjẹ́. Lọ́wọ́ kejì, àwọn òfin Ọlọ́run wúlò, ó sì máa ń ṣeni láǹfààní. (Àìsáyà 48:17, 18) Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe ìwà téèyàn bá hù nìkan ni òfin yẹn dá lé, ó tún kan ohun tó ń sún èèyàn ṣe nǹkan. (Mátíù 22:37, 39) Ká rántí pé Ọlọ́run lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa, torí náà ó lè fìfẹ́ tọ́ wa sọ́nà tá a bá ní èrò tí kò tọ́.​—Jeremáyà 17:10.

A fẹ́ kó o wá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ìjọba kan ń bọ̀ tí kò ní hùwà ìbàjẹ́.

  • Tó o bá fẹ́ rí ìdí mẹ́ta míì tó kò fi ní sí ìwà ìbàjẹ́ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìjọba Ọlọ́run, Ìjọba Tó Bọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ìbàjẹ́.”

  • Tó o bá fẹ́ mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé ṣe, wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

  • Tó o bá fẹ́ mọ bí àwọn ìlérí inú Bíbélì ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní, o lè ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

a Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé, “ìwà ìbàjẹ́” ni kéèyàn ṣi agbára tó wà níkàáwọ́ ẹ̀ lò fún àǹfààní ara rẹ̀.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”

Wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà? kó o lè mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ìbàjẹ́ táwọn ìjọba ń hù àtàwọn nǹkan míì tó ń jẹ́ káwa èèyàn máa jìyà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́