Ìpàdé Ọdọọdún—October 7, 1995
ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti mẹ́ḿbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a ó ṣe ní October 7, 1995, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ìpàdé àṣeṣáájú ti kìkì àwọn mẹ́ḿbà yóò bẹ̀rẹ̀ ní agogo 9:30 òwúrọ̀, tí ìpàdé ọdọọdún ti gbogbogbòò yóò sì tẹ̀lé e ní agogo 10:00 òwúrọ̀.
Àwọn mẹ́ḿbà Àjọ-Ẹgbẹ́ níláti fi tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí nípa ìyípadà èyíkéyìí nínú àwọn àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn ní àárín ọdún tí ó kọjá kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tí a ń lò déédéé baà lè dé ọ̀dọ̀ wọn kété ní July.
Àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni náà, tí a óò fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ḿbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún, ni a níláti dá padà ki ó baà lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society láìpẹ́ ju August 1 lọ. Mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan níláti kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíámọ́sá kí ó sì dá a padà ní sísọ yálà pé òun yóò wà ní ibi ìpàdé náà fúnra òun tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Ìsọfúnni tí a fifúnni lórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan níláti ṣe pàtó lórí kókó yìí, níwọ̀n bí a óò ti gbáralé e ní pípinnu àwọn wo ni yóò wà níbẹ̀ fúnra wọn.
A retí pé gbogbo àkókò ìjókòó náà, títí kan àwọn ìpàdé iṣẹ́ àmójútó elétò-àṣà àti àwọn ìròyìn, ni a óò parí rẹ̀ ní agogo 1:00 ọ̀sán tàbí kété lẹ́yìn náà. Kì yóò sí àkókò ìjókòó ọ̀sán. Nítorí àyè tí o mọ níwọ̀n, ìgbàwọlé yóò jẹ́ nípasẹ̀ tíkẹ́ẹ̀tì nìkan ṣoṣo. Kò sí ìṣètò kankan fún síso ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ wáyà tẹlifóònù lọ sí àwọn gbọ̀ngàn àwùjọ mìíràn.