ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/15 ojú ìwé 31
  • Ìpàdé Ọdọọdún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpàdé Ọdọọdún
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé Ọdọọdún
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 7, 2000
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 7, 2000
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 4, 1997
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/15 ojú ìwé 31

Ìpàdé Ọdọọdún

OCTOBER 7, 1995

ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti àwọn mẹ́ḿbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a óò ṣe ní October 7, 1995, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ìpàdé àṣeṣaájú ti kìkì àwọn mẹ́ḿbà ni yóò bẹ̀rẹ̀ ní agogo 9:30 òwúrọ̀, tí ìpàdé ọdọọdún ti gbogbogbòò yóò sì tẹ̀lé e ní agogo 10:00 òwúrọ̀.

Àwọn mẹ́ḿbà Àjọ-Ẹgbẹ́ níláti fi tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí nípa ìyípadà èyíkéyìí nínú àwọn àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn láàárín ọdún tí ó kọjá kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tí a ń lò déédéé baà lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní July.

Àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni náà, tí a óò fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ḿbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún, ni a níláti dá padà kí ó baà lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society láìpẹ́ ju August 1 lọ. Mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan níláti kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíámọ́sá kí ó sì dá a padà ní sísọ yálà òun yóò wà ní ibi ìpàdé náà fúnra-òun tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Ìsọfúnni tí a fifúnni lórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan níláti ṣe pàtó lórí kókó yìí, níwọ̀n bí a óò ti gbáralé e ní pípinnu àwọn wo ni yóò wà níbẹ̀ fúnra wọn.

A retí pé gbogbo àkókò ìjókòó náà, títí kan àwọn ìpàdé iṣẹ́ àmójútó elétò-àṣà àti àwọn ìròyìn, ni a óò parí rẹ̀ ni agogo 1:00 ọ̀sán tàbí kété lẹ́yìn náà. Kì yóò sí àkókò ìjókòó ọ̀sán. Nítorí àyè tí ó mọníwọ̀n, ìgbàwọlé yóò jẹ́ nípasẹ̀ tíkẹ́ẹ̀tì nìkan ṣoṣo. Kò sí ìṣètò kankan fún síso ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ wáyà tẹlifóònù lọ sí àwọn gbọ̀ngàn àwùjọ mìíràn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́