Ìgbà Ti Yípadà
Ẹ WO irú ìdùnnú-ayọ̀ tí ó ti gbọ́dọ̀ jẹ́ láti gbé ní Israeli ìgbàanì lábẹ́ ìṣàkóso ológo olùṣòtítọ́ Ọba Solomoni! Ó jẹ́ sànmánì alálàáfíà, aláásìkí, àti aláyọ̀. Nígbà tí Solomoni dúró gbọn-in-gbọn-in fún ìjọsìn tòótọ́, Jehofa bùkún orílẹ̀-èdè náà lọ́pọ̀ yanturu. Kì í ṣe ọrọ̀ ńlá nìkan ni Ọlọrun fún Ọba Solomoni, ṣùgbọ́n ó tún fún un ní “ọkàn ọgbọ́n àti ìmòye” kí Solomoni ba lè ṣàkóso ní òdodo àti ìfẹ́. (1 Awọn Ọba 3:12) Bibeli sọ pé: “Gbogbo àwọn ọba ayé sì ń wá ojú Solomoni, láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ tí Ọlọrun ti fi sí i ní ọkàn.”—2 Kronika 9:23.
Jehofa fún àwọn ènìyàn náà ní ààbò, àlàáfíà, àti àwọn ohun rere lọ́pọ̀ yanturu. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Juda àti Israeli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá.” Níti gidi àti lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn náà “ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ . . . ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.”—1 Awọn Ọba 4:20, 25.
Ìgbà ti yípadà. Ìgbésí-ayé lónìí ti yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọjọ́ aláyọ̀ ti ìgbà tí ó ti kọjá sẹ́yìn. Ìṣòro tí ó pọ̀ jù lónìí ni òṣì, èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ ní ìgbà ti Solomoni. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ pàápàá, òṣì wà. Fún àpẹẹrẹ, ní United States àti nínú Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ṣepọ̀ Ilẹ̀ Europe, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdá 15 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn ni ń gbé nínú òṣì, ni Ètò Ìdàgbàsókè Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàkíyèsí.
Nípa bí nǹkan ṣe rí káàkiri àgbáyé, àkọsílẹ̀ ìròyìn The State of the World’s Children 1994, ìròyìn kan láti ọwọ́ ètò-àjọ UNICEF (Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé), ṣàkíyèsí pé ìdá kan nínú márùn-ún àwọn olùgbé ayé ní ń gbé nínú òṣì pátápátá, ó fi kún un pé ìgbésí-ayé fún èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn òtòṣì ní ayé “túbọ̀ ń lekoko síi tí kò sì sí ìrètí.”
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ìfòsókè fíofío owó-ọjà tún ń dákún ìṣòro àwọn òtòṣì. Obìnrin kan ní ilẹ̀ Africa kan sọ pé: “Bí o bá rí ohun kan ní ọjà, tí o sọ pé, ‘Kò burú, jẹ́ kí ń lọ sílé kí n lọ mówó wá láti wá rà á.’ Bí o bá padà débẹ̀ ní wákàtí kan lẹ́yìn náà kìkì ohun tí wọn yóò sọ fún ọ ni pé o kò lè rà á nítorí iye owó rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sókè. Kí ni ẹnì kan yóò ṣe? Ó ń jánikulẹ̀ gan-an ni.”
Obìnrin mìíràn níbẹ̀ sọ pé: ‘Láti lè là á já, a ń gbàgbé àwọn àìní mìíràn. Ohun tí ó bá wa ni bí a óò ṣe rí oúnjẹ.’
Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ, ọjọ́-iwájú ṣú bàìbàì. Ètò-àjọ UNICEF, fún àpẹẹrẹ, fojúdíwọ̀n pé bí ìlọsókè iye ènìyàn nísinsìnyí bá ń bá a lọ, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ òtòṣì kárí ayé yóò lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́rin “láàárín àkókò ìgbésí-ayé kanṣoṣo.”
Síbẹ̀, láìka ipò ọrọ̀-ajé àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ń burú síi sí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ìdí láti nímọ̀lára nǹkan-yóò-dára. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé láàárín àwọn wọnnì tí ń wo ọjọ́-iwájú pẹ̀lú èrò nǹkan-kò-lè-dára, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ń wo ọjọ́-iwájú pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ àti ìgbọ́kànlé. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò wádìí èéṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
De Grunne/Sipa Press