Èrè Ìtẹpẹlẹmọ́
OBÌNRIN ará Griki ni tí ń gbé ní Foniṣia ní ọdún 32 C.E. Ọmọbìnrin rẹ̀ ń ṣàìsàn gidigidi, obìnrin náà sì gbékútà láti lè rí ìwòsàn. Ní gbígbọ́ pé àlejò kan wá ṣèbẹ̀wò sí ẹkùn-ilẹ̀ rẹ̀—àjèjì kan tí òkìkí rẹ̀ kàn pé ó ní agbára láti wo aláìsàn sàn—ó pinnu láti rí i kí ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ rẹ̀.
Nígbà tí ó bá a pàdé, ó kúnlẹ̀, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ pé: “Ṣàánú fún mi, Oluwa, Ọmọkùnrin Dafidi. Ẹ̀mí-èṣù gbé ọmọbìnrin mi dè burúkú-burúkú.” Lọ́nà yẹn, obìnrin ará Griki náà bẹ Jesu láti wo ọmọbìnrin rẹ̀ sàn.
O ha lè finúwòye ìgboyà àti ìrẹ̀lẹ̀ tí ó béèrè lọ́dọ̀ obìnrin náà láti ṣe èyí? Ẹni pàtàkì tí ó ní agbára àti orúkọ rere ni Jesu jẹ́, ó sì ti jẹ́ kí ó di mímọ̀ ṣáájú pé òun kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí òun wà. Ó mú àwọn aposteli rẹ̀ lọ sí Foniṣia láti lè rí àyè sinmi, kì í ṣe láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn Kèfèrí aláìgbàgbọ́. Síwájú síi, Júù ni Jesu obìnrin náà sì jẹ́ Kèfèrí, kò sì sí iyèméjì pé obìnrin náà mọ̀ nípa ìkórìíra tí àwọn Júù ní sí kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí a fojú tẹ́ḿbẹ́lú. Síbẹ̀síbẹ̀, ó dúró ti ìpinnu rẹ̀ láti gba ìwòsàn fún ọmọ rẹ̀.
Jesu àti àwọn aposteli rẹ̀ gbìdánwò láti rọ obìnrin náà láti máṣe wá ìrànwọ́ ní àkókò yẹn. Lákọ̀ọ́kọ́, Jesu kò dá a lóhùn. Lẹ́yìn náà, nítorí ẹkún rẹ̀ léraléra, tí ó sì tẹpẹlẹmọ́ ọn, àwọn aposteli fi pẹ̀lú ìbínú sọ fún Jesu pé: “Rán an lọ; nitori pé ó ń ké jáde tẹ̀lé wa lẹ́yìn ṣáá.”
Ṣùgbọ́n kò dẹ́kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń sọ pé: “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́!”
Ní títọ́ka sí ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ ní pàtàkì sí àwọn ọmọ Israeli àti, ní àkókó kan náà, ní dídán ìgbàgbọ́ àti ìpinnu rẹ̀ wò, Jesu fi pẹ̀lú ìyọ́nú ṣàlàyé fún un pé: “Kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì awọn ọmọ [Israeli] kí a sì sọ ọ́ sí awọn ajá kéékèèké [àwọn Kèfèrí].”
Kàkà kí ọ̀rọ̀ àìbáradé náà tí a sọ sí ìran rẹ̀ mú un bínú, ó fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ tẹpẹlẹmọ́ ìwákiri rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa; ṣugbọn awọn ajá kéékèèké níti gidi máa ń jẹ ninu èérún tí ń jábọ́ lati orí tábìlì awọn ọ̀gá wọn.”
Jesu san èrè fún ìtẹpẹlẹmọ́ obìnrin ará Griki náà nípa gbígbóríyìn fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti fífi ojúrere hàn sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀. Finúwòye ìdùnnú-ayọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó padà sí ilé tí ó sì rí ọmọbìnrin rẹ̀ tí ara rẹ̀ ti yá pátápátá!—Matteu 15:21-28; Marku 7:24-30.
Gẹ́gẹ́ bíi ti obìnrin ọ̀rúndún kìn-ínní náà, a gbọ́dọ̀ tẹpẹlẹmọ́ ọn nínú ìsapá wa láti mú inú Jehofa dùn kí a sì jèrè ojúrere rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti rí níti obìnrin ará Griki náà, Bibeli mú un dá wa lójú pé ìtẹpẹlẹmọ́ wa “ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀” ni a óò san èrè fún.—Galatia 6:9.
Kí ni ìtẹpẹlẹmọ́? Èéṣe tí a fi nílò rẹ̀? Àwọn kókó-abájọ wo ni ó lè mú kí a pàdánù ànímọ́ yìí, láti káàárẹ̀ tàbí juwọ́sílẹ̀? Èrè wo ni a lè retí láti gbà bí a bá ń lo ìtẹpẹlẹmọ́ nísinsìnyí nínú ṣíṣiṣẹ́sin Ẹlẹ́dàá àti Bàbá wa, Jehofa?
Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe náà “tẹpẹlẹmọ́” sí “láti di ète, ipò, tàbí ìdáwọ́lé kan mú ṣinṣin tàbí láìyẹsẹ̀, láìka àwọn ohun ìdènà, ìkìlọ̀, tàbí ìfàsẹ́yìn sí. . . . láti máa wàláàyè nìṣó; láti wà pẹ́ títí.”
Léraléra ni Bibeli gba àwọn ìránṣẹ́ Jehofa níyànjú láti máa tẹpẹlẹmọ́ ṣíṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, a sọ fún wa láti “máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa . . . lákọ̀ọ́kọ́,” láti “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin,” láti “máa ní ìforítì ninu àdúrà,” kí a má sì ṣe “juwọ́sílẹ̀” ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.—Matteu 6:33; 1 Tessalonika 5:21; Romu 12:12; Galatia 6:9.
Nínú àlámọ̀rí ìgbésí-ayé ojoojúmọ́, ìtẹpẹlẹmọ́ jẹ́ ànímọ́ kan tí gbogbo wa gbọ́dọ̀ ní kí a sì mú dàgbà kí a baà lè làájá. Láìsí i a kò lè ṣàṣeyọrí ohunkóhun tí ó ní ìníyelórí tòótọ́, tí ó sì wà pẹ́ títí. Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ ọmọ-ọwọ́ tí ó ń gbìyànjú láti dìde dúró kí ó sì rìn tàgé tàgé fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó ṣòro kí ìkókó náà kọ́ láti dìde kí ó sì rìn fàlàlà ní ọjọ́ kanṣoṣo. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ-ọwọ́, gbogbo wa ni ó lè jẹ́ pé a ti gbìyànjú tí a sì ti kùnà lọ́pọ̀ ìgbà ṣáájú kí a to ní ìwọ̀nba àṣeyọrí sí rere díẹ̀ nínú rínrìn. Kí ni ìbá ti ṣẹlẹ̀ bí ó bá jẹ́ pé gbàrà tí a ti ṣubú lákọ̀ọ́kọ́, ni a ti pinnu láti dáwọ́ gbígbìyànjú dúró? A ṣì lè máa rákòrò káàkiri síbẹ̀síbẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ àti eékún wa! Ìtẹpẹlẹmọ́ ṣe kókó kí ọwọ́ baà lè tẹ góńgó tí ó níyelórí kí a sì jèrè òye-iṣẹ́ àti ọ̀wọ̀-ara-ẹni púpọ̀ síi tí ó ṣe rẹ́gí. Gẹ́gẹ́ bí àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí ó lókìkí kan ṣe sọ pé, “Àwọn olùborí kì í sá láé, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí ń sá kì í borí láé.”
Àwọn aṣáájú-ọ̀nà ọlọ́jọ́ pípẹ́ mọ̀ pé kì í ṣe àkànṣe agbára-ìṣe tàbí tálẹ́ǹtì ni ó ń pinnu àṣeyọrí sí rere. Ó ń béèrè ẹ̀mí ìdìrọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ nǹkan, ìpinnu láti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, àti ìgboyà lójú ìfàsẹ́yìn onígbà díẹ̀, àní ìkìmọ́lẹ̀ pàápàá. Góńgó nínípìn-ín títí láé nínú àwọn ìbùkún Ọlọrun gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a ń darí gbogbo àfiyèsí sí.
Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo àwa tí ń gbìyànjú láti jèrè ojúrere Jehofa tí a sì ń gbìyànjú láti jagunmólú nínú eré ìje fún ìyè nílò ìtẹpẹlẹmọ́, ìforítì, àti ìfaradà. Láìsí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe kí a pàdánù ojúrere Jehofa àti èrè ìgbésí-ayé tòótọ́ gidi.—Orin Dafidi 18:20; Matteu 24:13; 1 Timoteu 6:18, 19.
Ó sábà máa ń ṣòro púpọ̀ fún Kristian kan láti tẹpẹlẹmọ́ àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí rẹ̀ ju àwọn ojúṣe mìíràn lọ. Ọkùnrin kan lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ajé láti lè bójútó àìní ìdílé rẹ̀ nípa tara, ṣùgbọ́n ó lè ‘rẹ̀ ẹ́ jù’ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹ̀lú aya àti àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn kókó-abájọ wo ni ó mú kí ìtẹpẹlẹmọ́ iṣẹ́ Kristian di ohun tí ó ṣòro fún ọ̀pọ̀lọpọ̀?
Kókó-abájọ kan ni ìrẹ̀wẹ̀sì, tí ń wá láti inú ìkùnà àti àìlera tiwa fúnra wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Bí a bá ń ronú lọ́nà òdì nípa àṣìṣe wa, a lè sọ̀rètínù kí a sì káàárẹ̀, kí a máa ronú pé Jehofa kì yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá láé.
Kókó-abájọ mìíràn ni atẹ́gùn ìwà-pálapàla, ìwà-ìbàjẹ́, àti ìkórìíra tí ó jẹ́ ti ayé. (1 Johannu 2:15, 16) Ọ̀kan lára “awọn àṣà-ìhùwà wíwúlò” tí agbára ìdarí ayé lè bà jẹ́ ni ìtẹpẹlẹmọ́ Kristian.—1 Korinti 15:33.
Ìtẹpẹlẹmọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa ni a lè sọ di aláìlera nípasẹ̀ àtakò láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn tàbí ìdágunlá sí iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa. Nítorí ìjákulẹ̀, a lè parí èrò sí pé àwọn ènìyàn ní agbègbè ìpínlẹ̀ wa kò wulẹ̀ fẹ́ òtítọ́ náà. Èyí lè sún wa láti béèrè pé, ‘Kí tilẹ̀ ni àǹfààní gbogbo wàhálà yìí?’ kí a sì fẹ́ láti fi àkànṣe àǹfààní iṣẹ́-ìsìn iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa sílẹ̀.
Ẹ̀mí ayé ti ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ tún lè nípa ìdarí lórí wa. Èéṣe tí a fi níláti jìjàkadì kí a sì fi ara wa rúbọ tóbẹ́ẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ pé olúkúlùkù ni ó dàbí ẹni ń gbádùn ara wọn tàbí tí wọ́n ń dẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́?—Fiwé Matteu 16:23, 24.
Láti tẹpẹlẹmọ́ ṣíṣe ìfẹ́-inú Jehofa, a níláti gbé àkópọ̀-ìwà Kristian wọ̀ kí a sì jẹ́ kí ẹ̀mí máa darí wa, kì í ṣe ẹran-ara. (Romu 8:4-8; Kolosse 3:10, 12, 14) Níní ojú-ìwòye Jehofa lórí ọ̀ràn náà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa tí ó ṣe pàtàkì lọ.—1 Korinti 16:13.
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìtẹpẹlẹmọ́
Jehofa ti pèsè ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tí ń runisókè ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin àti olùṣòtítọ́ sí i jálẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdánwò. Nípa gbígbé wọn yẹ̀wò, a ń rí bí a ṣe lè mú wọn dàgbà kí a sì lo ìtẹpẹlẹmọ́ Kristian àti ìdí tí ó fi níyelórí tóbẹ́ẹ̀.
Àpẹẹrẹ títóbi jùlọ ni ti Jesu, ẹni tí ó jìyà púpọ̀ láti lè fi ògo fún orúkọ Jehofa. Bibeli fún wa ní ìṣírí láti farabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwà ìfọkànsìn onítẹpẹlẹmọ́ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Nipa bayii, nígbà naa, nitori tí a ní àwọsánmà awọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí awa pẹlu mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò ati ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹlu ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré-ìje tí a gbéka iwájú wa, bí a ti ń fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú ati Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jesu. Nitori ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀ ó farada òpó igi oró, ó tẹ́ḿbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Nítòótọ́, ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nipa ẹni naa tí ó ti farada irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lati ẹnu awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn, kí ó má baà rẹ̀ yín kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì ninu ọkàn yín.”—Heberu 12:1-3.
Eré ìje fún ìyè jẹ́ èyí tí ó gùn, kì í ṣe eré sísá onígbà díẹ̀, tàbí eré sísá kúṣẹ́kúṣẹ́. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí a fi nílò ìtẹpẹlẹmọ́ bíi ti Kristi. A lè má rí góńgó náà lọ́ọ̀ọ́kán, òpin eré ìje náà, fún apá tí ó pọ̀ jùlọ nínú eré ìje náà. Góńgó náà gbọ́dọ̀ ṣe kedere ní ọkàn wa tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé a lè máa nàgà fún un pẹ̀lú èrò-orí jálẹ̀ gbogbo ipa-ọ̀nà, tí ń béèrè ọ̀pọ̀ ìsapá náà. Jesu ní irú àwòrán elérò-orí bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ̀, ìyẹn ni, “ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀.”
Kí ni ohun tí ìdùnnú-ayọ̀ ní nínú fún àwọn Kristian lónìí? Ohun kan ni pé, ó jẹ́ èrè ìyè àìleèkú ní ọ̀run fún àwọn kéréje àti ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀-ayé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. Bákan náà, ó jẹ́ ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn tí ń wá láti inú mímọ̀ pé ẹnì kan ń mú ìdùnnú bá ọkàn-àyà Jehofa tí ó sì ti kó ipa kan nínú sísọ orúkọ Ọlọrun di mímọ́.—Owe 27:11; Johannu 17:4.
Ohun tí ó tún wà nínú ìdùnnú-ayọ̀ yìí ni, ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó gbádùnmọ́ni pẹ̀lú Jehofa. (Orin Dafidi 40:8; Johannu 4:34) Irú ipò-ìbátan bẹ́ẹ̀ ń fúnni lókun ó sì ń gbé ìwàláàyè ró, ní fífún ẹnì kan ní okun láti sá eré ìje náà pẹ̀lú ìfaradà kí ó má sì ṣe káàárẹ̀. Síwájú síi, Jehofa ń bùkún ipò-ìbátan náà nípa títú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jáde sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, èyí tí ń yọrí sí ìdùnnú-ayọ̀ púpọ̀ síi àti ìgbòkègbodò onídùnnú-ayọ̀.—Romu 12:11; Galatia 5:22.
Gbígbé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ onítẹpẹlẹmọ́ ti Jobu yẹ̀wò ń ṣeni láǹfààní. Ó jẹ́ aláìpé, ìmọ̀ rẹ̀ nípa ipò rẹ̀ sì láàlà. Nítorí náà nígbà mìíràn, ó ṣubú sínú ìdára-ẹni-láre àti ìsọ̀rètínù. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fi ìpinnu dídúró gbọn-in hàn nígbà gbogbo láti di ìwàtítọ́ rẹ̀ sí Jehofa mú kí ó má sì ṣe kọ̀ Ọ́ sílẹ̀. (Jobu 1:20-22; 2:9, 10; 27:2-6) Jehofa san èrè fún Jobu fún ìfọkànsìn onítẹpẹlẹmọ́ rẹ̀, ní fífún un ní ìbùkún nípa tẹ̀mí àti nípa tara àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jobu 42:10-17; Jakọbu 5:10, 11) Bíi ti Jobu, a lè ní ìrírí ìjìyà àti òfò púpọ̀ nígbà ìgbésí-ayé wa nísinsìnyí, ṣùgbọ́n a tún lè ní ìdánilójú ìbùkún Jehofa lórí ìgbàgbọ́ onífaradà wa.—Heberu 6:10-12.
Ní àkókò òde-òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lápapọ̀ ti fi ìtẹpẹlẹmọ́ ti Kristian hàn ní ṣíṣe ìfẹ́-inú Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ilé-dé-ilé wọn àti ìwàásù ìtagbangba mìíràn tí wọ́n tẹpẹlẹmọ́ tí fa àfiyèsí kárí-ayé sí wọn àti ìhìn-iṣẹ́ wọn. Àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn ti sọ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ìtara àti ìpinnu wọn láti wàásù ìhìnrere láìka àtakò àti àdánwò sí. Ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí tilẹ̀ gbé kókó ìròyìn kan jáde pé “Kò sí ẹni tí ó bọ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!”—Matteu 5:16.
Jehofa ti bùkún ìsapá onítẹpẹlẹmọ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ pẹ̀lú èso púpọ̀ síi nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Kíyèsí ìrírí àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n mọ ojútùú sí àwọn ìṣòro ní Itali ní àwọn ọdún 1960 nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí bí 10,000 ń wàásù fún orílẹ̀-èdè kan tí ó lé ní 53,000,000 ènìyàn. Ní ìlú kan tí ó ní 6,000 olùgbé, kò sí Ẹlẹ́rìí kankan rárá. Àwọn arákùnrin tí ń ṣe ìbẹ̀wò ni a fi ìhùwàpadà oníkanra hàn sí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn.
Ní gbogbo ìgbà tí àwọn arákùnrin náà bá lọ síbẹ̀ láti wàásù, ọ̀pọ̀ lára àwọn obìnrin, àti àwọn ọkùnrin pàápàá, tí ó wà ní ìlú náà yóò kó àwọn ọmọdékùnrin jọ, ní fífún wọn ní ìṣírí láti tẹ̀lé àwọn Ẹlẹ́rìí kí wọ́n sì máa súfèé tẹ̀lé wọn kí wọ́n sì máa pariwo gèè. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣe èyí, a fipá mú àwọn arákùnrin náà láti kúrò níbẹ̀ kí wọ́n sì lọ sí ìlú mìíràn. Nínú ìsakun wọn láti jẹ́rìí tí ó jẹ́ àjẹ́tán fún gbogbo àwọn olùgbé ìlú náà ó kéré tán lẹ́ẹ̀kanṣoṣo, àwọn ará pinnu láti wàásù níbẹ̀ kìkì ní ọjọ́ tí òjò bá rọ̀, pẹ̀lú ìrètí pé àwọn ọmọdékùnrin náà kì yóò yọ wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ṣàkíyèsí pé àwọn ará ìlú náà kò múratán láti jẹ́ kí ara wọn rẹ kìkì láti dí àwọn akéde náà lọ́wọ́. Ní ọ̀nà yìí wọ́n jẹ́rìí tí ó jíire. Wọ́n rí àwọn olùfìfẹ́hàn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli titun. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, kì í ṣe kìkì pé a dá ìjọ kan tí ń gbilẹ̀ sílẹ̀ ní ìlú kékeré yẹn nìkan ni ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìwàásù náà ni a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ní ọjọ́ tí oòrùn bá mú pàápàá. Jehofa ti ń bá a nìṣó láti máa bùkún ìtẹpẹlẹmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ní agbègbè náà àti jákèjádò Itali. Iye tí ó ju 200,000 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ó wà ní orílẹ̀-èdè náà báyìí.
Èrè ìtẹpẹlẹmọ́ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ga lọ́lá. Nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí Ọlọrun, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti ṣàṣeparí akitiyan tí a kò gbọ́ irú rẹ̀ rí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, ìyẹn ni ti wíwàásù ìhìnrere Ìjọba náà, ní ẹnu-ọ̀nà àti lọ́nà mìíràn, fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn. (Sekariah 4:6) Wọ́n ti fi pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli nínú ìdàgbàsókè yíyanilẹ́nu àti okun ètò-àjọ Jehofa tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé. (Isaiah 54:2; 60:22) Wọ́n di ẹ̀rí-ọkàn tí ó dára mú sí Ọlọrun, wọ́n sì kún fún inúdídùn nínú ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ń gbádùn ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá, Jehofa Ọlọrun.—Orin Dafidi 11:7.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Jesu san èrè ìrẹ̀lẹ̀ onítẹpẹlẹmọ́ fún obìnrin ará Griki yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìyè nínú Paradise wà lára ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú àwọn Kristian lónìí