ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 8/15 ojú ìwé 3-4
  • Báwo Ni O Ṣe Lè Yèbọ́ ní Àdúgbò Eléwu?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni O Ṣe Lè Yèbọ́ ní Àdúgbò Eléwu?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídi Ìṣarasíhùwà Ìfojúṣọ́nà fún Rere Mú
  • Ogun Àjàpàdánù Tí A Ń Bá Ìwà Ọ̀daràn Jà
    Jí!—1998
  • Ìgbà Kan Tí Ìwà Ọ̀daràn Kò Sí
    Jí!—1998
  • Kí Ló Fà á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Bẹ̀rù?
    Jí!—2005
  • Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 8/15 ojú ìwé 3-4

Báwo Ni O Ṣe Lè Yèbọ́ ní Àdúgbò Eléwu?

MARIA sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni àyà máa ń fò mí. Ẹ̀rù ń bà mí lórí àtẹ̀gùn tí ń lo iná mànàmáná. Ẹ̀rù ń bà mí nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi. Ẹ̀rù máa ń bà mí nínú ilé mi. Ìwà-ọ̀daràn wà níbi gbogbo. Ìgbà gbogbo ni a ń ja àwọn ènìyàn lólè.” O ha nímọ̀lára bíi ti obìnrin ará Brazil yìí bí, tí ẹ̀rù sì ń bà ọ́ ní àdúgbò rẹ, ní pàtàkì ní òru dúdú bí?

Kíkà nípa ìtàn ìṣèwádìí ìwà-ọ̀daràn máa ń ru ìmọ̀lára sókè, ṣùgbọ́n nínú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níti gidi kì í fìgbà gbogbo ní àbájáde aláyọ̀. Ìwà-ọ̀daràn kan lè wà láìyanjú. Tàbí nínú ọ̀ràn ìpànìyàn, ẹnì kan níláti máa wàláàyè lọ láìní ọkọ, bàbá, tàbí ọmọkùnrin, láìní aya, ìyá, tàbí ọmọbìnrin. Ìwà-ọ̀daràn oníwà-ipá ha ń peléke síi ní agbègbè rẹ bí? O ha ń yánhànhàn fún ibi kan tí ó parọ́rọ́ níbi tí ìdílé rẹ ti lè wà láìséwu bí? Tàbí, bí ó dá di ọ̀ranyàn fún ọ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà ní agbègbè tí ìwà-ọ̀daràn ti wọ́pọ̀, kí ni o lè ṣe láti yèbọ́?

Òtítọ́ ni pé, àwọn ìlú-ńlá kan wà níbi tí ìwà-ọ̀daràn kò ti tó nǹkan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀, àwọn ènìyàn ṣì ń gbé nínú ìgbèríko tí ó parọ́rọ́ tàbí àwọn abúlé tí wọ́n tutù minimini. Ṣùgbọ́n nǹkan ń yípadà lọ́nà yíyá kánkán àní ní àwọn agbègbè tí a rò pé kò sí ìwà-ipá tẹ́lẹ̀rí pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, ní Brazil ní 50 ọdún sẹ́yìn, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn náà ń gbé àwọn ìgbèríko. Nísinsìnyí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ń gbé ní àwọn ìlú-ńlá. Ní àfikún sí àwọn àǹfààní rírí iṣẹ́ ṣe, àwọn ìṣòro ìlú-ńlá tí ń peléke síi tún ti jẹyọ, irú bíi ìwà-ọ̀daràn àti ìwà-ipá. Yálà o ń gbé ní agbègbè eléwu tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, o ṣì níláti lọ sí ibi-isẹ́ tàbí ilé-ẹ̀kọ́ kí o sì ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan níbi tí ó jìnnà sí ilé.

Ní mímọ “àrùn ìfòyà” tí ó gbalégbòde, ọ̀gá ọlọ́pàá kan ní Rio de Janeiro mẹ́nu kan àìṣèdájọ́ òdodo ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ìwà-ọ̀daràn tí a ṣètò gẹ́gẹ́ bí àwọn kókó-abájọ tí ń ṣokùnfà rẹ̀. Ó tún ronú pé àwọn ìwé agbéròyìnjáde àti tẹlifíṣọ̀n ti ṣokùnfà ìbẹ̀rù tí ń tànkálẹ̀, “ní fífi àwọn ìròyìn ìbànújẹ́ tí ń múni sọ̀rètínù ba àwọn ènìyàn lọ́kàn jẹ́.” Sísọ oògùn di bárakú, ìwólulẹ̀ ìdílé, àti ẹ̀kọ́ èké tí ìsìn ń kọ́ni tún ń dákún ìwà-àìlófin tí ń pọ̀ síi. Kí sì ni ọjọ́-ọ̀la yóò mú wá? Àwọn ìran oníwà-ọ̀daràn tí a ń wò lemọ́lemọ́, tí a ń fojú kéré gẹ́gẹ́ bí eré ìnàjú nínú àwọn ìwé àti fíìmù, yóò ha mú kí àwọn ènìyàn má fi ìmọ̀lára hàn fún àwọn ẹlòmíràn bí? Àwọn agbègbè tí a rò pé kò sí ìwà-ọ̀daràn ha lè di eléwu bí?

Níwọ̀n bí ìwà-ọ̀daràn kò ti jẹ́ ohun amúdùnnúwá fún òjìyà náà, a ní ìfẹ́-ọkàn tí ó lágbára láti fẹ́ láti wà láìséwu. Abájọ tí àwọn aráàlú tí ọ̀ràn kàn fi ń béèrè fún àwọn ọlọ́pàá púpọ̀ síi ní òpópónà àti ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n tí ó gbóná síi tàbí ìjìyà tí ó lékenkà pàápàá! Láìka ewu náà sí, àwọn kan ń ní ìbọn fún ìgbèjà ara-ẹni. Àwọn mìíràn ń fẹ́ kí àwọn aláṣẹ fi òté lé títa ìbọn-ẹlẹ́tù. Ṣùgbọ́n láìka àwọn ìròyìn búburú pé ìwà-ọ̀daràn ń gogò síi sí, kò sí ìdí láti sọ̀rètínù. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ olùgbé irú àwọn ìlú-ńlá bí Johannesburg, Mexico City, New York, Rio de Janeiro, àti São Paulo ni a kò tí ì jà lólè rí. Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn ènìyàn ṣe ń kojú ìwà-ọ̀daràn ní àdúgbò eléwu.

Dídi Ìṣarasíhùwà Ìfojúṣọ́nà fún Rere Mú

Nípa agbègbè tí ìwà-ọ̀daràn ti wọ́pọ̀, òǹkọ̀wé kan sọ̀rọ̀ lórí “ọgbọ́n-ìhùmọ̀ àti ìforítì ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Brazil tí wọ́n ti mú iyì àti ẹ̀yẹ díẹ̀ dàgbà láti inú ipò ìgbésí-ayé tí ó ṣì le koko síbẹ̀síbẹ̀.” Lẹ́yìn ọdún 38 ní Rio de Janeiro, Jorge sọ pé: “Mo ń yẹra fún àwọn òpópónà àti agbègbè kan èmi kì í sìí fi ìfẹ́-ojúmìító kankan hàn. Mo tún máa ń yẹra fún dídúró pẹ́ ní òpópónà ní alẹ́ èmi kì í sìí fi ìbẹ̀rù tí ó rékọjá ààlà hàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń ṣọ́ra, mo ń fojú wo àwọn ènìyàn bí ẹni pé wọ́n jẹ́ aláìlábòsí, mo ń hùwà sí wọn pẹ̀lú iyì àti ọ̀wọ̀.”

Bẹ́ẹ̀ni, yẹra fún wàhálà tí kò pọndandan. Fi tìrẹ ṣe tìrẹ. Máṣe fojú kéré òkodoro òtítọ́ náà pé ìbẹ̀rù tí ó bonimọ́lẹ̀ lè wu iṣan ìmọ̀lára léwu, o lè mú kí àwọn ènìyàn oníwà ọmọlúwàbí hùwà lọ́nà tí kò bọ́gbọ́n mu. Níti iṣẹ́ rẹ̀ ní àwọn agbègbè eléwu, Odair ṣàkíyèsí pé: “Mo gbìyànjú láti jẹ́ olùfojúsọ́nà fún rere, n kì í fi ìbẹ̀rù àwọn nǹkan búburú tí ó lè ṣẹlẹ̀ bọ́ èrò-inú mi nítorí pé èyí ń fa pákáǹleke àti ìpayà tí kò pọndandan. Mo ń gbìyànjú láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún gbogbo ènìyàn.” Yàtọ̀ sí wíwà lójúfò àti yíyẹra fún àwọn wọnnì tí ó fura sí, ó fi àrànṣe mìíràn láti ṣàkóso ìmọ̀lára ẹni kún un pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo mú ìgbọ́kànlé nínú Jehofa Ọlọrun dàgbà, ní rírántí pé kò sí ohun kan tí ojú rẹ̀ kò tó àti pé ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ jẹ́ nípa ìyọ̀ǹda rẹ̀.”

Síbẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ láti máa gbé nínú ìbẹ̀rù ìgbà gbogbo. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ta ni yóò sẹ́ pé ìbẹ̀rù àti másùnmáwo tí ó rékọjá ààlà ń ṣèpalára fún ìlera níti ìmọ̀lára àti ti ara? Nítorí náà, ìrètí wo ni ó wà fún àwọn wọnnì tí ń bẹ̀rù pé a lè kọlù wọ́n nígbàkigbà? Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ń bẹ̀rù pé èyí tí ó burú jù nípa ìwà-ọ̀daràn ṣì wà níwájú, àwa yóò ha rí òpin ìwa-ipá bí? A késí ọ láti ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yìí, “Nígbà Wo Ni Ìbẹ̀rù Yóò Dópin?”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́