ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 8/15 ojú ìwé 12-17
  • Ìkésíni Onífẹ̀ẹ́ Sí Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkésíni Onífẹ̀ẹ́ Sí Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wọnnì “Tí Ń Ṣe Làálàá Tí A Sì Di Ẹrù Wọ̀ Lọ́rùn”
  • Ohun tí Ó Fa Ìnira Níti Gidi
  • Ìkésíni Jesu Lónìí
  • Ìtura Àlàáfíà àti Ìtura
  • Mátíù 11:28-30—“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi . . . Èmi Yóò Fún Yín Ní Ìsinmi”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • “Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Oògùn Ajẹ́bíidán Fún Másùnmáwo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 8/15 ojú ìwé 12-17

Ìkésíni Onífẹ̀ẹ́ Sí Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú

“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára.”—MATTEU 11:28.

1. Kí ni Jesu rí ní Galili nígbà ìrìn-àjò ìwàásù rẹ̀ kẹta?

BÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọdún 32 C.E. ti ń súnmọ́lé, Jesu wà nínú ìrìn-àjò ìwàásù rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta ní àgbègbè Galili. Ó rìnrìn-àjò la àwọn ìlú-ńlá àti abúlé já, “ó ń kọ́ni ninu awọn sinagọgu wọn ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba naa ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn ati gbogbo onírúurú àìlera ara.” Bí ó ti ń ṣe èyí, ó rí ogunlọ́gọ̀ náà, “àánú wọ́n [sì] ṣe é, nitori a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.”—Matteu 9:35, 36.

2. Báwo ni Jesu ṣe ran àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́?

2 Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu ṣe ju wíwulẹ̀ káàánú fún ogunlọ́gọ̀ náà. Lẹ́yìn tí ó ti fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni láti gbàdúrà sí “Ọ̀gá ìkórè,” Jehofa Ọlọrun, ó rán wọn jáde láti ran àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́. (Matteu 9:38; 10:1) Lẹ́yìn náà ó fún àwọn ènìyàn náà ní ìdánilójú tí òun fúnra rẹ̀ ní nípa ọ̀nà sí ojúlówó ìtura àti ìtùnú. Ó nawọ́ ìkésíni amọ́kànyọ̀ yìí sí wọn: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nitori onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi, ẹ̀yin yoo sì rí ìtura fún ọkàn yín.”—Matteu 11:28, 29.

3. Èéṣe tí ìkésíni Jesu fi jẹ́ èyí tí ó fanimọ́ra lónìí lọ́nà kan náà?

3 Lónìí a ń gbé ní àkókò kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nímọ̀lára pé a di ẹrù-ìnira rù wọ́n tí a sì di ẹrù wọ̀ wọ́n lọ́rùn gidigidi. (Romu 8:22; 2 Timoteu 3:1) Fún àwọn kan, gbígbọ́ bùkátà ìgbésí-ayé nìkan ń gba ọ̀pọ̀ nínú àkókò àti agbára wọn tí ó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba ni ó ṣẹ́kù sílẹ̀ fún ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn, tàbí ohunkóhun mìíràn. Ọ̀pọ̀ ni àmódi lílekoko, ìpọ́njú, ìsoríkọ́, àti àwọn ìṣòro ti ara àti ti èrò-ìmọ̀lára mìíràn di ẹrù-ìnira rù. Bí wọ́n ti ń nímọ̀lára ìkìmọ́lẹ̀ náà, àwọn kan gbìyànjú láti wá ìtura nípa ríri ara wọn bọnú ìlépa adùn, oúnjẹ jíjẹ, ọtí mímu, àní oògùn ìlòkulò pàápàá. Àmọ́ ṣáá o, èyí wulẹ̀ ń tì wọ́n láti inú ìbànújẹ́ kan bọ́ sínú òmíràn ni, tí ó ń mú ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ìkìmọ́lẹ̀ wá fún wọn. (Romu 8:6) Ní kedere, ìkésíni onífẹ̀ẹ́ Jesu ń dún lọ́nà tí ó fanimọ́ra gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nígbà yẹn lọ́hùn-ún.

4. Àwọn ìbéèrè wo ni a níláti gbéyẹ̀wò láti baà lè jàǹfààní láti inú ìkésíni onífẹ̀ẹ́ Jesu?

4 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ohun wo ni a fi àwọn ènìyàn ọjọ́ Jesu sábẹ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n farahàn bí ẹni tí ‘a bó láwọ tí a sì fọ́n wọn ká,’ tí ó sún Jesu láti káàánú fún wọn? Kí ni àwọn ẹrù-ìnira àti ẹrù tí wọ́n níláti gbé, báwo sì ni ìkésíni Jesu yóò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè ràn wá lọ́wọ́ gidigidi nínú jíjàǹfààní láti inú ìkésíni onífẹ̀ẹ́ tí Jesu nawọ́ rẹ̀ sí àwọn tí àárẹ̀ mú.

Àwọn Wọnnì “Tí Ń Ṣe Làálàá Tí A Sì Di Ẹrù Wọ̀ Lọ́rùn”

5. Èéṣe tí ó fi bá a mu pé aposteli Matteu ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu?

5 Ó dùn mọ́ni pé Matteu nìkan ni ó ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu. Níwọ̀n bí ó ti jẹ agbowó-orí tẹ́lẹ̀rí, Matteu, tí a tún mọ̀ sí Lefi, mọ ẹrù-ìnira kan tí àwọn ènìyàn náà ń rù ní àmọ̀dunjú. (Matteu 9:9; Marku 2:14) Ìwé náà Daily Life in the Time of Jesus sọ pé: “Owó-orí ti [àwọn Júù níláti] san lówó àti ní irú mìíràn ti pọ̀ jù, àwọn ni ó sì jẹ́ èyí tí ó pọ̀ jùlọ níti pé owó-orí oríṣi méjì ni wọ́n ń san lọ́wọ́ kan náà, owó-orí ti ìlú àti owó-orí ti ìsìn; kò sì sí èyí tí ó kéré.”

6. (a) Ètò owó-orí wo ni a ń lò ní àkókò Jesu? (b) Èéṣe ti àwọn agbowó-orí fi ní irú orúkọ búburú bẹ́ẹ̀? (d) Kí ni Paulu nímọ̀lára àìní rẹ̀ láti rán àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí?

6 Ohun tí ó mú kí gbogbo èyí jẹ́ ẹrù-ìnira ní pàtàkì ni ètò owó-orí ní àkókò náà. Àwọn onípò àṣẹ ilẹ̀ Romu fi ẹ̀tọ́ láti gba owó-orí ní àwọn àgbègbè-ìpínlẹ̀ sí ìkáwọ́ àwọn tí ó bá lè mú iye owó tí ó pọ̀ jùlọ wá. Àwọn, ẹ̀wẹ̀, gba àwọn ènìyàn ní àwọn ẹgbẹ́-àwùjọ àdúgbò láti bójútó iṣẹ́ gbígba owó-orí náà gan-an. Gbogbo ẹni tí ó wà nínú ọgbọ́n jìbìtì yìí nímọ̀lára pé òun ní ẹ̀tọ́ dáadáa láti fi èlé tòun kún un, tàbí dín in kù. Fún àpẹẹrẹ, Luku ròyìn pe “ọkùnrin kan wà . . . tí a ń pè ní orúkọ naa Sakeu; oun sì jẹ́ olórí agbowó-orí, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.” (Luku 19:2) Sakeu “olórí agbowó-orí” àti àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ kó ọrọ̀ wọn jọ láti inú ìṣẹ́ àwọn ènìyàn náà. Ìfìyàjẹni àti ìwà ìbàjẹ́ tí irú ètò bẹ́ẹ̀ ṣokùnfà mú kí àwọn ènìyàn náà ka àwọn agbowó-orí mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aṣẹ́wó, ó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn tọ́ sí wọn nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ. (Matteu 9:10; 21:31, 32; Marku 2:15; Luku 7:34) Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn náà ti nímọ̀lára ẹrù-ìnira tí kò ṣeé faradà, kò yanilẹ́nu nígbà náà pé aposteli Paulu nímọ̀lára àìní náà láti rán àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí láti máṣe bínú lábẹ́ àjàgà Romu ṣùgbọ́n láti fi “ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, fún ẹni tí ó béèrè fún owó-orí, owó-orí; fún ẹni tí ó béèrè fún owó-òde, owó-òde.”—Romu 13:7a; fiwé Luku 23:2.

7. Báwo ni àwọn òfin ìjẹniníyà Romu ṣe dákún ẹrù-ìnira àwọn ènìyàn náà?

7 Paulu tún rán àwọn Kristian létí láti fi “fún ẹni tí ó béèrè fún ìbẹ̀rù, irúfẹ́ ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀; fún ẹni tí ó béèrè fún ọlá, irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” (Romu 13:7b) A mọ àwọn ará Romu fún ìwà-ìkà àti bí àwọn òfin ìjẹniníyà wọn ti lekoko tó. Ìnàlọ́rẹ́, ìnàlẹ́gba, sáà tí ó lekoko, àti ìfikúpani ni a máa ń lò lọ́pọ̀ ìgbà láti baà lè mú kí àwọn ènìyàn náà wà ní ìtẹríba. (Luku 23:32, 33; Ìṣe 22:24, 25) A tilẹ̀ fún àwọn aṣáájú Júù pàápàá láṣẹ láti fi irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹni bí wọ́n bá ti rí i pé ó tọ́. (Matteu 10:17; Ìṣe 5:40) Irú ètò bẹ́ẹ̀ dájúdájú jẹ́ agbonimọ́lẹ̀ lọ́nà gíga jùlọ, bí kì í bá ṣe aninilára ní tààràtà fún ẹnikẹ́ni tí ń gbé lábẹ́ rẹ̀.

8. Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn ṣe di ẹrù-ìnira ru àwọn ènìyàn náà?

8 Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí ó burú ju owó-orí àti àwọn òfin Romu, ni ẹrù-ìnira tí àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà náà dì lé àwọn gbáàtúù ènìyàn lórí. Níti gidi, ó dàbí ẹni pé èyí ni àníyàn Jesu ní pàtàkì nígbà tí ó ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni tí “ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.” Jesu sọ pé dípò fífún àwọn ènìyàn tí a ti ni lára ní ìrètí àti ìtùnú, àwọn aṣáájú ìsìn “di awọn ẹrù wíwúwo wọ́n sì gbé wọn lé èjìká awọn ènìyàn, ṣugbọn awọn tìkára wọn kò fẹ́ lati fi ìka wọn sún wọn kẹ́rẹ́.” (Matteu 23:4; Luku 11:46) Nínú àwọn ìwé Ìròyìnrere, bí a ṣe fi àwọn aṣáájú ìsìn hàn láìsí àṣìṣe—pàápàá àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi—gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ onírera, aláìláàánú, àti alágàbàgebè ṣe kedere. Wọn kẹ́gàn àwọn ènìyàn gbáàtúù gẹ́gẹ́ bí àwọn púrúǹtù àti aláìmọ́, wọ́n sì tẹ́ńbẹ́lú àwọn àjèjì tí ó wà láàárín wọn. Àlàyé kan lórí ìwà wọn sọ pé: “Ẹnì kan tí ó bá di ẹrù ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ju bí ó ti yẹ lọ lóde-òní ni a lè fi òfin mú. Ti ẹni tí ó di ẹrù 613 òfin ru ‘àwọn ènìyàn ilẹ̀’ tí wọn kò ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ níti ìsìn; àti lẹ́yìn náà, tí kò ṣe ohunkóhun láti ràn wọ́n lọ́wọ́, tí ó dá wọ́n lẹ́bi gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́lọ́run ńkọ́?” Àmọ́ ṣáá o, ẹrù-ìnira náà níti gidi, kì í ṣe Òfin Mose, bíkòṣe ọ̀pọ̀ jaburata òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí a gbé ka àwọn ènìyàn náà lórí.

Ohun tí Ó Fa Ìnira Níti Gidi

9. Báwo ni ipò àwọn ènìyàn ní àkókò Jesu ṣe jọra pẹ̀lú ti ọjọ́ Ọba Solomoni?

9 Nígbà mìíràn ẹrù-ìnira ti ìnáwó tí ó wà lórí àwọn ènìyàn náà jẹ ọ̀kan tí ó wúwo, tó bẹ́ẹ̀ tí ipò òṣì fi gbalẹ̀ rẹpẹtẹ. Àwọn ọmọ Israeli níláti san owo-orí tí ó mọníwọ̀n tí Òfin Mose là sílẹ̀. Lẹ́yìn náà nígbà ìṣàkóso Solomoni, àwọn ènìyàn náà bójútó iṣẹ́ ìdáwọ́lé olówó gọbọi ti orílẹ̀-èdè, irú bí kíkọ́ tẹmpili àti àwọn ilé ràgàjì mìíràn. (1 Ọba 7:1-8; 9:17-19) Síbẹ̀, Bibeli sọ fún wa pé àwọn ènìyàn “ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá. . . . Juda àti Israeli ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dani títí dé Beerṣeba, ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.” (1 Ọba 4:20, 25) Kí ni ó fa ìyàtọ̀ náà?

10. Kí ni ó jẹ́ ìdí fún ipò tí Israeli wà ní ọ̀rúndún kìn-ínní?

10 Níwọ̀n bí orílẹ̀-èdè náà bá ti dúró gbọn-in-gbọn-in fún ìjọsìn tòótọ́, wọ́n ń gbádùn ojúrere Jehofa a sì fi ààbò àti aásìkí jíǹkí wọn láìka ìnáwó ńláǹlà ti orílẹ̀-èdè náà sí. Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa kìlọ̀ pé ‘bí wọ́n bá yípadà láti máa tọ òun lẹ́yìn, tí wọn kò sì pa òfin òun mọ́,’ wọn yóò jìyà ìfàsẹ́yìn ńláǹlà. Níti tòótọ́, “Israeli yóò sì di òwe àti ìfiṣẹ̀sín láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè.” (1 Awọn Ọba 9:6, 7) Bí ọ̀ràn ti rí gan-an nìyẹn. Israeli bọ́ sí abẹ́ àkóso ilẹ̀ àjèjì, ìjọba ológo tí ó sì wà nígbà kan rí ni a rẹ̀ sílẹ̀ sí ibi tí a ń ṣàkóso lé lórí lásán láti ilẹ̀ àjèjì. Ẹ wo bí àbájáde náà ti burú tó nítorí kíkọ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe wọn nípa tẹ̀mí sílẹ̀!

11. Èéṣe tí Jesu fi nímọ̀lára pé ‘a bó àwọn ènìyàn láwọ tí a sì fọ́n wọn ká gẹ́gẹ́ bí àgùtàn láìní olùṣọ́ àgùtàn’?

11 Gbogbo èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí Jesu fi nímọ̀lára pé àwọn ènìyàn tí òun rí ní a ti ‘bó láwọ̀ tí a sì fọ́n ká.’ Àwọn ọmọ Israeli nìwọ̀nyí, àwọn ènìyàn Jehofa, tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Ọlọrun àti láti máa bá ìjọsìn wọn lọ ní ọ̀nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà ní gbogbo ọ̀nà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò wọn nífà a sì ni wọ́n lára kì í ṣe láti ọwọ́ àwọn alágbára òṣèlú àti ìṣòwò nìkan ṣùgbọ́n láti ọwọ́ àwọn aṣáájú ìsìn apẹ̀yìndà pẹ̀lú láàárín wọn. Wọ́n dà bí “àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn” nítorí pé wọn kò ní ẹnì kankan láti bójútó wọn tàbí láti gbèjà wọn. Wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti kojú àwọn ipò lílekoko. Ẹ wo bí ìkésíni onífẹ̀ẹ́ àti onínúure Jesu ti bọ́ sí àkókò tó!

Ìkésíni Jesu Lónìí

12. Àwọn ìkìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun àti àwọn olótìítọ́ ọkàn mìíràn ń nímọ̀lára rẹ̀ lónìí?

12 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà àwọn nǹkan jọra lónìí. Àwọn olótìítọ́ ọkàn tí ń gbìyànjú láti gbé ìgbésí-ayé aláìlábòsí ń rí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ àti ohun tí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ó ti bàjẹ́ ń béèrè fún gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó nira láti faradà. Àní àwọn wọnnì tí wọ́n ti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa kò ní àjẹsára lòdì sí èyí. Ìròyìn fi hàn pé àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ń rí i pé ó túbọ̀ ń nira láti mú gbogbo ẹrù-iṣẹ́ wọn ṣẹ, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n nímọ̀lára pé a di ẹrù-ìnira rù wọ́n, àárẹ̀ mú wọn. Àwọn kan tilẹ̀ rò pé ìtura ni yóò jẹ́ bí àwọn bá lè yọwọ́-yọsẹ̀ nínú ohun gbogbo kí wọ́n sì wá ibi kan sá sí kí wọ́n baà lè pọkànpọ̀. O ha ti nímọ̀lára lọ́nà bẹ́ẹ̀ rí bí? O ha mọ ẹnì kan tí ó súnmọ́ ọ tí ó wà nínú ipò yẹn bí? Bẹ́ẹ̀ni, ìkésíni amọ́kànyọ̀ Jesu ní ìtumọ̀ ńláǹlà fún wa lónìí.

13. Èéṣe ti a fi lè ní ìdálójú pé Jesu lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìsinmi àti ìtura?

13 Ṣáájú kí Jesu tó sọ ìkésíni onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jáde, ó sọ pé: “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi lé mi lọ́wọ́, kò sì sí ẹni kankan tí ó mọ Ọmọkùnrin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bíkòṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò mọ Baba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bíkòṣe Ọmọkùnrin ati ẹnikẹ́ni tí Ọmọkùnrin ní ìfẹ́-ìmúratán lati ṣí i payá fún.” (Matteu 11:27) Nítorí ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ yìí láàárín Jesu àti Bàbá rẹ̀, a mú un dá wa lójú pé nípa títẹ́wọ́gba ìkésíni Jesu àti dídi ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, a lè wọnú ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa, “Ọlọrun ìtùnú gbogbo.” (2 Korinti 1:3; fiwé Johannu 14:6.) Ní àfikún síi, níwọ̀n bí a ti fi ‘ohun gbogbo lé e lọ́wọ́,’ Jesu Kristi nìkan ni ó ní agbára àti ọlá-àṣẹ láti mú àwọn ẹrù-ìnira wa fúyẹ́. Àwọn wo? Àwọn wọnnì tí ètò-ìgbékalẹ̀ òṣèlú, ọrọ̀-ajé, àti ìsìn tí ó ti díbàjẹ́ gbé kà wá lórí, títí kan ẹrù-ìnira tí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá àti àìpé gbé kà wá lórí. Ẹ wo bí ó ti jẹ èrò tí ń fúnni níṣìírí tí ó sì ń fúnni ní ìdálójú tó tí ó jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ gan-an!

14. Làálàá wo ni Jesu lè pèsè ìtura fún?

14 Jesu ń báa lọ láti sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára.” (Matteu 11:28) Dájúdájú kì í ṣe pé Jesu ń sọ̀rọ̀ lòdì sí iṣẹ́ àṣekára, nítorí pé lọ́pọ̀ ìgbà ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ní ìmọ̀ràn láti tiraka nínú iṣẹ́ tí ó wà níkàáwọ́ wọn. (Luku 13:24) Ṣùgbọ́n “làálàá” (“ṣíṣe òpò,” Kingdom Interlinear) mú òpò tí ń súni tí a fàgùn lọ́wọ́, tí kì í sábà ní àbájáde tí ó wúlò. “Di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” sì gbé èrò jíjẹ́ ẹni tí a di ẹrù rù ju bí agbára ti mọ lọ jáde. Ìyàtọ̀ náà ni a lè fiwé èyí tí ó wà láàárín ẹnì kan tí ń gbẹ́ ilẹ̀ fún ìṣúra tí ó farasin àti ẹni tí ń gbẹ́ kòtò ní ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n jùmọ̀ ń ṣe irú iṣẹ́ alágbára kan náà. Fún ọ̀kan, iṣẹ́-òpò náà ni a fi ìháragàgà ṣe, ṣùgbọ́n fún ẹnìkejì, iṣẹ́ tí ń súni tí kò lópin ni. Ohun tí ó fa ìyàtọ̀ ni ète iṣẹ́ náà tàbí àìní ète.

15. (a) Àwọn ìbéèrè wo ni a níláti bi ara wa bí a bá nímọ̀lára pé a gbé ẹrù-ìnira wíwúwo lé èjìká wa? (b) Kí ni a lè sọ nípa orísun àwọn ẹrù-ìnira wa?

15 Ìwọ ha nímọ̀lára pé o ‘ń ṣe làálàá ti ẹrù sì wọ̀ ọ́ lọ́rùn,’ pé àwọn ohun tí ń gba àkókò àti agbára rẹ ti pọ̀ jù? Àwọn ẹrù-ìnira tí ìwọ ń rù ha dàbí èyí tí ó wúwo jù fún ọ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣèrànwọ́ láti bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Kí ni mo ń ṣe làálàá lé lórí? Irú ẹrù wo ni mo ń rù?’ Lórí kókó yìí, olùṣàlàyé kan lórí Bibeli sọ ní èyí tí ó ju 80 ọdún sẹ́yìn pé: “Bí a bá gbé àwọn ẹrù-ìnira ìgbésí-ayé yẹ̀wò, wọn pín sí apá méjì; a lè pe ìwọ̀nyí ní èyí tí a gbé ka ara wa lórí àti èyí tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀: àwọn tí àwọn ìgbésẹ̀ wa ṣokùnfà, àti àwọn tí àwọn ìgbésẹ̀ wa kò ṣokùnfà.” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ nínú wa ni ẹnu yóò yà, lẹ́yìn àyẹ̀wò ara-ẹni fínnífínní, láti rí bí apá tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ẹrù-ìnira wa ti jẹ́ àwọn tí a gbé ka ara wa lórí.”

16. Àwọn ẹrù-ìnira wo ni a lè fi ìwà òmùgọ̀ gbé ka ara wa lórí?

16 Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹrù-ìnira tí a lè gbé ka ara wa lórí? Lónìí a ń gbé nínú ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, onífẹ̀ẹ́ adùn, àti oníwà àìmọ́. (2 Timoteu 3:1-5) Àní àwọn Kristian tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́ wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ ìgbà gbogbo láti bá àṣà àti ọ̀nà ìgbésí-ayé ti ayé mu. Aposteli Johannu kọ̀wé nípa “ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara ati ìfẹ́-ọkàn ti ojú ati fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí-ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Johannu 2:16) Àwọn ipa ìdarí tí ó lágbára tí ó lè tètè nípa lé wa lórí ni ìwọ̀nyí. Ó ti di mímọ̀ pé àwọn kan yàn láti kó wọnú gbèsè gan-an láti baà lè gbádùn ọ̀pọ̀ lára àwọn adùn ayé tàbí láti máa bá ọ̀nà ìgbésí-ayé kan nìṣó. Nígbà náà wọn wá rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ lo àkókò tí kò mọ níwọ̀n lórí iṣẹ́, tàbí kí wọ́n máa ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́, láti rí owó san gbèsè wọn.

17. Ipò wo ni ó lè mú kí gbígbé ẹrù náà túbọ̀ nira síi, báwo sì ni a ṣe lè yanjú èyí?

17 Nígbà tí ẹnì kan lè ronú pé kò lòdì láti ní díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí ẹlòmíràn ní tàbí láti ṣe díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe, ó ṣe pàtàkì láti ṣàyẹ̀wò bóyá ó ń dákun ẹrù rẹ̀ láìnídìí. (1 Korinti 10:23) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹnì kan kò lè rù ju bí agbára rẹ̀ ti tó, a gbọ́dọ̀ sọ àwọn ohun kan kalẹ̀ láti baà lè gbé ẹrù mìíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun tí ó ṣe kókó fún ire wa nípa tẹ̀mí—ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, pípésẹ̀ sí ìpàdé, àti iṣẹ́-ìsìn pápá—ni a ń sọ̀ kalẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni ìpàdánù okun nípa tẹ̀mí, èyí, ní ìdàkejì, mú kí ó túbọ̀ nira láti gbé ẹrù náà. Jesu Kristi kìlọ̀ nípa irú ewu bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ kíyèsí ara yín kí ọkàn-àyà yín má baà di èyí tí a dẹrùpa pẹlu àjẹjù ati ìmutíyó kẹ́ri ati awọn àníyàn ìgbésí-ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yoo sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” (Luku 21:34, 35; Heberu 12:1) Ó nira láti mọ ìdẹkùn kí a sì yẹra fún un bí ẹrù bá wọ ẹnì kan lọ́rùn tí ó sì ń ṣàárẹ̀.

Ìtura Àlàáfíà àti Ìtura

18. Kí ni Jesu nawọ́ rẹ̀ sí àwọn tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀?

18 Nítorí náà, lọ́nà onífẹ̀ẹ́, Jesu pèsè ojútùú náà: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . emi yoo sì tù yín lára.” (Matteu 11:28) Àwọn ọ̀rọ̀ náà ‘tù lára’ níhìn-ín àti “ìtura” ní ẹsẹ̀ 29 wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà tí ó bá ọ̀rọ̀ tí ẹ̀dà Septuagint lò láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “sábáàtì” tàbí “pípa sábáàtì mọ́,” mu. (Eksodu 16:23) Nípa báyìí, Jesu kò ṣèlérí fún àwọn wọnnì tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé wọn kì yóò ní iṣẹ́ mọ́, ṣùgbọ́n ó ṣèlérí pé òun yóò tù wọ́n lára kí wọ́n baà lè gbaradì fún iṣẹ́ tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ète Ọlọrun.

19. Báwo ni ẹnì kan ṣe ń ‘wá sọ́dọ̀ Jesu’?

19 Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni ẹnì kan ṣe ń ‘wá sọ́dọ̀ Jesu’? Fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jesu sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Matteu 16:24) Nítorí náà, láti wá sọ́dọ̀ Jesu túmọ̀ sí jíjọ̀wọ́ ìfẹ́-inú ara-ẹni fún ti Ọlọrun àti ti Kristi, títẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ kan, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo. Gbogbo èyí ha ti béèrè ohun tí ó pọ̀ jù bí? Ohun tí ó náni ha ti ga jù bí? Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí Jesu sọ lẹ́yìn tí ó nawọ́ ìkésíni onífẹ̀ẹ́ náà sí àwọn ẹni tí àárẹ̀ mú.

O Ha Lè Rántí Bí?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni a gbà di ẹrù-ìnira ru àwọn ènìyàn ọjọ́ Jesu?

◻ Kí ni okùnfà tòótọ́ fún ìnira àwọn ènìyàn náà?

◻ Báwo ni a ṣe níláti ṣàyẹ̀wò ara wa bí a bá nímọ̀lára pé a di ẹrù-ìnira rù wá?

◻ Àwọn ẹrù-ìnira wo ni a lè fi ìwà òmùgọ̀ gbé ka ara wa lórí?

◻ Báwo ni a ṣe lè gba ìtura tí Jesu ṣèlérí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹrù-ìnira tí a lè gbé ka ara wa lórí?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ onínúure Bahamas Ministry of Tourism

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́