ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/1 ojú ìwé 9
  • Jíjẹ́rìí Ń So Èso ní Ilé àti ní Ilé Ẹ̀kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́rìí Ń So Èso ní Ilé àti ní Ilé Ẹ̀kọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Kí N Bo Àṣírí Ọ̀rẹ́ Mi?
    Jí!—2009
  • Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀rẹ́ Kan Bá Wọ Gàù?
    Jí!—1996
  • Ọlọ́run Ń Pè Ọ́ Pé Kí O Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Kí Ló Dé Táwọn Ọ̀rẹ́ Mi Fi Máa Ń Ṣe Nǹkan Tó Dùn Mí?
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/1 ojú ìwé 9

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Jíjẹ́rìí Ń So Èso ní Ilé àti ní Ilé Ẹ̀kọ́

ÌGBÉSÍ ayé Kristian wé mọ́ ṣíṣe rere fún àwọn mìíràn, pàápàá jù lọ nípa ṣíṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú wọn. Owe 3:27 sọ pé: “Má ṣe fawọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí í ṣe tirẹ̀, bí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” Ní Argentina, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí ó wà ní ọdún kẹta rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, fẹ́ láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba náà pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ní ilé ẹ̀kọ́. Ṣíṣe tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, ní ìyọrísí púpọ̀.

Ní ọjọ́ kan, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà yán an létí ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé, kì í ṣe gbogbo ìsìn ni ó dára. Nígbà tí ọ̀dọ́ náà fèsì pé òun kò ṣe ohunkóhun tí ó burú, Ẹlẹ́rìí náà sọ pé: “Bákan náà ni o kò ṣe ohunkóhun fún Ọlọrun.” Èyí mú kí ọ̀dọ́ náà ronú. Lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé, ọjọ́ ìkẹyìn nìyí, àti pé, kí ẹnì kan baà lè rí ojú rere Ọlọrun, ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye ti Bibeli, kí ó sì fi í sílò. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gbà. Ṣùgbọ́n, ìdílé rẹ̀ yóò ha yọ̀ọ̀da fún un láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bí? Kí ó baà lè fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ohun kan láti ronú lé lórí, Ẹlẹ́rìí náà ní kí ó ka ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.

Nígbà tí ó ṣe, ọ̀rẹ́ náà kúrò ní ilé ẹ̀kọ́. A kò sì gbọ́ ohunkóhun nípa rẹ̀ mọ́ fún èyí tí ó lé ní ọdún kan. Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ kan, ó ya ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà lẹ́nu láti gba ìkésíni orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí ó sọ pé òun ti rí i pé, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ti ń ní ìmúṣẹ ní ti gidi. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ẹlẹ́rìí náà ṣètò láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀.

Nígbà tí ó lọ sí ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ tẹ́lẹ̀, ó ṣàkíyèsí pé àwọn òbí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ń ṣàníyàn gidigidi nípa ohun tí ọmọ wọn ti ń lọ́wọ́ sí. Àbúrò ọ̀rẹ́ rẹ̀ tilẹ̀ rò pé orí rẹ̀ ti yí ni. Nítorí náà, àwọn òbí rẹ̀ ní kí àbúrò náà jókòó tì wọ́n nígbà tí wọ́n tún fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí ó yá, pẹ̀lú omijé ní ojú rẹ̀, àbúrò yìí ròyìn fún àwọn òbí náà pé, orí ẹ̀gbọ́n òun kò yí, màmá náà sì figbe ta pé, “Dípò ìṣòro kan, mo ti ní méjì báyìí!”

Nítorí èyí, nígbà tí wọ́n tún fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, òun pẹ̀lú jókòó tì wọ́n, ó sì gbàgbọ́ pé orí àwọn ọmọ òun kò yí. Lẹ́yìn náà, a ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú òun àti ọkọ rẹ̀. Láìpẹ́, gbogbo ìdílé náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìyá wọn àgbà náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé. Láti ìgbà náà, ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe batisí. Ó ti gbéyàwó, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì jẹ́ akéde onítara.

Síwájú sí i, nípasẹ̀ ìjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà ní ilé ẹ̀kọ́, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà ti ran àwọn méjì mìíràn lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àti màmá pẹ̀lú àǹtí ọ̀kan lára wọn lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Lápapọ̀, ènìyàn 11 ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bibeli nítorí pé ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà kò fà sẹ́yìn ní ṣíṣe rere fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́. Ẹ wo àbájáde aláyọ̀ tí èyí jẹ́! Lóòótọ́, “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn náà, tí Jehofa jẹ́ Ọlọrun wọn!”—Orin Dafidi 144:15, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́