ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 13-15
  • Kí Ló Dé Táwọn Ọ̀rẹ́ Mi Fi Máa Ń Ṣe Nǹkan Tó Dùn Mí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Táwọn Ọ̀rẹ́ Mi Fi Máa Ń Ṣe Nǹkan Tó Dùn Mí?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Ba Ọ̀rẹ́ Jẹ́
  • Ìdí Tí Okùn Ọ̀rẹ́ Fi Ń Já
  • Wá Nǹkan Ṣe Sí I
  • Kí Nìdí Táwọn Ọ̀rẹ́ Mi Fi Ń Ṣe Ohun Tó Ń Dùn Mí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?
    Jí!—1996
  • Ṣé Kí N Bo Àṣírí Ọ̀rẹ́ Mi?
    Jí!—2009
  • Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Mi Tòótọ́?
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèré Pé . . .

Kí Ló Dé Táwọn Ọ̀rẹ́ Mi Fi Máa Ń Ṣe Nǹkan Tó Dùn Mí?

“Mo láwọn ọ̀rẹ́ kan . . . Nígbà tó yá wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ọmọbìnrin kan ṣọ̀rẹ́, bí mo bá lọ bá wọn, wọ́n á dákẹ́ fẹ́mú. . . . Wọn ò jẹ́ kí n mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe mọ́. Ó mà dùn mí o.”—Karen.a

ÓLÈ ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pàápàá. Wọ́n lè di ọ̀rẹ́ fòní-rẹ́-fọ̀la-jà. Nora, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, sọ pé: “Ẹni táa ń pè lọ́rẹ̀ẹ́ gbọ́dọ̀ ṣeé gbára lé, kó ṣeé fọkàn tán, kó ṣeé sá lọ bá lábẹ́ ipòkípò táa bá wà.” Àmọ́ nígbà míì, ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí abínúkú ọ̀tá.

Ohun Tó Ń Ba Ọ̀rẹ́ Jẹ́

Kí ló dé táwọn ọ̀rẹ́ máa ń ya ara wọn? Ní ti Sandra, ìgbà tí Megan ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá yá aṣọ ẹ̀ tó dáa jù ni wàhálà bẹ̀rẹ̀. Sandra sọ pé: “Nígbà tó dá a padà, ńṣe ló dọ̀tí, ó sì ti ya díẹ̀ lápá. Kò tiẹ̀ sọ fún mi, bóyá ó rò pé mi ò ní rí i ni.” Báwo ni ìwà àìkanisí tí Megan hù yìí ṣe rí lára Sandra? Ó sọ pé: “Ìwà yẹn mà bí mi nínú o. Ó túmọ̀ sí pé kò bìkítà nípa nǹkan tó jẹ́ tèmi . . . kò tiẹ̀ bìkítà nípa bó ṣe máa rí lára mi.”

Pẹ̀lúpẹ̀lù, inú lè bí ẹ tí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá sọ nǹkan kan tàbí tó ṣe nǹkan kan tó tàbùkù ẹ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Cindy nìyí nígbà tó sọ fáwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ kan pé òun ò tíì ka ìwé tóun fẹ́ lò fún iṣẹ́ tóun fẹ́ kọ̀wé lé lórí. Ṣe ni Kate ọ̀rẹ́ rẹ̀ kàn bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i. Cindy rántí pé: “Ó tẹ́ mi níṣojú gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa. Mo bínú sí i gan-an. Àtìgbà yẹn ni nǹkan ò ti lọ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

Nígbà míì èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbúngbùngbún sọ́rẹ̀ẹ́ ẹ̀ tíyẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ bá àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tuntun ṣeré. Bonnie, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, sọ pé: “Mo ní ọ̀rẹ́ àtàtà kan tó bá ẹgbẹ́ mìíràn lọ. Kò tiẹ̀ ṣe bí ẹni tó mọ̀ mí mọ́.” Ó sì lè jẹ́ pé o bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé aríre báni jẹ lẹni tóo pè lọ́rẹ̀ẹ́ rẹ. Joe, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lèmi àti Bobby. Mo tiẹ̀ kọ́kọ́ rò pé nítorí irú èèyàn tí mo jẹ́ ló jẹ́ kó fẹ́ràn mi báyẹn, ṣùgbọ́n mi ò tètè mọ̀ pé tìtorí iṣẹ́ ìpolówó tí dádì mi ń ṣe ló jẹ́ kó máa ṣe kùrùkẹrẹ lọ́dọ̀ mi, àṣé kó lè máa ráyè wọlé síbi eré ìdárayá àti eré orí ìtàgé lówó pọ́ọ́kú ló fi ń bá mi ṣọ̀rẹ́.” Kí lèrò Joe báyìí? Ó ní: “Mi ò lè fọkàn tán Bobby mọ́ láé!”

Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ṣe ni ọ̀rẹ́ rẹ lọ sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tóo sọ fún un fẹ́lòmíì. Fún àpẹẹrẹ, Allison sọ fún Sara ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípa ìṣòro tí alábàáṣiṣẹ́ wọn kan ní. Lọ́jọ́ kejì, ṣe ni Sara la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ níṣojú alábàáṣiṣẹ́ náà. Allison sọ pé: “Mi ò mọ̀ láyé pé irú ẹlẹ́nu bórobòro bẹ́ẹ̀ ni! Inú mà bí mi o.” Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Rachel, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ lọ tú àṣírí ọ̀rọ̀ táwọn méjèèjì jọ sọ níkọ̀kọ̀ síta. Rachel sọ pé: “Ojú tì mí, mo sì mọ̀ pé ó dà mí. Mo sọ ọ́ lọ́kàn ara mi pé, ‘Ǹjẹ́ ẹni yìí ṣeé bá sọ̀rọ̀ àṣírí mọ́ báyìí?’”

Ọ̀rẹ́ lè jẹ́ alábàárò ẹni, àgàgà nígbà tẹ́ẹ bá bìkítà fún ara yín, tẹ́ẹ fọkàn tán ara yín, tí ẹ ò sì ríra yín fín. Àmọ́, èdèkòyédè lè ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pàápàá. Bíbélì sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nígbà tó wí pé: “Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wà tí wọ́n nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” (Òwe 18:24) Ohun yòówù kó fà á, ó lè dùn ẹ́ wọnú eegun tóo bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ rẹ dà ẹ́. Kí ló máa ń fà á?

Ìdí Tí Okùn Ọ̀rẹ́ Fi Ń Já

Kò sí àjọṣe ẹ̀dá—yálà láàárín èwe tàbí àgbà—tí kì í níṣòro nínú. Ó ṣe tán, bí Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù, ti wí, ló rí gẹ́lẹ́, ó kọ̀wé pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2; 1 Jòhánù 1:8) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo wa là ń ṣàṣìṣe, ó yẹ ká mọ̀ pé, ó pẹ́ ni ó yá ni, ọ̀rẹ́ yóò ṣe nǹkan kan tàbí kó sọ nǹkan kan táá dùn wá. Ìwọ alára tiẹ̀ lè rántí ìgbà kan tí ìwọ náà ṣe ohun tó dun ẹni yẹn. (Oníwàásù 7:22) Lisa, ọmọ ogún ọdún, sọ pé: “Aláìpé ni gbogbo wa, a ò lè ṣe ká má ṣẹ ara wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”

Yàtọ̀ sí ti àìpé ẹ̀dá, àwọn nǹkan míì tún wé mọ́ ọn. Rántí pé bóo ti ń dàgbà sí i, ṣe ni àwọn ohun tó ń gbàfiyèsí rẹ—àti tàwọn ọ̀rẹ́ rẹ—ń yí padà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹni méjì tó jọ ń ṣe gbogbo nǹkan pọ̀ tẹ́lẹ̀ lè wá rí i pé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọ̀nà àwọn ò fẹ́ pa pọ̀ mọ́. Ọ̀dọ́langba kan sọ tẹ̀dùntẹ̀dùn nípa ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ̀ pé: “A kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè bára wa sọ̀rọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, nígbà táa bá sì sọ̀rọ̀, agbára káká lohùn wa fi ń ṣọ̀kan.”

Ṣùgbọ́n, níní èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí a ti ń dàgbà kò tó ohun táà gbé pọ́n. Àmọ́, kí ló dé táwọn kan máa ń dìídì ṣe ohun tó dun ọ̀rẹ́ wọn? Táa bá wá a lọ wá a bọ̀, kò lè ṣẹ̀yìn owú jíjẹ. Bí àpẹẹrẹ, bóyá ohun tó mú kí ọ̀rẹ́ kan máa bínú ẹ ni àwọn ẹ̀bùn àbínibí tóo ní tàbí àwọn àṣeyọrí ẹ. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 37:4; 1 Sámúẹ́lì 18:7-9.) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, “owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.” (Òwe 14:30) Ó máa ń fa ìlara àti asọ̀. Ohun yòówù kó fà á, kí lo lè ṣe táwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́?

Wá Nǹkan Ṣe Sí I

Rachel sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, màá ṣọ́ onítọ̀hún, kí n lè mọ̀ bóyá ó mọ̀ọ́mọ̀ ni.” Bí ẹnì kan bá fi ohun tó sọ tàbí ohun tó ṣe kàn ọ́ lábùkù, má kù gìrì gbégbèésẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, mú sùúrù, ro ọ̀ràn náà dáadáa. (Òwe 14:29) Fífi ìwàǹwára gbégbèésẹ̀ lórí ohun kan tó jọ àbùkù ha lè yanjú ọ̀ràn náà bí? Lẹ́yìn tóo bá ro ọ̀ràn náà, o lè yàn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Sáàmù 4:4, tó sọ pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” O lè wá yàn láti jẹ́ kí ‘ìfẹ́ bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.’—1 Pétérù 4:8.

Àmọ́ bọ́ràn náà bá dùn ẹ́ débi pé ó ṣòro fún ẹ láti gbójú fò ó ńkọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, á dáa kóo lọ bá onítọ̀hún. Frank, ọmọ ọdún mẹ́tàlá, sọ pé: “Ẹ pera yín, ẹ̀yin méjèèjì nìkan, kí ẹ sì jíròrò ohun tó ṣẹlẹ̀. Bí o ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní onítọ̀hún sínú.” Susan, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ní èrò kan náà. Ó sọ pé: “Ohun tó dáa jù lọ ni láti sọ fún wọn pé o gbọ́kàn lé wọn, ṣùgbọ́n wọ́n já ẹ kulẹ̀.” Jacqueline pẹ̀lú gbà pé ó sàn láti bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Màá fẹ́ ká bára wa sòótọ́ ọ̀rọ̀. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ẹni náà yóò sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ẹ, ó sì lè ṣeé ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà lójú ẹsẹ̀.”

Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ yẹra fún lílọ fìbínú bá ọ̀rẹ́ ẹ sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn tí ó kún fún ìhónú ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lọ́ra láti bínú ń mú aáwọ̀ rọlẹ̀.” (Òwe 15:18) Nítorí náà, dúró kí inú rẹ rọ̀, kóo tó lọ yanjú ọ̀ràn náà. Lisa sọ pé: “Inú á kọ́kọ́ bí ẹ, àmọ́, o gbọ́dọ̀ bomi sùúrù mu. Dúró dìgbà tínú ò bí ẹ sẹ́ni náà mọ́. Ìgbà yẹn ni kóo lọ bá a, kí ẹ jọ jókòó, kí ẹ yanjú rẹ̀ ní ẹ̀mí àlàáfíà.”

Gbólóhùn náà, “ní ẹ̀mí àlàáfíà,” ṣe pàtàkì púpọ̀. Rántí pé góńgó rẹ kì í ṣe láti lọ na ọ̀rẹ́ rẹ lẹ́gba ọ̀rọ̀. Góńgó rẹ ni láti yanjú ọ̀ràn náà ní ìtùnbí-ìnùbí, bó bá sì ṣeé ṣe, kí ẹ máa bá ọ̀rẹ́ yín lọ. (Sáàmù 34:14) Nítorí náà, sọ̀rọ̀ látọkànwá. Lisa dábàá pé: “O lè sọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ làwa méjèèjì jẹ́; ṣùgbọ́n mo fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.’ Ó yẹ kóo mọ̀dí tó fi hu irú ìwà yẹn. Nígbà tóo bá mọ̀dí abájọ, ọ̀ràn náà kò ní ṣòroó yanjú.”

Dájúdájú, ó lòdì láti máa wá ọ̀nà láti gbẹ̀san, bóyá nípa sísọ̀rọ̀ ẹni náà lẹ́yìn, kí àwọn èèyàn lè gbè sẹ́yìn rẹ. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Róòmù pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17) Ká sòótọ́, bó ti wù kí nǹkan náà dùn ẹ́ tó, gbígbẹ̀san yóò kàn túbọ̀ bọ̀ràn jẹ́ ni. Nora sọ pé: “Kò dáa kéèyàn ránró, nítorí pé tóo bá ránró, ẹ ò ní rẹ́ mọ́ láé.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi kún un pé bóo bá sa gbogbo ipá rẹ láti rí i pé ẹ dọ̀rẹ́ padà “inú ìwọ náà yóò dùn jọjọ.”

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo bóo ṣe ń sapá láti yanjú ọ̀ràn náà, bí ọ̀rẹ́ rẹ ò bá gbà ńkọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, rántí pé oríṣiríṣi ọ̀rẹ́ ló wà. Judith McCleese, tí ń gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìdílé, sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo ọ̀rẹ́ la lè mú ní kòríkòsùn. Kí o mọ̀ pé o lè ní onírúurú ọ̀rẹ́.” Síbẹ̀síbẹ̀, pé o tiẹ̀ ṣe ipa tìrẹ láti mú àlàáfíà bọ̀ sípò yóò tù ẹ́ nínú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.

Èdèkòyedè máa ń ṣẹlẹ̀, kódà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Bóo bá lè yanjú èdèkòyedè náà láìbẹ̀rẹ̀ sí fi ojú burúkú wo àwọn ẹlòmíì, tí o ò sì fi ara rẹ wọ́lẹ̀, a jẹ́ pé ìwọ náà ti ń dàgbà dénú nìyẹn. Bí àwọn kan tilẹ̀ “nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì,” Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé, “ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.”—Òwe 18:24.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ẹ lè parí ìjà yín nípa sísọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́