ORÍ 10
Kí Nìdí Táwọn Ọ̀rẹ́ Mi Fi Ń Ṣe Ohun Tó Ń Dùn Mí?
“Ọ̀rẹ́ mi àtàtà ni Kerry. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń lọ fi mọ́tò mi gbé e wálé láti ibi iṣẹ́ torí kò ní mọ́tò tiẹ̀. Ìgbà tó yá ni mo wá rí i pé ohun tó ń rí gbà lọ́wọ́ mi ló jẹ́ kó máa bá mi ṣọ̀rẹ́.
“Kò mọ̀ ju kó máa fi fóònù ẹ̀ pè tàbí kó máa tẹ̀ ẹ́ lọ tó bá ti wà nínú mọ́tò mi. Kò tiẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ mi rí, ó tún kọ̀ láti máa fowó sílẹ̀ ká lè máa fi ra epo sí mọ́tò. Ọ̀rọ̀ tí ò dùn ún gbọ́ létí ló sì máa ń sọ. Inú wá bẹ̀rẹ̀ sí bí mi torí pé mo ti gbà á láyè jù!
“Lọ́jọ́ kan mo sọ fún un pé mi ò ní wá gbé e lọ sílé mọ́. Òun náà ò tiẹ̀ wá mi wá mọ́ látìgbà yẹn, ìyẹn ló wá jẹ́ kó dá mi lójú pé tọwọ́ mi tó ń rí gbà ló jẹ́ kó máa bá mi ṣọ̀rẹ́. Ọ̀rọ̀ yẹn sì dùn mí gan-an!”—Nicole.
OHUN tá à ń wí yìí lè ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pàápàá. Ọ̀rọ̀ wọn lè jẹ́ òní eré, ọ̀la ìjà. Kí ló lè fa ìjà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ méjì lọ́sàn-án kan òru kan?
● Ohun tó fa ìjà láàárín Jeremy àtọ̀rẹ́ ẹ̀ ni pé ó kó lọ síbi tó jìnnà tó nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà. Jeremy sọ pé: “Látìgbà tó ti lọ, kò pè mí rí, ìyẹn sì dùn mí gan-an.”
● Kerrin kíyè sí i pé ìwà ọ̀rẹ́ òun, táwọn ti ń bára àwọn bọ̀ fún ọdún márùn-ún kàn ṣàdédé yí pa dà. Ó sọ pé: “Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ àti bó ṣe ń hùwà máa ń kó ìdààmú ọkàn bá mi. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹnu àtẹ́ lu àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí mi. Bá a bá sì ní ká jọ parí ìjà, ṣe ló máa bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lẹ́bi pé àṣejù mi ti pọ̀ jù àti pé ṣe ni mo máa ń rò pé èmi nìkan ni mo mọ gbogbo nǹkan ṣe, ó ní òun ò rí àǹfààní kankan látinú bíbá mi ṣọ̀rẹ́!”
● Ọ̀rẹ́ Gloria ò sọ nǹkan kan fún un kó tó já a jù sílẹ̀. Gloria sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ làwa méjèèjì tẹ́lẹ̀, ó tiẹ̀ sọ fún mi pé ṣe ni mo dà bí ọmọ ìyá òun. Àfi bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í di pé kì í jẹ́ ká jọ ṣe nǹkan pọ̀ mọ́, àwọn àwáwí tó sì máa ń ṣe kì í lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.”
● Ìjà dé láàárín Laura àti Daria nígbà tí Daria bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ bọ̀bọ́ tí Laura ń fẹ́. Laura sọ pé: “Gbogbo ìgbà ló máa ń bá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù, tí wọ́n á jọ máa sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ó dẹ̀ mọ̀ pé ẹni tí mò ń fẹ́ nìyẹn. Ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ dà mí, ẹni tí n bá sì fi ṣọkọ náà tún já mi sílẹ̀!”
Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Gan-an?
Kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe. Torí náà kò yẹ kó bá ẹ lójijì tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ṣe nǹkan tó dùn ẹ́ gan-an. Ká sòótọ́, ìwọ náà lè rántí àwọn ìgbà tó o ti ṣe nǹkan tó dun àwọn ẹlòmíì. (Oníwàásù 7:22) Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lisa sọ pé: “Aláìpé ni gbogbo wa, a ò sì lè ṣe ká má ṣẹra wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ẹ lè yanjú àṣìlóye tí kò jẹ́ kọ́rọ̀ yín yéra yín bẹ́ ẹ bá jọ ń sọ ọ́.
Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé, nǹkan tó fa ìjà kì í ṣohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ lẹ̀yin méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ìwà yín ò dọ́gba tó bẹ́ ẹ ṣe rò tẹ́lẹ̀. Má gbàgbé pé, bó o ṣe ń dàgbà làwọn nǹkan tó o nífẹ̀ẹ́ sí ń yí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni tàwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Kí lo wá lè ṣe tó o bá ti rí i pé àárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ ń dà rú lọ díẹ̀díẹ̀?
Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Parí Ìjà Yín
Ṣé aṣọ ẹ kan tó o fẹ́ràn gan-an ti fàya rí? Kí lo wá ṣe sí i? Ṣó o sọ ọ́ nù ni àbí o rán ibi tó ti fà ya? Ó dájú pé bó o bá ṣe fẹ́ràn aṣọ yẹn tó àti bó ṣe fàya tó ló máa pinnu nǹkan tó o máa ṣe. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo fẹ́ràn aṣọ yẹn, wàá fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti tún un ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó o lè ṣe nìyẹn ti ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ní aáwọ̀. Ohun tó máa pinnu ìyẹn náà ni ohun tó fa ìjà yẹn àti bó o ṣe fẹ́ràn ọ̀rẹ́ ẹ yẹn tó.a
Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá ti sọ̀rọ̀ kan tàbí tó hùwà kan tí ò dáa, o lè gbójú fò ó dá tó o bá fetí sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Sáàmù 4:4 tó ní: “Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” Torí náà, kó o tó sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ pé o ò ṣe mọ́, rò ó dáadáa. Ṣó mọ̀ọ́mọ̀ ni? Bí kò bá dá ẹ lójú, o ò ṣe gbàgbé ẹ̀? Kó o máa jẹ́ kí ‘ìfẹ́ bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀’ lọ́pọ̀ ìgbà.—1 Pétérù 4:8.
O tún lè yẹ ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ wò kó má lọ jẹ́ pé ìwọ gan-an ti dá kún un. Bí àpẹẹrẹ, tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá sọ̀rọ̀ àṣírí tó o fi pa mọ́ sí i lọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíì, o lè wò ó pé ‘àbí kò tiẹ̀ yẹ kí n sọ̀rọ̀ yẹn fún un?’ Ìbéèrè míì tó o lè bi ara ẹ ni pé, ‘àbí ìwọ lo lọ gbéra ẹ síta torí pé ò ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ kó o máa sọ?’ (Òwe 15:2) Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o bi ara ẹ pé, ‘Ṣó yẹ kí n ṣàwọn ìyípadà kan, kí ọ̀rẹ́ mí lè máa fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí?’
“Ṣé Ká Jọ Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tó Ṣẹlẹ̀?”
Bó o bá wá rí i pé ọ̀rọ̀ náà kọjá ohun tó o kàn lè gbàgbé bẹ́ẹ̀ yẹn ńkọ́? Ó máa dáa kíwọ àtọ̀rẹ́ ẹ jọ sọ ọ́. Wàá ṣọ́ra ṣá o, kó o má lọ sọ̀rọ̀ nígbà tínú bá ń bí ẹ. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn tí ó kún fún ìhónú ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lọ́ra láti bínú ń mú aáwọ̀ rọlẹ̀.” (Òwe 15:18) Torí náà, ní sùúrù, kó o jẹ́ kó dìgbà tínú tó ń bí ẹ bá rọlẹ̀ kó o tó sọ pé o fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Bó o bá sì ti lọ bá ọ̀rẹ́ ẹ, máa rántí pé kì í ṣe torí àti “fi ibi san ibi” lo ṣe lọ bá a. (Róòmù 12:17) Àmọ́, ìdí tó o fi lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ lè parí ìjà yín, kẹ́yin méjèèjì sì máa bá ọ̀rẹ́ yín lọ. (Sáàmù 34:14) Torí náà, bọ́rọ̀ yẹn bá ṣe rí nínú ẹ gan-an ni kó o ṣe sọ ọ́. O lè sọ pé, “Ó ti pẹ́ tá a ti ń bá ọ̀rẹ́ wa bọ̀. Ṣé ká jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀?” Bẹ́ ẹ bá ti mọ ohun tó fa ìṣòro náà, ó ṣeé ṣe kó rọrùn fún yín láti parí ìjà yín. Bí ọ̀rẹ́ ẹ bá sì lóun ò ṣe mọ́, jẹ́ kí ọkàn tìẹ balẹ̀ pé o ti ṣohun tó o lè ṣe láti yanjú aáwọ̀ náà.
Ju gbogbo ẹ̀ lọ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, báwọn ‘alábàákẹ́gbẹ́ kan tiẹ̀ wà tí wọ́n nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́,’ “ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) Gbà pé àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pàápàá máa ń bára wọn jà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bó bá sì ti ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà. Ká sòótọ́, tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti parí ìjà tó bá wáyé láàárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ, a jẹ́ pé ìwọ náà ti ń dàgbà nìyẹn.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 8, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Àwọn ojúgbà ẹ kan lè máa lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí ni wọ́n ń wá lọ síbẹ̀?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ kan wà tí ò yẹ kéèyàn jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, pàápàá bí ìwà wọn ò bá bá ìlànà Kristẹni mu mọ́.—1 Kọ́ríńtì 5:11; 15:33.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.
ÌMỌ̀RÀN
Kọ́kọ́ gbọ́ ohun tí ọ̀rẹ́ ẹ ní í sọ, kó o tó pinnu ohun ti wàá ṣe.—Òwe 18:13.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Bí àárín àwọn èèyàn bá máa gún, ìwọ̀nba ni wọlé wọ̀de wọn gbọ́dọ̀ mọ. (Òwe 25:17) Béèyàn ò bá sì jẹ́ kí ọ̀rẹ́ ẹ̀ rímú mí, tí kì í fi í lọ́rùn sílẹ̀ nígbà gbogbo, ó lè fa ìjà àjàtúká.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí mo bá fẹ́ bá ọ̀rẹ́ mi kan sọ nǹkan tí ò dáa tó ṣe fún mi, ohun tí màá kọ́kọ́ sọ ni pé ․․․․․
Bí ohun tí ọ̀rẹ́ mi kan ṣe bá tiẹ̀ bí mi nínú, ohun tí màá ṣe kí àlááfíà lè wà ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí táwọn ọ̀rẹ́ fi máa ń yara wọn?
● Irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo, tí ọ̀rẹ́ ẹ ṣẹ̀ ẹ́, lo lè gbójú fò dá, àwọn wo lo sì gbọ́dọ̀ sọ fún un?
● Bí ọ̀rẹ́ ẹ bá ṣe ohun kan tó dùn ẹ́, ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ látinú ẹ̀?
● Kí làwọn ohun tó o lè ṣe, káwọn ọ̀rẹ́ ẹ má bàa ṣe ohun tó máa dùn ẹ́?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 95]
“Bá a bá pa dà dọ̀rẹ́, mi ò jẹ́ retí pé kò ní síjà láàárín wa. Màá túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ sọ́rọ̀ ẹ̀, màá máa tì í lẹ́yìn, mi ò sì ní máa ka àwọn àṣìṣe ẹ̀ sí bàbàrà. Torí pé mo ti wá rí i báyìí pé téèyàn bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà, àfi kó mọ bá a ṣe ń fara da ìṣòro.”—Keenon
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 94]
Bí ìjà bá wáyé láàárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ, ẹ lè parí ẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá rán aṣọ tó fà ya