ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/1 ojú ìwé 22-25
  • ‘A Gbé Mi Ṣánlẹ̀, Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Run’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘A Gbé Mi Ṣánlẹ̀, Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Run’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìlọsẹ́yìn Gidi
  • Ìdílé Aláyọ̀
  • Bíborí Yíyarọ Nípa Tẹ̀mí
  • Kíkojú Ìfàsẹ́yìn Mìíràn
  • Ṣíṣe Ohun Tí Mo Lè Ṣe
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìlera, Okun Inú Ń Gbé Mi Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Mò Ń sin Jèhófà Tayọ̀tayọ̀ Bí Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Aláìlera
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/1 ojú ìwé 22-25

‘A Gbé Mi Ṣánlẹ̀, Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Run’

GẸ́GẸ́ BÍ ULF HELGESSON TI SỌ Ọ́

Ní July 1983, àwọn dókítà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sọ́dọ̀ mi kígbe pé: “Ó ti jí o!” A ti yọ kókó ọlọ́yún tí ó gùn ní ṣẹ̀ǹtímítà 12 nínú ògóóró ẹ̀yìn mi nígbà iṣẹ́ abẹ dídíjú, oníwákàtí 15. Èyí sọ mi di arọ pátápátá.

ỌJỌ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, a gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 60 kìlómítà láti ìlú mi ní Hälsingborg, ní gúúsù Sweden. Mo dara pọ̀ mọ́ ètò kan níbẹ̀, tí yóò mú mi padà bọ̀ sípò. Oníṣègùn ara títò náà wí pé yóò ṣòro púpọ̀, síbẹ̀ mo ń hára gàgà láti bẹ̀rẹ̀. Mo ṣáà fẹ́ láti lè rìn lẹ́ẹ̀kan sí i. Nípa lílọ́wọ́ nínú ètò ìmárale oníwákàtí márùn-ún lójoojúmọ́ déédéé, mo tẹ̀ síwájú lọ́nà yíyá kánkán.

Oṣù kan lẹ́yìn náà, nígbà tí alábòójútó arìnrìn àjò ń bẹ ìjọ wa wò, òun àti àwọn Kristian alàgbà mìíràn rin ìrìn àjò gígùn láti wá ṣe ìpàdé àwọn alàgbà nínú yàrá mi ní ilé ìwòsàn. Ẹ wo bí ayọ̀ ti kún ọkàn mi tó sí ẹ̀rí ìfẹ́ ará yìí! Lẹ́yìn tí ìpàdé náà parí, àwọn nọ́ọ̀sì tí wọ́n wà ní wọ́ọ̀dù fún àwùjọ náà látòkèdélẹ̀ ní tíì àti ìpápánu.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìtẹ̀síwájú mi ya àwọn dókítà lẹ́nu. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, mo lè jókòó sára nínú kẹ̀kẹ́ mi, kí n tilẹ̀ tún nàró fún ìgbà díẹ̀. Mo láyọ̀, mo sì pinnu pátápátá láti rìn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìdílé mi àti àwọn Kristian ẹlẹ́gbẹ́ mi fún mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣírí nígbà ìbẹ̀wò wọn. Mo tilẹ̀ lè lọ sílé fún sáà díẹ̀.

Ìlọsẹ́yìn Gidi

Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ìyẹn, n kò tẹ̀ síwájú mọ rárá. Oníṣègùn ara títò náà fún mi ní ìsọfúnni bíbani nínú jẹ́ náà pé: “Ara rẹ kò lè yá ju báyìí lọ!” Góńgó náà báyìí ni, láti fún mi lókun kí n ba lè máa fúnra mi wa kẹ̀kẹ́-arọ káàkiri. Mo ṣe kàyéfì lórí kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí mi. Báwo ni ìyàwó mi yóò ṣe kojú rẹ̀? A ti ṣe iṣẹ́ abẹ líle koko fún òun fúnra rẹ̀, ó sì nílò ìrànlọ́wọ́ mi. Ipò mi yóò ha béèrè fún ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀ wíwà pẹ́ títí bí?

Ọkàn mí bàjẹ́ gidigidi. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, okun mi, ìgboyà mi àti agbára mi pòórá. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ kọjá, mo sì wà níbẹ̀ láìlè gbéra nílẹ̀. Kì í ṣe pé gbogbo ara mi rọ nìkan, ṣùgbọ́n èrò ìmọ̀lára mi kú, n kò sì ní ìmọ̀ kankan mọ́ nípa tẹ̀mí. A ‘gbé mi ṣánlẹ̀.’ Mo ti sábà máa ń wo ara mi bí alágbára nípa tẹ̀mí. Mo ní ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ nínú Ìjọba Ọlọrun. (Danieli 2:44; Matteu 6:10) Ìlérí Bibeli pé gbogbo àìsàn àti àìlera ni a óò wò sàn nínú ayé tuntun òdodo Ọlọrun àti pé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni a óò mú padà bọ̀ sípò sí ìyè pípé níbẹ̀ dá mi lójú. (Isaiah 25:8; 33:24; 2 Peteru 3:13) Nísinsìnyí, èmi kì í ṣe arọ nípa ti ara nìkan, ṣùgbọ́n nípa tẹ̀mí pẹ̀lú. Ó dà bíi pé a ‘pa mí run.’—2 Korinti 4:9.

Ṣáájú kí n tó máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ, ẹ jẹ́ kí ń sọ díẹ̀ fún yín nípa ipò àtilẹ̀wá mi.

Ìdílé Aláyọ̀

A bí mi ní 1934, ìlera mi sì ti máa ń fìgbà gbogbo dára. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, mo pàdé Ingrid, a sì ṣègbéyàwó ní 1958, a sì fìdí kalẹ̀ sí ìlú Östersund, ní àárín gbùngbùn Sweden. Ìyípadà dé bá ìgbésí ayé wa ní 1963, nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nígbà yẹn, a ní ọmọ kéékèèké mẹ́ta—Ewa, Björn, àti Lena. Láìpẹ́, gbogbo ìdílé wa ń kẹ́kọ̀ọ́, a sì ń tẹ̀ síwájú dáradára nínú ìmọ̀ òtítọ́ Bibeli.

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí a bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, a ṣí lọ sí Hälsingborg. Níbẹ̀, èmi àti ìyàwó mi ya ara wa sí mímọ́ fún Jehofa, a sì ṣe batisí ní 1964. Ayọ̀ wa pọ̀ sí i nígbà tí ọmọbìnrin wa tí ó dàgbà jù lọ, Ewa, ṣe batisí ní 1968. Ọdún méje lẹ́yìn náà, ní 1975, Björn àti Lena pẹ̀lú ṣe batisí, a sì yàn mi sípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Kristian ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e.

Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi mú kí ń lè pèsè dáradára fún àìní ìdílé mi nípa ti ara. Ayọ̀ wa sì pọ̀ sí i nígbà tí Björn àti Lena tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Láìpẹ́, a ké sí Björn láti wá ṣiṣẹ́ sìn ní ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Arboga. Lọ́nà àpẹẹrẹ, ìgbésí ayé dára fún wa. Lẹ́yìn náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ 1980, mo bẹ̀rẹ̀ sí nímọ̀lára kókó ọlọ́yún ti a yọ kúrò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà iṣẹ́ abẹ líle koko náà ní 1983.

Bíborí Yíyarọ Nípa Tẹ̀mí

Nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé n kò ní lè rìn mọ́, ìgbésí ayé dà bí èyí tí ó dojú dé fún mi. Báwo ni mo ṣe jèrè okun nípa tẹ̀mí padà? Ó rọrùn ju bí mo ti rò lọ. Mo wulẹ̀ gbé Bibeli mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Bí mo ti ń kà á tó, bẹ́ẹ̀ ni okun tẹ̀mí mi ń pọ̀ sí i. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo wá lóye Ìwàásù Jesu Lórí Òkè. Mo kà á ní àkàtúnkà, mo sì ṣàṣàrò lé e lórí.

A mú ojú ìwòye aláyọ̀ mi nípa ìgbésí ayé padà bọ̀ sípò. Nípa kíkàwé àti ṣíṣàṣàrò, mo bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn àǹfààní dípò àwọn ìdènà. Mo jèrè ìfẹ́ ọkàn mi láti ṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn padà, mo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn yìí lọ́rùn nípa jíjẹ́rìí fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn àti àwọn mìíràn tí mo bá pàdé. Ìdílé mi tì mí lẹ́yìn gbágbágbá, wọ́n sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe lè bójú tó mi. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo fi ilé ìwòsàn sílẹ̀.

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín mo padà sílé. Ẹ wo irú ọjọ́ aláyọ̀ tí ìyẹn jẹ́ fún gbogbo wa! Ìdílé mi ṣètò ìwéwèé tí ó ní àbójútó mi nínú. Björn, ọmọkùnrin mi, pinnu láti fi iṣẹ́ ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sílẹ̀, ó sì wá sílé láti ṣèrànwọ́ láti bójú tó mi. Ó tù mí nínú púpọ̀, láti jẹ́ ẹni tí ìdílé mi darí irú ìfẹ́ àti àníyàn bẹ́ẹ̀ sí.

Kíkojú Ìfàsẹ́yìn Mìíràn

Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìlera mi ń jó rẹ̀yìn, ó sì ṣòro fún mi láti rìn. Níkẹyìn, láìka ìsapá àtọkànwá tí ìdílé mi ti ṣe sí, kò ṣeé ṣe fún wọn mọ́ láti bójú tó mi nílé. Nítorí náà, mo rò pé, yóò dára jù tí mo bá lè lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn aláìlètọ́jú ara wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó béèrè àwọn ìyípadà àti ọ̀nà ìgbàṣe tuntun. Ṣùgbọ́n, n kò gbà kí èyí jẹ́ ìfàsẹ́yìn nípa tẹ̀mí.

N kò fìgbà kan dáwọ́ Bibeli kíkà àti ṣíṣe ìwádìí dúró. Mo ń bá a nìṣó láti ronú nípa ohun tí mo lè ṣe, kì í ṣe ohun tí n kò lè ṣe. Mo ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún nípa tẹ̀mí tí gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní. Mo sún mọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí nínú àdúrà, mo sì lo gbogbo àǹfààní láti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn.

Wàyí o, mo ń lo alẹ́ àti apá kan ojúmọmọ mi nínú ilé ìtọ́jú àwọn aláìlètọ́jú ara wọn. Mò ń lo ọ̀sán àti ìrọ̀lẹ́ ní yálà ilé tàbí ní ìpàdé àwọn Kristian. Ètò afẹ́nifẹ́re kan ṣètò fún gbígbé mi lọ sí àwọn ìpàdé láti ilé mi àti gbígbé mi padà wálé déédéé. Ìdílé mi onífọkànsìn, àwọn ará nínú ìjọ, àti àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé ìtọ́jú àwọn aláìlètọ́jú ara wọn, bójú tó mi lọ́nà yíyani lẹ́nu.

Ṣíṣe Ohun Tí Mo Lè Ṣe

N kò ka ara mi sí olókùnrùn, bẹ́ẹ̀ ni ìdílé mi kò gba irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ bá mi lò, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn Kristian arákùnrin mi. A bójú tó mi lọ́nà onífẹ̀ẹ́, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti máa ṣiṣẹ́ sìn nìṣó lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Mò ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó ṣòro fún mi láti ṣí Bibeli, nítorí náà, a ti yan ẹnì kan láti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìyẹn ní àwọn ìpàdé. Mo ń darí àwọn ìpàdé, mo sì ń sọ àwíyé látorí kẹ̀kẹ́ arọ mi.

Nípa báyìí, mo ṣì lè ṣe ohun púpọ̀ tí mo ń gbádùn láti ṣe tẹ́lẹ̀, títí kan ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. (1 Peteru 5:2) Mo ń ṣe èyí nígbà tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin bá wá ìrànlọ́wọ́ tàbí ìmọ̀ràn wá sọ́dọ̀ mi. Mo tún ń lo tẹlifóònù, ní lílo ìdánúṣe láti tẹ àwọn ẹlòmíràn láago. Ó ń yọrí sí ìṣírí fún tọ̀túntòsì. (Romu 1:11, 12) Ọ̀rẹ́ kan sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ìgbà tí ọkàn mí bá rẹ̀wẹ̀sì gan-an, ni o máa ń tẹ̀ mí láago láti fún mi níṣìírí.” Ṣùgbọ́n, a fún èmi náà níṣìírí, ní mímọ̀ pé Jehofa ń bù kún àwọn ìsapá mi.

Ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé, mo ń ní ìfararora tí ó dára pẹ̀lú àwọn ọmọdé tí ń bẹ nínú ìjọ. Níwọ̀n bí mo ti ń jókòó nínú àga arọ mi, a ń bá ara wa sọ̀rọ̀ ní ìfojúkojú. Mo mọrírì ọ̀rọ̀ àtọkànwá àti ṣíṣàìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ wọn. Ọ̀dọ́mọdékùnrin kan sọ fún mi nígbà kan pé: “Olókùnrùn tí ẹwà rẹ̀ gọntiọ ni yín!”

Nípa dídarí àfiyèsí sí ohun tí mo lè ṣe dípò ṣíṣàníyàn nípa ohun tí n kò lè ṣe, mo ti ń gbádùn ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. Mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi. Mo ti mọ̀ pé, àwọn àdánwò tí a ń là kọja ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń fún wa lókun.—1 Peteru 5:10.

Mo ti ṣàkíyèsí pé, ọ̀pọ̀ àwọn abarapá kùnà láti lóye pé, a gbọ́dọ̀ mú ìjọsìn wa sí Bàbá wa ọ̀run ní ọ̀kúnkúndùn. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ìpàdé wa, àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wa lè di ọ̀nà ìgbàṣe ojoojúmọ́ lásán. Mo ka àwọn ìpèsè wọ̀nyí sí ohun tí ó ṣe pàtàkì láti lè la òpin ayé yìí já sínú Paradise orí ilẹ̀ ayé tí Ọlọrun ti ṣèlérí.—Orin Dafidi 37:9-11, 29; 1 Johannu 2:17.

A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrètí ìwàláàyè nínú ayé tuntun Ọlọrun tí ń bọ̀ máa wà nínú ọkàn wa nígbà gbogbo. (1 Tessalonika 5:8) Mo tún ti kọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú ìjàkadì lòdì sí ìtẹ̀sí èyíkéyìí láti rẹ̀wẹ̀sì. Mo ti kọ́ lati ka Jehofa sí Bàbá mi àti ètò àjọ rẹ̀ sí Ìyá mi. Mo ti wá mọ̀ pé, bí a bà sapá, Jehofa lè lò ẹnikẹ́ni nínú wa láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó jáfáfá.

Bí mo tilẹ̀ máa ń nímọ̀lára pé a ti ‘gbé mi ṣánlẹ̀’ nígbà mìíràn, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a kò tí ì ‘pa mi run.’ Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀ kò tí ì fìgbà kankan pa mí tì, bẹ́ẹ̀ sì ni ìdílé mi àti àwọn Kristian arákùnrin mi. Ọpẹ́lọpẹ́ pé n kò jáwọ́ nínú rírọ̀ mọ́ Bibeli àti kíkà á, mo jèrè okun mi nípa tẹ̀mí padà. Mo ṣọpẹ́ fún Jehofa Ọlọrun, ẹni tí ń fúnni ní “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” nígbà tí a bá gbẹ́kẹ̀ lé e.—2 Korinti 4:7.

Pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Jehofa, mo ń fi pẹ̀lú ìháragàgà fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọlá. Mo ní ìgbọ́kànlé pé, láìpẹ́ jọjọ, Jehofa Ọlọrun yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa Paradise kan tí a mú padà bọ̀ sípò níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbùkún àgbàyanu tí yóò mú wá.—Ìṣípayá 21:3, 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́