ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/1 ojú ìwé 25-29
  • Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n ní “Ọkàn Rírẹ̀wẹ̀sì”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n ní “Ọkàn Rírẹ̀wẹ̀sì”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àwọn Ìrònú Tí Ń padà Síni Lọ́kàn”
  • Ó Ha Ṣẹlẹ̀ Ní Ti Gidi Bí?
  • Pípèsè Ibi Ìsádi
  • Dúró Gẹ́gẹ́ Bí Alágbára Nípa Tẹ̀mí
  • Ẹni Tí Ó Báni Ṣèṣekúṣe Náà Ńkọ́?
  • Kí Ni Àwọn Alàgbà Lè Ṣe?
  • Dídènà Èṣù
  • ‘Àwọn Ohun Àtijọ́ Ni A Kì Yóò Mú Wá sí Ìrántí’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo (Apá Kẹta Nínú Mẹ́rin)
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Bá A Ṣe Lè Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n Bá Lò Pọ̀ Nígbà Tí Wọ́n Wà Lọ́mọdé (Apá Kẹrin Nínú Mẹ́rin)
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/1 ojú ìwé 25-29

Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n ní “Ọkàn Rírẹ̀wẹ̀sì”

LÓNÌÍ, ayé Satani ti wá “rékọjá gbogbo agbára òye ìwàrere.” (Efesu 4:19; 1 Johannu 5:19) Panṣágà àti àgbèrè jẹ́ àjàkáyé. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìpín 50 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ọgọ́rùn-ún ìgbéyàwó ń jálẹ̀ sí ìkọ̀sílẹ̀. A ti tẹ́wọ́ gba ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ níbi púpọ̀. Àwọn ìròyìn sábà máa ń gbé ìbálòpọ̀ oníwà ipá jáde—ìfipábánilòpọ̀. Ìrùfẹ́ ìṣekúṣe sókè ti di iṣẹ́ tí ń pawó rẹpẹtẹ wọlé.—Romu 1:26, 27.

Bíbá àwọn ọmọdé tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbégbòdì tí ń ríni lára jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ayé Satani, bíbá àwọn ọmọdé lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ jẹ́ ìwà “ẹran, ti ẹ̀mí-èṣù.” (Jakọbu 3:15) Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ìròyìn tí ó ṣeé fẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ìkọlù ìbálòpọ̀ láti ọwọ́ àwọn olùkọ́ àti àwọn oníṣègùn, tí a ń fi sun ìjọba lọ́dọọdún lé ní 400,000” ní United States nìkan. Nígbà tí àwọn òjìyà ìwà ìkà yìí bá dàgbà, ọ̀pọ̀ lára wọn ṣì ń rántí ìwà ìkà yìí, òtítọ́ gidi sì ni ìwà ìkà yìí jẹ́! Bibeli sọ pé: “Ọkàn [ìtẹ̀sí èrò orí, ìmọ̀lára inú lọ́hùn-ún àti ìrònú] ènìyàn yóò fàyà rán àìlera rẹ̀; ṣùgbọ́n ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì [tí a ṣá lọ́gbẹ́, tí a pọ́n lójú], ta ni yóò gbà á?”—Owe 18:14.

Ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun ń fa àwọn onírúurú ènìyàn mọ́ra, títí kan àwọn “oníròbìnújẹ́ ọkàn” àti àwọn tí wọ́n ní “ẹ̀mí ìbànújẹ́.” (Isaiah 61:1-4) Kò yani lẹ́nu pé, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìrora ẹ̀dùn ọkàn ń dáhùn padà sí ìkésíni náà pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ . . . máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Ìjọ Kristian lè jẹ́ ibi ìtùnú fún àwọn wọ̀nyí. Wọ́n láyọ̀ láti mọ̀ pé, ìjìyà yóò di ohun àtijọ́ láìpẹ́. (Isaiah 65:17) Ṣùgbọ́n, kí àkókò náà tó tó, a lè ní láti ‘tù wọ́n nínú’ kí ọgbẹ́ wọn sì ‘san.’ Paulu fún àwọn Kristian nímọ̀ràn yíyẹ pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún awọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tessalonika 5:14.

“Àwọn Ìrònú Tí Ń padà Síni Lọ́kàn”

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn kan ti di “oníròbìnújẹ́ ọkàn” nítorí ìdí tí ó ṣòro fún àwọn mìíràn láti lóye. Wọ́n jẹ́ àwọn àgbàlagbà tí ó jẹ́ pé, lórí ìpìlẹ̀ ohun tí a ti ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “àwọn ìrònú tí ń padà síni lọ́kàn,” wọ́n sọ pé a ti bá àwọn lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ rí, nígbà tí àwọn wà lọ́mọdé.a Àwọn kan kò lérò pé a ti fìtínà wọn rí àfi, lójijì, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í nírìírí àwọn ìrònú ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá àti “àwọn ìrònú” pé àgbàlagbà kan (tàbí àwọn àgbàlagbà) ń bá àwọn ṣèṣekúṣe nígbà tí àwọ́n ṣì wà lọ́mọdé. Ẹnikẹni ha wà nínú ìjọ tí ó ní irú ìrònú dídani láàmú bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ní àwọn ilẹ̀ mélòó kan, àwọn olùṣèyàsímímọ́ wọ̀nyí sì lè nírìírí másùnmáwo jíjinlẹ̀, ìbínú, ẹ̀bi, ìtìjú, tàbí ìdánìkanwà. Bíi Dafidi, wọ́n lè nímọ̀lára pé àwọn jìnnà sí Ọlọrun, kí wọ́n sì kígbe pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi dúró ní òkèèrè réré, Oluwa; èé ṣe tí ìwọ fi fi ara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.”—Orin Dafidi 10:1.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka “àwọn ìrònú” wọ̀nyí ni àwọn ògbógi nínú ìṣègùn ọpọlọ kò lóye. Síbẹ̀, irú “àwọn ìrònú” bẹ́ẹ̀ lè nípa lórí ipò tẹ̀mí àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́. Nítorí náà, a óò yíjú sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún ìtọ́sọ́nà pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nígbà tí a bá ń bójú tó wọn. Bibeli pèsè “ìfòyemọ̀ . . . ninu ohun gbogbo.” (2 Timoteu 2:7; 3:16) Ó tún ń ran gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jehofa, “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ati Ọlọrun ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú ninu gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Korinti 1:3, 4.

Ó Ha Ṣẹlẹ̀ Ní Ti Gidi Bí?

Nínú ayé, awuyewuye púpọ̀ ń bẹ nípa ohun tí “àwọn ìrònú” wọ̀nyí jẹ́, àti bí wọ́n ṣe ń ṣojú fún àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi tó. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa “kì í ṣe apákan ayé,” wọn kò sì lọ́wọ́ nínú awuyewuye yìí. (Johannu 17:16) Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìròyìn tí a ti tẹ̀ jáde, nígbà mìíràn, “àwọn ìrònú” ti fi ẹ̀rí ìpéye wọn hàn. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí adíyelófò, Frank Fitzpatrick, “rántí” pé àlùfáà kan ti fìtínà òun rí, àwọn mìíràn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún jáde wá láti jẹ́wọ́ pé àlùfáà kan náà ti bá àwọn ṣèṣekúṣe rí pẹ̀lú. Ìròyìn sọ pé, àlùfáà náà gbà pé lóòótọ́ ni òun ṣe ìṣekúṣe náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó yẹ fún àfiyèsí pé, àwọn kan kò tí ì lè fi ẹ̀rí ti “àwọn ìrònú” wọn lẹ́yìn. Àwọn kan tí a pọ́n lójú lọ́nà yìí, ní kedere, ti rántí ẹnì kan ní pàtó tí ó bá wọn ṣèṣekúṣe tàbí ibi kan pàtó tí a ti bá wọn ṣèṣekúṣe náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀ mulẹ̀ tí ó tako ti ìṣáájú mú un ṣe kedere pé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ “ìrònú” yìí lè máà jóòótọ́.

Pípèsè Ibi Ìsádi

Síbẹ̀síbẹ̀, báwo ni a ṣe lè pèsè ìtùnú fún àwọn tí wọ́n nírìírí “ẹ̀mí ìbànújẹ́” nítorí irú “àwọn ìrònú” bẹ́ẹ̀? Rántí òwe àkàwé Jesu nípa aládùúgbò tí ó jẹ́ ará Samaria. Àwọn jàgùdà dá ọkùnrin kan lọ́nà, wọ́n lù ú, wọ́n sì gba ohun ìní rẹ̀. Nígbà tí ará Samaria náà dé, àánú ọkùnrin tí ó fara gbọgbẹ́ náà ṣe é. Kí ló ṣe? Ó ha rin kinkin mọ́ gbígbọ́ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa lílù náà bí? A ha júwe àwọn jàgùdà náà fún ará Samaria náà, tí ó sì lépa wọn lọ lójú ẹsẹ̀ bí? Rárá o. Wọ́n ti ṣa ọkùnrin náà lọ́gbẹ́! Nítorí náà, ará Samaria náà fẹ̀sọ̀ di ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi tìfẹ́tìfẹ́ gbé e lọ sí ibi ààbò ní ilé ìwòsàn kan tí ó wà nítòsí, kí ó baà lè kọ́fẹ padà.—Luku 10:30-37.

Lóòótọ́, ìyàtọ̀ wà nínú ọgbẹ́ gidi àti “ẹ̀mí ìbànújẹ́” tí bíbáni lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ nígbà ọmọdé ṣokùnfà. Ṣùgbọ́n, méjèèjì mú ìjìyà ńláǹlà dání. Nítorí náà, ohun tí ará Samaria náà ṣe fún Júù tí a ṣa lọ́gbẹ́ náà fi ohun tí a lè ṣe láti ran Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni, tí a ń pọ́n lójú lọ́wọ́ hàn. Ohun àkọ́kọ́ ni láti pèsè ìtùnú onífẹ̀ẹ́, kí a sì ràn án lọ́wọ́ láti kọ́fẹ padà.

Èṣù pọ́n Jobu olùṣòtítọ́ lójú, ó mọ̀ gbangba pé, ìrora ìmí ẹ̀dùn tàbí ti ara ìyára yóò ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. (Jobu 1:11; 2:5) Láti ìgbà náà, Satani ti fìgbà gbogbo gbìyànjú láti lo ìjìyà—yálà ó ṣokùnfà rẹ̀ ní tààràtà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́—láti sọ ìgbàgbọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun di aláìlágbára. (Fi wé 2 Korinti 12:7-9.) A ha lè ṣiyèméjì pé, nísinsìnyí, Èṣù ń lo ìbọ́mọdé ṣèṣekúṣe àti “ọkàn rírẹ̀wẹ̀sì” ti ọ̀pọ̀ àgbàlagbà tí wọ́n ti jìyà èyí (tàbí tí “àwọn ìrònú” pé wọ́n jìyà rẹ̀ ń dà láàmú) láti gbìyànjú láti sọ ìgbàgbọ́ àwọn Kristian di aláìlágbára? Bíi Jesu, nígbà tí ó wà lábẹ́ ìkọlù Satani, Kristian kan tí ń jìyà ìrora, ṣùgbọ́n tí ó fi tokunratokunra kọ̀ láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ tì ń sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Satani!”—Matteu 4:10.

Dúró Gẹ́gẹ́ Bí Alágbára Nípa Tẹ̀mí

“Olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ti tẹ ìsọfúnni jáde láti ṣèrànwọ́ láti lè yanjú ìpalára nípa tẹ̀mí àti ti ìmí ẹ̀dùn tí ìbọ́mọdé ṣèṣekúṣe mú wá. (Matteu 24:45-47) Ìrírí fi hàn pé, gbígbára lé ‘agbára Oluwa àti agbára ńlá okun rẹ̀,’ àti gbígbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun” wọ̀, lè ran òjìyà náà lọ́wọ́. (Efesu 6:10-17) Ìhámọ́ra ogun yìí ní “òtítọ́” Bibeli nínú, tí ń tú Satani fó gẹ́gẹ́ bí olórí ọ̀tá, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn tí òun àti àwọn dòǹgárì rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́. (Johannu 3:19) Lẹ́yìn náà, “àwo ìgbayà ti òdodo,” wà níbẹ̀. Olùpọ̀njú náà ní láti làkàkà láti di àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo mú. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ní ìsúnniṣe lílágbára láti pa ara wọn lára tàbí kí wọ́n hùwà pálapàla. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dènà àwọn ìsúnniṣe wọ̀nyí, wọ́n ja àjàyè!

Ìhámọ́ra tẹ̀mí tún ní “ìhìnrere àlàáfíà” nínú. Bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ète Jehofa ń fún ẹni náà tí ń sọ̀rọ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ń tẹ́tí sí i lókun. (1 Timoteu 4:16) Bí “ẹ̀mí ìbànújẹ́” bá ń mú kí ó nira fún ọ láti sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere náà, gbìyànjú láti dara pọ̀ mọ́ Kristian mìíràn, nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí. Má sì ṣe gbàgbé “apata ńlá ti ìgbàgbọ́.” Ní ìgbàgbọ́ pé Jehofa nífẹ̀ẹ́ rẹ, àti pé òun yóò mú gbogbo ohun tí o ti pàdánù padà bọ̀ sípò. Gbàgbọ́ láìṣiyèméjì pé, Jesu pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa kíkú fún ọ. (Johannu 3:16) Satani ti máa ń fìgbà gbogbo fi èké sọ pé Jehofa kò bìkítà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Òmíràn lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ irọ́ burúkú rẹ̀ nìyẹn.—Johannu 8:44; fi wé Jobu 4:1, 15-18; 42:10-15.

Bí ẹ̀dùn ọkàn bá mú kí ó ṣòro láti gbàgbọ́ pé Jehofa bìkítà nípa rẹ, yóò dára láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n gbàgbọ́ dájú pé òun ń bìkítà. (Orin Dafidi 119:107, 111; Owe 18:1; Heberu 10:23-25) Kọ̀ láti fàyè gba Satani láti já ẹ̀bùn ìwàláàyè gbà mọ́ ọ lọ́wọ́. Rántí pé, “àṣíborí ìgbàlà” jẹ́ apá kan ìhámọ́ra náà; bẹ́ẹ̀ sì ni “idà ẹ̀mí” pẹ̀lú. Ẹ̀mí mímọ́, tí Satani kò lè borí ni ó mí sí Bibeli. (2 Timoteu 3:16; Heberu 4:12) Àwọn ọ̀rọ̀ awonisàn rẹ̀ lè tu ìrora ìmí ẹ̀dùn lára.—Fi wé Orin Dafidi 107:20; 2 Korinti 10:4, 5.

Paríparí rẹ̀, gbàdúrà déédéé fún okun láti fara dà á. (Romu 12:12; Efesu 6:18) Àdúrà àtọkànwá mú Jesu dúró la ìrora ìmí ẹ̀dùn gbígbóná janjan kọjá, ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. (Luku 22:41-43) Ó ha ṣòro fún ọ láti gbàdúrà bí? Sọ pé kí àwọn ẹlòmíràn gbàdúrà pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n sì gbàdúrà fún ọ. (Kolosse 1:3; Jakọbu 5:14) Ẹ̀mí mímọ́ yóò ti àwọn àdúrà rẹ lẹ́yìn. (Fi wé Romu 8:26, 27.) Bí ó ti rí pẹ̀lú àmódi onírora nípa ti ara, àwọn kan tí wọ́n ní ọgbẹ́ jíjinlẹ̀ ti ìmí ẹ̀dùn lè máà rí ìwòsàn pátápátá nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, a lè lo ìfaradà, ìṣẹ́gun sì ni ìfaradà jẹ́, bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Jesu. (Johannu 16:33) “Gbẹ́kẹ̀ lé [Jehofa] nígbà gbogbo; ẹ̀yin ènìyàn, tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀; Ọlọrun ààbò fún wa.”—Orin Dafidi 62:8.

Ẹni Tí Ó Báni Ṣèṣekúṣe Náà Ńkọ́?

Ẹnì kan tí ó bá bọ́mọdé lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ ní ti gidi, jẹ́ afipábánilòpọ̀, ó sì yẹ kí a fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wò ó. Ẹnikẹ́ni tí a bá fìyà jẹ lọ́nà yìí ní ẹ̀tọ́ láti fi ẹ̀sùn kan ẹni tí ó bá a lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ náà. Síbẹ̀, a kò ní láti fẹ̀sùn kanni pẹ̀lú ìwàǹwára bí ó bá jẹ́ orí “àwọn ìrònú tí ń padà síni lọ́kàn” nìkan ni ẹni tí a bá lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́ náà gbé e kà. Nínú ọ̀ràn yìí, ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni kí òjìyà náà jèrè ìwàdéédéé ní ti èrò ìmọ̀lára dé ìwọ̀n kan. Lẹ́yìn tí àkókò díẹ̀ bá ti kọjá, ó lè wà ní ipò tí ó sàn jù láti yẹ “àwọn ìrònú” náà wò, kí ó sì pinnu, bí ohunkóhun bá wà, tí ó lè ṣe nípa wọn.

Gbé ọ̀ràn Donna yẹ̀ wò. A gbọ́ pé ìṣiṣẹ́gbòdì ètò ìjẹun ń yọ ọ́ lẹ́nu, ó sì lọ bá olùgbaninímọ̀ràn kan—ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ oníbékebèke. Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sùn ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan kan bàbá rẹ̀, a sì wọ́ ọ lọ sí ilé ẹjọ́. Ìgbìmọ̀ ìdájọ́ náà kò fohùn ṣọ̀kan, nítorí náà, bàbá náà kò lọ sí ẹ̀wọ̀n, ṣùgbọ́n, ó san 100,000 dọ́là owó ìgbẹ́jọ́. Lẹ́yìn gbogbo èyí, Donna sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, òun kò gbàgbọ́ mọ́ pé ìwà ìkà náà ṣẹlẹ̀!

Ọ̀rọ̀ Solomoni náà bọ́gbọ́n mu pé: “Má ṣe fi ìwàǹwára pẹjọ́.” (Owe 25:8, NW) Bí ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá wà láti fura pé ẹni tí a rò pé ó jẹ́ ọ̀daràn náà ṣì ń ṣèkà sí àwọn ọmọdé, a lè kì í nílọ̀. Àwọn alàgbà ìjọ lè ṣèrànwọ́ nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Bí kò bá sí rí bẹ́ẹ̀, má ṣe kánjú. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó lè tẹ́ ọ lọ́rùn pé kí a gbàgbé ọ̀ràn náà. Ṣùgbọ́n, bí o bá fẹ́ kojú ẹni tí ó rò pé ó jẹ́ ọ̀daràn náà (lẹ́yìn yíyẹ bí ìmọ̀lára rẹ yóò ti rí nípa àwọn ìhùwàpadà tí ó lè jẹyọ wò lákọ̀ọ́kọ́ ná), o ní ẹ̀tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Láàárín àkókò tí “àwọn ìrònú” tí ẹnì kan ń nírìírí fi ń san, àwọn ipò tí kò bára dé lè dìde. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè ní àwòrán ṣíṣe kedere nínú ọpọlọ nípa bí ẹnì kan tí òun ń rí lójoojúmọ́ ṣe fìtínà rẹ̀. Kò sí ìlànà kankan tí a lè gbé kalẹ̀ fún yíyanjú èyí. “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Galatia 6:5) Nígbà mìíràn ẹnì kan lè rò pé ìbátan kan tàbí mẹ́ḿbà ìdílé tí ó sún mọ́ni pẹ́kípẹ́kí ni ó ṣe é. Rántí àìṣeégbọ́kàn lé tí “àwọn ìrònú” kan “tí ń padà síni lọ́kàn” ní, nígbà tí ó bá di ọ̀ràn dídá ọ̀daràn tí a fura sí náà mọ̀. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí a kò bá tí ì fìdí ọ̀ràn náà múlẹ̀, kíkàn sí ìdílé náà—ó kéré tan nípa ìbẹ̀wò lóòrèkóòrè, nípa lẹ́tà, tàbí nípa tẹlifóònù—yóò fi hàn pé ẹni náà ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà Ìwé Mímọ́.—Fi wé Efesu 6:1-3.

Kí Ni Àwọn Alàgbà Lè Ṣe?

Bí mẹ́ḿbà ìjọ kan tí ń nírìírí àwọn ìrònú àtẹ̀yìnwá tàbí “àwọn ìrònú tí ń padà síni lọ́kàn” ti ìbọ́mọdé ṣèṣekúṣe, bá tọ àwọn alàgbà wá, méjì lára wọn ní a sábà máa ń yàn láti ṣèrànwọ́. Àwọn alàgbà wọ̀nyí ní láti fi pẹ̀lú inú rere fún olùpọ̀njú náà níṣìírí láti pọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí kíkojú másùnmáwo ti èrò ìmọ̀lára fún àkókò kan ná. Àwọn orúkọ abọ́mọdé ṣèṣekúṣe èyíkéyìí “tí a rántí” ní a ní láti fi pa mọ́ láṣìírí.

Ẹrù iṣẹ́ àkọ́kọ́ ti àwọn alàgbà ni láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn. (Isaiah 32:1, 2; 1 Peteru 5:2, 3) Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ní pàtàkì láti “fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ [ara wọn] láṣọ.” (Kolosse 3:12) Jẹ́ kí wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ lọ́nà onínúure, lẹ́yìn náà kí wọ́n sì lo àwọn ọ̀rọ̀ awonisàn láti inú Ìwé Mímọ́. (Owe 12:18) Àwọn kan tí “àwọn ìrònú” onírora ti pọ́n lójú ti sọ ọ̀rọ̀ ìmoore fun àwọn alàgbà tí wọ́n ṣe ìbẹ̀wò déédéé sọ́dọ̀ wọn tàbí tí wọ́n tilẹ̀ tẹ̀ wọ́n láago láti mọ bí nǹkan ti ń lọ sí. Kò yẹ kí irú ìkànsíni bẹ́ẹ̀ gba àkókò púpọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi hàn pé ètò àjọ Jehofa bìkítà. Nígbà tí olùpọ́njú náà bá mọ̀ pé àwọn Kristian arákùnrin òun nífẹ̀ẹ́ òun ní tòótọ́, a lè ràn án lọ́wọ́ láti jèrè ìwàdéédéé ti èrò ìmọ̀lára dé ìwọ̀n kan.

Bí òjìyà náà bá pinnu pé, òun fẹ́ fẹ̀sùn kanni ńkọ́?b Lẹ́yìn náà àwọn alàgbà lè fún un nímọ̀ràn pé, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Matteu 18:15, ó ní láti tọ ẹni tí ó fẹ̀sùn kàn náà lọ fúnra rẹ̀ lórí ọ̀ràn náà. Bí ìmí ẹ̀dùn ẹni tí ó fẹ̀sùn kanni náà kò bá lè gbé ṣíṣe èyí ní ojúkorojú, ó lè ṣe é nípa tẹlifóònù tàbí bóyá nípa kíkọ lẹ́tà. Lọ́nà yìí, a ń fún ẹni ti a fẹ̀sùn kàn náà láǹfààní láti bá Jehofa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdáhùn rẹ̀ sí ẹ̀sùn náà. Ó tilẹ̀ lè pèsè ẹ̀rí pé, òun kò bá ẹni náà lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́. Tàbí bóyá ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà yóò jẹ́wọ́, tí ìbárẹ́ yóò sì ṣeé ṣe. Ẹ wo irú ìbùkún tí èyí yóò jẹ́! Bí ó bá jẹ́wọ́, àwọn alàgbà méjì náà lè bójú tó ọ̀ràn náà síwájú sí i ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́.

Bí ó bá sẹ́, àwọn alàgbà ní láti ṣàlàyé fún ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà pé kò sí ohun mìíràn tí a lè ṣe mọ́ ní ti ọ̀nà ìdájọ́. Ìjọ náà yóò sì máa bá a nìṣó láti wo ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà gẹ́gẹ́ bí aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Bibeli sọ pé ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta gbọ́dọ̀ wà, kí a tó lè gbé ìgbésẹ̀ ìdájọ́. (2 Korinti 13:1; 1 Timoteu 5:19) Kódà bí àwọn tí ó “rántí” ìwà ìkà tí ẹnì kan náà ṣe bá ju ẹyọ kan lọ, bí àwọn ìrònú yìí ṣe rí kò dáni lójú rárá láti gbé ìpinnu ìdájọ́ kà wọ́n lórí láìsí àwọn ẹ̀rí mìíràn tí ó tì í lẹ́yìn. Èyí kò túmọ̀ sí pé a kà irú “àwọn ìrònú” bẹ́ẹ̀ sí irọ́ (tàbí pé a kà wọ́n sí òtítọ́). Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bibeli ní fífìdí ọ̀ràn ìdájọ́ kan múlẹ̀.

Ṣùgbọ́n, bí ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà—bí ó tilẹ̀ sẹ́ ìwà àìtọ́ náà—bá jẹ̀bi ní ti gidi ńkọ́? Ó ha “ṣe é gbé” bí? Dájúdájú kò rí bẹ́ẹ̀! Ọ̀ràn bóyá ó jẹ̀bi tàbí kò mọwọ́mẹsẹ̀ ni a lè fi lé Jehofa lọ́wọ́. “Ẹ̀ṣẹ̀ awọn ènìyàn kan a máa farahàn kedere ní gbangba, ní ṣíṣamọ̀nà sí ìdájọ́ ní tààràtà, ṣugbọn níti awọn ẹlòmíràn ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹlu a máa farahàn kedere lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” (1 Timoteu 5:24; Romu 12:19; 14:12) Ìwé Owe sọ pé: “Àbá olódodo ayọ̀ ni yóò já sí: ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.” “Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a dasán.” (Owe 10:28; 11:7) Ní òpin gbogbo rẹ̀, Jehofa Ọlọrun àti Kristi Jesu yóò fi ìdájọ́ òdodo ṣèdájọ́ àìnípẹ̀kun.—1 Korinti 4:5.

Dídènà Èṣù

Nígbà tí àwọn ọkàn tí ó ti ṣè ìyàsímímọ́ bá lo ìfaradà lójú ìrora ńláǹlà nípa ti ara tàbí ti ìmí ẹ̀dùn, ẹ wo irú ẹ̀rí tí èyí jẹ́ nípa okun inú wọn àti ìfẹ́ wọn fún Ọlọrun! Ẹ sì wo ẹ̀rí tí ó jẹ́ pé agbára ẹ̀mí Jehofa lè mú wọn dúró!—Fi wé 2 Korinti 4:7.

Àwọn ọ̀rọ̀ Peteru bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mu pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Satani], ní dídúró gbọn-in ninu ìgbàgbọ́.” (1 Peteru 5:9) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè má rọrùn. Nígbà mìíràn, ó tilẹ̀ lè ṣòro láti ronú lọ́nà ṣíṣe kedere, tí ó sì bọ́gbọ́n mu. Ṣùgbọ́n mọ́kàn le! Láìpẹ́, Èṣù àti àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ kì yóò sí mọ́. Lóòótọ́, a ń yán hànhàn fún àkókò náà nígbà tí “Ọlọrun fúnra rẹ̀ . . . yoo . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, [tí] ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Àwọn ìrònú tí ń padà síni lọ́kàn” àti àwọn gbólóhùn mìíràn tí ó fara pẹ́ ẹ ni a fi sínú àkámọ́ láti fi ìyàtọ̀ wọn hàn sí àwọn irú ìrònú wíwọ́pọ̀ tí gbogbo wa ń ní.

b Ó tún lè pọn dandan pé, kí a gbé irú ìgbésẹ̀ tí a là lẹ́sẹẹsẹ nínú ìpínrọ̀ yìí bí ọ̀ràn náà bá ti di mímọ̀ nínú ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́