Òfin Àtọwọ́dọ́wọ́ Ha Gbọ́dọ̀ Forí Gbárí Pẹ̀lú Òtítọ́ Bí?
ÓDÁ Martin Luther lójú pé òtítọ́ ni òun ń sọ. Ó gbà gbọ́ pé, Bibeli ti òun lẹ́yìn. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, Copernicus, onímọ̀ nípa sánmà, ọmọ ilẹ̀ Poland, lérò pé ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí gbogbo ènìyàn tẹ́wọ́ gbà, kò tọ̀nà.
Ìgbàgbọ́ wo ni? Pé ayé jẹ́ àárín gbùngbùn àgbáyé, àti pé ohun gbogbo ń yí i po. Copernicus sọ pé, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ayé fúnra rẹ̀ ń yí òòrùn po. Luther ta ko èyí, ní sísọ pé: “Àwọn ènìyàn ń tẹ́tí sí àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí wọ́n ń tiraka láti fi hàn pé ayé ń yípo, pé kì í ṣe àwọn ọ̀run tàbí òfuurufú, oòrùn àti òṣùpá ní ń yí.”—History of Western Philosophy.
ÌGBÀGBỌ́ àtọwọ́dọ́wọ́ sábà máa ń forí gbárí pẹ̀lú òtítọ́, àti pẹ̀lú òkodoro òtítọ́. Wọ́n tilẹ̀ lè mú kí àwọn ènìyàn ṣe ohun tí ó lè pa wọ́n lára.
Àmọ́ ṣáá o, èyí kò túmọ̀ sí pé, nígbà gbogbo ni òfin àtọwọ́dọ́wọ́ máa ń forí gbárí pẹ̀lú òtítọ́. Ní ti gidi, aposteli Paulu fún àwọn Kristian ọjọ́ rẹ̀ ní ìṣírí láti máa bá a lọ ní títẹ̀ lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó fi lé wọn lọ́wọ́, ní sísọ pé: “Wàyí o mo gbóríyìn fún yín nitori . . . ẹ . . . ń di awọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mú ṣinṣin gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”—1 Korinti 11:2; tún wo 2 Tessalonika 2:15; 3:6.
Kí ni Paulu ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé “òfin àtọwọ́dọ́wọ́”? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 1118, tọ́ka sí i pé ọ̀rọ̀ Griki náà, pa·raʹdo·sis, tí ó lò fún “òfin àtọwọ́dọ́wọ́,” túmọ̀ sí ohun kan tí a “ta látaré nípa ọ̀rọ̀ ẹnú, tàbí nípa kíkọ ọ́ sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Yorùbá náà túmọ̀ sí “ìsọfúnni, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, tàbí àwọn àṣà tí a ta látaré láti ọ̀dọ̀ òbí sí ọmọ tàbí tí ó ti di ọ̀nà ìronú tàbí ìhùwà tí ó fìdí múlẹ̀.”a Nítorí pé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí aposteli Paulu fà lé wọn lọ́wọ́ wá láti orísun rere, ó dára bí àwọn Kristian bá dì wọ́n mú ṣinṣin.
Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé, òfin àtọwọ́dọ́wọ́ lè jẹ́ òtítọ́ tàbí èké, ó lè dára tàbí kí ó burú. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ilẹ̀ Britain, ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, Bertrand Russell, gbóríyìn fún àwọn ènìyàn bíi Copernicus ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, tí ó fi àìlábòsí àti ìgboyà gbéjà ko àwọn ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́. Wọ́n mú “èrò náà pé ohun tí a gbà gbọ́ láti ìgbà àtijọ́ lè jẹ́ èké” dàgbà. Ìwọ pẹ̀lú ha rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti má ṣe tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ní gbundúku bí?—Fi wé Matteu 15:1-9‚ 14.
Nígbà náà, kí ni nípa ti àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn àti àṣà? A ha kàn lè méfò pé wọn tọ̀nà, wọn kò sì lè pani lára bí? Báwo ni a ṣe lè mọ̀? Kí ni a ní láti ṣe bí a bá rí i pé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn forí gbárí pẹ̀lú òtítọ́ ní ti gidi? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀yìn ìwé: Jean-Leon Huens © National Geographic Society
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Universität Leipzig