Nígbà Tí Òfin Àtọwọ́dọ́wọ́ Bá Forí Gbárí Pẹ̀lú Òtítọ́
EWU—OMI YÌÍ KÒ DÁRA FÚN MÍMU. A lè ti máa rí ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ àdúgbò, àwọn ènìyàn ń ṣọ́ra nípa omi tí wọ́n ń mu, nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn ìpèsè omi kan ní ohun tí a mọ̀ sí “àpòpọ̀ onímájèlé” nínú, tí oògùn olóró ti bà jẹ́. Ìwádìí kan sọ pé, nítorí ìbàjẹ́ yìí, dípò kí omi jẹ́ “ohun tí ń gbé ìwàláàyè ró, tí ó sì ń dáàbò bò ó,” ó lè di “ohun tí ń tàtaré kòkòrò àrùn àti . . . èròjà ẹlẹ́gbin.”—Water Pollution.
Bíba Omi Òtítọ́ Jẹ́
Àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n forí gbárí pẹ̀lú òtítọ́ dà bí ìpèsè omi ìdọ̀tí. A lè fi àìmọ̀kan di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mú ṣinṣin—ìsọfúnni, èrò, ìgbàgbọ́, tàbí àṣà tí a fi lé wa lọ́wọ́ láti iran kan dé òmíràn—tí ó ti di ohun tí “àpòpọ̀ onímájèlé” tí àwọn ìrònú àti ọgbọ́n èrò orí èké tí ń ṣini lọ́nà kó èérí bá, ní ti gidi. Gan-an bí omi eléèérí, wọ́n lè fa ìpalára tí kò ṣeé fẹnu sọ—ìpalára nípa tẹ̀mí.
Bí a bá tilẹ̀ ronú pé a gbé àwọn ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn wa ka Bibeli, gbogbo wa ní láti fara balẹ̀ láti fìṣọ́ra yẹ̀ wọ́n wò. Rántí pé, nígbà tí Martin Luther di ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ọjọ́ rẹ̀ mú ṣinṣin, tí ó sì bẹnu àtẹ́ lu Copernicus, ó gbà gbọ́ pé òún ní ìtìlẹyìn Bibeli. Ṣùgbọ́n, Luther kọ̀ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere ti àwọn ará Berea ìgbàanì, ‘tí wọ́n lọ́kàn rere ní ti fífẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá nǹkan wọnyi rí bẹ́ẹ̀.’—Ìṣe 17:10, 11.
Ronú nípa ìpalára tí ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ mú bá àwọn Júù díẹ̀, nígbà ayé Jesu. Pẹ̀lú ìtara, wọ́n gbàgbọ́ pé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọn jẹ́ òtítọ́. Nígbà tí wọ́n fara ya pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu kò tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́, Jesu gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú ìbéèrè náà pé: “Èéṣe tí ẹ̀yin pẹlu ń rékọjá ìlà àṣẹ Ọlọrun nitori òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín?” (Matteu 15:1-3) Kí ni ó ṣàìtọ́? Jesu tọ́ka sí ìṣòro náà, nígbà tí ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé: “Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn [Ọlọrun], nitori pé wọ́n ń fi awọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.”—Matteu 15:9; Isaiah 29:13.
Bẹ́ẹ̀ ni, dípò òtítọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, wọ́n ń fi ìrònú tí ó wá láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, tàbí, èyí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù, tí ó tilẹ̀ burú jù lọ dípò rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 506, ṣàlàyé pé: “Àwọn Farisi nígbà náà ń kọ́ni pé, níwọ̀n bí ẹnì kan bá ti kéde pé gbogbo ohun ìní òun jẹ́ ‘kọbani,’ tàbí ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kò lè lò wọ́n láti tẹ́ àìní àwọn òbí rẹ̀ lọ́rùn, bí ó ti wù kí àìní náà pọ̀ tó, ṣùgbọ́n, ó lè lo àwọn ohun ìní bẹ́ẹ̀ fúnra rẹ̀ títí tí yóò fi kú, bí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn tí ó sọ omi òtítọ́ di eléèérí ti ní ipa búburú lórí ipò tẹ̀mí àwọn Júù. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn tilẹ̀ kọ Messia tí wọ́n ti ń retí tipẹ́tipẹ́ náà sílẹ̀.
Kirisẹ́ńdọ̀mù Dá Kún Ìbàjẹ́ Náà
Irú ìbàjẹ́ kan náà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Jesu. Ọ̀pọ̀ tó jẹ́wọ́ pé àwọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ń tẹ̀ lé òfin àtẹnudẹ́nu gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ fún ẹ̀kọ́ tuntun. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, láti ọwọ́ McClintock àti Strong ti sọ, àwọn kan tí wọ́n fẹnu lásán jẹ́ Kristian gbà gbọ́ pé irú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ìtọ́ni tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà láti ẹnu àwọn aposteli, tí a ta látaré láti ìgbà àwọn aposteli, tí a sì pa mọ́ ní mímọ́ títí di ọjọ́ tiwọn.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí jẹ́ aláìmọ́, àti èrò òdì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia náà ti ṣàlàyé, “kì í ṣe kìkì pé” àwọn ọgbọ́n èrò orí wọ̀nyí “yàtọ̀ sí àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mìíràn nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún yàtọ̀ gidigidi sí ìwé tí àwọn aposteli ní lọ́wọ́.” Èyí kò ṣàjèjì. Aposteli Paulu ti kìlọ̀ fún àwọn Kristian pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹni kan lè wà tí yoo gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ọgbọ́n èrò-orí ati ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹlu òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹlu awọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé tí kò sì sí ní ìbámu pẹlu Kristi.”—Kolosse 2:8.
Lónìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ‘yàtọ̀ gidigidi sí ìwé àwọn aposteli.’ Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi àwọn èrò tí ẹ̀mí èṣù mí sí, bíi Mẹ́talọ́kan, ọ̀run àpáàdì, àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, àti ìbọ̀rìṣà sọ omi òtítọ́ náà di májèlé.a (1 Timoteu 4:1-3) Ìtàn jẹ́rìí sí i pé àìsàn tẹ̀mí ti bo àwọn ènìyàn tí wọ́n ti di ẹran ọdẹ fún ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù tí ó ti di ẹ̀kọ́ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù mọ́lẹ̀.—Fi wé Isaiah 1:4-7.
Ní ti gidi, sísọ òtítọ́ deléèérí bẹ́ẹ̀, ti ń ṣẹlẹ̀ láti ìgbà àtètèkọ́ṣe. Satani ti tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìlànà fífi irọ́ àti ẹ̀tàn sọ èrò inú ènìyàn di onímájèlé, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní Edeni. (Johannu 8:44; 2 Korinti 11:3) Lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Noa, bí àwọn ìdílé ẹ̀dá ènìyàn ti ń tàn kálẹ̀ ká gbogbo ayé, àwọn ènìyàn láti onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wá di ẹran ọdẹ fífi ọgbọ́n èrò orí àti èrò ti ẹ̀mí èṣù mọ̀ọ́mọ̀ sọ ibi tí a tọ́jú ìmọ̀ ẹ̀dá ènìyàn pa mọ́ sí di onímájèlé.
Àbájáde Ìbàjẹ́ Nípa Tẹ̀mí
Ìpalára wo ni irú ìsọdèérí nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lè mú wá? A lè fi wé àbájáde tí omi tí a ti bà jẹ́ ní lórí ìlera ara. Abẹnugan kan sọ pé: “Nǹkan bí 200 mílíọ̀nù ènìyàn ni wọ́n ti ní àrùn àtọ̀sí ajá, [tí ń fa àìlókun nínú, àìbalẹ̀ ara, àìlera lápapọ̀, àti ikú pàápàá], tí omi eléèérí tí ó wà lára awọ ara fà. Ẹ̀ẹ́gbẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù àwọn ènìyàn ní àrùn ojú pípọ́n tí ń ṣepin, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń fa ojú fífọ́, nítorí fífi omi ìdọ̀tí wẹ̀. . . . Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì lára ìran ènìyàn kò ní omi tí ó dára láti mu.” (Our Country, the Planet) A ti sọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn di aláàárẹ̀ àti afọ́jú nípa tẹ̀mí, a sì ti pa wọ́n pàápàá nítorí títẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti a ti fi ẹ̀kọ́ èké, àti ti ẹ̀mí èṣù sọ dìbàjẹ́.—1 Korinti 10:20‚ 21; 2 Korinti 4:3‚ 4.
Fún àpẹẹrẹ, a ti ṣì ọ̀pọ̀ lọ́nà tàbí fọ́ wọ́n lójú sí ìbátan tí ó wà láàárín Jesu Kristi àti Bàbá rẹ̀, Jehofa Ọlọrun. Ó ti dàṣà láàárín àwọn kan tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian láti yọ orúkọ mímọ́ Ọlọrun, Jehofa, kúrò nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì. George Howard sọ nínú Journal of Biblical Literature pé: “Lójú ìwòye tiwa, yíyọ àmì ọ̀rọ̀ Heberu mẹ́rin fún orúkọ Ọlọrun kúrò, ti dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ lọ́kàn àwọn Kèfèrí tí wọ́n kọ́kọ́ di Kristian, nípa ìbátan tí ó wà láàárín ‘Oluwa Ọlọrun’ àti ‘Kristi Oluwa.’”
Bákan náà, ronú nípa ìdàrúdàpọ̀, ìgbàgbọ́ ohun asán, àti ìbẹ̀rù tí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu pé, ọkàn ẹ̀dá ènìyàn kò lè kú, ti dá sílẹ̀. (Fi wé Oniwasu 9:5; Esekieli 18:4.) Ènìyàn mélòó ni ó wà lábẹ́ ìgbèkùn jíjọ́sìn àwọn baba ńlá tàbí tí ń gbé nínú ìbẹ̀rù nígbà gbogbo pé àwọn òkú yóò padà wá láti wá pa wọ́n lára? Ìgbàgbọ́ yìí tilẹ̀ ti mú kí àwọn ènìyàn kan pa ara wọn àti àwọn mìíràn.
Ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan lérò pé nígbà tí àwọ́n bá kú, ẹ̀mí wọn tí ó jáde lọ yóò pàdé ní ayé tọ̀hún. Nítorí náà, àwọn òbí kan tí wọ́n gbẹ̀mí ara wọn, ti rò pé ohun tí ó dára jù lọ ni kí àwọ́n pa àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú. Ìwé atúmọ̀ èdè, An English Dictionary of Japanese Ways of Thinking, ṣàlàyé pé: “Ní Japan, a kì í fìgbà gbogbo bẹnu àtẹ́ lu gbígbẹ̀mí ara ẹni, ṣùgbọ́n a sábà máa ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà, tí ẹnì kan fi lè tọrọ àforíjì fún ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tí ó ti dá . . . Ó ṣeé ṣe pàápàá kí a ròyìn ìdílé kan tí wọ́n gbẹ̀mí ara wọn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn.”
Dán Òfin Àtọwọ́dọ́wọ́ Náà Wò
Lójú ìwòye àwọn ewu tí ó wé mọ́ títẹ̀ lé ìgbàgbọ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ní gbundúku, kí ni a ní láti ṣe? Bí ọ̀rúndún kìíní ti ń lọ sí òpin, aposteli Johannu fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ máṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn àgbéjáde onímìísí wò [gan-an bí ẹ̀yin yóò ṣe yẹ omi wò bóyá ó mọ́] lati rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nitori ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.” (1 Johannu 4:1; tún wo 1 Tessalonika 5:21.) Báwo ni o ṣe lè mọ̀ bí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ kan bá léwu? O nílò ọlá àṣẹ kan, ọ̀pá ìdiwọ̀n ohun mímọ́, láti yẹ ohun tí o gbà gbọ́ wò.
Bibeli jẹ́ irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀. Jesu Kristi sọ pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Johannu 17:17) Ó tún sọ pé: “Wákàtí naa ń bọ̀, nísinsìnyí sì ni, nígbà tí awọn olùjọsìn tòótọ́ yoo máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:23) Nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mí sí, ìwọ yóò rí omi òtítọ́ mímọ́ gaara, dípò omi ẹlẹ́gbin ti ọgbọ́n èrò orí ti ẹ̀dá ènìyàn àti ti ẹ̀mí èṣù.—Johannu 8:31‚ 32; 2 Timoteu 3:16.
Rántí pé, ohun ìbàjẹ́ bínńtín pàápàá lè ní àbájáde búburú. Nígbà míràn, ó lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí àbájáde rẹ̀ tó jẹ yọ. Shridath Ramphal, ààrẹ Ẹgbẹ́ Olùdáàbò Bo Nǹkan Lágbàáyé tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé: “Omi ìdọ̀tí ti di ohun tí ó wọ́ pọ̀ jù lọ, tí ó sì burú jù lọ, tí ń pànìyàn lágbàáyé. Ó kéré tán, ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn ń kú lójoojúmọ́ nítorí lílò tí wọ́n ń lò ó.” Àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́, tí ó ti deléèérí nípa tẹ̀mí, tilẹ̀ tún léwu ju ìyẹn lọ.
Ìwọ ha ní ìgboyà láti já ara rẹ gbà kúrò lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó ti ṣeé ṣe kí o ti tẹ̀ lé fún ọ̀pọ̀ ọdún, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé, wọ́n forí gbárí pẹ̀lú òtítọ́ bí? Fetí sí ìkìlọ̀ náà. Dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ, nípa rírí i dájú pé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ rẹ bára mu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọrun, tí ó mọ́ gaara.—Orin Dafidi 19:8-11; Owe 14:15; Ìṣe 17:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Reasoning From the Scriptures fún ẹ̀rí pé irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kò ní ìpìlẹ̀ nínú Bibeli. Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ni ó tẹ ìwé yìí jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọrun dà bí omi odò aláìléèérí, mímọ́ gaara