Ǹjẹ́ O Lè Gba Bíbélì Gbọ́?
GBÍGBA Bíbélì gbọ́ ṣì gbilẹ̀, kódà, nínú ayé òde òní pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwádìí èrò aráàlú kan tí a ṣe láàárín àwọn ará Amẹ́ríkà láìpẹ́ yìí, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí. Yálà iye náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní àdúgbò rẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o lè mọ̀ pé àwọn tó ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń retí pé kí a kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nípa ọkàn tí ń jìyà lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti kú tán.
Ǹjẹ́ ibì kan wà nínú Bíbélì tí a ti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pọ́gátórì tàbí ọ̀run àpáàdì? Lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wé nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò dáhùn pé kò sí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ní àbárèbábọ̀, orí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ la gbé ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kátólíìkì nípa pọ́gátórì kà, a kò gbé e karí Ìwé Mímọ́.” Nípa ti hẹ́ẹ̀lì, ìwé atúmọ̀ èdè A Dictionary of Christian Theology sọ pé: “Nínú Májẹ̀mú Tuntun, a kò rí ibi tí a ti wàásù nípa ọ̀run àpáàdì ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.”
Ní tòótọ́, ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England ṣe tuntun láìpẹ́ yìí, nígbà tó sọ pé kí a yọ ẹ̀kọ́ nípa ọ̀run àpáàdì sọ nù pátápátá. Ọ̀mọ̀wé Tom Wright, olórí Kàtídírà Litchfield, sọ pé, bí a ṣe fi ọ̀run àpáàdì kọ́ni tẹ́lẹ̀ ti “sọ Ọlọ́run di òkú òǹrorò kan, ó sì ti dá ọgbẹ́ aronilára kan sí ọkàn ọ̀pọ̀ ènìyàn.” Àkọjáde ìgbìmọ̀ náà ṣàpèjúwe ọ̀run àpáàdì gẹ́gẹ́ bí “ohun tí kò sí níbikíbi rárá.”a Lọ́nà kan náà, nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ń sọ èrò ti Kátólíìkì, ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ìsìn nípa Ọlọ́run lóde òní rí ọ̀ràn nípa ọ̀run àpáàdì bí yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
Ní gidi, ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ọkàn yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀kọ́ pọ́gátórì àti ọ̀run àpáàdì. Lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ikú àwọn ọkàn. “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4; fi wé àwọn ìtumọ̀ ti King James àti Douay ti Kátólíìkì.) Ohun tí Bíbélì sọ ni pé, òkú kò mọ ohun kan, kò lè mọ ìrora. “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Ìrètí tí Bíbélì sọ pé òkú ní ni àjíǹde ọjọ́ iwájú. Nígbà tí ọ̀rẹ́ Jésù, Lásárù, kú, Jésù fi ikú wé oorun. Arábìnrin Lásárù, Màtá, mẹ́nu ba ìrètí tí Bíbélì fi kọ́ni nígbà tó wí pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Nípa jíjí Lásárù dìde láti tún wà láàyè, Jésù fìdí ìrètí yẹn múlẹ̀ fún aráyé.—Jòhánù 5:28, 29; 11:11-14, 24, 44.
Àwọn òpìtàn fi hàn pé ẹ̀kọ́ pé ènìyàn ní ọkàn kan tí kò lè kú lọ́tọ̀ kì í ṣe ti Bíbélì, inú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì ló ti pilẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé, àwọn Hébérù ìgbàanì kì í ronú nípa ènìyàn bí àpapọ̀ ara gidi kan àti ọkàn kan tí kò ṣeé rí. Nípa ìgbàgbọ́ àwọn Hébérù náà, ó sọ pé: “Nígbà tí èémí ìyè wọ inú ọkùnrin kìíní tí Ọlọ́run fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ, ó di ‘ẹ̀dá alààyè’ kan (J[ẹ́nẹ́sísì] 2:7). Wọ́n kò ka ikú sí yíya àwọn ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì tó para pọ̀ jẹ́ ènìyàn sọ́tọ̀, bí ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ṣe sọ; àmọ́ pé, èémí ìyè náà ló jáde, ènìyàn sì di ‘òkú ẹ̀dá’ kan (L[éfítíkù] 21.11; N[úmérì] 6.6; 19.13). Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ náà, ‘ẹ̀dá,’ jẹ́ ọ̀rọ̀ èdè Hébérù [neʹphesh], tí a sábà máa ń túmọ̀ sí ‘ọkàn’ ṣùgbọ́n tí ó dọ́gba ní gidi pẹ̀lú ẹni náà gan-an.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan náà sọ pé láìpẹ́ yìí, àwọn ọ̀mọ̀wé Kátólíìkì “ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Májẹ̀mú Tuntun kò kọ́ni pé ọkàn kò lè kú lọ́nà tí èrò àwọn Hélénì [Gíríìkì] gbà fi kọ́ni.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “A kò lè rí ojútùú pátápátá sí ìṣòro náà nínú ìméfò ìmọ̀ ọgbọ́n orí bí kò ṣe nínú ẹ̀bùn Àjíǹde tó kọjá agbára ènìyàn.”
Bíbélì Tàbí Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́?
Àmọ́, báwo ni àwọn èrò ti kò sí nínú Bíbélì ṣe wọnú ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì? Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló sọ pé Bíbélì ni àṣẹ tó ga jù fún àwọn. Bí àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí, Póòpù John Paul Kejì sọ pé ó yẹ kí “àwọn ọmọ ìjọ” tẹ́wọ́ gba Ìwé Mímọ́ “gẹ́gẹ́ bí ohun tó jẹ́ òtítọ́ látòkèdélẹ̀, tó sì jẹ́ àṣẹ gíga jù fún ìgbàgbọ́ wa.” Bí ó ti wù kí ó rí, a gbà ní gbogbo gbòò pé àwọn ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí kò bá ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dọ́gba rárá. Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ka àwọn Ìyípadà náà sí apá kan ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Ní àfikún sí i, Ìjọ Kátólíìkì gbà pé àṣẹ ọgbọọgba ni àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìwé Mímọ́ ní. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì “kò rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ kankan lórí ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ nìkan, láìka àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ sí, tàbí lórí ìpìlẹ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nìkan, láìka Ìwé Mímọ́ sí.”
Ìtàn fi hàn pé, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti fi àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbé karí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ rọ́pò àwọn tí a gbé karí Ìwé Mímọ́. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì lónìí ló gbà pé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kò tọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé ó “ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ kì í ṣe òtítọ́ nígbà tí a bá fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìtàn ti òde òní yiiri rẹ̀ wò.” Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì pé àwọn òkú kò mọ ohun kankan, ó fi kún un pé: “Kódà, nínú àwọn ọ̀ràn ìsìn pàápàá, Májẹ̀mú Láéláé jẹ́rìí sí i pé a kò ní ìmọ̀ kíkún nípa . . . ìyè lẹ́yìn ikú.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà tọ́ka sí Sáàmù 6:5 (ẹsẹ 6 nínú àwọn Bíbélì kan) bí àpẹẹrẹ èyí pé: “Kò sí mímẹ́nukàn ọ́ nínú ikú; nínú Ṣìọ́ọ̀lù, ta ni yóò gbé ọ lárugẹ?” Àwọn ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà àti kọ́lẹ́ẹ̀jì ti Pùròtẹ́sítáǹtì mélòó kan kò kọ́ni pé Bíbélì kò láṣìṣe mọ́. Nídà kejì, Ìjọ Kátólíìkì gbà pé òun ní àṣẹ ìkọ́ni, nípa èyí tí òun lè ṣètumọ̀ ohun tí Bíbélì ń kọ́ni. Àmọ́, o lè ṣe kàyéfì pé, ‘Bí ó bá wá jọ pé irú ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀ ta ko Ìwé Mímọ́ ńkọ́?’
Ìjẹ́pàtàkì Ìwé Mímọ́
Léraléra ni Jésù fa ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yọ bí àṣẹ, tí ó ń sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé,” kí ó tó máa sọ kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. (Mátíù 4:4, 7, 10; Lúùkù 19:46) Ní tòótọ́, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ipò tí ọkùnrin wà nínú ìgbéyàwó, kò fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú àbá ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, ṣùgbọ́n ó fà á yọ láti inú àkọsílẹ̀ tí ó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì nípa ìṣẹ̀dá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:24; Mátíù 19:3-9) Ó ṣe kedere pé Jésù ka Ìwé Mímọ́ sí ìwé tí Ọlọ́run mí sí, tó sì jẹ́ òtítọ́. Nígbà tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó wí pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17.b
Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ bí Jésù ṣe dá àwọn aṣáájú ìsìn lẹ́bi nígbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ fi ọgbọ́n féfé pa àṣẹ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín mú ṣinṣin. . . . Ẹ sì tipa báyìí sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.” (Máàkù 7:6-13) Bákan náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbéjà ko gbogbo ipá tó lè mú ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì tàbí àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọnú ohun tó ń kọ́ni. Ó kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra. Bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.” (Kólósè 2:8; 1 Kọ́ríńtì 1:22, 23; 2:1-13) Àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́ tàbí ẹ̀kọ́ kan wà, tí Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti dì mú ṣinṣin, àmọ́, a gbé ìwọ̀nyí karí Ìwé Mímọ́, wọ́n sì bá Ìwé Mímọ́ mu pátápátá. (2 Tẹsalóníkà 2:13-15) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní, . . . kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
Pọ́ọ̀lù rí i tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan yóò yapa sí Ìwé Mímọ́. Ó kìlọ̀ fún Tímótì pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, . . . wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́.” Ó rọ Tímótì pé: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo.” (2 Tímótì 4:3-5) Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan ni láti “ní ọkàn-rere.” Ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí sí “ìmúratán láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan, kí a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ láìṣègbè.” Lúùkù fi ọ̀rọ̀ yìí júwe àwọn olùgbọ́ Pọ́ọ̀lù ní Bèróà ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń kọ́ni ṣàjèjì sí wọn, wọn kò sì fẹ́ kí a ṣì àwọn lọ́nà. Nígbà tí Lúùkù ń yìn wọ́n, ó kọ̀wé pé: “Àwọn [ará Bèróà] ní ọkàn-rere ju àwọn ti Tẹsalóníkà lọ, nítorí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” Níní ọkàn-rere kò sọ àwọn ará Bèróà di oníyèméjì, tí kì í fẹ́ gba ohunkóhun gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwádìí olóòótọ́-inú tí wọ́n ṣe yọrí sí pé, “púpọ̀ nínú wọ́n di onígbàgbọ́.”—Ìṣe 17:11, 12.
Àwọn Àǹfààní Gbígbé Ayé ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbélì
A mọ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dáradára nítorí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé Bíbélì tí wọ́n sì ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ní “ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:5) Ìsìn Kristẹni òde òní tí kò bá bá ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mu kò lè ní agbára ìdarí rere lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn. Ǹjẹ́ èyí lè ṣàlàyé ìdí tí a fi ń rí ìwà ipá, ìwà pálapàla, ìdílé tí ń tú ká, àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tí ń pọ̀ sí i ní apá púpọ̀ jù nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù? Ní àwọn ilẹ̀ “Kristẹni” mélòó kan, àwọn ogun ẹ̀yà sí ẹ̀yà bíburújáì ń bá a lọ láàárín àwọn tó wà nínú ìsìn kan náà pàápàá.
Ṣé ẹ̀mí níní ọkàn rere ti àwọn ará Bèróà kò sí mọ́ ni? Ǹjẹ́ àwùjọ ènìyàn tó gba Bíbélì gbọ́, tó sì ń gbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì wà lónìí?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia Canadiana sọ pé: “Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìmúsọjí àti ìtúngbékalẹ̀ ìsìn Kristẹni ìjímìjí tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ní ọ̀rúndún kìíní àti èkejì nínú sànmánì tiwa.” Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ń sọ̀rọ̀ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí náà, ó wí pé: “Wọ́n ka Bíbélì sí orísun kan ṣoṣo tí wọ́n ní fún ìgbàgbọ́ àti ìlànà ìwà híhù wọn.”
Ó dájú pé èyí jẹ́ ìdí pàtàkì kan tí a fi mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń gbèrú, wọ́n ní àlàáfíà, wọ́n sì ní ayọ̀, lọ́nà tẹ̀mí. Nítorí náà, a rọ ẹ̀yin òǹkàwé wa pé kí ẹ kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tẹ̀mí gbígbámúṣé tí Bíbélì ń kọ́ni sí i. Ìmọ̀ púpọ̀ tilẹ̀ lè ṣamọ̀nà sí ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ sí i nínú Bíbélì àti ìgbàgbọ́ lílágbára sí i nínú Ọlọ́run. Àwọn àǹfààní ayérayé tí irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú wá mú kí ó yẹ láti sapá lórí rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a National Public Radio—“Morning Edition”
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí bí Bíbélì ṣe ṣeé gbára lé, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn mìíràn wàásù ní ọjà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “ka Bíbélì sí orísun kan ṣoṣo tí wọ́n ní fún ìgbàgbọ́ àti ìlànà ìwà híhù wọn”