Ìyípadà Tó Dé Bá “Ẹ̀sìn Kristẹni”—Ṣé Inú Ọlọ́run Dùn sí I?
KÁ NÍ o gbé iṣẹ́ fún ayàwòrán kan láti yàwòrán ara rẹ. Nígbà tó parí iṣẹ́ náà, inú rẹ dùn gan-an ni; ó ti lọ wà jù, bóo ṣe rí gẹ́lẹ́ làwòrán náà gbé jáde. O wá ronú nípa bí àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, àti àwọn ọmọ-ọmọ tiwọn yóò ṣe máa wo àwòrán náà pẹ̀lú ìwúrí ńláǹlà.
Àmọ́, ó wá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ìran ti kọjá lọ, ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ wá rí i pé irun hérehère tí wọ́n yà sínú àwòrán náà kò tẹ́ òun lọ́rùn, ló bá firun díẹ̀ kún un. Imú tí wọ́n yà síbẹ̀ ò wu ọmọ mìíràn, ló bá yí imú náà padà. Bí ìran kán ṣe ń lọ tí òmíràn ń dé ni “àwọn àtúnṣe” mìíràn ń yọjú, tó fi di pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwòrán náà ò wá jọ ẹ́ mọ́. Ká lóo lọ mọ̀ pé bọ́ràn ṣe máa rí nígbẹ̀yìngbẹ́yín nìyí, ṣe inú ẹ á dùn? Ó dájú pé inú rẹ kò ní dùn.
Ó bani nínú jẹ́ pé bí ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni aláfẹnujẹ́ ṣe rí gẹ́lẹ́ ni àwòrán yìí fi hàn. Ìtàn fi hàn pé kété lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì Kristi kú tán ni “ẹ̀sìn Kristẹni” ti bẹ̀rẹ̀ sí í padà kúrò ní bó ṣe rí ní ti gidi, èyí sì ṣẹlẹ̀ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀.—Mátíù 13:24-30, 37-43; Ìṣe 20:30.a
Àmọ́, ó tọ́ láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú onírúurú àṣà ìbílẹ̀ àti ní onírúurú sànmánì. Ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí yíyí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì padà kó lè bá ohun tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ ènìyàn mu. Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Fún àpẹẹrẹ, gbé àwọn ìyípadà tí wọ́n ti ṣe láwọn àgbègbè pàtàkì bíi mélòó kan yẹ̀ wò.
Ṣọ́ọ̀ṣì Ń Bá Ìjọba Ṣe Wọléwọ̀de
Jésù kọ́ni pé ìṣàkóso òun tàbí Ìjọba òun jẹ́ ti òkè ọ̀run, tí yóò pa gbogbo ìṣàkóso ènìyàn run, tí yóò sì ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé láìpẹ́. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Kò ní ṣàkóso nípasẹ̀ ètò òṣèlú ẹ̀dá ènìyàn. Jésù sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 17:16; 18:36) Ìdí nìyẹn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò fi bá wọn lọ́wọ́ sí òṣèlú, àmọ́ wọ́n ń pa òfin mọ́ o.
Àmọ́ ṣá, ní àkókò Olú Ọba Róòmù nì, Kọnsitantín ní ọ̀rúndún kẹrin, ojú bẹ̀rẹ̀ sí í kán ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn tí wọn ò sì lè dúró de ìpadàbọ̀ Kristi àti ìgbékalẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run mọ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìṣarasíhùwà wọn sí ìṣèlú yí padà. Ìwé Europe—A History, sọ pé: “Ṣáájú àkókò Kọnsitantín, àwọn Kristẹni ò bá wọn du ipò [òṣèlú] gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtimú kí ète àti ìgbàgbọ́ wọn gbilẹ̀ sí i. Lẹ́yìn Kọnsitantín ni ẹ̀sìn Kristẹni àti ìṣèlú gidi wá di èyí tó wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” Ẹ̀sìn Kristẹni tó yí padà yìí ló wá di “ti gbogbo gbòò,” tàbí “kátólíìkì,” tí í ṣe ẹ̀sìn tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù fàṣẹ sí.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Great Ages of Man sọ pé nítorí àjọṣe yìí tó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba, “nígbà tó fi máa di ọdún 385 Sànmánì Tiwa, ìyẹn ọgọ́rin ọdún péré lẹ́yìn inúnibíni líle koko tí wọ́n ṣe sí àwọn Kristẹni kẹ́yìn, ṣọ́ọ̀ṣì fúnra rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí i pa àwọn aládàámọ̀, àlùfáà rẹ̀ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí lo agbára tó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ti olú ọba dọ́gba.” Èyí ló bẹ̀rẹ̀ sànmánì kan tí idà ti wá rọ́pò ìyíniléròpadà tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ rí láti fi múni wọnú ẹ̀sìn, tí ẹgbẹ́ àlùfáà tí ń lẹ orúkọ oyè kàǹkàkàǹkà mọ́rí, tí agbára sì ń gùn wá dípò àwọn oníwàásù tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. (Mátíù 23:9, 10; 28:19, 20) Òpìtàn H. G. Wells kọ̀wé nípa “ìyàtọ̀ jàn-àn-ràn jan-an-ran tó wà láàárín” ẹ̀sìn Kristẹni ọ̀rúndún kẹrin “àti ẹ̀kọ́ Jésù ti Násárétì.” Àwọn “ìyàtọ̀ jàn-àn-ràn jan-an-ran” wọ̀nyí tún nípa lórí àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ táwọn èèyàn kọ́ nípa Ọlọ́run àti Kristi.
Yíyí Ọlọ́run Padà
Kristi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọ́ni pé “Ọlọ́run kan” ní ń bẹ, “Baba,” tí a fi orúkọ tiẹ̀ fúnra rẹ̀, Jèhófà, mọ̀ yàtọ̀, èyí tó fara hàn ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì ti ìjímìjí. (1 Kọ́ríńtì 8:6; Sáàmù 83:18) Bíbélì Douay Version ti Kátólíìkì sọ nínú Kólósè 1:15 pé, Ọlọ́run ló dá Jésù; òun sì ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” Nítorí èyí, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí a dá, Jésù fúnra rẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.”—Jòhánù 14:28.
Àmọ́, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹta, àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà kan tí wọ́n jẹ́ abẹnugan láwùjọ, wá gba ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan ti Plato, ìyẹn kèfèrí onímọ̀ ọgbọ́n orí ti Gíríìkì nì, bí ẹní gba igbá ọtí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yí Ọlọ́run padà kó lè bá ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan mu. Ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, ẹ̀kọ́ yìí ti wá gbé Jésù ga gan-an débí tó ti bá Jèhófà dọ́gba, ó sì tún sọ ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run di ẹni gidi kan, gbogbo èyí ló sì lòdì sí Ìwé Mímọ́.
Nítorí bí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe tẹ́wọ́ gba Mẹ́talọ́kan tó jẹ́ ẹ̀kọ́ Kèfèrí yìí, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Èròǹgbà tí wọ́n pè ní ‘Ọlọ́run kan nínú Ẹni mẹ́ta’ kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, dájúdájú a kò gbà á wọlé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ sínú ìgbésí ayé Kristẹni àti ìgbàgbọ́ Kristẹni ṣáájú òpin ọ̀rúndún kẹrin. Àmọ́, èròǹgbà wọn yìí gan-an ló kọ́kọ́ gba orúkọ náà ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Láàárín àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì, kò sí ohunkóhun, àní títí kan ohun tí ó kéré jù lọ pàápàá tí ó sún mọ́ irú ọ̀nà ìgbàronú bẹ́ẹ̀ tàbí irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀.”
Bákan náà ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ti ọ̀rúndún kẹrin kò gbé ẹ̀kọ́ Kristẹni ti ìjímìjí nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ yọ lọ́nà tó péye rárá; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yà bàrá kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yìí.” Ìwé The Oxford Companion to the Bible pe Mẹ́talọ́kan jẹ́ ọ̀kan lára “àwọn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n gbé kalẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe Mẹ́talọ́kan nìkan ní èròǹgbà kèfèrí tí wọ́n gbà wọlé sínú ṣọ́ọ̀ṣì.
Wọ́n Pa Ọkàn Dà
Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lónìí ni pé àwọn èèyàn ní ọkàn kan tí kò lè kú tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá ti kú. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé àfikún tí wọ́n ṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn lẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yìí? Jésù tẹ òtítọ́ Bíbélì náà mọ́ni lọ́kàn pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá,” pé wọ́n ń sùn ni, lọ́nà àpèjúwe. (Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11-13) Àjíǹde—‘dídìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i’ kúrò nínú oorun ikú—ni yóò tún padà mú wọn wà láàyè. (Jòhánù 5:28, 29) Bí ọkàn kan tí kò lè kú bá wà, a jẹ́ pé kò ní nílò àjíǹde nìyẹn, níwọ̀n bí àìleèkú ti fagi lé ikú.
Jésù tiẹ̀ fi ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde hàn nípa jíjí àwọn ènìyàn kan kúrò nínú ikú. Gbé àpẹẹrẹ Lásárù yẹ̀ wò, ẹni tí ó kú fún ọjọ́ mẹ́rin gbáko. Nígbà tí Jésù jí i dìde, Lásárù jáde wá láti inú ibojì láàyè ó sì ń mí. Kò sí ọkàn kan tí kò lè kú tó padà wá látinú ìgbádùn kẹlẹlẹ ní ọ̀run, tó sì padà sínú ara Lásárù nígbà tó jí kúrò nínú ikú. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí ni, a jẹ́ pé Jésù ò ṣe é lóore kankan nípa jíjí i dìde nìyẹn!—Jòhánù 11:39, 43, 44.
Ibo ni ọ̀rọ̀ nípa àìleèkú ọkàn ti wá jẹ jáde? Ìwé atúmọ̀ èdè The Westminster Dictionary of Christian Theology sọ pé èròǹgbà yẹn “bá ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì mu ju ohun tí Bíbélì ṣí payá lọ.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Ìgbàgbọ́ náà pé ọkàn ń bá a lọ láti máa wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú jẹ́ ìméfò ìmọ̀ ọgbọ́n orí tàbí ti ẹ̀kọ́ ìsìn dípò kí ó jẹ́ ti ìgbàgbọ́ tòótọ́, ìdí sì nìyẹn tí kò fi sí ibì kankan tí a ti fi kọ́ni ní kedere nínú Ìwé Mímọ́.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, orí irọ́ kan ni wọ́n tí máa ń bọ́ sórí òmíràn, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn nìyẹn. Òun ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìgbàgbọ́ kèfèrí nípa ìdálóró ayérayé nínú hẹ́ẹ̀lì oníná.b Àmọ́ Bíbélì sọ ọ́ ní kedere pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú”—kì í ṣe ìdálóró ayérayé. (Róòmù 6:23) Ìdí nìyẹn tí King James Version fi sọ báyìí nípa àjíǹde pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀; ikú àti hẹ́ẹ̀lì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn.” Bákan náà, Bíbélì ti Douay sọ pé, “òkun . . . àti ikú àti hẹ́ẹ̀lì jọ̀wọ́ òkú wọn.” Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn tó wà nínú hẹ́ẹ̀lì ti kú, ńṣe ni ‘wọ́n ń sùn,’ bí Jésù ṣe sọ.—Ìṣípayá 20:13.
Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ ní ti tòótọ́ pé ẹ̀kọ́ ìdánilẹ́bi ayérayé nínú hẹ́ẹ̀lì ń fa àwọn ènìyàn sún mọ́ Ọlọ́run? Rárá o. Èrò kan tó ń léni sá ló jẹ́ lọ́kàn àwọn olódodo ènìyàn àti àwọn tó nífẹ̀ẹ́! Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, Bíbélì kọ́ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” àti pé ó kórìíra híhu ìwà òǹrorò sí ẹranko pàápàá.—1 Jòhánù 4:8; Òwe 12:10; Jeremáyà 7:31; Jónà 4:11.
Bíba “Àwòrán” Náà Jẹ́ Lóde Òní
Bíba àwòrán Ọlọ́run àti ti ìsìn Kristẹni jẹ́ ṣì ń bá a lọ lóde òní. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan lórí ọ̀rọ̀ ìsìn ṣàpèjúwe ìjàkadì tó ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì rẹ̀ bí ìjà tí wọ́n ń jà “lórí ọlá àṣẹ Ìwé Mímọ́ àti ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ ní ìdojúùjà kọ ọlá àṣẹ àwọn èròǹgbà tó ṣàjèjì táwọn ènìyàn gbé kalẹ̀, láàárín àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ipò olúwa ti Kristi ní ìdojúùjà kọ àwọn tó fara mọ́ ìyípadà tí wọ́n ṣe sí ìsìn Kristẹni kó lè bá àkókò mú. Àríyànjiyàn tó wà nílẹ̀ báyìí ni pé: Ta ló ń tọ́ ṣọ́ọ̀ṣì náà sọ́nà . . . Ṣé Ìwé Mímọ́ ni tàbí èròǹgbà tí gbogbo gbòò fọwọ́ sí lákòókò yìí?”
Ó bani nínú jẹ́ pé “èròǹgbà tí gbogbo gbòò fọwọ́ sí lákòókò yìí” ló ṣì ń borí. Fún àpẹẹrẹ, kì í ṣe nǹkan àṣírí mọ́ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló ti yí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa onírúurú ọ̀ràn padà kí wọ́n lè fara hàn bí ẹni tó ń tẹ̀ síwájú tàbí ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan. Àgàgà nínú ọ̀ràn ìwà rere, ṣọ́ọ̀ṣì ti wá ń gbọ̀jẹ̀gẹ́ báyìí, bí a tí mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Àmọ́, Bíbélì là á mọ́lẹ̀ kedere pé àgbèrè, panṣágà, àti ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lójú Ọlọ́run, àti pé àwọn tó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Mátíù 5:27-32; Róòmù 1:26, 27.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ táa fà yọ lókè yìí, gbogbo ìwà ìbàjẹ́ tó wà láyé pátá ni àwọn Gíríìkì àti àwọn ará Róòmù tó yí i ká nígbà yẹn fi ń ṣèwà hù. Pọ́ọ̀lù ì bá ti ronú pé: ‘Òótọ́ ni pé Ọlọ́run sọ Sódómù òun Gòmórà di eérú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ tó burú jáì, àmọ́ ẹgbàá ọdún sẹ́yìn nìyẹn ṣá o! Ó dájú pé ìyẹn ò gbéṣẹ́ mọ́ lákòókò tójú ti là yìí.’ Síbẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí; ó kọ̀ láti ba òtítọ́ Bíbélì jẹ́.—Gálátíà 5:19-23.
Wo Ojúlówó “Àwòrán” Náà
Nígbà tí Jésù ń bá àwọn aṣáájú ìsìn Júù ìgbà ayé rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní ìjọsìn wọn ‘jẹ́ asán nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.’ (Mátíù 15:9) Ohun kan náà tí àwọn àlùfáà yẹn ṣe sí Òfin Jèhófà, tó tipasẹ̀ Mósè fún wọn, ni àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe sí ẹ̀kọ́ Kristi, tí wọn ò sì tíì jáwọ́ nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀—wọ́n fi “ọ̀dà” àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ bo òtítọ́ àtọ̀runwá mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù ṣí gbogbo èké wọ̀nyẹn kúrò fún àǹfààní àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìlábòsí-ọkàn. (Máàkù 7:7-13) Jésù sọ òtítọ́, yálà àwọn ènìyàn tẹ́wọ́ gbà á tàbí wọ́n kọ̀ ọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló máa ń fi ṣe ọlá àṣẹ rẹ̀ nígbà gbogbo.—Jòhánù 17:17.
Ẹ wo bí Jésù ṣe yàtọ̀ pátápátá sí àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́! Àní Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò máa yán hànhàn fún ohun tuntun, wọ́n ó sì kó . . . olùkọ́ jọ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn tiwọn; lẹ́yìn náà, kàkà kí wọ́n fetí sí òtítọ́, wọn óò yíjú sí ìtàn àròsọ.” (2 Tímótì 4:3, 4, The Jerusalem Bible) Àwọn “ìtàn àròsọ” wọ̀nyí, tí a ti gbé díẹ̀ lára wọn yẹ̀ wò, máa ń ba ipò tẹ̀mí jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ńṣe ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń gbéni ró, ó sì ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Òtítọ́ yìí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà ọ́ níyànjú láti gbé yẹ̀ wò.—Jòhánù 4:24; 8:32; 17:3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fi hàn nínú òwe àlìkámà àti èpò àti nínú àpèjúwe ọ̀nà gbígbòòrò àti ọ̀nà híhá (Mátíù 7:13, 14), bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ni yóò máa ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ láti àwọn sànmánì wọ̀nyí wá. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀pọ̀ jù lọ tó dà bí èpò, tí wọn ó máa gbé ara wọn àti àwọn ẹ̀kọ́ tiwọn lárugẹ bí ẹni pé tiwọn ni ojúlówó ẹ̀sìn Kristẹni, yóò máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Àdàmọ̀dì yìí gan-an ni àpilẹ̀kọ wa ń tọ́ka sí.
b “Hẹ́ẹ̀lì” ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà Ṣìọ́ọ̀lù àti ti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Hédíìsì, tí àwọn méjèèjì wulẹ̀ túmọ̀ sí “sàréè.” Nípa bẹ́ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣètumọ̀ Bíbélì King James Version ní èdè Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ Ṣìọ́ọ̀lù sí “hell” [hẹ́ẹ̀lì] nígbà mọ́kànlélọ́gbọ̀n, wọ́n tún tú u sí “grave” [sàréè] nígbà mọ́kànlélọ́gbọ̀n, wọ́n sì tú u sí “pit” [ihò] nígbà mẹ́ta, tó ń fi hàn pé ohun kan náà ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ibi Tí Orúkọ Náà, Kristẹni, Ti Wá
Ó kéré tán, fún ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ikú Jésù, ohun tí wọ́n mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí ni àwọn tí ó jẹ́ ti “Ọ̀nà Náà.” (Ìṣe 9:2; 19:9, 23; 22:4) Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n gbé ọ̀nà ìgbésí ayé wọn ka ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ẹni tí ó jẹ́ “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” (Jòhánù 14:6) Nígbà tó yá, ní sáà kan lẹ́yìn ọdún 44 Sànmánì Tiwa, ní ìlú Áńtíókù ti Síríà, wọ́n “tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá” pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù “ní Kristẹni.” (Ìṣe 11:26) Kíá ni wọn mọ orúkọ yìí bí ẹní mowó, kódà láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba pàápàá. (Ìṣe 26:28) Orúkọ tuntun yìí kò yí ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni padà, èyí tó ń bá a lọ láti máa tẹ̀ lé àwòkọ́ṣe Kristi.—1 Pétérù 2:21.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba tí wọ́n ń ṣe darí àwọn ènìyàn sínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìkẹ́ta láti apá òsì: Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè/Fọ́tò láti ọwọ́ Saw Lwin