ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 12/1 ojú ìwé 9-14
  • Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nígbà Tí Àwọn Ẹlòmíràn Bá Já Wa Kulẹ̀
  • Nígbà Tí Ó Bá Kù Díẹ̀ Káà Tó
  • Nígbà Tí A Bá Nímọ̀lára Àìṣetó
  • Nígbà Tí A Bá Ń Béèrè Púpọ̀ Sí i Lọ́wọ́ Wa
  • Nítorí Òpin Kò Tí ì Dé
  • Jehofa Ń fún Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú Lágbára
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ọjọ́ Iwájú Ni Kó O Tẹjú Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Mò Ń Dá Ara Mi Lẹ́bi​—Ṣé Bíbélì Lè Mú Kára Tù Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Ohun Tó Burú Ni Kí Ẹ̀rí Ọkàn Máa Dá Èyàn Lẹ́bi?
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 12/1 ojú ìwé 9-14

Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!

“Ẹ máṣe jẹ́ kí a juwọ́sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nitori ní àsìkò yíyẹ awa yoo kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—GALATIA 6:9.

1, 2. (a) Ní àwọn ọ̀nà wo ni kìnnìún gbà ń ṣọdẹ? (b) Àwọn wo ni Èṣù lọ́kàn ìfẹ́ ní pàtàkì láti fi ṣẹran ọdẹ?

ONÍRÚURÚ ọ̀nà ni kìnnìún gbà ń dọdẹ. Nígbà míràn, yóò ba de ẹran ọdẹ rẹ̀ níbi kòtò olómi, tàbí lẹ́bàá ipa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà déédéé. Ṣùgbọ́n, nígbà mìíràn, ìwé náà, Portraits in the Wild, sọ pé, kìnnìún kan, “wulẹ̀ máa ń lo àǹfààní ipò kan—fún àpẹẹrẹ, bíbá ọ̀dọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà kan níbi tí ó ń sùn.”

2 Aposteli Peteru ṣàlàyé pé, “elénìní” wa, “Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.” (1 Peteru 5:8) Ní mímọ̀ pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù fún òún kúrú, Satani ń tiraka láti mú ẹ̀dá ènìyàn wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ ńláǹlà ju ti ìgbàkígbà rí lọ, kí ó lè dí wọn lọ́wọ́ ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. Ṣùgbọ́n, ní pàtàkì, “kìnnìún tí ń ké ramúramù” yìí lọ́kàn-ìfẹ́ nínú fífi àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ṣẹran ọdẹ. (Ìṣípayá 12:12, 17) Ọ̀nà ìṣọdẹ rẹ̀ jọra pẹ̀lú ti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láwùjọ àwọn ẹranko. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀?

3, 4. (a) Àwọn ọgbọ́n wo ni Satani ń lò láti fi àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ṣẹran ọdẹ? (b) Nítorí “awọn àkókò lílekoko láti bálò” nìyí, àwọn ìbéèrè wo ni a gbé dìde?

3 Nígbà míràn, Satani ń gẹ̀gùn—nípa ṣíṣe inúnibíni tàbí àtakò tí ó ní ète bíba ìwà títọ́ wa jẹ́, kí a baà lè jáwọ́ nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. (2 Timoteu 3:12) Ṣùgbọ́n, bíi kìnnìún, nígbà mìíràn, Èṣù wulẹ̀ ń lo àǹfààní ipò kan ni. Yóò dúró títí a óò fi rẹ̀wẹ̀sì, tàbí tí àárẹ̀ yóò fi mú wa, yóò sì wá gbìyànjú láti lo àǹfààní ipò ìsoríkọ́ wa, láti lè mú kí a juwọ́ sílẹ̀. A kò gbọdọ̀ di ẹran ọdẹ tí ó rọrùn láti mú!

4 Síbẹ̀, a ń gbé ní sáà tí ó nira jù lọ nínú gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ní “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ nínú wa lè rẹ̀wẹ̀sì tàbí sorí kọ́ nígbà míràn. (2 Timoteu 3:1) Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè yẹra fún ṣíṣàárẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fi di ẹran ọdẹ tí ó rọrùn fún Èṣù láti mú? Àní, báwo ni a ṣe lè kọbi ara sí ìmọ̀ràn onímìísí tí Paulu pèsè pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a juwọ́sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nitori ní àsìkò yíyẹ awa yoo kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀”?—Galatia 6:9.

Nígbà Tí Àwọn Ẹlòmíràn Bá Já Wa Kulẹ̀

5. Kí ni ó mú kí Dafidi káàárẹ̀, ṣùgbọ́n kí ni kò ṣe?

5 Ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ jù lọ pàápàá ti lè sorí kọ́ nígbà míràn. Onipsalmu náà, Dafidi, kọ̀wé pé: “Agara ìkérora mi dá mi: ní òru gbogbo ni èmi ń mú ẹní mi fó lójú omi; èmi fi omijé mi rin ibùsùn mi. Ojú mi bàjẹ́ tán nítorí ìbìnújẹ́.” Èé ṣe tí Dafidi, fi nímọ̀lára lọ́nà yẹn? Ó ṣàlàyé pé: “Nítorí gbogbo àwọn ọ̀tá mi.” Ìgbésẹ̀ àwọn mìíràn tí ó dùn ún dénú, fa irú ìrora ọkàn-àyà bẹ́ẹ̀ fún Dafidi, tó bẹ́ẹ̀ tí omijé fi ń dà wàràwàrà lójú rẹ̀. Síbẹ̀, Dafidi kò yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa, nítorí ohun tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti ṣe sí i.—Orin Dafidi 6:6-9.

6. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe àwọn ẹlòmíràn ṣe lè nípa lórí wa? (b) Báwo ni àwọn kan ṣe ń sọ ara wọn di ẹran ọdẹ tí ó rọrùn fún Èṣù?

6 Bákan náà, àwọn ọ̀rọ̀ àti ìgbésẹ̀ àwọn ẹlòmíràn lè mú kí a sorí kọ́ pẹ̀lú ìrora ọkàn-àyà púpọ̀. Owe 12:18 (NW) sọ pé: “Àwọn kan ń bẹ tí ń sọ̀rọ̀ láìgbatẹnirò bí ìgúnni idà.” Nígbà tí aláìgbatẹnirò náà bá jẹ́ Kristian arákùnrin tàbí arábìnrin, ‘ọgbẹ́ idà’ náà lè jinlẹ̀. Ìtẹ̀sí ẹ̀dá ènìyàn lè jẹ́ láti bínú, bóyá láti di kùnrùngbùn sínú. Èyí jẹ́ òtítọ́, ní pàtàkì, bí a bá rò pé a ti bá wa lò lọ́nà ìkà tàbí lọ́nà àìtọ́. A lè rí i pé ó nira láti bá ẹni tí ó ṣẹ̀ wá sọ̀rọ̀; a tilẹ̀ lè mọ̀ọ́mọ̀ máa yẹra fún un. Nítorí kùnrùngbùn tí ó ti mú wọn sorí kọ́, àwọn kan ti juwọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ti dẹ́kun wíwá sí àwọn ìpàdé Kristian. Ó bani nínú jẹ́ pé, wọ́n tipa báyìí “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù” láti kápá wọn gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ tí ó rọrùn.—Efesu 4:27.

7. (a) Báwo ni a ṣe lè yẹra fún fífún ètekéte Èṣù lókun, nígbà tí àwọn mìíràn bá já wa kulẹ̀ tàbí mú wa bínú? (b) Èé ṣe ti a kò fi ní láti fàyè gba kùnrùngbùn?

7 Báwo ni a ṣe lè yẹra fún fífún ètekéte Èṣù lókun nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá já wa kulẹ̀ tàbí mú wa bínú? A gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti má ṣe di kùnrùngbùn sínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, lo àtinúdá láti wá àlàáfíà tàbí yanjú ọ̀ràn bí ó bá ti lè tètè yá tó. (Efesu 4:26) Kolosse 3:13 rọ̀ wá pé: “Ẹ máa bá a lọ ní . . . [dí]dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nìkínní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” Ìdáríjì yẹ, ní pàtàkì, nígbà tí ẹni tí ó ṣẹni bá ti gba àṣìṣe rẹ̀, tí ó sì tọrọ àforíjì látọkànwá. (Fi wé Orin Dafidi 32:3-5 àti Owe 28:13.) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ń ràn wá lọ́wọ́, bí a bá fi í sọ́kàn pé, dídárí jì kò túmọ̀ sí fífàyè gba ìwà àìtọ́ àwọn ẹlòmíràn tàbí fífojú kéré rẹ̀. Dídárí jì kan jíjáwọ́ nínú dídi kùnrùngbùn. Kùnrùngbùn jẹ́ ẹrù tí ó ṣòro láti gbé. Ó lè gba ìrònú wa, kí ó sì já ayọ̀ wa gbà. Ó tilẹ̀ lè nípa lórí ìlera wa. Ní òdì kejì, ìdáríjì, nígbà tí ó bá tọ́, ń ṣiṣẹ́ fún ire wa. Gẹ́gẹ́ bíi Dafidi, ǹjẹ́ kí a má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé, kí a má sì ṣe fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Jehofa, nítorí ohun tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn míràn sọ tàbí ṣe sí wa!

Nígbà Tí Ó Bá Kù Díẹ̀ Káà Tó

8. (a) Èé ṣe tí àwọn kan fi máa ń nímọ̀lára ẹ̀bi ní pàtàkì nígbà míràn? (b) Ewu wo ni ó wà nínú jíjẹ́ kí ẹ̀bi wọ̀ wa lára débi pé a juwọ́ sílẹ̀?

8 Jakọbu 3:2 sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà.” Nígbà tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti nímọ̀lára ẹ̀bi. (Orin Dafidi 38:3-8) Ìmọ̀lára ẹ̀bi, lè lágbára, ní pàtàkì, bí a bá ń bá àìlera ti ẹran ara jìjàkadì, tí a sì ń nírìírí ìfàsẹ́yìn láti ìgbà dégbà.a Kristian kan tí ó dojú kọ irú ìjàkadì bẹ́ẹ̀ ṣàlàyé pé: “Mo fẹ́ láti kú, nítorí n kò mọ̀ bóyá mo ti dẹ́ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Mo rò pé, mo lè má làkàkà nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa mọ́, nítorí, bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe kí ó máà sí ìrètí kankan fún mi mọ́.” Nígbà tí ẹ̀bi bá ti wọ̀ wá lára tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ju ara wa sílẹ̀, a ń fún Èṣù láyè—ó sì lè tètè lo àǹfààní náà! (2 Korinti 2:5-7, 11) Ó lè jẹ́ pé ohun tí a nílò ni ojú ìwòye tí ó túbọ̀ wà déédéé nípa ẹ̀bi.

9. Èé ṣe ti a fi ní láti ní ìgbọ́kànlé nínú àánú Ọlọrun?

9 Bí a bá dẹ́ṣẹ̀, ó tọ́ láti nímọ̀lára ẹ̀bi dé ìwọ̀n àyè kan. Ṣùgbọ́n, nígbà míràn, ìmọ̀lára ẹ̀bi máa ń bá a nìṣó nítorí pé Kristian kan rò pé òun kò lè jẹ́ ẹni yíyẹ mọ́, láti rí àánú Ọlọrun gbà. Síbẹ̀, Bibeli fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Bí a bá jẹ́wọ́ awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, oun jẹ́ aṣeégbíyèlé ati olódodo tí yoo fi dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá tí yoo sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò ninu gbogbo àìṣòdodo.” (1 Johannu 1:9) Ìdí yíyè kooro kankan ha wà láti gbà gbọ́ pé, Ọlọrun kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ fún wa bí? Rántí pé, nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jehofa sọ pé, òún “múra àti dárí jì.” (Orin Dafidi 86:5; 130:3, 4) Níwọ̀n bí kò ti lè purọ́, òun yóò ṣe bí ó ti ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kìkì bí a bá tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú ọkàn-àyà onírònúpìwàdà.—Titu 1:2.

10. Ìdánilójú amọ́kànyọ̀ wo ni a tẹ̀ jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà ní ìgbà kan sẹ́yìn, nípa bíbá àìlera ẹran ara jìjàkadì?

10 Kí ni o ní láti ṣe, bí o bá ń bá àìlera kan jìjàkadì, tí ó sì tún ń padà wá? Má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Pípadà tí ó tún ń padà wá, kò fi dandan fagi lé ìtẹ̀síwájú tí o ti ní. Ẹ̀dà ìwé àtìgbàdégbà yìí, ti November 1954, fúnni ní ìdánilójú amọ́kànyọ̀ yìí pé: “A [lè] ri ti a nkọsẹ ti a si nṣubu nigbakugba lori iwa ibajẹ ti o ti gbadun mọ wa lara ninu igbesi aiye wa atijọ ti o si sọ wa di alaimọra. . . . Maṣe ro ara rẹ pin pe iwọ ti daràn ti ko ṣe fori rẹ̀ jinni. Bi Satani ti fẹ ko jọ loju rẹ leyi. Niwọnbi o ti banujẹ ti o si dun ọ denu, eyiyi fihan daju wipe o kò tii lọ jinna ju. Iwọ ko gbọdọ jẹ ki o su ọ lati fi irẹlẹ yipada si ọdọ Ọlọrun, pẹlu itara ki o si wa aforiji ati iwẹnumọ lati ọdọ Ọlọrun pẹlu iranlọwọ lati ọdọ rẹ̀. Lọ sọdọ rẹ̀ gẹgẹbi ọmọ ti tọ baba rẹ̀ lọ nigbati o ba wa ninu iyọnu ti ko si su bi o ti wu ki o jẹ igbagbogbo to biotilẹjẹpe lori ailera kanna ni. Jehofa yoo ṣe iyọnu si ọ ninu ọpọ irọnu anu rẹ̀, bi iwọ ba si fi otitọ inu ṣe eyi yio jẹki o ri mọ daju wipe a ti wẹ ọ mọ nipa ẹri-ọkan rere.”

Nígbà Tí A Bá Nímọ̀lára Àìṣetó

11. (a) Irú ìmọ̀lára wo ni ó yẹ kí a ní nípa nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà? (b) Ìmọ̀lára wo, nípa nínípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni àwọn Kristian kan ń bá jìjàkadì?

11 Iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé Kristian, nínípìn-ín nínú rẹ̀ sì máa ń mú ayọ̀ wá. (Orin Dafidi 40:8) Ṣùgbọ́n, àwọn Kristian kan máa ń nímọ̀lára ẹ̀bi gan-an nípa ṣíṣàìlè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Irú ẹ̀bi bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ lè ba ayọ̀ wa jẹ́, kí ó sì mú wa juwọ́ sílẹ̀, ní ríronú pé Jehofa lérò pé a kò ṣe tó. Gbé ìmọ̀lára tí àwọn kan ń bá jìjàkadì yẹ̀ wò.

Kristian arábìnrin kan tí òun àti ọkọ rẹ̀ ń tọ́ ọmọ mẹ́ta kọ̀wé pé: “Ìwọ ha mọ bí ìṣẹ́ ṣe ń gba àkókò tó bí? Mo ní láti ṣọ́wó ná bí mo bá ti lè ṣe tó. Èyí túmọ̀ sí lílo àkókò láti máa wá ìsọ̀ bọ́síkọ̀rọ̀ àti ọjà gbàǹjo kiri, tàbí kí n tilẹ̀ máa fúnra mi rán aṣọ pàápàá. Mo tún máa ń lo wákàtí kan tàbí méjì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní wíwá ìpolówó [ẹ̀dínwó oúnjẹ] kiri nínú ìwè ìròyìn—ní gígé wọn, títò wọ́n, àti ṣíṣe pàṣípààrọ̀ wọ́n. Nígbà míràn, mo máa ń nímọ̀lára pé mo jẹ̀bi gan-an fún ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ní ríronú pé inú iṣẹ́ ìsìn pápá ni ó ti yẹ kí n lo àwọn àkókò náà.”

Arábìnrin kan tí ó ní ọmọ mẹ́rin àti ọkọ aláìgbàgbọ́, ṣàlàyé pé: “Mo lérò pé ìfẹ́ tí mo ní sí Jehofa kò pọ̀ tó. Nítorí náà, mo jìjàkadì láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa. Mo gbìyànjú gidigidi, ṣùgbọ́n lójú mi, kò fìgbà kankan tó rí. Ṣé o rí i, n kò ní ìmọ̀lára pé mo já mọ́ nǹkankan, nítorí náà, n kò lè ronú bí Jehofa ṣe lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn mi sí i.”

Kristian kan tí ó pọn dandan fún láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀ sọ pé: “Ara mi kò gbà á pé mo ń kùnà nínú ìpinnu mi láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa ní àkókò kíkún. Ìwọ kò lè mọ bí ìjákulẹ̀ mi ti pọ̀ tó! Mo máa ń sunkún nísinsìnyí nígbà tí mo bá rántí.”

12. Èé ṣe ti àwọn Kristian kan fi ń nímọ̀lára pé àwọn jẹ̀bi gan-an nípa pé àwọn kò lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?

12 Ó jẹ́ ìwà àdánidá láti fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn Jehofa bí ó bá ti ṣeé ṣe tó. (Orin Dafidi 86:12) Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí àwọn kan fi ń nímọ̀lára ẹ̀bi pé àwọn kò lè ṣe púpọ̀ sí i? Ní ti àwọn kan, ó dà bíi pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkankan rárá, bóyá tí ó jẹ́ àbájáde ìrírí àìbáradé nínú ìgbésí ayé. Ní ti àwọn mìíràn, ẹ̀bi tí kò yẹ lè jẹ́ àbájáde níní ojú ìwòye tí kò ṣe déédéé nípa ohun tí Jehofa ń retí láti ọ̀dọ̀ wa. Kristian arábìnrin kan jẹ́wọ́ pé: “Mo ti máa ń lérò pé, bí o kò bá ṣiṣẹ́ débi tí ẹ̀mí rẹ yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́, o kò tí ì ṣe tó.” Nítorí èyí, ó fi àwọn góńgó tí ó ga ré kọjá àlà síwájú ara rẹ̀—ó sì nímọ̀lára ẹ̀bi tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tí kò bá lè lé góńgó náà bá.

13. Kí ni Jehofa ń retí láti ọ̀dọ̀ wa?

13 Kí ni Jehofa ń retí láti ọ̀dọ̀ wa? Ní ṣókí, Jehofa ń retí pé ki a ṣiṣẹ́ sin òun tọkàntọkàn, ní ṣiṣe gbogbo ohun tí ipò wa bá yọ̀ọ̀da. (Kolosse 3:23) Ṣùgbọ́n, ìyàtọ̀ ńláǹlà lè wà láàárín ohun tí a fẹ́ láti ṣe àti ohun tí a lè ṣe ní tòótọ́. Àwọn ohun bí ọjọ́ orí, ìlera, okunra, àti ẹrù iṣẹ́ ìdílé lè ká wa lọ́wọ́ kò. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a bá ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, a lè ní ìmọ̀lára ìdánilójú pé iṣẹ́ ìsìn wa sí Jehofa jẹ́ tọkàntọkàn—tí kò pọ̀ jù, tí kò sì dín kù ní jíjẹ́ tọkàntọkàn sí ti ẹnì kan tí ìlera àti ipò rẹ̀ yọ̀ọ̀da fún un láti máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.—Matteu 13:18-23.

14. Kí ni o lè ṣe bí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ ní pípinnu ohun tí o lè retí láti ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní tòótọ́?

14 Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè mọ ohun tí o lè retí láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ní tòótọ́? O lè jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú Kristian ọ̀rẹ́ kan tí ó dàgbà dénú, tí o sì fọkàn tán, bóyá alàgbà kan tàbí arábìnrin kan tí ó nírìírí, tí ó mọ agbára rẹ, ibi tí o mọ, àti ẹrù iṣẹ́ ìdílé rẹ. (Owe 15:22) Rántí pé lójú Ọlọrun, a kò fi bí o ti ṣe tó nínú iṣẹ́ ìsìn pápá díye lé ìníyelórí rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Haggai 2:7; Malaki 3:16‚ 17) Ohun tí o ṣe nínú iṣẹ́ wíwàásù lè pọ̀ tàbí kéré sí ti àwọn yòókù, ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ gbogbo ohun tí o lè ṣe nìyẹn, inú Jehofa dùn sí i, kò sì sí ìdí fún ọ láti máa nímọ̀lára ẹ̀bi.—Galatia 6:4.

Nígbà Tí A Bá Ń Béèrè Púpọ̀ Sí i Lọ́wọ́ Wa

15. Ní àwọn ọ̀nà wo ni a gbà ń béèrè púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ?

15 Jesu sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí a bá fi púpọ̀ fún, púpọ̀ ni a óò fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Luku 12:48) Dájúdájú, ‘púpọ̀ ni a fi dandan béèrè lọ́wọ́’ àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Gẹ́gẹ́ bíi Paulu, wọ́n ń lo ara wọn nítorí ìjọ. (2 Korinti 12:15) Wọ́n ní láti múra àsọyé sílẹ̀, kí wọ́n ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, kí wọ́n sì bójú tó àwọn ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́—gbogbo rẹ̀ láìpa ìdílé wọn tì. (1 Timoteu 3:4‚ 5) Ọwọ́ àwọn alàgbà míràn tún máa ń dí fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣíṣiṣẹ́ sìn nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, àti yíyọ̀ọ̀da ara wọn ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọpọ̀ àgbègbè. Báwo ni àwọn ọkùnrin akíkanjú, olùfọkànsìn wọ̀nyí ṣe lè yẹra fún ṣíṣàárẹ̀ lábẹ́ irú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo bẹ́ẹ̀?

16. (a) Ojútùú gbígbéṣẹ́ wo ni Jetro fún Mose? (b) Ànímọ́ wo ni yóò mú kí alàgbà kan pín ẹrù iṣẹ́ tí ó yẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?

16 Nígbà tí ẹ̀mí Mose, ọkùnrin oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti onírẹ̀lẹ̀ náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ nítorí bíbójú tó ìṣòro àwọn ẹlòmíràn, àna rẹ̀, Jetro, pèsè ojútùú gbígbéṣẹ́: pín ẹrù iṣẹ́ kan fún àwọn ọkùnrin mìíràn tí wọ́n tóótun. (Eksodu 18:17-26; Numeri 12:3) Owe 11:2 (NW) sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú oníwọ̀ntúnwọ̀nsì.” Láti jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì túmọ̀ sí mímọ̀ àti títẹ́wọ́ gba ibi tí agbára rẹ mọ. Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì kì í lọ́ra láti yan iṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, kì í sì í bẹ̀rù pé bí òún bá pín ẹrù iṣẹ́ fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n tóótun, apá òun kì yóò ká wọn mọ́.b (Numeri 11:16‚ 17‚ 26-29) Dípò bẹ́ẹ̀, ó ń hára gàgà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú.—1 Timoteu 4:15.

17. (a) Báwo ni àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ṣe lè mú kí ẹrù àwọn alàgbà fúyẹ́? (b) Ìrúbọ wo ni ìyàwó àwọn alàgbà ń ṣe, báwo sì ni a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì èyí?

17 Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ lè ṣe púpọ̀ láti mú kí ẹrù àwọn alàgbà fúyẹ́. Ní lílóye pé àwọn alàgbà ní ìdílé tiwọn láti bójú tó, àwọn mìíràn kì yóò fi àìfòyebánilò béèrè fún àkókò àti àfiyèsí àwọn alàgbà. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì yóò ṣàìmọrírì ìrúbọ tọkàntọkàn tí ìyàwó àwọn alàgbà máa ń ní ní fífi àìmọtara ẹni nìkan yọ̀ọ̀da láti ṣàjọpín àkókò àwọn ọkọ wọn pẹ̀lú ìjọ. Obìnrin ọlọ́mọ mẹ́ta kan, tí ọkọ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ṣàlàyé pé: “Ohun kan ti n kì í ráhùn lé lórí ni àfikún ẹrù iṣẹ́ tí mo ń fínnúfíndọ̀ gbé nínú ilé, kí ọkọ mi baà lè ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Mo mọ̀ pé ìbùkún Jehofa wà lórí ìdílé wa ní jìngbìnnì, nítorí pé ó ń ṣiṣẹ́ sìn, n kò sì kùn sí ìwọ̀n tí ó bá lè ṣe. Síbẹ̀, òtítọ́ ni pé, mo ní láti ṣiṣẹ́ púpọ̀ sí i nínú ọgbà, kí n sì ṣe púpọ̀ sí i nínú títọ́ àwọn ọmọ wa ju bí ǹ bá ti ṣe lọ, nítorí ọwọ́ ọkọ mi dí púpọ̀.” Ó bani nínú jẹ́ pé, arábìnrin yìí rí i pé, dípò mímọrírì àfikún iṣẹ́ rẹ̀, àwọn kan ń sọ̀rọ̀ àìgbatẹnirò bí i, “Èé ṣe ti o kò fi jẹ́ aṣáájú ọ̀nà?” (Owe 12:18) Ẹ wo bí ó ti dára tó láti gbóríyìn fún àwọn mìíràn nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe, ju kí á máa ṣe lámèyítọ́ wọn nítorí ohun tí wọn kò lè ṣe!—Owe 16:24; 25:11.

Nítorí Òpin Kò Tí ì Dé

18, 19. (a) Èé ṣe tí ìsinsìnyí kì í fi í ṣe àkókò láti dáwọ́ eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun dúró? (b) Ìmọ̀ràn tí ó bá àkókò mu wo ni aposteli Paulu fún àwọn Kristian ní Jerusalemu?

18 Nígbà tí eléré ìje kan bá mọ̀ pé òún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé òpin eré ìje gígùn, kò jẹ́ juwọ́ sílẹ̀. Ara rẹ̀ lè fẹ́rẹ̀ẹ́ má gbà á mọ́—kí ó ti rẹ̀ ẹ́, kí ó máa làágùn, kí ọ̀fun rẹ̀ sì ti gbẹ—ṣùgbọ́n kò yẹ kí ó dáwọ́ eré dúró ní àsìkò tí ó ti sún mọ́ òpin. Bákan náà, gẹ́gẹ́ bíi Kristian, a ń sá eré ìje fún ẹ̀bùn ìwàláàyè, a sì ti sún mọ́ òpin rẹ̀. Ìsinsìnyí kọ́ ni àsìkò fún wa láti ṣíwọ́ eré sísá!—Fi wé 1 Korinti 9:24; Filippi 2:16; 3:13, 14.

19 Àwọn Kristian ní ọ̀rúndún kìíní dojú kọ irú ipò kan náà. Ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa, aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian ní Jerusalemu. Àkókò ti ń tán lọ—“ìran” búburú, ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù apẹ̀yìndà, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ “kọjá lọ.” Ní pàtàkì, àwọn Kristian tí wọ́n wà ní Jerusalemu ní láti wà lójúfò, kí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́; wọ́n ní láti sá kúrò ní ìlú náà nígbà tí wọ́n bá rí i pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini ti yí i ká. (Luku 21:20-24‚ 32) Ìmọ̀ràn onímìísí ti Paulu bọ́ sí àkókò nígbà náà pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.’ (Heberu 12:3) Níhìn-ín aposteli Paulu lo ọ̀rọ̀ ìṣe méjì tí ó hàn kedere: “rẹ̀” (kaʹmno) àti “rẹ̀wẹ̀sì” (e·klyʹo·mai). Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bibeli kan ti sọ, àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì wọ̀nyí ni “Aristotle lò fún àwọn eléré ìje tí wọ́n fà sẹ́yìn, tí wọ́n sì ṣubú lulẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n ti kọjá òpin eré náà. Àwọn òǹkàwé [lẹ́tà Paulu] ṣì wà lẹ́nu eré ìje náà. Wọn kò gbọdọ̀ juwọ́ sílẹ̀ láàárín méjì. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àárẹ̀ mú wọn dákú kí wọ́n sì ṣubú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tí ẹnì kan bá ń dojú kọ ipò líle koko, èyí ń béèrè ìforítì.”

20. Èé ṣe ti ìmọ̀ràn Paulu fi bá àkókò mu fún wa lónìí?

20 Ẹ wo bí ìmọ̀ràn Paulu ti bá àkókò mu tó fún wa lónìí! Nígbà tí a bá ń dojú kọ ìkìmọ́lẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, ìgbà míràn lè wà, tí a lè nímọ̀lára bí eléré ìje tí ó ti rẹ̀, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dá. Ṣùgbọ́n nítorí a ti sún mọ́ òpin eré náà, a kò gbọdọ̀ juwọ́ sílẹ̀! (2 Kronika 29:11) Ìyẹn gan-an ni Elénìní wa, “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” yóò fẹ́ ki a ṣe. Ọpẹ́ ni pé, Jehofa ti ṣe ìpèsè tí ń fi “agbára fún aláàárẹ̀.” (Isaiah 40:29) Ohun tí àwọn ìpèsè wọ̀nyí jẹ́, àti bí a ṣe lè jàǹfààní wọn ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan lè jìjàkadì láti ṣàkóso àkópọ̀ ìwà kan tí ó ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù, irú bí inú fùfù, tàbí láti borí ìṣòro ìdánìkan hùwà ìbálòpọ̀.—Wo Jí!, November 22, 1988, ojú ìwé 19 sí 21; May 8, 1983, ojú ìwé 13 sí 19; àti Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ojú ìwé 198 sí 211, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ẹyin Alagba—Ẹ Yan Iṣẹ́ Fúnni!” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti October 15, 1992, ojú ìwé 20 sí 23.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún jíjuwọ́ sílẹ̀ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá já wa kulẹ̀ tàbí tí wọ́n bá mú wa bínú?

◻ Ojú ìwòye tí ó ṣe déédéé nípa ẹ̀bi wo ni kì yóò jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀?

◻ Kí ni Jehofa ń retí láti ọ̀dọ̀ wa?

◻ Báwo ni jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe lè ran àwọn alàgbà ìjọ lọ́wọ́ láti yẹra fún kíkáàárẹ̀?

◻ Èé ṣe tí ìmọ̀ràn Paulu nínú Heberu 12:3 fi bá àkókò mu fún wa lónìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́