ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 12/1 ojú ìwé 14-19
  • Jehofa Ń fún Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú Lágbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Ń fún Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú Lágbára
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Agbára Àdúrà
  • Ìfẹ́ Ẹgbẹ́ Àwọn Ará
  • Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
  • Àwọn Alàgbà Tí Wọ́n Jẹ́ “Ibi Ìlùmọ́ Kúrò Lójú Ẹ̀fúùfù”
  • Àìsáyà 40:31—“Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Máa Jèrè Okun Pa Dà”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jèhófà Ń fi Agbára Fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • “Ẹ Máa Wá Jèhófà Àti Okun Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 12/1 ojú ìwé 14-19

Jehofa Ń fún Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú Lágbára

“Àwọn tí ó bá dúró de Oluwa yóò tún agbára wọn ṣe; wọn óò fi ìyẹ́ [gun] òkè bí idì.”—ISAIAH 40:31.

1, 2. Kí ni Jehofa ń fún àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e, kí sì ni a óò gbé yẹ̀ wò nísinsìnyí?

IDÌ wà lára àwọn ẹyẹ tí ó lágbára jù lọ lójú òfuurufú. Wọ́n lè fò lọ síbi jíjìnnà réré láìju ìyẹ́ apá wọn. Pẹ̀lú apá tí ó lè fẹ̀ tó mítà méjì, “Ọba àwọn Ẹyẹ,” idì oníwúrà, jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn idì fífani mọ́ra jù lọ; ní fífò kọjá àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, [ó] ń fò lọ sókè fíofío fún ọ̀pọ̀ wákàtí lórí téńté òkè ńlá, lẹ́yìn náà ni yóò fò yíká títí yóò fi dà bí àmì bíntín kan ni ojú òfuurufú.”—The Audubon Society Encyclopedia of North American Birds.

2 Pẹ̀lú agbára fífò idì tí ó ní lọ́kàn, Isaiah kọ̀wé pé: “[Jehofa] ń fi agbára fún aláàárẹ̀; ó sì fi agbára kún àwọn tí kò ní ipá. Àní àárẹ̀ yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọdé, yóò sì rẹ̀ wọ́n, àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yóò tilẹ̀ ṣubú pátápátá: ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Oluwa yóò tún agbára wọn ṣe; wọn óò fi ìyẹ́ [gun] òkè bí idì; wọn óò sáré, kì yóò sì rẹ̀ wọ́n; wọn óò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.” (Isaiah 40:29-31) Ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti mọ̀ pé Jehofa ń fún àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní agbára láti máa tẹ̀ síwájú, bíi pé ó ń mú wọn gbara dì pẹ̀lú ohun tí ó dà bí apá idì tí kì í rẹ̀, tí ó fò lọ sókè fíofío! Wàyí o, gbé díẹ̀ lára àwọn ìpèsè tí ó ti ṣe láti fún àwọn aláàárẹ̀ lágbára yẹ̀ wò.

Agbára Àdúrà

3, 4. (a) Kí ni Jesu rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe? (b) Kí ni a lè retí pé kí Jehofa ṣe ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa?

3 Jesu rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “lati máa gbàdúrà nígbà gbogbo ati lati máṣe juwọ́sílẹ̀.” (Luku 18:1) Ṣíṣí ọkàn wa payá fún Jehofa ha lè ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi láti tún rí agbára gbà, kí a sì yẹra fún jíjuwọ́ sílẹ̀ nígbà tí ìkìmọ́lẹ̀ ìgbésí ayé bá dà bí èyí tí ń boni mọ́lẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n àwọn ohun kan wà tí a ní láti fi sọ́kàn.

4 A gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tí a retí kí Jehofa ṣe ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa. Kristian kan, tí ó ti yọ̀ tẹ̀rẹ́ sínú ìsoríkọ́ gíga gan-an, ṣàkíyèsí lẹ́yìn náà pé: “Bí i ti àwọn àìlera mìíràn, Jehofa kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu ní àsìkò yìí. Ṣùgbọ́n ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀ kí a sì sàn dé ìwọ̀n tí ó ṣeé ṣe nínú ètò ìgbékalẹ̀ yìí.” Nígbà tí ó ń ṣàlàyé ìdí tí àdúrà rẹ fi mú ìyàtọ̀ wá, ó fi kún un pé: “Mo ní àǹfààní láti rí ẹ̀mí mímọ́ Jehofa gbà ni gbogbo wákàtí 24 tí ó wà ní ọjọ́ kan.” Nípa báyìí, Jehofa kì í dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìkìmọ́lẹ̀ ìgbésí ayé tí ó lè bò wá mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó máa ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún awọn wọnnì tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Luku 11:13; Orin Dafidi 88:1-3) Ẹ̀mí yẹn lè mú kí á kojú ìdánwò tàbí ìkìmọ́lẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá dojú kọ wá. (1 Korinti 10:13) Bí ó bá pọn dandan, ó lè fún wa ní “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti fara dà títí tí Ìjọba Ọlọrun yóò fi mú gbogbo ìṣòro atánnilókun kúrò nínú ayé tuntun tí ó ti sún mọ́lé.—2 Korinti 4:7.

5. (a) Kí àdúrà wa tó lè gbéṣẹ́, àwọn ohun méjì wo ni ó ṣe pàtàkì? (b) Báwo ni a ṣe lè gbàdúrà, bí a bá ń jìjàkadì pẹ̀lú àìlera ẹran ara? (d) Kí ni àdúrà tí a tẹpẹlẹmọ́, tí a sì sọ ojú abẹ níkòó, yóò fi han Jehofa?

5 Ṣùgbọ́n, kí àdúrà wa baà lè gbéṣẹ́, a ní láti máa forí tì, a sì ní láti sọ ojú abẹ níkòó. (Romu 12:12) Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ń káàárẹ̀ nígbà míràn nítorí tí o ń bá àìlera ẹran ara kan jìjàkadì, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, bẹ Jehofa láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún jíjuwọ́ sílẹ̀ fún àìlera pàtó náà ní ọjọ́ yẹn. Gbàdúrà bákan náà jálẹ̀ ọjọ́ náà àti ṣáájú kí o tó sùn lálaalẹ́. Bí ìfàsẹ́yìn bá wà, bẹ Jehofa láti dárí jì ọ́, ṣùgbọ́n tún sọ ohun tí ó fa ìfàsẹ́yìn náà fún un, àti ohun tí o lè ṣe láti yẹra fún irú ipò yìí lọ́jọ́ iwájú. Irú àdúrà tí a tẹpẹlẹ mọ́, tí ó sì ṣe pàtó bẹ́ẹ̀ yóò fi ìfẹ́ àtọkànwá rẹ̀ láti borí ìjà náà han “Olùgbọ́ àdúrà.”—Orin Dafidi 65:2, NW; Luku 11:5-13.

6. Èé ṣe tí ó fi tọ́ láti retí pé kí Jehofa gbọ́ àdúrà wa àní nígbà tí a lè nímọ̀lára àìtóótun láti gbàdúrà pàápàá?

6 Ṣùgbọ́n, nígbà míràn, àwọn tí wọ́n ti káàárẹ̀ lè nímọ̀lára àìtóótun láti gbàdúrà. Kristian obìnrin kan tí ó ti nímọ̀lára ní ọ̀nà yìí, sọ lẹ́yìn náà pé: “Èyí jẹ́ èrò tí ó léwu gan-an, nítorí ó túmọ̀ sí pé a ti sọ ara wa di onídàájọ́ ara wa, ṣùgbọ́n ìyẹn kì í ṣe iṣẹ́ wa.” Ní ti gidi, “Ọlọrun tìkara rẹ̀ ni onídàájọ́.” (Orin Dafidi 50:6) Bibeli mú un dá wa lójú pé, bí ó tilẹ̀ jẹ̀ pé “ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, Ọlọrun tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Johannu 3:20) Ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti mọ̀ pé, bí a tilẹ̀ dá ara wa lẹ́bi pé a kò tóótun láti gbàdúrà, Jehofa lè má ro èyí sí wa! Ó “mọ ohun gbogbo” nípa wa, títí kan ipò ìgbésí ayé wa, tí ó lè mú wa nímọ̀lára àìtóótun. (Orin Dafidi 103:10-14) Àánú rẹ̀, àti bí òye rẹ̀ ti jinlẹ̀ tó ń sún un láti gbọ́ àdúrà láti inú “ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.” (Orin Dafidi 51:17) Báwo ni yóò ṣe kọ̀ láti gbọ́ igbe wa fún ìrànlọ́wọ́, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ bẹnu àtẹ́ lu “ẹnikẹ́ni tí ó bá di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú”?—Owe 21:13.

Ìfẹ́ Ẹgbẹ́ Àwọn Ará

7. (a) Kí ni ìpèsè míràn tí Jehofa ti ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti tún rí agbára gbà? (b) Kí ni a lè mọ̀ nípa àwọn ẹgbẹ́ ará, tí ó lè fún wa lókun?

7 Ẹgbẹ́ àwọn ará Kristian jẹ́ ìpèsè míràn tí Jehofa ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti tún rí agbára gbà. Ẹ wo àǹfààní iyebíye tí ó jẹ́ láti jẹ́ apá kan ìdílé àwọn arákùnrin àti arábìnrin kárí ayé! (1 Peteru 2:17) Nígbà tí ìkìmọ́lẹ̀ ìgbésí ayé bá mú wa sorí kọ́, ìfẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará lè ràn wá lọ́wọ́ láti tún rí agbára gbà. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Kìkì mímọ̀ pé a kò dá wà ní kíkojú àwọn ìpèníjà tí ń tánni lókun, lè fún wa lókun. Ó dájú pé, láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, àwọn kan wà tí wọ́n ti dojú kọ ìkìmọ́lẹ̀ àti ìdánwò tí ó jọ èyí, tí wọ́n sì ti ní ìrírí ìmọ̀lára tí ó jọ tiwa. (1 Peteru 5:9) Ó ń fọkàn balẹ̀ láti mọ̀ pé, ohun tí a ń nírìírí rẹ̀ wọ́ pọ̀, àti pé ìmọ̀lára wa kò ṣàjèjì.

8. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó fi hàn pé a lè rí ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú tí a nílò láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ará wa? (b) Ní ọ̀nà wo ni “alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ tòótọ́” ti gbà ran ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lọ́wọ́ tàbí tí ó ti tù ọ́ nínú?

8 Nínú ìfẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará, a lè rí ‘àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ tòótọ́’ tí ó lè pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú tí a nílò nígbà tí a bá ní ìrora ọkàn. (Owe 17:17, NW) Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kìkì ohun tí ń béèrè ni àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe onínúure. Kristian kan tí ó jìjàkadì pẹ̀lú ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkankan rántí pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí ń sọ àwọn ohun tí ń gbéni ró nípa ara mi fún mi, láti lè ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìrònú òdì tí mo ní.” (Owe 15:23) Ó ṣòro fún arábìnrin kan, lẹ́yìn ikú ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré, láti kọrin Ìjọba ní àwọn ìpàdé ìjọ, ní pàtàkì, àwọn orin tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú àjíǹde. Ó rántí pé: “Ní ọjọ́ kan, arábìnrin kan tí ó jókòó ní òdì kejì rí i pé mo ń sunkún. Ó wá sọ́dọ̀ mi, ó gbọ́wọ́ lé mi, ó sì kọ ìyókù orin náà pẹ̀lú mi. Mo fẹ́ràn àwọn arákùnrin àti arábìnrin, mo sì láyọ̀ pé a ti dé ìpàdé, ní ti pé mo mọ̀ pé níbẹ̀ ni ìrànlọ́wọ́ wa wà, níbẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.”

9, 10. (a) Báwo ni a ṣe lè dá kún ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará wa? (b) Ta ni ó nílò ìkẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé ní pàtàkì? (d) Kí ni a lè ṣe láti ran àwọn wọnnì tí wọ́n nílò ìṣírí lọ́wọ́?

9 Dájúdájú, gbogbo wa ni a ní ẹrù iṣẹ́ lílọ́wọ́ sí ìfẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará, ti Kristian. Nítorí náà, ọkàn wa ní láti “gbòòrò síwájú” láti ní gbogbo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú. (2 Korinti 6:13) Ẹ wo bí yóò ti ba àwọn tí wọ́n ti káàárẹ̀ nínú jẹ́ tó, láti máa ronú pé ìfẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará sí wọn, ti ń jó lọ sílẹ̀! Síbẹ̀, àwọn Kristian kan máa ń ròyìn pé àwọn ń nímọ̀lára ìdánìkanwà, tí a sì pa wọ́n tì. Arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ ta ko òtítọ́ jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Ta ni kò fẹ́, tí kò sì nílò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ń gbéni ró, ìṣírí, àti ìbáṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́? Ẹ jọ̀wọ́, rán àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa létí pé a nílò wọn!” Bẹ́ẹ̀ ni, ní pàtàkì, àwọn tí ipò ìgbésí ayé wọn ti mú wọn sorí kọ́—àwọn tí wọ́n ní alábàágbéyàwó tí kò gbà gbọ́, àwọn òbí anìkàntọ́mọ, àwọn tí wọ́n ní ìṣòro àìlera líle koko, àwọn tí wọ́n ti darúgbó, àti àwọn mìíràn—nílò ìbáṣepọ̀ tí ó gbámúṣé. Ó ha yẹ kí a rán àwọn kan lára wa létí bí?

10 Kí ni a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ kí a mú ìfihàn ìfẹ́ wa gbòòrò síwájú sí i. Nígbà ti a bá ń nawọ́ ẹ̀mí aájò àlejò, ẹ máà jẹ́ kí a gbàgbé àwọn tí wọ́n nílò ìṣírí. (Luku 14:12-14; Heberu 13:2) Kàkà tí a óò fi méfò pé ipò wọn kì yóò jẹ́ kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, èé ṣe tí a kò fi pè wọ́n ná? Nígbà náà, kí a jẹ́ kí wọ́n pinnu. Bí wọn kò bá tilẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, ó dájú pé yóò fún wọn ní ìṣírí láti mọ̀ pé àwọn mìíràn ronú nípa wọn. Ó lè jẹ́ kìkì ohun tí wọ́n nílò nìyẹn láti tún rí agbára wọn gbà.

11. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn tí wọ́n sorí kọ́ lè gbà nílò ìrànlọ́wọ́?

11 Àwọn tí wọ́n ti sorí kọ́, lè nílò ìrànlọ́wọ́ ní àwọn ọ̀nà míràn. Fún àpẹẹrẹ, ìyá anìkàntọ́mọ lè nílò ìrànlọ́wọ́ arákùnrin kan tí ó dàgbà dénú láti fi ìfẹ́ hàn sí ọmọkùnrin rẹ̀ aláìníbaba. (Jakọbu 1:27) Arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí ó ní ìṣòro àìsàn líle koko lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti ra nǹkan tàbí ṣe iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Àgbàlagbà kan lè máa yán hànhàn fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tàbí kí ó nílò ìrànlọ́wọ́ láti jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Nígbà tí àìní bá wà fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, ó ń ‘dán jíjẹ́-ojúlówó ìfẹ́ wa wò.’ (2 Korinti 8:8) Dípò fífà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìní, nítorí àkókò àti ìsapá tí èyí ní nínú, ǹjẹ́ kí a yege nínú ìdánwò ìfẹ́ Kristian nípa títètè ní ìmọ̀lára àti títètè dáhùn padà sí àìní àwọn mìíràn.

Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọrun

12. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti tún rí agbára gbà?

12 Ẹnì kan tí ó ṣíwọ́ oúnjẹ jíjẹ yóò sọ okun, tàbí agbára rẹ̀ nù láìpẹ́. Bákan náà, ọ̀nà míràn tí Jehofa ń gbà fún wa ní agbára láti máa tẹ̀ síwájú ni nípa rírí sí i pé a bọ́ wa dáradára nípa tẹ̀mí. (Isaiah 65:13‚ 14) Oúnjẹ nípa tẹ̀mí wo ni ó pèsè? Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. (Matteu 4:4; fi wé Heberu 4:12.) Báwo ni ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti tún rí agbára gbà? Nígbà tí ìkìmọ́lẹ̀ àti ìṣòro tí a ń dojú kọ bá bẹ̀rẹ̀ síí tán wa lókun, a lè rí okun gba láti inú kíkà nípa ìmọ̀lára àti ìjàkadì tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an sí àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ ní àkókò Bibeli. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere ní ti dídi ìwàtítọ́ mu, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn “tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.” (Jakọbu 5:17; Ìṣe 14:15) Wọ́n dojú kọ ìdánwò àti ìkìmọ́lẹ̀ tí ó fara jọ tiwa. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ kan.

13. Àwọn àpẹẹrẹ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó fi hàn pé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní ìgbà Bibeli ní ìmọ̀lára àti ìrírí tí ó jọ tiwa?

13 Abrahamu, baba ńlá náà, kẹ́dùn gan-an nítorí ikú ìyàwó rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. (Genesisi 23:2; fi wé Heberu 11:8-10‚ 17-19.) Dafidi, olùronúpìwàdà náà, lérò pé ẹ̀ṣẹ̀ òun ti sọ òun di ẹni tí kò yẹ láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa. (Orin Dafidi 51:11) Mose ní ìmọ̀lára àìtóótun. (Eksodu 4:10) Epafroditu rẹ̀wẹ̀sì, nígbà tí ó mọ̀ pé àìsàn líle koko ti pààlà sí ìgbòkègbodò òun nínú “iṣẹ́ Oluwa.” (Filippi 2:25-30) Paulu ní láti bá ẹran ara aláìpé jìjàkadì. (Romu 7:21-25) Ó dájú pé aáwọ̀ wà láàárín Euodia àti Sintike, àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró nínú ìjọ Filippi. (Filippi 1:1; 4:2‚ 3) Ẹ wo bí ó ti fúnni níṣìírí tó láti mọ̀ pé àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ní ìmọ̀lára àti ìrírí bí i tiwa, síbẹ̀ wọn kò juwọ́ sílẹ̀! Bẹ́ẹ̀ sì ni Jehofa kò pa wọ́n tì.

14. (a) Ohun èlò wo ni Jehofa ti lò láti ràn wá lọ́wọ́ láti rí okun gbà láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Èé ṣe tí àwọn ìwé àtìgbàdégbà náà, Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, fi ń jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ọ̀ràn ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, ìdílé, àti èrò ìmọ̀lára?

14 Láti lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí okun nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jehofa ń lo ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú láti pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu” fún wa déédéé. (Matteu 24:45) Tipẹ́tipẹ́ ni olùṣòtítọ́ ẹrú ti ń lo àwọn ìwé àtìgbàdégbà náà, Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, láti gbèjà òtítọ́ Bibeli àti láti polongo Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún ènìyàn. Ní pàtàkì, ní ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn ìwé àtìgbàdégbà wọ̀nyí ti gbé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu jáde lórí ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, ìdílé, àti ìpèníjà èrò ìmọ̀lára tí àwọn kan lára àwọn ènìyàn Ọlọrun tilẹ̀ ń dojú kọ. Fún ète wo ni a ṣe tẹ irú àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí jáde? Dájúdájú, ó jẹ́ láti ran àwọn tí ń nírìírí àwọn ìpèníjà wọ̀nyí lọ́wọ́ láti rí okun àti ìṣírí gbà láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣùgbọ́n, irú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tún ń ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti lóye ohun tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kan ń dojú kọ yékéyéké. Nípa báyìí, a múra wa sílẹ̀ dáradára láti kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ Paulu pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún awọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tessalonika 5:14.

Àwọn Alàgbà Tí Wọ́n Jẹ́ “Ibi Ìlùmọ́ Kúrò Lójú Ẹ̀fúùfù”

15. Kí ni Isaiah sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ẹrù iṣẹ́ wo sì ni èyí gbé lé wọn léjìká?

15 Jehofa ti pèsè ohun mìíràn láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí a bá sorí kọ́—àwọn alàgbà ìjọ. Wòlíì Isaiah kọ̀wé nípa àwọn wọ̀nyí pé: “Ẹnì kan yóò sì jẹ́ ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì; bí odò omi ní ibi gbígbẹ, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.” (Isaiah 32:1, 2) Nígbà náà, àwọn alàgbà ní ẹrù iṣẹ́ dídé ojú ìwọ̀n ohun tí Jehofa ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn. Wọ́n “yóò . . . jẹ́” orísun ìtùnú àti ìtura fún àwọn mìíràn, wọ́n sì ní láti ṣe tán láti “máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù-ìnira [tàbí, “àwọn nǹkan oníwàhálà”; ní olówuuru, “àwọn ohun wíwúwo”] ara [wọn] lẹ́nìkínní kejì.” (Galatia 6:2, àlàyé ẹsẹ̀ ìwé, NW) Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe èyí?

16. Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti ran ẹnì kan tí ń nímọ̀lára àìtóótun láti gbàdúrà lọ́wọ́?

16 Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, nígbà míràn, ẹnì kan tí àárẹ̀ ti mú, lè nímọ̀lára àìtóótun láti gbàdúrà. Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe? Wọ́n lè gbàdúrà pẹ̀lú onítọ̀hún, kí wọ́n sì gbàdúrà fún un. (Jakọbu 5:14) Kìkì bíbéèrè lọ́wọ́ Jehofa, ní etígbọ̀ọ́ ẹni tí ń káàárẹ̀ náà, láti ràn án lọ́wọ́ láti lóye bí Jehofa àti àwọn mìíràn ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó, dájúdájú yóò tù ú nínú. Gbígbọ́ àdúrà tí alàgbà kan fìgbónára gbà látọkànwá, lè ṣèrànwọ́ láti fún ìgbọ́kànlé onírora ọkàn lókun. A lè ràn án lọ́wọ́ láti ronú pé, bí àwọn alàgbà bá nígbọkànlé pé Jehofa yóò dáhùn àwọn àdúrà tí wọ́n gbà nítorí ẹnì náà, nígbà náà òun pẹ̀lú lè ṣàjọpín irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀.

17. Èé ṣe tí àwọn alàgbà fi ní láti jẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ tí ń gba tẹni rò?

17 Jakọbu 1:19 sọ pé: “Olúkúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ yára nipa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ.” Àwọn alàgbà ní láti jẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ tí ń gba tẹni rò, kí wọ́n baà lè ran ẹni tí ó káàárẹ̀ lọ́wọ́, láti tún rí agbára gbà. Ní àwọn ìgbà míràn, àwọn mẹ́ḿbà ìjọ lè máa jìjàkadì pẹ̀lú ìṣòro tàbí ìkìmọ́lẹ̀ tí kò lè yanjú nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Nígbà náà, ohun tí wọ́n lè nílò, kì í ṣe ojútùú láti “yanjú” àwọn ìṣòro wọn, ṣùgbọ́n kìkì láti bá olùtẹ́tísílẹ̀ rere kan sọ̀rọ̀—ẹnì kan tí kì yóò sọ irú ìmọ̀lára tí ó yẹ kí wọ́n ní fún wọn, ṣùgbọ́n tí yóò tẹ́tí sílẹ̀ láìjẹ́ adánilẹ́jọ́.—Luku 6:37; Romu 14:13.

18, 19. (a) Báwo ni yíyára láti gbọ́ ṣe lè ràn alàgbà kan lọ́wọ́ láti yẹra fún mímú kí ẹrù ẹnì kan tí ń káàárẹ̀ túbọ̀ wúwo sí i? (b) Kí ni máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ nígbà tí àwọn alàgbà bá fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn?

18 Ẹ̀yin alàgbà, yíyára láti gbọ́, lè ràn yín lọ́wọ́ láti yẹra fún fífi àìmọ̀ọ́mọ̀ mú kí ẹrù ẹni tí ń káàárẹ̀ túbọ̀ wúwo sí i. Fún àpẹẹrẹ, bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ti pa àwọn ìpàdé kan jẹ, tàbí tí ó ti fà sẹ́yìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ohun tí ó nílò ha ni ìmọ̀ràn nípa ṣíṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi tàbí wíwá sí àwọn ìpàdé déédéé bí? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n o ha lóye gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ bí? Ìṣòro àìlera ha ń pọ̀ sí i bí? Ẹrù iṣẹ́ ìdílé ha ti yí padà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? Ipò tàbí ìkìmọ́lẹ̀ míràn ha wà tí ń mú un sorí kọ́ bí? Rántí pé, ẹni náà ti lè máa nímọ̀lára ẹ̀bi pé òun kò lè ṣe púpọ̀ sí i tẹ́lẹ̀.

19 Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè ran arákùnrin tàbí arábìnrin náà lọ́wọ́? Ṣáájú kí o tó dórí ìpinnu, kí o sì tó fún un ní ìmọ̀ràn, tẹ́tí sílẹ̀! (Owe 18:13) Lo àwọn ìbéèrè amòye láti ‘fa’ èrò ọkàn onítọ̀hún ‘jáde.’ (Owe 20:5) Má ṣe gbójú fo àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí—pe àfiyèsí sí wọn. A lè ní láti mú un dá ẹnì kan tí ó káàárẹ̀ lójú pé Jehofa bìkítà nípa wa, ó sì lóye pé nígbà míràn, ipò wa lè ká wa lọ́wọ́ kò. (1 Peteru 5:7) Nígbà tí àwọn alàgbà bá fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” bẹ́ẹ̀ hàn, àwọn tí wọ́n ń káàárẹ̀ yóò ‘rí ìtura fún ọkàn wọn.’ (1 Peteru 3:8; Matteu 11:28-30) Nígbà tí wọ́n bá rí irú ìtura bẹ́ẹ̀, a kì yóò ní láti sọ fún wọn láti ṣe púpọ̀ sí i; ọkàn wọn yóò sún wọn láti ṣe gbogbo ohun tí ó bọ́gbọ́n mu fún wọn láti ṣe ní ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa.—Fi wé 2 Korinti 8:12; 9:7.

20. Pẹ̀lú bí òpin ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí ti ń sún mọ́ etílé, kí ni a ní láti pinnu láti ṣe?

20 Lóòótọ́, a ń gbé ní àkókò tí ó nira jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ìkìmọ́lẹ̀ gbígbé tí a ń gbé ní ayé Satani ń pọ̀ sí i bí a ti ń sún mọ́ òpin. Rántí pé, gẹ́gẹ́ bíi kìnnìún tí ń ṣọdẹ, Èṣù ń dúró dè wá láti káàárẹ̀, kí a sì juwọ́ sílẹ̀, kí ó baà lè rí àyè láti fi wa ṣẹran ọdẹ. Ẹ wo bí a ti ní láti ṣọpẹ́ tó, pé Jehofa ń fún àwọn tí àárẹ̀ mú lágbára! Ǹjẹ́ kí a lo àǹfààní ìpèsè tí ó ti ṣe láti fún wa ní agbára láti máa tẹ̀ síwájú, bí i pé ó ń fún wa ní apá ńlá ti idì kan tí ń fò lọ sókè fíofío. Bí òpin iran búburú yìí ti ń sún mọ́lé, ìsinsìnyí kì í ṣe àkókò láti ṣíwọ́ sísá eré ìje fún ẹ̀bùn náà—ìyè àìnípẹ̀kun.—Heberu 12:1.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

◻ Kí ni a lè retí pé kí Jehofa ṣe ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni a fi lè rí okun gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristian ẹgbẹ́ ará wa?

◻ Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti tún rí agbára wa gbà?

◻ Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti ran àwọn tí ń rẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́ láti tún rí agbára gbà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Nígbà tí a bá ń nawọ́ ẹ̀mí aájò àlejò, ẹ má ṣe jẹ́ kí a gbàgbé àwọn tí wọ́n nílò ìṣírí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn alàgbà lè bẹ Jehofa láti ran àwọn tí ń káàárẹ̀ lọ́wọ́ láti lóye bí a ti nífẹ̀ẹ́ wọn tó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́