ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 3/1 ojú ìwé 4-7
  • Ọlọrun Bìkítà Nípa Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Bìkítà Nípa Rẹ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Ìgbàanì Kan
  • Jehofa Ti Fà Ọ́
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jesu
  • Jehofa di Olùsẹ̀san
  • Ṣé Ẹnì Kankan Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Mi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jèhófà Bìkítà Fún Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jehófà Ni “Olùsẹ̀san Fún Àwọn Tí Ń Fi Taratara Wá A”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 3/1 ojú ìwé 4-7

Ọlọrun Bìkítà Nípa Rẹ

MARY, Kristian obìnrin kan tí ó ti lé dáradára ní ẹni 40 ọdún, ti jìyà púpọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Panṣágà ọkọ rẹ̀ ti yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀ ní èyí tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Lẹ́yìn ìgbà náà, Mary ń tiraka láti ṣe ojúṣe rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin gẹ́gẹ́ bí òbí anìkàntọ́mọ. Ṣùgbọ́n ó ṣì dá wà, nígbà míràn ìdánìkanwà náà máa ń dà bí ohun tí ó ṣòro láti fara dà. Mary ṣe kàyéfì pé, ‘Ó ha túmọ̀ sí pé Ọlọrun kò bìkítà nípa mi tàbí àwọn ọmọ mi tí kò ní bàbá bí?’

Yálà o ti nírìírí wàhálà tí ó jọ èyí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ, ó dájú pé o lè bá Mary kẹ́dùn. Gbogbo wa ni a ti fara da àwọn àyíká ìpò tí ń dánni wò, a sì lè ti ṣe kàyéfì ìgbà náà gan-an tí Jehofa yóò gbèjà wa àti bí yóò ṣe ṣe é. Àwọn kan lára àwọn ìrírí wọ̀nyí jẹ́ ìyọrísí tààràtà ti pé a dìrọ̀ pinpin mọ́ àwọn òfin Ọlọrun. (Matteu 10:16-18; Ìṣe 5:29) Àwọn mìíràn jẹ́ àbájáde pé a jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé tí ń gbé nínú ayé tí Satani ń ṣàkóso. (1 Johannu 5:19) Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora papọ̀ ati ní wíwà ninu ìrora papọ̀.”—Romu 8:22.

Ṣùgbọ́n, nítorí pé o ń dojú kọ ìdánwò líle koko kò túmọ̀ sí pé Jehofa ti pa ọ́ tì tàbí pé kò ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ire rẹ. Báwo ni èyí ṣe lè dá ọ lójú? Kí ni ó fi hàn pé Ọlọrun bìkítà nípa rẹ?

Àpẹẹrẹ Ìgbàanì Kan

Bibeli pèsè ẹ̀rí kedere nípa ìbìkítà Jehofa fún ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Gbé ti Dafidi yẹ̀ wò. Jehofa ní ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni nínú ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùntàn yìí, ní rírí i pé ó jẹ́ “ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀.” (1 Samueli 13:14) Lẹ́yìn náà, nígbà tí Dafidi ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, Jehofa ṣèlérí fún un pé: “Èmi óò . . . wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ́ ń lọ.”—2 Samueli 7:9.

Èyí ha túmọ̀ sí pé Dafidi gbé ìgbésí ayé “onígbàádùn” tí kò sí ìṣòro bí? Rárá o, Dafidi dojú kọ àwọn ìdánwò líle koko ṣáájú àti nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ó tóó di ọba, Ọba Saulu apànìyàn náà lé e láìdẹwọ́. Láàárín sáá yìí nígbà ayé rẹ̀, Dafidi kọ̀wé pé: “Ọkàn mi wà láàárín àwọn kìnnìún . . . èyíinì ni àwọn ọmọ ènìyàn, eyín ẹni tí í ṣe ọ̀kọ̀ àti ọfà.”—Orin Dafidi 57:4.

Síbẹ̀, ní gbogbo ìgbà wàhálà yìí, ìbìkítà Jehofa dá Dafidi lójú. Ó sọ nínú àdúrà kan sí Jehofa pé: “Ìwọ ń ka ìrìnkiri mi.” Bẹ́ẹ̀ ni, lójú Dafidi, ṣe ni ó dà bíi pé Jehofa ń ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ìrírí agbonijìgì náà. Lẹ́yìn náà Dafidi fi kún un pé: “Fi omijé mi sínú [ìgò aláwọ, NW] rẹ: wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ bí?”a (Orin Dafidi 56:8) Pẹ̀lú àpèjúwe yìí, Dafidi sọ ìgbọ́kànlé rẹ̀ jáde pé, kì í ṣe pé Jehofa mọ̀ nípa ipò náà nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún mọ̀ nípa ipa tí èrò ìmọ̀lára rẹ̀ ní pẹ̀lú.

Ní apá tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, Dafidi lè kọ̀wé láti inú ìrírí ara rẹ̀ pé: “A ṣe ìlànà ẹsẹ̀ ènìyàn láti ọwọ́ Oluwa wá: ó sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ ṣubu, a kì yóò ta a nù kúrò pátápátá; nítorí tí Oluwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.” (Orin Dafidi 37:23, 24) Ìwọ pẹ̀lú lè ní ìgbọ́kànlé pé àní bí àwọn ìdánwò rẹ̀ bá ń bá a lọ tí ó sì ń tẹ̀ síwájú, Jehofa ń ka ìfaradà rẹ sí, ó sì mọrírì rẹ̀. Paulu kọ̀wé pé: “Ọlọrun kì í ṣe aláìṣòdodo tí yoo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ tí ẹ fihàn fún orúkọ rẹ̀, níti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún awọn ẹni mímọ́ ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Heberu 6:10.

Síwájú sí i, Jehofa lè gbèjà rẹ nípa fífún ọ ní okun láti fara da ìdènà èyíkéyìí tí ó bá wà ní ọ̀nà rẹ. Dafidi kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣùgbọ́n Oluwa gbà a nínú wọn gbogbo.” (Orin Dafidi 34:19) Ní tòótọ́, Bibeli sọ fún wa pé ojú Jehofa “ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé, láti fi agbára fún àwọn ẹni ọlọ́kàn pípé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kronika 16:9.

Jehofa Ti Fà Ọ́

Ẹ̀rí síwájú sí i nípa bíbìkítà tí Jehofa bìkítà, ni a lè rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu. Ó wí pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Johannu 6:44) Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa ń ràn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ láti lo àǹfààní ẹbọ Kristi. Báwo? Dé ìwọ̀n àyè púpọ̀, ó jẹ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Lóòótọ́, iṣẹ́ yìí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè,” síbẹ̀ ó ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Òtítọ́ náà pé, ò ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ìhìn iṣẹ́ ìhìn rere náà tí o sì ń dáhùn padà, jẹ́ ẹ̀rí pé Jehofa fúnra rẹ̀ bìkítà nípa rẹ.—Matteu 24:14.

Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Jehofa ń fa àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan sún mọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀ àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Èyí ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti lóye kí wọ́n sì fi àwọn òtítọ́ nípa tẹ̀mí sílò láìka àwọn ààlà àti àìpé tí a ti jogún sí. Ní tòótọ́, ẹnì kan kò lè lóye àwọn ète Ọlọrun láìsí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọrun. (1 Korinti 2:11, 12) Gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé sí àwọn ará Tessalonika pé, “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tessalonika 3:2) Jehofa ń fi ẹ̀mí rẹ̀ fún kìkì àwọn tí wọ́n fi ìmúratán láti ṣeé fà fún un hàn.

Jehofa ń fa àwọn ènìyàn nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, ó sì fẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà. Ẹ wo ẹ̀rí tí ó fìdí múlẹ̀ nípa bíbìkítà tí Jehofa bìkítà! Jesu wí pé: “Kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí pé kí ọ̀kan ninu awọn ẹni kékeré wọnyi ṣègbé.” (Matteu 18:14) Bẹ́ẹ̀ ni, lójú Ọlọrun, ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ní pàtó. Ìdí nìyẹn tí Paulu fi lè kọ̀wé pé: “Oun yoo . . . san án fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu awọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Romu 2:6) Aposteli Peteru sì wí pé: “Ọlọrun kì í ṣe ojúsàájú, ṣugbọn ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni [ẹnì kọ̀ọ̀kan] tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jesu

Ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni tí Ọlọrun ní nínú ẹ̀dá ènìyàn ni a fi hàn lọ́nà tí ó fi ìmọ̀lára hàn nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu ṣe. Ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bá àwọn ìwòsàn wọ̀nyí rìn. (Marku 1:40, 41) Níwọ̀n bí Jesu “kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bíkòṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe,” ìyọ́nú rẹ̀ ṣàpèjúwe àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí Jehofa ní fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Johannu 5:19.

Kíyè sí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kan tí Jesu ṣe, tí a kọ̀ sílẹ̀ nínú Marku 7:31-37. Níbí yìí ni Jesu ti wo ọkùnrin kan tí ó dití tí ó sì ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ sàn. Bibeli ròyìn pé, ó “mú [ọkùnrin náà] lọ kúrò lọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ naa ní oun nìkan.” Lẹ́yìn náà, “ní gbígbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run ó mí kanlẹ̀ ó sì wí fún un pé: ‘Efata,’ èyíinì ni, ‘Là.’”

Èé ṣe tí Jesu fi mú ọkùnrin yìí kúrò lọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà? Òtítọ́ ni pé, ó ṣeé ṣe kí adití tí kò lè sọ̀rọ̀ dáradára nímọ̀lára àìbalẹ̀ ara níwájú àwọn òǹwòran. Ó ṣeé ṣe kí Jesu ti ṣàkíyèsí ìnira ọkùnrin yìí, ìdí sì nìyẹn tí ó fi yàn láti wò ó sàn ní ìkọ̀kọ̀. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bibeli kan ṣàkíyèsí pé: “Ìtàn náà látòkèdélẹ̀ fi hàn wá ní ọ̀nà tí ó ṣe kedere jù lọ pé Jesu kò wulẹ̀ ka ọkùnrin náà sí aláìsàn agbàtọ́jú kan; ó kà á sí ẹnì kan. Ọkùnrin náà ní àìní àrà ọ̀tọ̀ kan, àti ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan, Jesu sì fi ìgbatẹnirò oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ lọ́nà tí ó gà jù lọ, tí ó bo àṣírí ìmọ̀lára rẹ̀, àti ní ọ̀nà tí ó lè lóye bá a lò.”

Àkọsílẹ̀ yìí fi hàn pé, Jesu ní àníyàn ara ẹni fún àwọn ènìyàn. Ní ìdánilójú pé ó ní ọkàn-ìfẹ́ nínú rẹ bákan náà. Ní tòótọ́, ikú onírùúbọ rẹ̀ jẹ́ fífi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún gbogbo ayé tí ó ṣeé rà padà. Síbẹ̀, o lè pe ìṣe náà mọ́ ara rẹ, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti ṣe, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Ọmọkùnrin Ọlọrun . . . nífẹ̀ẹ́ mi tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Galatia 2:20) Níwọ̀n bí Jesu sì ti sọ pé “ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹlu,” a lè ní ìdánilójú pé Jehofa ní ọkàn-ìfẹ́ kan náà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Johannu 14:9.

Jehofa di Olùsẹ̀san

Gbígba ìmọ̀ Ọlọrun sínú kan mímọ apá kọ̀ọ̀kan àkópọ̀ ìwà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti ṣí i payá. Orúkọ náà gan-an Jehofa túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Wà” tí ó dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, Jehofa lè di ohun tí ó bá fẹ́ láti lè mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ. Jálẹ̀ ìtàn, ó ti kó onírúurú ipa iṣẹ́, títí kan ti Ẹlẹ́dàá, Bàbá, Oluwa Ọba Aláṣẹ, Olùṣọ́ Àgùntàn, Jehofa àwọn ọmọ ogun, Olùgbọ́ àdúrà, Onídàájọ́, Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, àti Olùràpadà.b

Láti lè lóye ìtumọ̀ orúkọ Ọlọrun ní kíkún, a tún gbọ́dọ̀ mọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Olùsẹ̀san. Paulu kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe lati wù ú dáadáa, nitori ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọrun wá gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé ó ń bẹ ati pé oun di olùsẹ̀san fún awọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.”—Heberu 11:6.

Jehofa ti ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise kan lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn tí wọ́n bá yàn láti ṣiṣẹ́ sìn ín tọkàntara. Kì í ṣe ìmọtara-ẹni-nìkan láti máa fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ ìlérí kíkọyọyọ náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ìyájú láti fojú wo ara ẹni bí ẹni tí ń gbé ibẹ̀. Mose “fi tọkàntara wo sísan èrè-ẹ̀san naa.” (Heberu 11:26) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí Paulu fi ìtara fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọrun fún àwọn Kristian ẹni àmì òróró. Ó kọ̀wé pé: “Mo ń lépa góńgó naa nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọrun sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jesu.”—Filippi 3:14.

Ìwọ pẹ̀lú lè fojú sọ́nà fún èrè tí Jehofa ṣèlérí fún àwọn tí wọ́n fara dà. Ríretí èrè náà jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìmọ̀ Ọlọrun àti ìfaradà rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Nítorí náà, ṣàṣàrò lójoojúmọ́ lórí àwọn ìbùkún tí Jehofa ní ní ìpamọ́ fún ọ. Mary, tí a mẹ́nu kan ní ìbẹ̀rẹ̀, ti ṣe àkànṣe ìsapá láti ṣe èyí. Ó wí pé: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi, mo gbà láìpẹ́ yìí pé ẹbọ ìràpadà Jesu kàn mí. Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára pé Jehofa bìkítà fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Mo ti jẹ́ Kristian fún èyí tí ó lé ní 20 ọdún, ṣùgbọ́n kìkì lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gba èyí gbọ́ ní ti gidi.”

Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò àtọkànwá lórí Bibeli, Mary, pa pọ̀ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn, ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pé Jehofa bìkítà nípa àwọn ènìyàn rẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àwùjọ nìkan, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú. Èyí dá aposteli Peteru lójú debi tí ó fi kọ̀wé pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé Ọlọrun, nitori ó ń bìkítà fún yín.’ (1 Peter 5:7) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọrun bìkítà nípa rẹ!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìgò aláwọ ni ìkóǹkansí tí a fi awọ ẹranko ṣe láti gba nǹkan bí omi, òróró, wàrà, wáìnì, bọ́tà, àti wàràkàṣì dúró. Ìtóbi àti ìrísí àwọn ìgò ìgbàanì máa ń yàtọ̀ síra lọ́pọ̀lọpọ̀, àwọn kan nínú wọn máa ń jẹ́ àpamọ́wọ́ tí a fi awọ ṣe, àwọn mìíràn sì máa ń ní ọrùn tín-ínrín tí ó ní ìdérí.

b Wo Awọn Onidajọ 11:27; Orin Dafidi 23:1; 65:2; 73:28; 89:26; Isaiah 8:13; 30:20; 40:28; 41:14; tún wo New World Translation of the Holy Scriptures—With References, Àsomọ́ 1J, ojú ìwé 1568, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àjíǹde​—⁠Ẹ̀rí Pé Ọlọrun Bìkítà

Ẹ̀RÍ tí ó múná dóko nípa ọkàn-ìfẹ́ tí Ọlọrun ní nínú ẹnì kọ̀ọ̀kan ni a rí nínú Bibeli ní Johannu 5:​28, 29 pé: “Wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn [Jesu] wọn yoo sì jáde wá.”

Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà mne·meiʹon (ibojì ìrántí) ni a lò níhìn-⁠ín dípò taʹphos (sàréè). Ọ̀rọ̀ náà taʹphos wulẹ̀ gbé èrò ìsìnkú síni lọ́kàn. Ṣùgbọ́n mne·meiʹon dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, àkọsílẹ̀ nípa ẹnì kan tí ó ti kú ni a rántí.

Ní ti èyí, ṣáà ronú nípa ohun tí àjíǹde yóò béèrè lọ́wọ́ Jehofa Ọlọrun. Láti mú ẹnì kan padà wá sí ìwàláàyè, ó ní láti mọ ohun gbogbo nípa onítọ̀hún​—⁠títí kan àwọn ìwà ànímọ́ tí ó jogún àti iyè ìrántí rẹ̀ látòkèdélẹ̀. Kìkì nígbà náà ni a lè mú ẹni náà padà wá bí ó ti ṣe rí gan-⁠an.

Dájúdájú, èyí kò ṣeé ṣe láti ojú ìwòye ènìyàn, ṣùgbọ́n “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọrun.” (Marku 10:27) Ó tilẹ̀ lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn-àyà ẹnì kan. Bí ẹnì kan bá tilẹ̀ ti kú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìrántí Ọlọrun nípa rẹ̀, kò ṣákìí; kò ṣá. (Jobu 14:​13-15) Nípa báyìí, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Abrahamu, Isaaki, àti Jakobu, Jesu lè sọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn tí wọ́n kú pàápàá pé, Jehofa “kì í ṣe Ọlọrun awọn òkú, bíkòṣe ti awọn alààyè, nitori gbogbo wọ́n wà láàyè lójú rẹ̀.”​—⁠Luku 20:⁠38.

Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tí wọ́n ti kú ni Jehofa Ọlọrun ṣì rántí látòkèdélẹ̀. Ẹ wo ẹ̀rí yíyani lẹ́nu tí èyí jẹ́ pé Ọlọrun bìkítà nípa ẹ̀dá ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jesu ní ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni nínú àwọn tí ó wò sàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́