Wíwà ní Ìṣọ̀kan Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọrun Jálẹ̀ Àwọn Àkókò Dídára àti Búburú
Gẹ́gẹ́ bí Michel àti Babette Muller ti sọ ọ́
DÓKÍTÀ náà wí pé: “Mo ní ìròyìn búburú fún yín. Ẹ mọ́kàn kúrò nínú ìgbésí ayé míṣọ́nnárì yín ní Áfíríkà.” Ó kọjú sí ìyàwó mi, Babette, ó wí pé: “O ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú.”
Ẹnú yà wá debi pé a kò lè sọ̀rọ̀. Oríṣiríṣi èrò wá sí wa lọ́kàn. A ti lérò pé ìbẹ̀wò yìí sí ọ̀dọ̀ dókítà yóò jẹ́ kìkì àyẹ̀wò ara ẹni tí yóò kẹ́yìn. A ti ra ìwé ìrìnnà wa padà sí orílẹ̀-èdè Benin, ní Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà. A lérò láti padà síbẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ náà. Ní ọdún 23 tí a ti gbéyàwó, a ti nírìírí àwọn ìgbà dídára àti búburú. Pẹ̀lú ọkàn dídàrú àti ìbẹ̀rù, a gbara dì fún bíbá àrùn jẹjẹrẹ jìjàkadì.
Jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. A bí Michel ní September 1947, a sì bí Babette ní August 1945. Ilẹ̀ Faransé ni a dàgbà sí, a sì ṣègbéyàwó ní 1967. A gbé ní Paris. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní 1968, Babette pẹ́ kí ó tó lọ ibi iṣẹ́. Obìnrin kan wá sí ẹnu ọ̀nà, ó sì fi ìwé pẹlẹbẹ tí ó jẹ́ ti ìsìn lọ̀ ọ́; ó tẹ́wọ́ gbà á. Lẹ́yìn náà, obìnrin náà wí pé: “Mo ha lè padà wá pẹ̀lú ọkọ mi láti wá bá ìwọ àti ọkọ rẹ sọ̀rọ̀ bí?”
Babette ń ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀. Ó fẹ́ kí obìnrin náà máa lọ, nítorí náà ó wí pé, “Kò burú, kò burú.”
Michel ròyìn pé: “N kò lọ́kàn-ìfẹ́ sí ìsìn, ṣùgbọ́n ìwé pẹlẹbẹ náà gba àfiyèsí mi, mo sì kà á. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, obìnrin náà, Joceline Lemoine, padà wá pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Claude. Ọkùnrin náà mọ Bibeli lò dáradára. Ó dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè mi. O wú mi lórí púpọ̀.
“Kátólíìkì paraku ni Babette, ṣùgbọ́n kò ní Bibeli, èyí kò ṣàjèjì láàárín àwọn Kátólíìkì. Rírí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti kíkà á ru ú lọ́kàn sókè púpọ̀. Láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, a mọ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn èrò ìsìn tí a ti kọ́ wa jẹ́ èké. A bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ń kọ́. Ní January 1969, a di Ẹlẹ́rìí tí a batisí fún Jehofa. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, a batisí mẹ́sàn-án lára àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ wa.”
Ṣíṣiṣẹ́ Sìn Níbi Tí A Ti Nílò Àwọn Oníwàásù
Kété lẹ́yìn batisí wa, a ronú pé: ‘A kò ní ọmọ kankan. Èé ṣe tí a kò fi gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?’ Nítorí náà ní 1970, a fi iṣẹ́ wa sílẹ̀, a forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, a sì ṣí lọ sí ìlú kékeré Magny-Lormes, nítòsí Nevers, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Faransé.
Ó jẹ́ iṣẹ́ àyànfúnni tí ó le. Ó ṣòro láti rí ènìyàn tí ó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. A kò rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe, nítorí náà, owó díẹ̀ ni a ní. Nígbà míràn kìkì ànànmọ́ ni a ní fún jíjẹ. Nígbà òtútù, ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù máa ń lọ sílẹ̀ gan-an lábẹ́ ìwọ̀n òfo lórí ìdiwọ̀n ti Celsius. A máa ń pe ìgbà tí a lò níbẹ̀ ní ìgbà màlúù méje tí ó rù.—Genesisi 41:3.
Ṣùgbọ́n Jehofa mú wá dúró. Ní ọjọ́ kan, tí oúnjẹ wa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán, akólẹ́tà gbé àpótí wàrà ńlá kan wá fún wa, tí arábìnrin Babette fi ránṣẹ́. Ní ọjọ́ mìíràn, a padà dé láti òde ìwàásù, a sì bá àwọn ọ̀rẹ́ kan tí wọ́n wa ọkọ̀ wá láti 500 kilómítà láti wá rí wa. Nítorí pé wọ́n ti gbọ́ bí nǹkan ti le koko tó, àwọn arákùnrin wọ̀nyí di oúnjẹ kún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn méjèèjì wá fún wa.
Lẹ́yìn ọdún kan àbọ̀, Society yàn wá gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ní ọdún mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e, a ṣiṣẹ́ sìn ní Nevers, lẹ́yìn náà ní Troyes, àti níkẹyìn ní Montigny-lès-Metz. Ní 1976, a yan Michel láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé.
Ọdún méjì lẹ́yìn náà, nígbà ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn alábòójútó àyíká, a rí lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ Watch Tower Society, tí ń ké sí wa láti lọ sí òkè òkun gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì; lẹ́tà náà sọ pé kí a yàn nínú Chad àti Burkina Faso (tí a mọ̀ sí Upper Volta nígbà náà). A yan Chad. Láìpẹ́ a rí lẹ́tà míràn gbà, pé a yàn wá láti ṣiṣẹ́ lábẹ́ ẹ̀ka ti Tahiti. A béèrè fún Áfíríkà, tí ó jẹ́ àgbáálá ilẹ̀ ńlá, ṣùgbọ́n láìpẹ́, a bá ara wa ní erékùṣù kékeré kan!
Ṣíṣiṣẹ́ Sìn ní Gúúsù Pacific
Tahiti jẹ́ erékùṣù olóoru tí ó rẹwà ní Gúúsù Pacific. Nígbà tí a débẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún àwọn ará wà ní pápá ọkọ̀ òfuurufú láti pàdé wa. Wọ́n fi òdòdó tí a sín bí ìlẹ̀kẹ̀ kọ́ wa lọ́rùn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wá lẹ́yìn ìrìn àjò wa gígùn láti ilẹ̀ Faransé, a láyọ̀ púpọ̀.
Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn tí a dé Tahiti, a wọ ọkọ̀ ojú omi kékeré kan tí a kó àgbọn gbígbẹ kún inú rẹ̀. Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà, a dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa tuntun—erékùṣù Nuku Hiva ní Erékùṣù Marquesas. Nǹkan bí 1,500 ènìyàn ni ń gbé erékùṣù náà, ṣùgbọ́n kò sí ará kankan níbẹ̀. Afi àwa nìkan.
Ojú ṣì dúdú nígbà náà. A ń gbé ilé kéreké kan tí a fi kọnkéré àti ọparun kọ́. Kò sí iná mànàmáná. A ní omi ẹ̀rọ tí ń yọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n omi náà máa ń ní ẹrẹ̀. Fún ìgbà tí ó pọ̀ jù lọ, a máa ń lo omi òjò tí ó jò sínú ihò tí a gbẹ́. Kò sí ọ̀nà ọlọ́dà, kìkì ọ̀nà eléruku tóóró ni ó wà.
A ní láti háyà ẹṣin, láti lè dé àwọn apá tí ó jìnnà ní erékùṣù náà. Pákó ni a fi ṣe gàárì náà—ó ń nira gan-an, pàápàá fún Babette, tí kò tí ì gẹṣin rí. A máa ń mú àdá rìn láti lè fi gé àwọn ọparun tí wọ́n ṣubú sójú ọ̀nà. Ó yàtọ̀ pátápátá sí ìgbésí ayé ní ilẹ̀ Faransé.
A máa ń ṣe ìpàdé ọjọ́ Sunday, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa méjì nìkan ni ó máa ń wá. Lákọ̀ọ́kọ́, a kì í ṣe àwọn ìpàdé yòókù, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì àwa méjì ni ó wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa ń ka àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà pa pọ̀.
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, a pinnu pé kò dára láti máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Michel ròyìn pé: “Mo wí fún Babette pé, ‘A ní láti múra dáradára. Ìwọ yóò jókòó níbẹ̀ yẹn, èmi yóò sì jókòó níhìn-ín. N óò fi àdúrà bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn náà a óò ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun àti Ìpàdé Iṣẹ́-Ìsìn. N óò béèrè ìbéèrè, ìwọ yóò sì dáhùn, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ nìkan ni ẹlòmíràn tí ó wà nínú yàrá.’ Ó dára tí a ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó rọrùn láti fà sẹ́yìn nípa tẹ̀mí nígbà tí kò bá sí ìjọ.”
Ó pẹ́ díẹ̀ kí a tó rí àwọn ènìyàn tí ń wá sí àwọn ìpàdé Kristian wa. Àwa méjì dá nìkan wà fún oṣù mẹ́jọ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ẹnì kan, ẹni méjì, tàbí nígbà míràn ẹni mẹ́ta yóò kún wa. Ní ọdún kan, kìkì àwa méjì ni a bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́wàá, àwọn kan dé, nítorí náà, mo dánu dúró, mo sì tún àsọyé náà bẹ̀rẹ̀.
Lónìí, akéde 42 àti ìjọ 3 ni ó wà ní àwọn Erékùṣù Marquesas. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn wa ni wọ́n ṣe apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ náà, àwọn kan tí a kàn sí nígbà náà lọ́hùn ti ṣe batisí nísinsìnyí.
Àwọn Arákùnrin Wa Ṣeyebíye
A kọ́ láti ní sùúrù ní Nuku Hiva. A ní láti ní sùúrù fún gbogbo nǹkan yàtọ̀ sí àwọn nǹkan kò-ṣeé-mánìí. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá fẹ́ ìwé, o ní láti kọ̀wé fún un, lẹ́yìn náà, ìwọ yóò dúró fún oṣù méjì tàbí mẹ́ta kí ó tó dé.
Ẹ̀kọ́ mìíràn tí a kọ́ ni pé àwọn arákùnrin wa ṣeyebíye. Nígbà tí a bẹ Tahiti wò, tí a sì lọ sí ìpàdé, tí a gbọ́ bí àwọn arákùnrin wa ti ń kọrin, orí wa wú debi pé a bẹ̀rẹ̀ sí i sunkún. Ó lè jẹ́ òtítọ́ pé ó ṣòro láti bá àwọn arákùnrin kan lò, ṣùgbọ́n nígbà tí o bá dá nìkan wà, ìwọ yóò mọrírì bí ó ti dára tó láti wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará. Ní 1980, Society pinnu pé kí a padà sí Tahiti, kí a sì ṣiṣẹ́ sìn nínú iṣẹ́ àyíká. Níbẹ̀, aájò àlejò tọ̀yàyàtọ̀yàyà tí àwọn arákùnrin ní àti ìfẹ́ wọn fún iṣẹ́ ìwàásù fún wa ní ìṣírí púpọ̀. A lo ọdún mẹ́ta nínú iṣẹ́ àyíká ní Tahiti.
Láti Erékùṣù dé Erékùṣù
Lẹ́yìn náà a yàn wá sí ilé àwọn míṣọ́nnárì ní Raïatéa, tí ó jẹ́ erékùṣù Pacific mìíràn, a sì wà níbẹ̀ fún nǹkan bí ọdún méjì. Lẹ́yìn Raïatéa, a rán wa lọ fún iṣẹ́ àyíká nínú àwùjọ erékùṣù Tuamotu. A lo ọkọ̀ ojú omi láti bẹ erékùṣù 25 nínú 80 wò. Ó ṣòro fún Babette. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá rìnrìn àjò pẹ̀lú ọkọ̀ ojú omi ni ó máa ń ṣàìsàn.
Babette sọ pé: “Kò rọrùn rárá! Mo máa ń ṣàìsàn ní gbogbo ìgbà tí a bá wà nínú ọkọ̀ ojú omi. Bí a bá lo ọjọ́ márùn-ún lójú omi, n óò fi ọjọ́ márùn-ún ṣàìsàn. Òògùn kankan kò ràn mí. Síbẹ̀, láìka àìsàn mi sí, mo lérò pé òkun lẹ́wà púpọ̀. Ó jẹ́ ìran tí ó kàmàmà. Ẹja lámùsóò máa ń sáré lé ọkọ ojú omi wa. Wọ́n sábà máa ń fò jáde kúrò nínú omi bí o bá pàtẹ́wọ́!”
Lẹ́yìn ọdún márùn-ún nínú iṣẹ́ àyíká, a tún yàn wa sí Tahiti fún ọdún méjì, a sì tún gbádùn iṣẹ́ wíwàásù. Ìjọ wa fò sókè ní ìlọ́po méjì láti akéde 35 sí 70 láàárín ọdún kan àbọ̀. Méjìlá lára àwọn tí a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni wọ́n ti ṣe batisí nígbà tí ó kù díẹ̀ kí a kúrò. Àwọn kan lára wọn ti di alàgbà nínú ìjọ nísinsìnyí.
A lo àpapọ̀ ọdún 12 ní Gúúsù Pacific. Lẹ́yìn náà a rí lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ Society tí ń sọ pé wọn kò nílò míṣọ́nnárì mọ́ ní erékùṣù náà níwọ̀n bí àwọn ìjọ náà ti fìdí múlẹ̀ dáradára nísinsìnyí. Nǹkan bí 450 akéde ni o wà ní Tahiti nígbà tí a dé ibẹ̀, tí iye tí ó lé ní 1,000 sì wà níbẹ̀ nígbà tí a kúrò.
Áfíríkà Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
A padà sí ilẹ̀ Faransé, àti lẹ́yìn oṣù kan àbọ̀, Society fún wa ní iṣẹ́ àyànfúnni tuntun—orílẹ̀-èdè Benin, ní Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà. A ti fẹ́ láti lọ sí Áfíríká ní ọdún 13 sẹ́yìn, nítorí náà inú wa dùn púpọ̀.
A dé orílẹ̀-èdè Benin ní November 3, 1990, a sì wà lára míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí ó débẹ̀ lẹ́yìn tí a ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìfòfindè ọlọ́dún 14 lórí ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà. Ó mórí yá púpọ̀. Ara wa tètè mọlé nítorí pé ìgbésí ayé níbẹ̀ jọ ti àwọn erékùṣù Pacific. Àwọn ènìyàn náà nífẹ̀ẹ́ gan-an wọ́n sì lẹ́mìí àlejò ṣiṣe. O lè dúró kí o sì bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ lópòópónà.
Ní kìkì ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí a dé sí orílẹ̀-èdè Benin, Babette ṣàkíyèsí kókó kan ní ọmú rẹ̀. Nítorí náà a lọ sí ilé ìtọ́jú aláìsàn kékeré kan tí ó wà nítòsí ọ́fíìsì ẹ̀ka tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Dókítà náà yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì wí pé ó nílò iṣẹ́ abẹ láìpẹ́. Ní ọjọ́ kejì, a lọ sí ilé ìtọ́jú aláìsàn míràn, níbi tí a ti rí dókítà ará Europe kan, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ìtọ́jú obìnrin, tí ó wá láti ilẹ̀ Faransé. Òun pẹ̀lú sọ pé a ní láti lọ sí ilẹ̀ Faransé ní kíákíá kí a baà lè ṣe iṣẹ́ abẹ fún Babette. Ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, a wà ní inú ọkọ òfuurufú láti lọ sí ilẹ̀ Faransé.
Ó dùn wá púpọ̀ láti fi orílẹ̀-èdè Benin sílẹ̀. Nítorí òmìnira ìsìn tí a tún fàyè gbà ní orílẹ̀-èdè náà, inú àwọn arákùnrin dùn púpọ̀ láti ní míṣọ́nnárì tuntun, àwa náà sì láyọ̀ láti wà níbẹ̀. Nítorí náà ọkàn wá dàrú pé a ní láti kúrò, lẹ́yìn lílo ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré ní orílẹ̀-èdè náà.
Nígbà tí a dé ilẹ̀ Faransé, oníṣẹ́ abẹ náà yẹ Babette wò, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó nílò iṣẹ́ abẹ. Àwọn dókítà náà gbé ìgbésẹ̀ kíákíá, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ kékeré kan, wọ́n sì yọ̀ọ̀da kí Babette kúrò ní ilé ìwòsàn ní ọjọ́ kejì. A lérò pé òpin gbogbo ọ̀ràn náà nìyẹn.
Ní ọjọ́ kẹjọ, a pàdé oníṣẹ́ abẹ náà. Ìgbà yẹn ni ó tó sọ fún wa pé Babette ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú.
Nígbà tí ó ń rántí irú ìmọ̀lára tí ó ní nígbà náà, Babette sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ọkàn mi kò dàrú tó ti Michel. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tí a gbọ́ ìròyìn búburú náà, n kò nímọ̀lára kankan. N kò lè sunkún. N kò lè rẹ́rìn-ín. Mo lérò pé n óò kú ni. Lójú tèmi, àrùn jẹjẹrẹ àti ikú jẹ́ ọgbọọgba. Ìṣarasíhùwà mi ni pé, A ní láti ṣe ohunkóhun tí ó bá yẹ.”
Ìjàkadì Pẹ̀lú Àrùn Jẹjẹrẹ
A gbọ́ ìròyìn búburú náà ní ọjọ́ Friday, a sì ṣètò pé kí Babette wá ṣiṣẹ́ abẹ kejì ní ọjọ́ Tuesday. Ọ̀dọ̀ àǹtí Babette ni a ti ń dúró sí, ṣùgbọ́n ara òun náà kò yá, nítorí náà, a kò lè máa bá a lọ láti máa gbé ilé rẹ̀ kékeré.
A ronú ibi tí a lè lọ. Nígbà náà ni a rántí Yves àti Brigitte Merda, tọkọtaya kan tí a ti bá gbé rí. Tọkọtaya yìí ti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí wa. Nítorí náà a tẹ Yves láago, a sì wí fún un pé Babette ní láti ṣiṣẹ́ abẹ àti pé a kò mọ ibi tí a óò máa gbé. A tún sọ fún un pé Michel ń fẹ́ iṣẹ́.
Yves pèsè iṣẹ́ fún Michel ní àgbègbè ilé rẹ̀. Àwọn arákùnrin ṣètìlẹyìn, wọ́n sì fún wa níṣìírí pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìwà onínúure. Wọ́n tún ràn wá lọ́wọ́ ní ti ọ̀ràn ìnáwó. Society san owó ìtọ́jú ìṣègùn Babette.
Iṣẹ́ abẹ tí ó le ni. Àwọn dókítà náà ní láti gé kókó ọlọ́yún àti ọmú náà kúrò. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìtọ́jú oníkẹ́míkà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún Babette láti kúrò ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, ṣùgbọ́n ó ní láti padà ní ọ̀sẹ̀ mẹ́tamẹ́ta fún ìtọ́jú síwájú sí i.
Ní àkókò tí Babette ń gbàtọ́jú ní ilé ìwòsàn, àwọn arákùnrin nínú ìjọ ràn wá lọ́wọ́ púpọ̀. Arábìnrin kan tí òun náà ti ní àrùn jẹjẹrẹ rí fún wa ní ìṣírí púpọ̀. Ó sọ ohun tí Babette ní láti retí fún un, ó sì fún un ní ìtùnú púpọ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, a ṣàníyàn nípa ọjọ́ iwájú wa. Ní fífi òye mọ èyí, Michel àti Jeanette Cellerier mú wa lọ́ sí ilé ìjẹun láti jẹun.
A wí fún wọn pé a ní láti fi iṣẹ́ ìsìn Míṣọ́nnárì sílẹ̀, àti pé a kò ní padà lọ sí Áfíríkà mọ́ láé. Ṣùgbọ́n, Arákùnrin Cellerier wí pé: “Kínla? Ta ní sọ pé ẹ gbọ́dọ̀ fiṣẹ́ sílẹ̀? Ṣé Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni? Ṣé àwọn arákùnrin ní ilẹ̀ Faransé ni? Ta ni onítọ̀hùn?”
Mo dáhùn pé: “Ẹnikẹ́ni kò sọ bẹ́ẹ̀, èmi ni mo ń sọ ọ́.”
Arákùnrin Cellerier wí pé: “Rárá, rárá! Ẹ óò padà!”
Ìtọ́jú onítànṣán, tí ó parí ní òpin August 1991, ni ó tẹ̀ lé ti oníkẹ́míkà. Àwọn dókítà wí pé àwọn kò rí ìṣòro nínú pípadà wa sí Áfíríká, tí Babette bá ti ń wá sí ilẹ̀ Faransé fún àyẹ̀wò déédéé.
A Padà sí Orílẹ̀-èdè Benin
Nítorí náà a kọ̀wé sí orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn, láti béèrè àṣẹ láti padà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. A ń hára gàgà láti gbọ́ èsì wọn. Ó dà bíi pé ọjọ́ náà pẹ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Michel kò lè dúró mọ́, nítorí náà ó tẹ Brooklyn láago, ó sì béèrè bí wọ́n bá rí lẹ́tà wa gbà. Wọ́n sọ pé àwọ́n ti gbà á rò—a lè padà sí orílẹ̀-èdè Benin! Ẹ wo bí a ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa tó!
Ìdílé Merda ṣètò àpèjẹ ńlá kan láti ṣayẹyẹ ìròyìn náà. Ní November 1991, a padà sí orílẹ̀-èdè Benin, àwọn arákùnrin sì fi àsè kan kí wa káàbọ̀!
Ó dà bíi pé Babette ti gbádùn nísinsìnyí. A ti padà sí ilẹ̀ Faransé láti ìgbà dé ìgbà fún àyẹ̀wò ìṣègùn látòkèdélẹ̀, àwọn dókítà kò sì rí ohun tí ó jọ àrùn jẹjẹrẹ mọ́. A láyọ̀ láti padà sẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì wa. A nímọ̀lára pé a nílò wa ní orílẹ̀-èdè Benin, Jehofa sì ti bù kún iṣẹ́ wa. Láti ìgbà tí a ti padà, a ti ran àwọn ènìyàn 14 lọ́wọ́ dórí ṣíṣe batisí. Márùn-ún nínú wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé nísinsìnyí, wọ́n sì ti yan ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. A sì ti rí i tí ìjọ wa kékeré ti dàgbà tí a sì ti pín-in sí ìjọ méjì.
Ní àwọn ọdún yìí wá, a ti ṣiṣẹ́ sin Jehofa gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya, a sì ti gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún, tí a sì tún ti mọ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn àtàtà. Ṣùgbọ́n Jehofa tún ti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti fún wa lókun láti fara da ìṣòro pẹ̀lú àṣeyọrí. Bíi Jobu, a kì í fìgbà gbogbo lóye ìdí tí àwọn nǹkan fi ń ṣẹlẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n a máa ń mọ̀ pé Jehofa máa ń wà níbẹ̀ nígbà gbogbo láti ràn wá lọ́wọ́. Ó rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti sọ pé: “Kíyè sí i, ọwọ́ Oluwa kò kúrú láti gbani, bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò wúwo tí kì yóò fi gbọ́.”—Isaiah 59:1.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Michel àti Babette Muller nínú aṣọ ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Benin
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Iṣẹ́ míṣọ́nnárì láàárín àwọn ará Polynesia ní ilẹ̀ olóoru ti Tahiti