Easter tàbí Ìṣe Ìrántí Èwo ni Ó Yẹ Kí O Ṣe?
BÍ Ọ̀YẸ̀ ti ń là bọ̀ ní April 7, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ yóò kí ọjọ́ mímọ́ wọn jù lọ nínú ọdún káàbọ̀—Easter. Ní ìgbà kan, orúkọ náà tọ́ka sí sáà àsè àti ààwẹ̀ ọlọ́gọ́fà ọjọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú họlidé tí a ń pè ní Septuagesima, tí ó sì parí ni ọjọ́ tí a ń pè ní Ọjọ́ Mẹ́talọ́kan. Lónìí, orúkọ náà ni a ń lò fún ọjọ́ kan ṣoṣo tí a ń ṣèrántí àjíǹde Jesu—Easter Sunday.
Ṣùgbọ́n, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ kan náà yẹn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn yóò pàdé pọ̀ láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, tí a tún mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa. Ó jẹ́ ayẹyẹ kan tí Jesu fúnra rẹ̀ dá sílẹ̀ ní alẹ́ tí ó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Luku 22:19.
Èwo ni ó yẹ kí o ṣe?
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Easter
Orúkọ náà, Easter, tí a ń lò ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, kò sí nínú Bibeli. Ìwé náà, Medieval Holidays and Festivals, sọ fún wa pé “ọjọ́ ìsinmi náà ni a sọ ní orúkọ Abo Ọlọrun Ọ̀yẹ̀ àti ti Ìgbà Ìrúwé ti àwọn kèfèrí, Eostre.” Ta sì ni abo ọlọrun yìí? Ìwé The American Book of Days dáhùn pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtayébáyé ti sọ, Eostre ni ẹni náà tí ó ṣílẹ̀kùn Valhalla láti gba Baldur, tí a ń pè ní Ọlọrun Funfun, nítorí ìwà funfun rẹ̀, tí a sì tún ń pè ní Ọlọrun Oòrun, nítorí iwájú orí rẹ̀ ń pèsè ìmọ́lẹ̀ fún aráyé.” Ó fi kún un pé: “Kò sí àníàní pé ní ìbẹ̀rẹ̀, Ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà kèfèrí àtijọ́, wọ́n sì mú un wọnú ìsìn Kristian. Níwọ̀n bí àjọyọ̀ Eostre ti jẹ́ ayẹyẹ títún ìwàláàyè ṣe nígbà ìrúwé, ó rọrùn láti sọ ọ́ di ayẹyẹ àjíǹde Jesu láti inú òkú, ìhìn rere ẹni tí wọ́n ń wàásù rẹ̀.”
Ohun tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà yìí ṣàlàyé bí àwọn àṣà Easter kan, irú bí ẹyin Easter, ehoro Easter, àti àkàrà gbígbóná alámì àgbélébùú, ti ṣe wáyé ní àwọn ilẹ̀ kan. Ìwé náà, Easter and Its Customs, sọ nípa àṣà ṣiṣe àkàrà gbígbóná alámì àgbélébùú, “ti orí wọn jíjóná tí ó sì ń dán ní àmì . . . àgbélébùú,” pé: “Àgbélébùú jẹ́ àmì abọ̀rìṣà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ó tó rí ìjẹ́pàtàkì ayérayé gbà láti ara àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ Good Friday àkọ́kọ́, búrẹ́dì àti àkàrà ni a sì máa ń fi àmì náà sí ní àwọn àkókò tí ó ṣáájú ìgbà Kristian.”
A kò rí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí a ti mẹ́nu kan àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀rí kankan pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà wọ́n gbọ́. Ní tòótọ́, aposteli Peteru ní kí a “ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí [a] lè dàgbà dé ìgbàlà.” (1 Peteru 2:2) Nítorí náà, kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù fi gba irú àwọn àmì tí ó dájú pé ó jẹ́ ti ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀ sínú ìgbàgbọ́ àti ìṣe wọn?
Ìwé náà, Curiosities of Popular Customs, dáhùn pé: “Ó jẹ́ àṣà tí ó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì ní ìgbàanì láti mú ayẹyẹ kèfèrí tí kò ṣeé pa run náà wọnú ìsìn Kristian níwọ̀n bí wọn kò ti lè mú un kúrò nílẹ̀. Ní ti ọ̀ràn Easter, ìyípadà náà rọrùn ní pàtàkì. Ayọ̀ bí oòrùn tí a dá ṣe ń yọ, àti ayọ̀ bí àwọn ewéko ṣe ń jí pépé láti inú ọ̀gbẹlẹ̀ ìgbà ìrúwé, wá di ayọ̀ ìgbà yíyọ Oòrun òdodo, nígbà àjíǹde Kristi láti inú sàréè. Àwọn kan lára àwọn ohun tí àwọn Keferi ń ṣe tí ń wáyé ní nǹkan bí ọjọ́ Kìíní oṣù May ni a tún yí padà láti bá ayẹyẹ Easter mu.” Dípò yíyẹra pátápátá fún àwọn àṣà kèfèrí àti àwọn ààtò onídán tí ó wọ́pọ̀, àwọn aṣáájú ìsìn fàyè gbà wọ́n, wọ́n sì “mú wọn wọnú ìsìn Kristian.”
O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣùgbọ́n, ìyẹ́n ha burú bí?’ Àwọn kan kò rò bẹ́ẹ̀. Alan W. Watts, tí ó jẹ́ àlùfáà ìsìn Episcopal sọ nínú ìwé rẹ̀, Easter—Its Story and Meaning, pé: “Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ mìíràn bá mú ìsìn kan, irú bí ìsìn Kristian wọ àárín àwọn ènìyàn míràn, wọ́n máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn kan lára àwọn àṣà ìṣẹ̀m̀báyé tí ó jẹ yọ láti inú àwọn ìsìn àtijọ́, wọ́n sì ‘ń fọwọ́ sí i.’ Ó mú àwọn ayẹyẹ tí ó dà bíi pé wọ́n ní ìlànà ayérayé kan náà pẹ̀lú èyí tí Ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni wọnú ààtò ìjọsìn àwọn gbáàtúù.” Lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ti pé ṣọ́ọ̀ṣì wọ́n fọwọ́ sí àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí, tí wọ́n sì ń ṣe wọ́n bí ohun mímọ́ ti tó fún wọn láti tẹ́wọ́ gbà á. Ṣùgbọ́n, wọ́n gbójú fo àwọn ìbéèrè pàtàkì kan. Ojú wo ni Ọlọrun fi ń wo àwọn àṣà wọ̀nyí? Ó ha ti fún wa ní àwọn ìtọ́sọ́nà kankan láti tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn náà bí?
Rírí Ojú Ìwòye Ọlọrun
Christina Hole, nínú ìwé rẹ̀, Easter and Its Customs, sọ pé: “Ọjọ́ Easter, Àsè Àjíǹde Oluwa Wa, jẹ́ ayẹyẹ tí ó ga jù lọ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kristian.” Àwọn òǹkọ̀wé mìíràn gbà bẹ́ẹ̀. Robert J. Myers, nínú ìwé náà, Celebrations, ṣàkíyèsí pé: “Kò sí ọjọ́ mímọ́ tàbí ayẹyẹ kankan nínú ọdún Kristian tí a lè fi ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ wéra pẹ̀lú Easter Sunday.” Ṣùgbọ́n, ìyẹ́n gbé àwọn ìbéèrè kan dìde. Bí ṣiṣe ayẹyẹ Easter bá ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí kò bfi sí àṣẹ kan ní pàtó nínú Bibeli láti máa ṣe ẹ́ẹ̀? Àkọsílẹ̀ kankan ha wà nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu ní ìjímìjí pé wọ́n ṣe Easter Sunday bí?
Kì í ṣe pé Bibeli kùnà láti fúnni ní ìtọ́sọ́nà nípa ohun tí a ní láti ṣe tàbí èyí tí a kò ní láti ṣe. Ní ti èyí, Ọlọrun sọ ojú abẹ níkòó fún orílẹ̀-èdè Israeli, bí a sì ti ṣàkíyèsí ṣáájú, a fún àwọn Kristian ní àwọn ìtọ́ni kedere láti máa bá ṣíṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi nìṣó. (1 Korinti 11:23-26; Kolosse 2:16, 17) Ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ fún wa pé: “Kò sí ìtọ́kasí ṣíṣe àjọ̀dún Easter nínú Májẹ̀mú Tuntun, tàbí nínú àkọsílẹ̀ àwọn Kristian òǹkọ̀wé ní àkókò àwọn aposteli. Ìjẹ́mímọ́ àkókò pàtàkì jẹ́ èrò ìgbàgbọ́ tí kò sí nínú èrò inú àwọn Kristian àkọ́kọ́. . . . Yálà Oluwa tàbí àwọn aposteli rẹ̀, kò fọwọ́ sí ṣíṣe àjọ̀dún yìí tàbí òmíràn.”
Àwọn kan lérò pé ìdùnnú irú àjọ̀dún bẹ́ẹ̀ àti ayọ̀ tí ń mú wá ti tó fún dídá ṣíṣe wọ́n láre. Bí ó tiwu kí ó rí, a lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, nígbà tí àwọn ọmọ Israeli tẹ́wọ́ gba àṣà ìjọsìn àwọn ará Egipti, tí wọ́n sì sọ ọ́ ní orúkọ mìíràn, “àjọ fún Oluwa.” Àwọn pẹ̀lú “jókòó láti jẹ àti láti mu” àti “láti dìde láti ṣiré.” Ṣùgbọ́n àwọn ìṣe wọn bí Jehofa Ọlọrun nínú púpọ̀púpọ̀, ó sì fìyà jẹ wọ́n gidigidi.—Eksodu 32:1-10, 25-28, 35.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe kedere gan-an. Kò lè sí àjọpín kankan láàárín “ìmọ́lẹ̀” àwọn ìgbàgbọ́ tòótọ́ àti “òkùnkùn” ayé Satani; kò lè sí “ìbáramu” kankan láàárín Kristi àti ìjọsìn kèfèrí. A sọ fún wa pé: “‘Nitori naa ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jehofa wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ ninu fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú emi yoo sì gbà yín wọlé.’”—2 Korinti 6:14-18.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí nìkan—kì í ṣe Easter—ni a pa láṣẹ fún àwọn Kristian nínú Bibeli, a ní láti ṣe é. Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè ṣayẹyẹ rẹ̀ lọ́nà yíyẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
“Àjọ fún Oluwa” tí àwọn ọmọ Israeli ṣe bí Ọlọrun nínú púpọ̀púpọ̀
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀yìn ìwé: M. Thonig/H. Armstrong Roberts