ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/1 ojú ìwé 22-26
  • “Ẹ Ṣiṣẹ́, Kì í Ṣe Fún Oúnjẹ Tí ń ṣègbé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Ṣiṣẹ́, Kì í Ṣe Fún Oúnjẹ Tí ń ṣègbé”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Ìṣòtítọ́ Màmá
  • Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi
  • Iṣẹ́ Ìsìn ní Orílé-Iṣẹ́ Àgbáyé
  • Ìdílé Atinilẹ́yìn
  • Ìgbéyàwó àti Ìdílé
  • Oúnjẹ Tẹ̀mí Mú Mi Dúró
  • Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Wíwá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́ Ló Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Wa Kún fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti Ayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Jèhófà Bù Kún Ìpinnu Tí Mo Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/1 ojú ìwé 22-26

“Ẹ Ṣiṣẹ́, Kì í Ṣe Fún Oúnjẹ Tí ń ṣègbé”

GẸ́GẸ́ BÍ DAVID LUNSTRUM ṢE SỌ Ọ́

Èmi àti àbúrò mi ọkùnrin, Elwood, wà lórí pẹpẹ àgùnlé tí ó ga tó mítà mẹ́sàn-án sílẹ̀, a ń kọ àkọlé tuntun sára ògiri ilé iṣẹ́ Watchtower. Ní èyí tí ó lé ní 40 ọdún lẹ́yìn náà, ó ṣì wà níbẹ̀, tí ń rọni pé: “MÁA KA Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN BIBELI MÍMỌ́ LÓJOOJÚMỌ́.” Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ń rí àkọlé yìí bí wọ́n ṣe ń kọjá lórí Afárá Brooklyn olókìkí nì.

ÀWỌN ohun tí mo lè rántí pé mo ṣe lọ́mọdé ní nínú, ọjọ́ ìfọṣọ ìdílé. Ní agogo 5:00 ìdájí, Màmá yóò ti jí, yóò ti máa fọ aṣọ ìdílé wa ńlá, Dádì pẹ̀lú yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra ibi iṣẹ́. Wọn yóò bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ìjíròrò gbígbóná jù lọ tí wọ́n máa ń ní, Dádì yóò jiyàn pé ní èyí tí ó lé ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún sẹ́yìn, ènìyàn ṣàdédé wà, Mọ́mì yóò sì ṣàyọlò Bibeli láti fẹ̀rí hàn pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ ìṣẹ̀dá tààràtà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

Àní nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún méje péré, mo mọ̀ pé Màmá ní ń sọ òtítọ́. Bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ Dádì tó, mo lè rí i pé èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò nawọ́ ìrètí kankan fún ọjọ́ ọ̀la. Ẹ wo bí Màmá yóò ti láyọ̀ tó láti mọ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, méjì nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ àkọlé kan tí ó fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti ka Bibeli, ìwé kan tí ó fẹ́ràn púpọ̀púpọ̀!

Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ìtàn mi ṣe rí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ni mo ṣe ń sọ ọ́. Báwo ni mo ṣe ní àǹfààní irú iṣẹ́ yẹn? Mo ní láti padà sí ọdún 1906, ọdún mẹ́ta ṣáájú kí a tó bí mi.

Àpẹẹrẹ Ìṣòtítọ́ Màmá

Ní àkókò yẹn, Mọ́mì àti Dádì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni, wọ́n sì ń gbé nínú àgọ́ kan ní Arizona. Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan, bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà yẹn, wá, ó sì fún Mọ́mì ní ọ̀wọ́ àwọn ìwé tí Charles Taze Russell kọ, tí a pe orúkọ rẹ̀ ni Studies in the Scriptures. Ó ṣàìsùn láti kà wọ́n, kò pẹ́ kò jìnnà tí ó fi mọ̀ pé èyí ni òtítọ́ náà tí òún ti ń wá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè dúró kí Dádì dé láti ibi tí ó wá iṣẹ́ lọ.

Ohun tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni kò tẹ́ Dádì lọ́rùn, nítorí náà, fún àkókò kan, ó tẹ́wọ́ gba àwọn òtítọ́ Bibeli wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó ṣe, ó ya sí ọ̀nà tirẹ̀ ní ti ìsìn, ó sì tilẹ̀ mú kí nǹkan nira fún Màmá. Síbẹ̀, màmá mí kò dẹ́kun bíbójú tó àìní àwọn ọmọ rẹ̀ nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí.

N kò lè gbàgbé láé bí Màmá ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ láti àjà kejì lálaalẹ́, lẹ́yìn ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára jálẹ̀ gbogbo ọjọ́, láti ka apá kan nínú Bibeli fún wa tàbí láti ṣàjọpín àwọn ohun iyebíye nípa tẹ̀mí pẹ̀lú wa. Òṣìṣẹ́ aláápọn ní Dádì pẹ̀lú, bí mo sì ṣe ń dàgbà sí i, ó kọ́ mi ní iṣẹ́ fífi ọ̀dà dárà. Bẹ́ẹ̀ ni, Dádì kọ́ mi láti ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n Mọ́mì kọ́ mi láti ṣiṣẹ́ fún ‘oúnjẹ tí kì í ṣègbé,’ gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fúnni ní ìtọ́ni.—Johannu 6:27.

Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìdílé wa fìdí kalẹ̀ sí ìlú kékeré Ellensburg ní ìpínlẹ̀ Washington, nǹkan bí 180 kìlómítà sí ìlà oòrùn Seattle. Nígbà tí àwa ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí í bá Màmá lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, inú àwọn ilé àdáni ni a ti ń pàdé. Gbogbo àwọn ọkùnrin kò wá sí àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ̀, nígbà tí a tẹnu mọ́ àìní náà láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n Màmá kò yẹsẹ̀. Èyí mú kí èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn náà wà lọ́kàn mí fún ìgbà pípẹ́ pé, kí n máa gbẹ́kẹ̀ lé ìdarí ètò àjọ Jehofa nígbà gbogbo.

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Bàbá àti Màmá ní ọmọ mẹ́sàn-án. A bí mi ní October 1, 1909, èmi ni ọmọ wọn kẹta. Lápapọ̀, mẹ́fà nínú wa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tí Mọ́mì fi lélẹ̀, a sì di onítara Ẹlẹ́rìí fún Jehofa.

Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi

Nígbà tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ogun ọdún, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jehofa, mo sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ìrìbọmi ní 1927. A ṣe ìrìbọmi náà ní Seattle nínú ilé àtijọ́ kan tí ó jẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Baptist tẹ́lẹ̀. Inú mi dùn pé wọ́n ti wó ilé agogo rẹ̀ lulẹ̀. A sìn wá lọ sí inú adágún omi náà ní ìsàlẹ̀ ilé, níbi tí a ti fún wa ní ẹ̀wù dúdú láti wọ̀. Ó dà bí pé a ń lọ ibi ìsìnkú.

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, mo tún wà ní Seattle, lọ́tẹ̀ yìí ni mo tọ́ ìjẹ́rìí láti ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà wò fún ìgbà àkọ́kọ́. Ẹni tí ń ṣáájú wa darí mi pé, “Ìwọ yóò jẹ́rìí ní apá ibí yìí, èmi yóò sì gba apá ibẹ̀ yẹn.” Láìka ojora tí ó mú mi sí, mo fi ìdì ìwé pẹlẹbẹ méjì síta sọ́dọ̀ obinrin oníwà rere kan. Mo ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà lọ nígbà tí mo padà sí Ellensburg, nísinsìnyí, ni ohun tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 70 ọdún lẹ́yìn náà, irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ ṣì jẹ́ ìdùnnú ńláǹlà fún mi.

Iṣẹ́ Ìsìn ní Orílé-Iṣẹ́ Àgbáyé

Kò pẹ́ kò jìnnà, ẹnì kan tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn rí ní Beteli Brooklyn, orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti Watch Tower Society, fún mi níṣìírí láti yọ̀ǹda ara mi láti ṣiṣẹ́ sìn níbẹ̀. Kété lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa, ìfilọ̀ kan wáyé nínú ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà tí ó fi hàn pé a nílò ìrànlọ́wọ́ ní Beteli. Nítorí náà mo kọ̀wé béèrè fún un. N kò lè gbàgbé bí inú mi ti dùn tó nígbà tí mo gba lẹ́tà náà láti wá fún iṣẹ́ ìsìn Beteli ní Brooklyn, New York, ní March 10, 1930. Bí iṣẹ́ alákòókò kíkún, iṣẹ́ ìgbésí ayé mi ti ṣíṣiṣẹ́ fún ‘oúnjẹ tí kì í ṣègbé,’ ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.

Ẹnì kan lè ronú pé, pẹ̀lú ìrírí mi gẹ́gẹ́ bí afọ̀dà-dárà, wọn yóò yàn mí láti máa fọ̀dà dára sí nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ mi àkọ́kọ́ ni lílo ẹ̀rọ̀ ìdìwé ní ilé iṣẹ́. Bí èyí tilẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ kan tí ń tètè súni, mo gbádùn iṣẹ́ náà fún ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́fà. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo tí a ń fi tífẹ̀tìfẹ́ pè ní ọkọ̀ ogun ojú omi ògbólógbòó ń pèsè àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí ẹ̀rọ agbéwèérìn ń gbé wá sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ wa. Ó ń dùn mọ́ wa láti rí i, bí a bá lè gán àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà pọ̀ kíá bí a ti ń rí wọn gbà láti orí ẹ̀rọ tí ń tẹ̀ wọ́n.

Lẹ́yìn èyí, mo ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ka iṣẹ, títí kan ibi tí a ti ń ṣe ẹ̀rọ tí ń lu rẹ́kọ́ọ̀dù. A ń lo àwọn ẹ̀rọ yìí láti gbé àwọn ìhìn iṣẹ́ Bibeli tí a ti gbà sílẹ̀ sáfẹ́fẹ́ ní ẹnu-ọ̀nà àwọn onílé. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka iṣẹ́ wa ṣètò ẹ̀rọ pẹlẹbẹ kan tí ń lu rẹ́kọ́ọ̀dù, wọ́n sì ṣe é jáde. Kì í ṣe kìkì ìhìn iṣẹ́ tí a ti gbà sílẹ̀ ni ẹ̀rọ tí ń lu rẹ́kọ́ọ̀dù yìí ń gbé jáde, ṣùgbọ́n wọ́n tún ní àwọn àyè àkànṣe tí a lè kó ìwé pẹlẹbẹ àti ìpápánu sí. Ní àpéjọpọ̀ ní Detroit, Michigan, ní 1940, mo ní àǹfààní ṣíṣe àṣefihanni bí a ṣe ń lo irin iṣẹ́ tuntun yìí.

Ṣùgbọ́n, a ń ṣe ju àwọn ojúlówó ẹ̀rọ lọ. A tún ń ṣe àwọn àtúnṣebọ̀sípò pàtàkì nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, tẹ́lẹ̀ rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń fi ohun ọ̀ṣọ́ tí ó ní àgbélébùú àti adé há ẹ̀wù wọn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà a wá lóye pé, orí igi dídúró ṣánṣán ní a kan Jesu mọ́, kì í ṣe orí àgbélébùú. (Ìṣe 5:30) Nítorí náà, a fòpin sí fífi ohun ọ̀sọ́ yìí ha ẹ̀wù. Mo ní àǹfààní láti yọ àwọn pín-ìn-nì náà kúrò. Lẹ́yìn náà, a yọ́ wúrà ara rẹ̀, a sì tà á.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ dídí fọ́fọ́ ọlọ́jọ́ márùn-ún àbọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀. Lọ́jọ́ kan, a fàṣẹ ọba mú 16 nínú wa, a sì jù wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Brooklyn. Èé ṣe? Tóò, nígbà yẹn, a gbà pé gbogbo ìsìn ni ìsìn èké. Nítorí náà, a máa ń gbé àwọn àkọlé tí ó kà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan pé “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” àti ní ẹ̀gbẹ́ kejì pé “Ṣiṣẹ́ Sin Ọlọrun àti Kristi Ọba.” A fi wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí gbígbé àwọn àkọlé wọ̀nyí, ṣùgbọ́n Hayden Covington, agbẹjọ́rò Watch Tower Society, gba ìdúró wa. Nígbà yẹn, a gbé ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òmìnira ìjọsìn wá sí iwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní United States, ó sì múni lọ́kàn yọ̀ láti wà ní Beteli, kí a sì kọ́kọ́ gbọ́ àwọn ìròyìn nípa àjàṣẹ́gun wa.

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a yàn mí sí iṣẹ́ tí ó mú kí n lo ìrírí mi gẹ́gẹ́ bí afọ̀dà-dárà. A gbé ilé iṣẹ́ rédíò wa, WBBR, kalẹ̀ sí Erékùṣù Staten, ọ̀kan nínú àwọn ẹkùn márùn-ún tí a pín New York City sí. Ọwọ̀n alátagbà ilé iṣẹ́ rédíò náà ga ju 60 mítà lọ, a sì fi ọwọ́ wáyà mẹ́ta so ó mọ́lẹ̀. Mo jókòó sórí pátákó pẹlẹbẹ, tí ó fẹ̀ ní 90 sẹ̀ǹtímítà, tí ó sì gùn ní 20 sẹ̀ǹtímítà, tí a fi okùn so rọ̀, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan sì tì mí sókè. Ní jíjókòó sí òkèlókè lórí ìjókòó kékeré yẹn, mo kun àwọn wáyà àti ọwọ̀n alátagbà náà. Àwọn kan ti bi mí léèrè bóyá a kò gbàdúrà púpọ̀ nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ yẹn!

Iṣẹ́ ìgbà ẹ̀rùn kan tí n kò lè gbàgbé láé ni fífọ fèrèsé àti kíkun àwọn férémù fèrèsé ilé iṣẹ́. A ń pè é ní àkókò ìsinmi ìgbà ẹ̀rùn. A ṣe pẹpẹ àgùnlé onígi, pẹ̀lú àgbá kẹ̀kẹ́ tí a so okùn mọ́, a ń gbé ara wa lọ́ sókè sódò nínú ilé alájà mẹ́jọ náà.

Ìdílé Atinilẹ́yìn

Ní 1932, bàbà mi dolóògbé, mo sì ronú bóyá kí ń padà sílé, kí n lọ tọ́jú Mọ́mì. Nítorí náà, ṣáájú oúnjẹ ọ̀sán ní ọjọ́ kan, mo fi ìwé pélébé kan sórí tábìlì tí Arákùnrin Rutherford, ààrẹ Society nígbà náà máa ń jókòó sí. Nínú rẹ̀, mo ní mo fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tí ó gbọ́ àníyàn mi, tí ó sì rí i pé mo ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ṣì ń gbé nílé, ó béèrè pé, “O ha fẹ́ dúró sí Beteli kí o sì máa ṣe iṣẹ́ Oluwa bí?”

Mo dáhùn pé, “Dájúdájú mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.”

Nítorí náà, ó dámọ̀ràn pé kí n kọ lẹ́tà sí Màmá láti rí i bí ó bá gbà pẹ̀lú ìpinnu mi láti dúró. Ohun tí mo ṣe nìyẹn, ó sì kọ̀wé padà ní fífara mọ́ ìpinnu mi pátápátá. Mo mọrírì inú rere àti ìmọ̀ràn Arákùnrin Rutherford.

Ní àwọn ọdún púpọ̀ tí mo fi wà ní Beteli, mo máa ń kọ lẹ́tà sí ìdílé mi déédéé, mo sì máa ń fún wọn níṣìírí láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa, gan-an gẹ́gẹ́ bí Màmá ti ṣe fún mi níṣìírí. Màmá dolóògbé ní July 1937. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìṣírí fún ìdílé wa tó! Kìkì ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin nìkan, Paul àti Esther, àti àbúrò mi obìnrin, Lois, ni wọn kò di Ẹlẹ́rìí. Ṣùgbọ́n, Paul nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa, ó sì pèsè ilẹ̀ fún wa, lórí èyí tí a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àkọ́kọ́ sí.

Ní 1936, àbúrò mi obìnrin, Eva, di aṣáájú ọ̀nà, tàbí oníwàásù alákòókò kíkún. Ní ọdún kan náà yẹn, Ralph Thomas gbé e níyàwó, ní 1939, a yàn wọ́n sí iṣẹ́ arìnrìn àjò láti ṣiṣẹ́ sin ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí lọ sí Mexico, níbi tí wọ́n ti lo ọdún 25 ní ṣíṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ Ìjọba náà.

Ní 1939, àwọn àbúrò mi obìnrin, Alice àti Frances, tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó láti rí Alice tí ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn káńtà ní ẹ̀ka kan ní àpéjọpọ̀ St. Louis ní 1941, tí ń fi bí a ṣe ń lo ẹ̀rọ tí ń lu rẹ́kọ́ọ̀dù hàn, ẹ̀rọ̀ tí mo ṣèrànwọ́ láti ṣe! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Alice ń ní láti dá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rẹ̀ dúró nítorí àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, lápapọ̀, ó ti lò ju 40 ọdún lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Frances tẹ̀ síwájú dé lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní 1944, ó sì ṣiṣẹ́ sìn fún àkókò kan gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Puerto Rico.

Joel àti Elwood, àwọn méjì tí wọ́n kéré jù lọ nínú ìdílé náà, di aṣáájú ọ̀nà ní Montana ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940. Joel ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́, ó sì ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Elwood dara pọ̀ mọ́ mi ní Beteli ní 1944, ní mímú ọkàn mi láyọ̀ gan-an. Kò tí ì pé ọmọ ọdún márùn-ún nígbà tí mo fi ilé sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ ṣáájú, a jọ kọ àkọlé tí ó wà lára ògiri ilé iṣẹ́ yẹn ni, tí ó kà pé, “Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Bibeli Mímọ́ Lójoojúmọ́.” Mo máa ń fìgbà gbogbo ronú nípa iye ènìyàn tí wọ́n ti rí àkọlé yẹn jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, tí a sì ti fún níṣìírí láti ka Bibeli.

Elwood ṣiṣẹ́ sìn ní Beteli títí di 1956 nígbà tí ó gbé Emma Flyte níyàwó. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Elwood àti Emma ṣisẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ní ṣíṣiṣẹ́ sìn fún ìgbà díẹ̀ ní Kenya, Áfíríkà, àti Spain. Àrùn jẹjẹrẹ kọ lu Elwood, ó sì kú ní Spain ní 1978. Emma ṣì wà ní Spain nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà títí di òní.

Ìgbéyàwó àti Ìdílé

Ní September 1953, mo fi Beteli sílẹ̀ láti fẹ́ Alice Rivera, aṣáájú ọ̀nà kan ní Ìjọ Brooklyn Center tí mò ń lọ. Mo jẹ́ kí Alice mọ̀ pé mo ní ìrètí ti ọ̀run, ṣùgbọ́n, ó ṣì ní ọkàn-ìfẹ́ láti fẹ́ mi síbẹ̀síbẹ̀.—Filippi 3:14.

Lẹ́yìn ọdún 23 tí mo ti ń gbé ní Beteli, ìmúra-ẹni-ba-ipò-mu gidi ni ó gbà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ gẹ́gẹ́ bí afọ̀dà-dárà, láti lè gbọ́ bùkátà ara mi àti Alice nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Alice ti fìgbà gbogbo jẹ́ alátìlẹyìn, àní nígbà tí ó tilẹ̀ ní láti fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀ nítorí àìlera. Ní 1954, a ń retí ọmọ wa àkọ́kọ́. Ìbímọ náà kò rọgbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọkùnrin wa, John, lera. Alice pàdánù ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ nígbà iṣẹ́ abẹ náà, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn dókítà kò fi rò pé ó lè rù ú là. Nígbà tí ó ṣe, wọn kò tilẹ̀ lè mọ́ bóyá ó ń mí. Síbẹ̀, ó la òru náà já, láàárín àkókò díẹ̀, ó kọ́fẹ padà.

Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí bàbá Alice kú, a ṣí lọ sí Erékùṣù Long láti lọ́ wà pẹ̀lú màmá rẹ̀. Níwọ̀n bí a kò ti ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, mo máa ń fẹsẹ̀ rìn tàbí kí n wọ bọ́ọ̀sì tàbí ọkọ̀ abẹ́ ilẹ̀. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe fún mi láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ, kí n sì máa gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Ayọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ju àwọn ìrúbọ mi lọ fíìfíì. Ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́—àwọn ẹni bíi Joe Natale lọ́wọ́, ẹni tí ó fi iṣẹ́ ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí eléré baseball tí ì bá mú owó wá sílẹ̀ láti di Ẹlẹ́rìí—ti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀pọ̀ ìbùkún mi.

Ní 1967, bí ipò nǹkan ṣe ń burú sí i ní agbègbè New York, mo pinnu láti mú Alice àti John lọ sí ìlú mi ní Ellensburg, kí wọ́n lè máa gbé níbẹ̀. Nísinsìnyí, ère ni ó jẹ́ fún mi láti rí àwọn ọmọ-ọmọ àti ọmọ-ọmọ-ọmọ màmá mi tí wọ́n ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àwọn kan tilẹ̀ ń ṣiṣẹ́ sìn ní Beteli. John pẹ̀lú aya rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jehofa.

Ó bà mí lọ́kàn jẹ́ pé, mo pàdánù aya mi olùfẹ́, Alice, nínú ikú ní 1989. Jíjẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti ràn mí lọ́wọ́ láti fara da òfò náà. Èmi àti arábìnrin mi, Alice, ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀ nísinsìnyí. Ẹ wo bí ó tí dára tó láti gbé pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i lábẹ́ òrùlé kan náà, kí a sì rí tí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ pàtàkì jù lọ yìí!

Nígbà ìrúwé 1994, mo ṣèbẹ̀wò sí Beteli fún ìgbà àkọ́kọ́ láti nǹkan bí ọdún 25. Ẹ wo irú ìdùnnú tí ó jẹ́ láti rí púpọ̀ lára àwọn tí mo bá ṣiṣẹ́ ní èyí ti ó lé ní 40 ọdún sẹ́yìn! Nígbà tí mo lọ sí Beteli ní 1930, 250 péré ní gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé náà, ṣùgbọ́n lónìí, mẹ́ḿbà ìdílé Beteli ní Brooklyn ti lé ní 3,500!

Oúnjẹ Tẹ̀mí Mú Mi Dúró

Ní ọ̀pọ̀ ìdájí, mo máa ń dọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ lọ sí Odò Yakima tí ó wà lẹ́bàá ilé wa. Láti ibẹ̀, mo lè rí Òkè Rainier gíga lọ́lá tí yìnyín bò mọ́lẹ̀, tí ó ga ju 4,300 mítà lọ sí òfuurufú. Àwọn ẹranko pọ̀ lọ jàra. Nígbà míràn, mo máa ń rí àgbọ̀nrín, mo tilẹ̀ rí elk ní ẹ̀ẹ̀kan.

Àwọn àkókò dídákẹ́ rọ́rọ́, tí mo wà lémi nìkan wọ̀nyí ti yọ̀ọ̀da fún mi láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìpèsè àgbàyanu Jehofa. Mo gbàdúrà fún okun láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọrun wa, Jehofa, pẹ̀lú ìṣòtítọ́. Mo tún máa ń fẹ́ràn láti máa kọrin bí mo ṣe ń dọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ lọ, ní pàtàkì orin náà, “Mímú Ọkàn-Àyà Jehofa Dùn,” tí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ọlọrun awa ti jẹjẹ; lati f’ọgbọn ṣe iṣẹ rẹ. ’Gba naa l’awa yoo lè n’ipa lati m’ọkan ’fẹ rẹ layọ.”

Inú mi dùn pé mo yàn láti ṣe iṣẹ́ kan tí ń mú ọkàn-àyà Jehofa láyọ̀. Àdúrà mi ni pé, kí n lè máa bá iṣẹ́ yìí nìṣó títí tí n óò fi gbà èrè ti ọ̀run tí a ti ṣèlérí. Ìfẹ́ ọkàn mi ni pé àkọsílẹ̀ yìí yóò sún àwọn ẹlòmíràn láti lo ìgbésí ayé wọn nínú ‘ṣíṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí kì í ṣègbé.’—Johannu 6:27.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Elwood ń kọ àkọlé náà “MÁA KA Ọ̀RỌ̀ ỌLỌRUN BIBELI MÍMỌ́ LÓJOOJÚMỌ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Pẹ̀lú Grant Suiter àti John Kurzen, wọ́n ń ṣe àṣefihanni ẹ̀rọ tí ń lu rẹ́kọ́ọ̀dù tuntun náà ní àpéjọpọ̀ ní 1940

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ní 1944, àwa tí a wà nínú òtítọ́ wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún: David, Alice, Joel, Eva, Elwood, àti Frances

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwa ọmọ òbí kan náà tí a wà láàyè, láti ọwọ́ òsì: Alice, Eva, Joel, David, àti Frances

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́