Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
A máa ń gbọ́ nígbà míràn tí àwọn arákùnrin máa ń sọ tàbí gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọrun dé sí ilẹ̀ ayé. Gbólóhùn yìí ha tọ̀nà bí?
Kí a sọ bí ó ṣe rí gan-an, kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ìjọba Ọlọrun jẹ́ ti ọ̀run. Nípa báyìí, aposteli Paulu lè kọ̀wé pé: “Oluwa yoo dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú yoo sì gbà mí là fún ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run. Oun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé ati láéláé. Àmín.”—2 Timoteu 4:18; Matteu 13:44; 1 Korinti 15:50.
A gbé Ìjọba náà kalẹ̀ ní ọ̀run ní 1914, a kì yóò sì gbé e wá sí Paradise tí a óò mú padà wá sí ilẹ̀ ayé tàbí sí ibòmíràn. Jesu Kristi ni Ọba Ìjọba náà. Gẹ́gẹ́ bí Ọba, Jesu ní ọlá àṣẹ lórí àwọn áńgẹ́lì. Nítorí náà, ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun ní ọ̀run ni ibi agbára ìṣàkóso rẹ̀ tí ó tọ́. Àwọn Kristian ẹni àmì òróró dara pọ̀ mọ́ ọn ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà.—Efesu 1:19-21; Ìṣípayá 5:9, 10; 20:6.
Nígbà náà, èyí ha túmọ̀ sí pé a kò ní láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ tí a ti rí nínú apá kan Àdúrà Oluwa fún Ọlọrun mọ́, tí ó wí pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́-inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀-ayé pẹlu?” (Matteu 6:10) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àdúrà yẹn tọ́, ó sì ní ìtumọ̀ kíkún síbẹ̀síbẹ̀.
Ìjọba Ọlọrun yóò gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà onípinnu sí ilẹ̀ ayé yìí, ohun tí a sì ní lọ́kàn nìyí nígbà tí a bá ń gbàdúrà, tí a sì ń lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fara jọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Àdúrà Oluwa. Fún àpẹẹrẹ, Danieli 2:44 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ìjọba náà yóò “wá” láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, yóò sì gba ìṣàkóso ilẹ̀ ayé yìí. Ìṣípayá 21:2 sọ̀rọ̀ nípa Jerusalemu Tuntun tí ń sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀run wá. Jerusalemu Tuntun náà para pọ̀ jẹ́ 144,000 Kristian ẹni àmì òróró tí yóò jẹ́ ìyàwó Kristi. Wọ́n tún jẹ́ ajogún pẹ̀lú Jesu nínú Ìjọba náà. Nítorí náà Ìṣípayá 21:2 ṣàpèjúwe yíyí àfiyèsí wọn sí ilẹ̀ ayé, èyí tí yóò yọrí sí ìbùkún ńláǹlà fún aráyé olùṣòtítọ́.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Títí di ìgbà tí a bá mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu wọ̀nyí àti àwọn mìíràn ṣẹ, yóò tọ́ láti máa bá a nìṣó ní gbígbàdúrà sí Jehofa Ọlọrun ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé, “Kí ìjọba rẹ dé.” Ṣùgbọ́n a ní láti fi sọ́kàn pé, Ìjọba náà kì yóò wá sórí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé ní ti gidi. Ìṣàkóso Ìjọba náà wà ní ọ̀run, kì í ṣe lórí ilẹ̀ ayé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Ilẹ̀ Ayé: A gbé e karí fọ́tò NASA