ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 6/15 ojú ìwé 3
  • O Ha Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní Ti Gidi Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Ha Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní Ti Gidi Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Rírìn Pẹ̀lú Ọlọ́run Tòótọ́ Náà
  • “Ẹ Ní Ìfẹ́ni Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Fún Ara Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Kíkọ́ Ìfẹ́ Títayọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 6/15 ojú ìwé 3

O Ha Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní Ti Gidi Bí?

ỌLỌ́RUN sọ pé: “Kò sí ènìyàn kan tí í rí mi, tí í sì í yè.” (Ẹ́kísódù 33:20) Síwájú sí i, bẹ̀rẹ̀ láti àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, kò tí ì sí ẹ̀rí pé ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí ì ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ojúkojú pẹ̀lú rẹ̀ rí. Kò ha dà bíi pé ó ṣòro—pé kò ṣeé ṣe pàápàá—láti mú ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ dàgbà fún ẹnì kan tí ìwọ kò tí ì rí lójúkojú tàbí gbóhùn rẹ̀ rí? Ó ha ṣeé ṣe ní ti gidi láti ní ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá àgbáyé bí?

Kò yẹ kí iyè méjì wà pé ó ṣeé ṣe láti mú ìfẹ́ni ọlọ́yàyà ti ara ẹni dàgbà fún Ọlọ́run. Nínú Diutarónómì 6:5, a kà pé a fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àṣẹ pé: “Kí ìwọ kí ó sì fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ.” Jésù Kristi lẹ́yìn náà tún fi ìdí òfin yìí múlẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì fi kún un pé: “Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkínní.” (Mátíù 22:37, 38) Bíbélì yóò ha gbà wá níyànjú láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bí irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ kò bá ṣeé ṣe bí?

Ṣùgbọ́n Jèhófà ha retí pé kí á nífẹ̀ẹ́ òun kìkì nítorí pé ó pa á láṣẹ bí? Rárá o. Ọlọ́run dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ pẹ̀lú agbára láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. A kò fi agbára mú Ádámù àti Éfà wọnú ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run mú kí àyíká ipò tí ó bára dé yí wọn ká, nínú èyí tí wọn yóò ti mú ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ dàgbà fún un. Àwọn ni yóò pinnu—láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tàbí láti fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ádámù àti Éfà yàn láti ṣọ̀tẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:6, 7) Ṣùgbọ́n, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn yóò ní agbára fún mímú ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn dàgbà.

Rírìn Pẹ̀lú Ọlọ́run Tòótọ́ Náà

Fún àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì, a sọ̀rọ̀ Ábúráhámù pé ó jẹ́ “ọ̀rẹ́” Ọlọ́run. (Jákọ́bù 2:23) Síbẹ̀, ó dájú pé kì í ṣe Ábúráhámù ni ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé mìíràn tí wọ́n fi ojúlówó ìfẹ́ni hàn fún Jèhófà, tí wọ́n sì ‘bá Ọlọ́run tòótọ́ náà rìn.’—Jẹ́nẹ́sísì 5:24; 6:9; Jóòbù 29:4; Sáàmù 25:14; Òwe 3:32.

A kò bí ìfẹ́ àti ìfẹ́ni fún Ọlọ́run mọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Wọ́n mú un dàgbà ni. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Nípa mímọ̀ ọ́n pẹ̀lú orúkọ ara ẹni rẹ̀, Jèhófà. (Ẹ́kísódù 3:13-15; 6:2, 3) Nípa lílóye wíwà rẹ̀, àti ipò jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀. (Hébérù 11:6) Nípa ṣíṣàṣàrò lóòrèkóòrè lórí àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 63:6) Nípa sísọ èrò ọkàn wọn nínú lọ́hùn-ún jáde nínú àdúrà sí Ọlọ́run. (Sáàmù 39:12) Nípa kíkọ́ nípa ìwà rere rẹ̀. (Sekaráyà 9:17) Nípa mímú ìbẹ̀rù gbígbámúṣé láti má ṣe mú un bínú dàgbà.—Òwe 16:6.

O ha lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí o sì bá a rìn bí? Ní tòótọ́, o kò lè rí Ọlọ́run tàbí gbọ́ ohùn rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, Jehofa ń ké sí ọ láti di ‘àtìpó nínú àgọ́ rẹ̀,’ ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 15:1-5) Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún ọ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, báwo ni o ṣe lè mú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ àti onífẹ̀ẹ́ni dàgbà pẹ̀lú rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́