Kíkọ́ Ìfẹ́ Títayọ
Kosovo, Bosnia, Lẹ́bánónì, àti Ireland. Àwọn orúkọ táa sábà máa ń gbọ́ nínú ìròyìn láwọn ọdún àìpẹ́ yìí nìwọ̀nyí. Táwọn èèyàn bá ti gbọ́ wọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀, jíju bọ́ǹbù, àti ìpànìyàn ló máa ń mú wá sọ́kàn wọn. Àmọ́ ṣá o, rògbòdìyàn tí ẹ̀sìn, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, tàbí èyí tí àwọn nǹkan mìíràn tó fa ìyàtọ̀ máa ń dá sílẹ̀ kì í ṣe nǹkan tuntun rárá. Àní, mélòó la ó kà nínú wọn, wọ́n sì tí fi onírúurú ìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ jẹ aráyé.
NÍGBÀ táwọn èèyàn rí i pé jálẹ̀ ìtàn ni ogun ti ń jà, ohun tí ọ̀pọ̀ wá parí èrò sí ni pé ogun ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, àti pé ìwà táa dá mọ́ àwa èèyàn ni pé ká máa kórìíra ara wa. Àmọ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fi kọni. Ìwé Mímọ́ là á mọ́lẹ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ó hàn gbangba pé Ẹlẹ́dàá fẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
Bíbélì tún fi hàn pé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Èyí wá túmọ̀ sí pé a dá ènìyàn lọ́nà tó fi lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ, èyí tó sì ta yọ jù lọ níbẹ̀ ni ìfẹ́. Nígbà tó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, kí ló wá dé táwọn èèyàn fi kùnà pátápátá láti fìfẹ́ hàn síra wọn jálẹ̀ ìtàn? Bíbélì tún ṣàlàyé ohun tó fà á. Ìdí ni pé tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Àbájáde rẹ̀ ni pé, gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ wọn wá jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Róòmù 3:23 ṣàlàyé pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” Ànímọ́ tí Ọlọ́run fún wa láti nífẹ̀ẹ́ wá di èyí tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé bà jẹ́. Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn ò lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́ ni? Ìrètí wo ló wà pé a ó tún lè gbé lálàáfíà pẹ̀lú ọmọnìkejì wa, tí a ó sì tún máa fìfẹ́hàn síra wa?
A Gbọ́dọ̀ Kọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ pé pẹ̀lú gbogbo bí nǹkan ṣe rí, ó ṣì ṣeé ṣe fún ènìyàn láti nífẹ̀ẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi ní kí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ wu òun sa gbogbo ipá wọn láti fìfẹ́ hàn dé gbogbo ibi tí agbára wọn bá gbé e dé. Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ló jẹ́ kí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe yìí hàn kedere nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ó sọ àṣẹ tó tóbi jù lọ nínú Òfin táa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sọ pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́.”—Mátíù 22:37-40.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló rò pé ó ṣòro gan-an láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan táwọn ò lè rí, àwa ènìyàn sì rèé, a ò lè rí Jèhófà Ọlọ́run nítorí pé Ẹ̀mí ni. (Jòhánù 4:24) Síbẹ̀, ojoojúmọ́ là ń gbádùn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe, nígbà tó jẹ́ pé àwọn ohun dáradára tó dá fún àǹfààní wa ni gbogbo wá gbára lé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù la òtítọ́ yìí mọ́lẹ̀ nígbà tó sọ pé: “[Ọlọ́run] kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:17.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa là ń jàǹfààní láti inú àwọn ìpèsè Ẹlẹ́dàá lọ́nà kan tàbí òmíràn, síbẹ̀ ìwọ̀nba kéréje làwọn tó ń fi ìmoore hàn sí i tàbí tí wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí èyí, ó yẹ kí a gbé gbogbo ohun rere tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa yẹ̀ wò, kí a sì wá ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ àgbàyanu tó sún un ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fòye mọ ọgbọ́n amúnikúnfún-ẹ̀rù àti agbára tí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wá ní. (Aísáyà 45:18) Lékè gbogbo rẹ̀, ó ní láti ràn wá lọ́wọ́ láti rí i bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ tó, ní ti pé kò wúlẹ̀ fún wa láǹfààní àtiwàláàyè nìkan, àmọ́, ó tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ọ̀pọ̀ ohun tó ń mú kí ìgbésí ayé lárinrin.
Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àìlóǹkà onírúurú òdòdó rírẹwà tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé. Ohun àgbàyanu ló mà jẹ́ fún wa o, pé ó tún fún wa lágbára àtirí àwọn nǹkan mèremère wọ̀nyí, kí wọ́n sì máa mú inú wa dùn! Bákan náà, Ọlọ́run tún pèsè oríṣiríṣi oúnjẹ́ amáralókun láti gbé ẹ̀mí wa ró. Ẹ wo bó ṣe jẹ́ olóye tó, tó fi jẹ́ pé ó tún dá agbára ìtọ́wò mọ́ wa ká lè máa gbádùn àwọn oúnjẹ tí à ń jẹ! Ǹjẹ́ ìwọ̀nyí kì í ṣe ẹ̀rí tó hàn gbangba pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa ní tòótọ́ àti pé ire wa ló ń fẹ́ lọ́jọ́ gbogbo?—Sáàmù 145:16, 17; Aísáyà 42:5, 8.
Yàtọ̀ sí pé Ẹlẹ́dàá náà fi ara rẹ̀ hàn wá nípasẹ̀ “ìwé ìṣẹ̀dá,” ó tún fi irú Ọlọ́run tí òun jẹ́ hàn wá nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. Ìdí ni pé inú Bíbélì la kọ ọ̀pọ̀ àwọn ohun onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe láyé ọjọ́un sí, ibẹ̀ náà la sì tún kọ àwọn ìbùkún rẹpẹtẹ tó ṣèlérí láti ṣe fún ìran ènìyàn lọ́jọ́ iwájú sí. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18; Ẹ́kísódù 3:17; Sáàmù 72:6-16; Ìṣípayá 21:4, 5) Lékè gbogbo rẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ìfẹ́ títóbi jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí aráyé—ìyẹn ni, fífúnni ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo láti jẹ́ Olùràpadà wa, kí a lè di òmìnira kúrò lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:8) Láìsí àní-àní, bí a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni bí a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ látọkàn wá yóò ṣe máa pọ̀ sí i.
Kíkọ́ Báa Ṣe Ń Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ènìyàn Ẹlẹgbẹ́ Wa
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ, ní àfikún sí nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa, àti èrò inú wa, a tún ní láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. Ní tòótọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run sọ ọ́ di dandan fún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàlàyé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Ó tún tẹnu mọ́ ọn síwájú sí i pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí. Àṣẹ yìí ni a sì gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, pé ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní láti máa nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.”—1 Jòhánù 4:11, 20, 21.
Inú ayé kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ti ń fi ẹ̀mí tèmi-làkọ́kọ́ hàn là ń gbé lóde òní, nípa jíjẹ́ “olùfẹ́ ara wọn,” bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀. (2 Tímótì 3:2) Nítorí náà, báa bá fẹ́ kọ́ ìfẹ́ títayọ, a ní láti sa gbogbo ipá wa láti yí èrò inú wa padà, kí a sì fara wé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, dípò tí a ó fi máa tẹ̀ lé ọ̀nà onímọtara-ẹni-nìkan tí àwọn ènìyàn lápapọ̀ ń gbé. (Róòmù 12:2; Éfésù 5:1) Kódà, Ọlọ́run tún “jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú,” ó sì “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” Níwọ̀n bí Baba wa ọ̀run ti fi irú àpẹẹrẹ títayọ bẹ́ẹ̀ lélẹ̀ fún wa, a gbọ́dọ̀ tiraka láti jẹ́ onínúure sí gbogbo ènìyàn, kí a sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè fẹ̀rí hàn pé a jẹ́ ‘ọmọ Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.’—Lúùkù 6:35; Mátíù 5:45.
Nígbà mìíràn, irú àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti di olùjọsìn Ọlọ́run òtítọ́. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, abilékọ kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbìyànjú láti sọ ìhìn iṣẹ́ Bíbélì fún aládùúgbò rẹ̀ kan, ṣùgbọ́n bí ẹní lé ajá ni obìnrin náà ṣe lé e dànù. Àmọ́, kò jẹ́ kí ìwà tí ó hù yẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló túbọ̀ ń finúure hàn sí aládùúgbò rẹ̀ náà tó sì ń ràn án lọ́wọ́. Ìgbà kan wà tó ran aládùúgbò rẹ̀ náà lọ́wọ́ láti kó lọ sí ilé mìíràn. Ó tún ṣètò pé kí ẹnì kan sin aládùúgbò rẹ̀ yìí lọ sí pápákọ̀ òfuurufú láti lọ pàdé àwọn ìbátan aládùúgbò náà. Nígbà tó yá, aládùúgbò náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó di Kristẹni kan tó jẹ́ aláápọn láìfi inúnibíni líle koko ti ọkọ rẹ̀ ṣe sí i pè. Dájúdájú, irú àwọn ọ̀nà ìfìfẹ́ hàn wọ̀nyẹn ń fi ìpìlẹ̀ ìbùkún ayérayé lélẹ̀.
Táa bá fẹ́ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, a ó gbà pé kì í ṣe nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ànímọ́ títayọ táa ní ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ọ̀pọ̀ àléébù àti ìkù-díẹ̀-káàtó. Nígbà náà, àwa náà gbọ́dọ̀ kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa láìka bí àwọn àléébù wọ́n ṣe lè pọ̀ tó sí. Tí a bá fi kọ́ra láti máa rí àwọn ànímọ́ rere tí àwọn ẹlòmíràn ní, tí a sì mọrírì wọn, dípò tí a ó fi máa wo àwọn àléébù wọn, yóò túbọ̀ rọrùn fún wa láti nífẹ̀ẹ́ wọn. Kódà ìfẹ́ tí a óò ní fún wọn kò ní jẹ́ èyí tí a gbé karí ìlànà nìkan, yóò jẹ́ ìfẹ́ ọlọ́yàyà àti ìfẹ́ tó lágbára tó máa ń wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.
Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Rẹ Dàgbà
Ó ṣe pàtàkì pé kí a mú ìfẹ́ àti ìbárẹ́ dàgbà, lára àwọn ohun tó sì lè jẹ́ kó ṣeé ṣe ni jíjẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tí kì í ṣàbòsí. Àwọn kan máa ń fi àwọn àléébù wọn pa mọ́, kí wọ́n lè dà bí ẹni rere lójú àwọn tí wọ́n fẹ́ bá dọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, èéfín nìwà, rírú ní í rú, nígbà táwọn èèyàn bá wá mọ irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ níkẹyìn, ṣe ni irú ìwà àbòsí bẹ́ẹ̀ yóò lé wọn sá. Nítorí náà, kò yẹ ká máa fìwà wa pa mọ́, káwọn èèyàn má bàa mọ irú ẹni táa jẹ́—kódà báa tilẹ̀ ní àwọn àlèébù tí a ń làkàkà láti ṣẹ́pá. Èyí lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́.
Fún àpẹẹrẹ, ìyá àgbàlagbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nínú ìjọ kan tó wà níbi Jíjìnnà Réré ní Ìlà Oòrùn ayé kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé. Síbẹ̀, kì í fi èyí pa mọ́. Fún àpẹẹrẹ, ó là á mọ́lẹ̀ pé, òun ò lè ṣàlàyé fáwọn èèyàn bí wọn ṣe lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ láti inú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti ìtàn pé ọdún 1914 ni Ìgbà Àwọn Kèfèrí dópin.a Ṣùgbọ́n, ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ìtara tó ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, títí kan ìfẹ́ àti ìwà ọ̀làwọ́ tó ní fún àwọn ará, débi pé tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi ń tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí ẹni ọ̀wọ́n nínú ìjọ náà.
Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, àwọn èèyàn ò kì í fojú tó dáa wo ká máa fi ìfẹ́ni hàn ní gbangba; ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn ènìyàn ni pé bí wọ́n tiẹ̀ fẹ́ kí èèyàn pàápàá, gbogbo ẹ kò gbọ́dọ̀ kọjá káàárọ̀ oò jíire. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára ká jẹ́ni tó mọ̀wàá hù, ká sì máa gba ti àwọn ẹlòmíràn rò, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà ọmọlúwàbí dí wa lọ́wọ́ tàbí kó mú wa ti ilẹ̀kùn ìfẹ́ tó yẹ ká ní fún àwọn ẹlòmíràn. Jèhófà kò tijú láti sọ irú ìfẹ́ tó ní fáwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ láyé ọjọ́un, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ fún wọn pé: “Ìfẹ́ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni mo fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.” (Jeremáyà 31:3) Bákan náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Tẹsalóníkà pé: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹsalóníkà 2:8) Nítorí náà, báa ti ń gbìyànjú láti mú ojúlówó ìfẹ́ dàgbà fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, dípò tí a ó fi tẹ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ rì, ohun tó bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu jù ni kí a fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn bó ṣe rí lọ́kàn wa gan-an.
Ó Ń Béèrè Ìsapá Tí Kò Lópin
Kíkọ́ bí a ṣe ń nífẹ̀ẹ́ tí a sì ń fi hàn sí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ojúṣe kan tí kò lópin. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń béèrè ọ̀pọ̀ ìsapá látọ̀dọ̀ wa, nítorí pé a ní láti sakun gan-an ni ká tó lè ṣẹ́pá àìpé tiwa fúnra wa àti ká tó lè dènà ipa lílágbára tí ayé aláìnífẹ̀ẹ́ yìí ń ní lórí wa. Àmọ́, èrè jìngbìnnì tí èyí ń mú wá mú kí ìsapá yìí tó bẹ́ẹ̀ kó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Mátíù 24:12.
Kódà, láyé aláìpé yìí pàápàá, a lè gbádùn ìbátan tó sunwọ̀n sí i pẹ̀lú àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa, tí yóò sì yọrí sí ọ̀pọ̀ ayọ̀, àlàáfíà, àti ìtẹ́lọ́rùn fún àwa fúnra wa àti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Nípa ṣíṣe irú ìsapá bẹ́ẹ̀, a ó lè fara wa hàn bí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìrètí àgbàyanu ti wíwàláàyè títí láé nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run. Lékè gbogbo rẹ̀, nípa kíkọ́ ìfẹ́ títayọ yìí, Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ yóò lè tẹ́wọ́ gbà wá, yóò sì lè bù kún wa, nísinsìnyí àti títí ayérayé!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé kíkún rẹ́rẹ́, wo Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 132 sí 135.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
A lè fi ìfẹ́ Kristẹni hàn nípa jíjẹ́ onínúure
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
UN PHOTO 186226/M. Grafman