ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 10/15 ojú ìwé 4-7
  • Báwo Ni Kìràkìtà Àtipẹ́láyé Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Kìràkìtà Àtipẹ́láyé Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Omi Ìsúnniṣe àti Apilẹ̀ Àbùdá Tọ́jú Ara—Wọ́n Ha Tó Gbọ́kàn Lé Bí?
  • Ṣé Ìlànà Nanotechnology àti Sísọ Òkú Di Yìnyín Ni Ojútùú Rẹ̀?
  • Ibo Ló Yẹ Ká Gbọ́kàn Wa Lé?
  • Lájorí Ohun Tí Ń Fa Ọjọ́ Ogbó àti Ikú
  • Ìrètí Tòótọ́
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Párádísè Kan Lórí Ilẹ̀ Ayé
  • Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó?
    Jí!—2006
  • Ọmọ Aráyé Ń Wá Ọ̀nà Tí Wọ́n Lè Gbà Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ǹjẹ́ Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Lè Mú Ìyè Àìnípẹ̀kun Wá?
    Jí!—2000
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 10/15 ojú ìwé 4-7

Báwo Ni Kìràkìtà Àtipẹ́láyé Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí?

ÀWỌN kan gbà gbọ́ pé ẹgbẹ̀rúndún tuntun ni yóò pèsè ojútùú sí ọ̀ràn àtipẹ́láyé táráyé ti ń bá yí tipẹ́tipẹ́. Dókítà Ronald Klatz jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Òun ni ààrẹ Àjọ Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Lórí Oògùn Agbógunti Ọjọ́ Ogbó ní Amẹ́ríkà, àjọ kan tó jẹ́ ti àwọn oníṣègùn àti àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ láti mú kí ọjọ́ ayé ènìyàn túbọ̀ gùn sí i. Òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pinnu pé àwọn ó lo ọdún tó pọ̀ gan-an láyé. Dókítà Klatz sọ pé: “Mo ń wò ó pé ó kéré tán, máa lo àádóje ọdún láyé. A gbà gbọ́ pé ọjọ́ ogbó kì í ṣe ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti wà báyìí tó lè dín bí ara ṣe ń di hẹ́gẹhẹ̀gẹ kù, kó dín àrùn tí a ń pè ní ọjọ́ ogbó báyìí kù, kó dáwọ́ wọn dúró, tàbí kó tiẹ̀ yí gbogbo rẹ̀ padà pátápátá.” Kí Dókítà Klatz pàápàá bàa lè pẹ́ láyé, nǹkan bí egbòogi ọgọ́ta ló ń kó jẹ lójoojúmọ́.

Fífi Omi Ìsúnniṣe àti Apilẹ̀ Àbùdá Tọ́jú Ara—Wọ́n Ha Tó Gbọ́kàn Lé Bí?

Fífi omi ìsúnniṣe tọ́jú ara jẹ́ ọ̀nà kan tí ń fini lọ́kàn balẹ̀. Àyẹ̀wò tí wọ́n fi omi ìsúnniṣe tí a mọ̀ sí DHEA ṣe dà bí pé ó dín dídarúgbó àwọn ẹranko tí wọ́n fi ń ṣèwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kù.

Nígbà tí Aftonbladet, tó jẹ́ ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ nílẹ̀ Sweden ń sọ̀rọ̀ nípa omi ìsúnniṣe tó wà nínú ewéko, èyí táa pè ní kinetin, ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Dókítà Suresh Rattan, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Aarhus, Denmark, tó sọ pé: “Àwọn àyẹ̀wò tí a ṣe ní ibi ìwádìí fi hàn pé àwọn sẹ́ẹ̀lì awọ ara ènìyàn tí a fi sínú kinetin kò hunjọ bó ṣe máa ń rí nígbà tí ènìyàn bá ń dàgbà. Jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, ṣe ni wọ́n ń dán gbinrin.” Àwọn kòkòrò tí wọ́n lo omi ìsúnniṣe kan náà fún fi ìpín ọgbọ̀n sí márùndínláàádọ́ta pẹ́ láyé jù iye ọdún tí wọ́n sábà máa ń lò lọ.

Fífi omi ìsúnniṣe melatonin tọ́jú àwọn èkúté làwọn kan ti sọ pé o fi ohun tí ó tó ìpín márùndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún mú kí ọjọ́ orí irú àwọn èkúté bẹ́ẹ̀ gùn sí i. Láfikún sí i, ara èkúté náà jà yọ̀yọ̀ sí i, ó ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún, ó sì túbọ̀ lókun sí i.

Àwọn tí ń ṣalágbàwí omi ìsúnniṣe tí ń darí bí ènìyàn ṣe ń dàgbà (hGH) sọ pé ó ń mú kí awọ èèyàn máa dán, kí èèyàn túbọ̀ níṣu lára, ó ń fi kún ìfẹ́ tó ní sí ìbálòpọ̀, ó ń jẹ́ kó túbọ̀ máa láyọ̀, ó ń jẹ́ kí orí ẹni jí pépé sí i, kéèyàn sì lókun, kó máa ta kébékébé.

Àwọn kan tún gbójú lé apilẹ̀ àbùdá. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé àwọn lè darí bí ekòló kan tàbí aràn kan yóò ṣe pẹ́ láyé tó nípa yíyí apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ padà. Àní, wọ́n ti mú kí ẹ̀mí àwọn kan lára wọn fi ìlọ́po mẹ́fà gùn ju bí ẹ̀mí wọn ṣe máa ń gùn tó. Èyí mú kí wọ́n máa retí pé àwọn lè rí apilẹ̀ àbùdá kan náà lára ènìyàn, káwọn sì yí i padà. Ìwé ìròyìn Time ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Dókítà Siegfried Hekimi ti Yunifásítì McGill, ní Montreal, tó sọ pé: “Tí a bá lè rí gbogbo apilẹ̀ àbùdá to ń pinnu bí ọjọ́ orí ènìyàn ṣe ń gùn tó, ṣe ni à bá kàn tún wọn ṣe díẹ̀, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ẹ̀mí ènìyàn gùn sí i.”

Ó pẹ́ tí àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ti mọ̀ pé ìràlẹ̀rálẹ̀ àwọn chromosome tí a sábà máa ń pè ní telomere, máa ń dín kù sí i ní gbogbo ìgbà tí sẹ́ẹ̀lì kan bá ń mú sẹ́ẹ̀lì mìíràn jáde. Nígbà tí nǹkan bí ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún telomere bá ti pòórá, sẹ́ẹ̀lì náà kò ní lágbára mọ́ láti mú òmíràn jáde, yóò sì kú. Èròjà kan tó ń jẹ́ telomerase lè dá telomere padà sí bó ṣe gùn tó tẹ́lẹ̀, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ fún sẹ́ẹ̀lì náà ní àyè láti máa pín ara rẹ̀. Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ sẹ́ẹ̀lì ló ti jẹ́ pé a kì í jẹ́ kí èròjà yìí lo agbára rẹ̀, tí yóò sì wá tipa bẹ́ẹ̀ di èyí tí kò gbéṣẹ́ mọ́, àmọ́, wọ́n ti fi èròjà telomerase tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì kan, èyí ti wá mú kí wọ́n tètè dàgbà, kí wọ́n sì ti pín ara wọn níye ìgbà tó pọ̀ gan-an ju bí wọ́n ti máa ń pín ara wọn lọ.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn olùwádìí sọ, èyí ló mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rò pé ó lè ṣeé ṣe fáwọn láti gbógun ti àwọn àrùn tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ogbó. Fífi àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń sọ ara dọ̀tun táa ti fi telomerase sọ di “sẹ́ẹ̀lì tí kò lè kú” rọ́pò àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń sọ ara dọ̀tun, tí ń bẹ nínú ara ńkọ́? Ọ̀mọ̀wé William A. Haseltine sọ pé: “Èyí jẹ́ èròǹgbà kan tí àlàyé rẹ̀ yéni yékéyéké nípa bí ènìyàn kò ṣe ní kú mọ́, èyí tí a ó bẹ̀rẹ̀ sí ní mú wá sójútáyé ní àádọ́ta ọdún sígbà táa wà yìí.”—The New York Times.

Ṣé Ìlànà Nanotechnology àti Sísọ Òkú Di Yìnyín Ni Ojútùú Rẹ̀?

Ìlànà nanotechnology, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ó lè rọ ẹ̀rọ bíńtín, tí yóò sì ní agbára tó wà nínú ẹ̀rọ ràgàjì jẹ́ ohun mìíràn táwọn kan gbọ́kàn lé. Àwọn tó ń wo sàkun ẹ̀ka ìmọ̀ yẹn gbà pé lọ́jọ́ iwájú, yóò ṣeé ṣe láti ṣe àwọn ẹ̀rọ bíńtín tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ tó kéré gan-an ju sẹ́ẹ̀lì lọ, tí yóò lè máa tún àwọn sẹ́ẹ̀lì, ẹran ara, àti ẹ̀ya ara tó ti ń gbó ṣe, kí ó sì sọ wọ́n dọ̀tun. Níbi ìpàdé àpérò kan tí wọ́n ṣe láti gbógun ti ọjọ́ ogbó, olùwádìí kan sọ pé ó lè ṣeé ṣe fún àwọn oníṣègùn ọ̀rúndún kọkànlélógún láti fi ìlànà nanotechnology sọ ènìyàn di ẹni tí kò lè kú.

Ọgbọ́n sísọ òkú di yìyín jẹ́ èyí tí à ń ṣe pẹ̀lú èrò pé yóò ṣeé ṣe fún sáyẹ́ǹsì láti mú àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ti kú náà sọjí padà, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú wọn tún padà wà láàyè. Ó ṣeé ṣe láti sọ gbogbo ara di yìnyín tàbí láti sọ ọpọlọ nìkan di yìnyín. Ọkùnrin kan tiẹ̀ sọ aṣọ bẹ́ẹ̀dì di yìnyín. Aṣọ bẹ́ẹ̀dì kẹ̀? Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó sọnù ló ni ín, ó sì láwọn sẹ́ẹ̀lì awọ ara àti àwọn irun díẹ̀ lára. Ó sọ wọ́n di yìnyín kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ báa lè padà wà láàyè bí sáyẹ́ǹsì bá báṣẹ́ wọn dórí lílo ìwọ̀nba sẹ́ẹ̀lì díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo pàápàá lára ènìyàn láti fi tún onítọ̀hún dá.

Ibo Ló Yẹ Ká Gbọ́kàn Wa Lé?

Gẹ́gẹ́ báa ti dá wa, èèyàn máa ń fẹ́ láti wà láàyè ni, a kì í fẹ́ẹ́ kú. Nítorí náà, bí sáyẹ́ǹsì ṣe ń tẹ̀ síwájú lórí ọ̀ràn yìí làwọn èèyàn ń gbóṣùbà fún wọn, tí wọ́n sì ń retí pé nǹkan yóò ṣẹnuure. Àmọ́, títí di báyìí, kò sí ẹ̀rí kankan pé DHEA, kinetin, melatonin, hGH, tàbí àwọn èròjà mìíràn lè dí ènìyàn lọ́wọ́ dídarúgbó. Àwọn olùṣelámèyítọ́ èrò yìí bẹ̀rù pé kò sí ohun mìíràn tí fífi èròjà telomerase sínú sẹ́ẹ̀lì máa ṣe ju pé kí ó kó àwọn sẹ́ẹ̀lì tó lè fa àrùn jẹjẹrẹ ranni. Àti pé títí di ìsinsìnyí, ìlànà nanotechnology àti sísọ òkú di yìnyín ṣì jẹ́ àròsọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, kò tíì dòótọ́ rárá.

Sáyẹ́ǹsì ti mú kí ẹ̀mí àwọn kan gùn sí i, ó ti mú kí ara àwọn kan le sí i, ó sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá, àmọ́, kò lè fún ẹnikẹ́ni ní ìyè ayérayé láé. Èé ṣe? Ní ṣókí, ìdí ni pé lájorí okùnfà ọjọ́ ogbó àti ikú ré kọjá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí èèyàn hùmọ̀ rẹ̀.

Lájorí Ohun Tí Ń Fa Ọjọ́ Ogbó àti Ikú

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé ọjọ́ ogbó àti ikú dà bí ohun kan tí a ti fi sínú apilẹ̀ àbùdá wa lọ́nà kan ṣáá. Ìbéèrè tó wá ń jẹyọ ní pé: Nígbà wo ni wọ́n wọnú apilẹ̀ àbùdá wa, báwo ni wọ́n ṣe wọ̀ ọ́, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi wọ̀ ọ́?

Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tó rọrùn—bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ ọ́ bí ẹní ń sọ̀rọ̀ nípa apilẹ̀ àbùdá tàbí ásíìdì DNA. Róòmù 5:12 kà pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”

Ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé. Gbogbo ohun tí ara rẹ fẹ́ láti lè wà láàyè, kó sì gbádùn ìyè ayérayé la ti ṣètò sínú rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ìyè ayérayé sinmi lórí ohun kan. Ádámù ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Orísun ìyè, ìyẹn Ẹlẹ́dàá rẹ̀, kí ó sì ṣègbọràn sí i, kí ó lè máa wà láàyè títí lọ fáàbàdà.—Jẹ́nẹ́sísì 1:31; 2:15-17.

Ádámù yàn láti ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá náà. Ohun tí Ádámù dọ́gbọ́n fìwà rẹ̀ sọ ni pé, ohun tí ì bá dára jù lọ ni pé kí ènìyàn máa ṣàkóso ara rẹ̀ láìsí pé Ọlọ́run ń dá sí wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dẹ́ṣẹ̀. Láti ìgbà yẹn lọ ló ti dà bíi pé a yí apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ padà. Kàkà tí Ádámù ì bá fi jẹ́ kí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ jogún ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ rẹ̀, ikú àti ẹ̀ṣẹ̀ ló fi sílẹ̀ fún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 19; Róòmù 6:23.

Ìrètí Tòótọ́

Àmọ́, ipò yẹn kò ní wà bẹ́ẹ̀ títí láé. Róòmù 8:20 sọ pé: “A tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí.” Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ènìyàn, ló yọ̀ǹda kí ikú jọba lórí ènìyàn nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí i, àmọ́, bó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́ ló tún fi ìpìlẹ̀ kan tó fúnni ní ìrètí lélẹ̀.

Ìpìlẹ̀ yìí wá hàn gbangba nígbà tí Jésù Kristi wá sórí ilẹ̀ ayé. Jòhánù 3:16 sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Àmọ́, báwo ni lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ṣe lè gbà wá lọ́wọ́ ikú?

Tó bá jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fa ikú, a jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ kúrò kí ikú tó kúrò nìyẹn. Nígbà ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí Kristi, Jòhánù Olùbatisí sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòhánù 1:29) Jésù Kristi kò dẹ́ṣẹ̀ kankan rárá. Nítorí èyí, a kò yọ̀ǹda kí ikú tó jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jọba lé e lórí. Síbẹ̀síbẹ̀, ó gbà kí wọ́n pa òun. Èé ṣe? Nítorí pé, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa.—Mátíù 20:28; 1 Pétérù 3:18.

Nípa sísan gbèsè yẹn, ọ̀nà àtiwàláàyè láìkú rárá wá ṣí sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Sáyẹ́ǹsì lè ṣàlékún mímú kí ẹ̀mí wa gùn dé ààyè kan, àmọ́, lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ni ojúlówó ọ̀nà àtirí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù jèrè irú ìyè bẹ́ẹ̀ lókè ọ̀run, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ àtàwọn díẹ̀ mìíràn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwa táa lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ni yóò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run bá mú Párádísè orí ilẹ̀ ayé padà bọ̀ sípò.—Aísáyà 25:8; 1 Kọ́ríńtì 15:48, 49; 2 Kọ́ríńtì 5:1.

Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Párádísè Kan Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ọkùnrin kan béèrè pé: “Ẹni mélòó ni yóò kà á sí ohun yíyẹ láti wà láàyè lákòókò kan tí wọn ò ní kú mọ́?” Ṣé ìwàláàyè láìsí ikú yóò súni? Bíbélì mú un dá wa lójú pé kò ní súni. “Ohun gbogbo ni ó ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” (Oníwàásù 3:11) Àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run dá pọ̀ yanturu, wọ́n sì jẹ́ onírúurú débi pé yóò máa fà wá lọ́kàn mọ́ra ṣáá ni, tí yóò máa mórí wa gbé pẹ́pẹ́, tí yóò sì máa fún wa láyọ̀ níwọ̀n ìgbà táa bá wà láàyè—àní táa bá wà láàyè títí láé.

Ọkùnrin kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹyẹ kan táa mọ̀ sí Siberian Jay pè é ní “ọ̀rẹ́ àrà ọ̀tọ̀, tí ń múnú ẹni dùn” ó sì sọ pé wíwo ẹyẹ náà lásán jẹ́ ọ̀kan nínú ohun tí òun tíì gbádùn jù lọ láyé. Bó ṣe ń kọ́ nípa ẹyẹ náà sí i, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń rí i bó ṣe fani mọ́ra tó. Ó sọ pé kódà lẹ́yìn tóun lo ọdún méjìdínlógún lórí rẹ̀, òun ò tíì mọ ìgbà tí ẹ̀kọ́ náà yóò parí. Bí ẹyọ ẹyẹ kan bá lè fa onílàákàyè ènìyàn kan mọ́ra, tó ta á jí, tó sì ń fún un láyọ̀ láàárín ọdún méjìdínlógún tó fi kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa rẹ̀, wá finú wòye ayọ̀ tí a ń fojú sọ́nà fún àti ìtẹ́lọ́rùn tó gbọ́dọ̀ wà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa gbogbo ìṣẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé lápapọ̀.

Fojú inú wo gbogbo ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì dídùn mọ́ni tí yóò ṣí sílẹ̀ fún ẹnì kan tó láǹfààní láti lo àkókò bó ṣe fẹ́. Fojú inú wo gbogbo ibi fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí a ó lè rìnrìn àjò lọ, àti gbogbo àwọn ẹni iyì ẹni ẹ̀yẹ tí a óò bá pàdé. Gbìyànjú láti fojú inú wo bí yóò ti ṣeé ṣe fún wa láti ronú nípa àwọn nǹkan, tí a ó ṣe wọ́n, tí a ó sì gbé wọn kalẹ̀. Àǹfààní táa ní láti ṣe àwọn nǹkan fúnra wa, ká sì lò wọ́n, kò ní lópin. Nígbà táa bá ronú nípa ọ̀pọ̀ yanturu ohun tí Ọlọ́run da, ó hàn gbangba pé àfi táa bá lè wà láàyè títí ayé nìkan la fi lè rí àkókò tí ó tó fún wa láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe nínú ìgbésí ayé.

Bíbélì fi hàn pé àwọn tó ti kú pàápàá yóò tún wà láàyè títí láé nípasẹ̀ àjíǹde. (Jòhánù 5:28, 29) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìtàn tí a kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn yóò wá ṣe kedere sí wa nígbà táa bá rí àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí gan-an tí wọ́n ń sọ bó ṣe rí fún wa, tí wọ́n sì ń dáhùn àwọn ìbéèrè wa. Ronú nípa gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn sáà ìtàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn tó jí dìde yóò máa sọ fún wa.—Ìṣe 24:15.

Nígbà tóo bá ń ronú nípa àkókò yẹn, o lè mọyì bí Jóòbù tó jíǹde yóò ṣe tún ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jóòbù 14:1 sọ. Bóyá ohun tí yóò sọ dípò ohun tó sọ tẹ́lẹ̀ ni pé: ‘Ènìyàn, tí obìnrin bí, ń wà láàyè títí láé báyìí, ó sì kún fún ìtẹ́lọ́rùn.’

Fún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí wọ́n sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, ẹ̀mí gígùn tó wà fún àkókò tó lọ kánrin kì í ṣe àlá kan tí kò lè ṣẹ. Yóò ṣẹ láìpẹ́. Ọjọ́ ogbó àti ikú yóò dópin. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 68:20, tó sọ pé: “Ti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì ni àwọn ọ̀nà àbájáde kúrò lọ́wọ́ ikú.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mu káwọn èèyàn túbọ̀ gbà pé yóò ṣeé ṣe láti pẹ́ láyé sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àfi táa bá lè wà láàyè títí ayé nìkan la fi lè rí àkókò tí ó tó fún wa láti ṣe gbogbo àwọn ohun tó ṣeé ṣe nínú ìgbésí ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́