Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Lè Mú Ìyè Àìnípẹ̀kun Wá?
LỌ́PỌ̀ ỌDÚN sẹ́yìn, irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè jọ bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ ní báyìí o, àwọn èèyàn kan ti ń wò ó pe ó lè ṣeé ṣe. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ti ṣeé ṣe fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti sọ ìgbésí ayé irú eṣinṣin àti aràn kan báyìí di ìlọ́po méjì èyí tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ nípa títa àwọn ọgbọ́n kan, èyí táwọn kan rò pé wọ́n lè lò fún èèyàn pẹ̀lú.
Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ohun tín-tìn-tín inú ara ènìyàn máa ń kú, ó sì níye àsìkò tí wọ́n lè fi pín sí wẹ́wẹ́ mọ. Lẹ́yìn èyí, wọn ò ní pín mọ́. Ọ̀nà tó ń gbà ṣiṣẹ́ yìí ni wọ́n fi wé aago tó ń sọ ìgbà táwọn èèyàn máa darúgbó àtìgbà tí wọ́n máa kú. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń báṣẹ́ lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láti yí ọwọ́ aago yẹn padà.
Àbá èrò orí tó wọ́pọ̀ kan sọ pé ohun tó máa ń fa dídi arúgbó wà ní ìparí àwọn fọ́nrán DNA, lápá ibì kan tí wọ́n ń pè ní telomere. Àwọn telomere yìí ni wọ́n fi wé rọ́bà kékeré tó máa ń wà lẹ́nu okùn bàtà káwọn okùn náà má bàa di yẹtuyẹtu. Àkíyèsí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ni pé gbogbo ìgbà táwọn ohun tín-tìn-tín yìí bá ti pín, ńṣe ni àwọn telomere yìí máa ń kúrú sí i bí ìgbà tí okùn àbẹ́là bá ń jó lọọlẹ̀. Tó bá yá, á wá dà bí ẹni pé àwọn telomere yìí ti kúrú débi tí àwọn ohun tín-tìn-tín yìí ò fi ní lè pín mọ́. Àmọ́ nítorí ti èròjà kan tó wà níbẹ̀, telomere kì í dín kù rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àbá èrò orí náà wí, ó lè wá ṣeé ṣe káwọn ohun tín-tìn-tín náà máa pín nìṣó láìdáwọ́dúró. Ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá ní ilé iṣẹ́ kan tó ń rí sí ọ̀ràn yìí sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ tí a máa ronú kàn án pé ó ṣeé ṣe kéèyàn máà kú nìyí.” Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà.
Ohun Tó Fa Ikú
Kò sí àní-àní pé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni àwọn èèyàn tó gba Bíbélì gbọ́ ti ní ìgbàgbọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dá ènìyàn máa gbé lọ títí ayé. Kì í wá ṣe inú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni ìgbẹ́kẹ̀lé wọn wà o, àmọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run ni, Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Gíga Jù Lọ, tó dá ohun gbogbo.—Sáàmù 104:24, 25.
Bíbélì fi hàn pé ikú ènìyàn kì í ṣe ara ète Ẹlẹ́dàá rárá. Àwòrán Ọlọ́run ni a dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, a sì fi wọ́n sínú Párádísè. Wọ́n jẹ́ pípé, wọn ò kù síbì kan, lára àti ní èrò inú. Fún ìdí yìí, wọ́n fojú sọ́nà láti máa gbé títí lọ gbére lórí ilẹ̀ ayé. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún wọn náà kúkú nìyẹn. Ó ní kí wọ́n bímọ, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ kí wọ́n mú Párádísè gbòòrò káàkiri ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:8, 9, 15.
Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta ti fi hàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù mọ̀ pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà, ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ìyẹn nìkan kọ́ o, nípa ṣíṣe àìgbọràn, ó mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò ì tíì bí. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé ẹ̀ rèé, ó ní: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, ara Ádámù kò tún pé mọ́ nítorí ó ti ṣẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí darúgbó díẹ̀díẹ̀, ó sì kú. Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ jogún àbùkù yìí.
Ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù àti ìdájọ́ Ọlọ́run tó tẹ̀ lé e tipa báyìí mú ikú wá sórí ẹ̀dá ènìyàn. Kò sóhun tí ẹ̀dá ènìyàn lè ṣe tó lè yí ìdájọ́ yẹn padà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìtẹ̀síwájú ló ti wáyé nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn ọ̀rọ̀ Mósè tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó kọ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn ṣì jẹ́ òtítọ́ pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.”—Sáàmù 90:10.
Ìpèsè Tí Jèhófà Ṣe Láti Fúnni ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
Inú wa dùn pé ìrètí ń bẹ! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní báyìí gbogbo ènìyàn ló ń kú, kì í ṣe ète Jèhófà pé kí ipò yìí máa bá a lọ títí láé. Nígbà tó jẹ́ pé Ádámù àti Éfà yẹ fún ikú, Ọlọ́run mọ̀ pé púpọ̀ lára àwọn ọmọ wọn tí wọn kò tíì bí yóò mọrírì àbójútó onífẹ̀ẹ́ òun. Ó ṣètò fún ìwàláàyè tí kò lópin lórí ilẹ̀ ayé fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Àmọ́ báwo lèyí á ṣe ṣeé ṣe?
Kì í ṣe pé kí àwọn èèyàn mọ àṣírí bí DNA ṣe ń ṣiṣẹ́ ni yóò mú kí èyí ṣeé ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ẹ̀bùn tí Jèhófà yóò fi fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti mọ̀ pé àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà nílò ìtúsílẹ̀, ó pèsè ọ̀nà láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun fún wọn, ìyẹn ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Ìpèsè yìí ni Jésù tọ́ka sí nígbà tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Jésù jẹ́ ènìyàn pípé gẹ́gẹ́ bíi ti Ádámù. Láìdà bí Ádámù, Jésù ṣègbọràn sí Ọlọ́run láìkù síbì kan. Jésù wá lè tipa bẹ́ẹ̀ fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ rúbọ láti kájú ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Nípa ìgbésẹ̀ onífẹ̀ẹ́ yìí, èyí tó bá ìdájọ́ òdodo mu rẹ́gí, á ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ádámù láti bọ́ lọ́wọ́ ikú. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù ni yóò gba ẹ̀bùn Ọlọ́run ti ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 5:18, 19; 1 Tímótì 2:5, 6.
Ká ní ó ṣeé ṣe fún ènìyàn láti káwọ́ àìpé kí wọ́n sì fún ara wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun ni, kì bá tí sí ìdí fún ìràpadà. Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, òkun, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn, Ẹni tí ń pa òótọ́ mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 146:3-6.
Látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìyè àìnípẹ̀kun yóò ti wá, kì í ṣe látinú ìwádìí sáyẹ́ǹsì. Gbogbo ohunkóhun tí Ọlọ́run bá fẹ́ láti ṣe ló lè ṣe, yóò sì ṣé é ní àṣeparí. “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:37.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]
© Charles Orrico/SuperStock, Inc.