ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 12/8 ojú ìwé 24-25
  • Òun Ló Gba Ẹ̀mí Rẹ̀ Là

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òun Ló Gba Ẹ̀mí Rẹ̀ Là
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Títẹ̀lé Ìmọ̀ràn
  • Ọ̀rẹ́ Tí Kò Ṣeé Yà ni Wá
    Jí!—1997
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Òwò Àwọn Apanilẹ́kún-Jayé
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé Ti Di Òwò Tó Kárí Ayé
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 12/8 ojú ìwé 24-25

Òun Ló Gba Ẹ̀mí Rẹ̀ Là

Ìtẹ̀jáde “Jí!” ti January 8, 2000, gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde nípa “Jíjí Èèyàn Gbé.” William Louis Terrell sọ pé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ inú “Jí!” yìí ló gba ẹ̀mí òun là.

AGOGO mẹ́wàá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá díẹ̀ ni ní òwúrọ̀ ọjọ́ Friday, March 10, 2000, nígbà tí Joseph C. Palczynski Kékeré yọ ìbọn sí Terrell, tó sì gbé e sá lọ kúrò ní ilé rẹ̀. Àwọn ìmọ̀ràn tí àwọn ògbógi pèsè nípa ohun tó yẹ kéèyàn ṣe tí wọ́n bá jí i gbé la kọ sísàlẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ inú Jí!, tí Terrell sọ pé òun ń rántí ní gbogbo àkókò tí òun wà nínú ìṣòro náà:

“Ṣe ohun tí wọ́n bá ní kí o ṣe; má ṣagídí. Wọ́n sábà máa ń fojú àwọn òǹdè tó bá ń ṣagídí gbolẹ̀, wọ́n sì lè pa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n fi ìyà jẹ òun nìkan.

“Má ṣe páyà. Rántí pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a ń jí gbé ló ń là á já.”

“Tó bá ṣeé ṣe, fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú wọn, kí o sì gbìyànjú láti bá wọn jíròrò. Bí àwọn ajínigbé náà bá wò ẹ́ gẹ́gẹ́ bí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n lè má ṣe ẹ́ léṣe tàbí kí wọ́n má pa ẹ́.

“Hùwà bí ọmọlúwàbí tí o bá fẹ́ béèrè ohun tí o nílò lọ́wọ́ wọn [ìyẹn, àwọn ajínigbé].”

“Àjọṣe . . . jẹ́ ààbò fún àwọn tí wọ́n ń jí gbé, gẹ́gẹ́ bí ìwé Criminal Behavior ṣe ṣàlàyé pé: ‘Bí àwọn tí a jí gbé àti àwọn tó jí wọn gbé bá ṣe wá mọ ara wọn dáadáa sí ni wọ́n á ṣe máa fẹ́ràn ara wọn sí i. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wá fi hàn pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, kò jọ pé ọ̀daràn náà máa ṣe ẹni tó jí gbé ní jàǹbá.’”

William Terrell, tí í ṣe ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sa gbogbo ipá rẹ̀ láti tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn yìí láàárín ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí mẹ́rìnlá tí ẹnì kan fi gbé e dè, tí ìbọn sì wà lọ́wọ́ ẹni náà ní èyí tó pọ̀ jù lọ lára àkókò náà. Ìrírí agbonijìgì náà bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́ lẹ́yìn tí Palczynski kan ilẹ̀kùn ilé Terrell ní ìgbèríko kan nítòsí Interstate Highway 95, níbi tí ọkọ̀ tí Palczynski jí gbé takú sí nígbà tí epo tán nínú rẹ̀.

Lẹ́yìn tí Terrell gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àlejò náà, ó sọ pé òun yóò ràn án lọ́wọ́. Palczynski ní kó fún òun ní omi, kó sì gbé òun dé ìlú Baltimore, ní ìpínlẹ̀ Maryland, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Terrell sọ pé òun á ṣètò kí ẹnì kan gbé e dé ìlú Fredericksburg, ní Ìpínlẹ̀ Virginia, níbi tí yóò ti wọ ọkọ̀ tí yóò gbé e dé ibi tó ń lọ. Nígbà tí Terrell gbé omi wá fún àlejò náà, ńṣe ló yọ ìbọn sí i. Palczynski pàṣẹ pé kí Terrell gbé òun lọ síbi tí òun ń lọ.

Títẹ̀lé Ìmọ̀ràn

Nígbà tí Terrell ń gbé Palczynski lọ ní àárín ọ̀nà Interstate 95, ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ń fún un pé kó máà sáré ju ohun tí òfin béèrè lọ, kí ó má sì wakọ̀ lọ́nà tí yóò fi pe àfiyèsí sáwọn. Terrell sinmẹ̀dọ̀, ó sì ń bá Palczynski, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kó mọ̀ pé òun bìkítà nípa rẹ̀ gan-an ni àti nípa ohun tó mú kí àwọn pàdé. Palczynski sọ pé ní ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, òun lọ wo ọ̀rẹ́bìnrin òun tó ń jẹ́ Tracy, tó já òun sílẹ̀. Níbẹ̀ ló ti yìnbọn pa àwọn ọ̀rẹ́ Tracy méjì àti aládùúgbò rẹ̀ kan tí wọ́n kò fẹ́ jẹ́ kí Tracy tẹ̀ lé e. Níkẹyìn, Tracy sá lọ.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, nígbà tí Palczynski ń gbìyànjú láti fipá gba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, ọta ìbọn rẹ̀ ba ọmọ ọdún méjì kan, ó sì fọ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ náà. Bákan náà ló tún rọ̀jò ọta lu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí Jennifer Lyn McDonel ń wà. Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀kan lára ọta náà pa á, òmíràn sì ba àga ìjókòó ọmọ wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún kan, ṣùgbọ́n ọmọ náà kò sí lórí àga náà. Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Jennifer àti ọkọ rẹ̀, Thomas, ń lọ, àwọn méjèèjì ló sì ní iṣẹ́ nípàdé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Sarah Francis, tí í ṣe ìyá Jennifer, ṣàlàyé pé: “Alẹ́ ọjọ́ yẹn nìkan ni wọn kò gbé ọmọ wọn jòjòló lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. [Ká ní wọ́n gbé e lọ ni] ọ̀fọ̀ àwọn méjèèjì là bá máa ṣe.”

Bí Terrell ti rọra ń bá ẹni tó jí i gbé náà sọ̀rọ̀, Palczynski sọ pé òun kò ní in lọ́kàn láti ṣe ẹnikẹ́ni léṣe àti pé òun nífẹ̀ẹ́ Tracy gan-an, òun sì fẹ́ kí àwọn jọ wà pọ̀. Terrell ṣàlàyé pé: “Mo sọ fún un pé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ná, àmọ́ ìyókù dọwọ́ ẹ̀, mo sì rọ̀ ọ́ pé kí ó fúnra rẹ̀ lọ bá àwọn agbèfọ́ba. Mo sọ fún un pé màá wá kí i ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, màá sì bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n sọ nínú ìròyìn pé láti ìgbà tí Palczynski ti jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ọdún 1987, oṣù mẹ́wàá péré ni kò fi sí lẹ́wọ̀n tàbí ní ibi ìtọ́jú alárùn ọpọlọ tàbí níbi tí wọ́n ti ń wò ó bóyá ọ̀daràn kan yóò yí ìwà padà.

Nípa lílo ìrírí tí Terrell ti ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni alàgbà tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́, kò yé jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin tí ìdààmú bá náà, nípa lílo àwọn àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an láti inú Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ ìrírí ọkùnrin rere kan, Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì, tí ọkàn rẹ̀ kò kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó Ùráyà, tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun Dáfídì. Nígbà tí obìnrin náà lóyún fún Dáfídì, ó ṣètò láti rí i pé Ùráyà kú sójú ogun. Nígbà tí wọ́n fọgbọ́n ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fún un, ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó sì jèrè ojú rere Ọlọ́run padà.—2 Sámúẹ́lì 11:2-12:14.

Terrell bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú ìsáǹsá náà, ó sì pè é ní orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Joby. Nígbà tí wọ́n dúró ní ilé ìtajà kan tí Palczynski ti rán Terrell pé kó lọ ra oúnjẹ àti tẹlifíṣọ̀n kan tó ṣeé gbé káàkiri wá, ó ní tó bá ta àwọn èèyàn lólobó òun á pa àwọn èèyàn sí i. Nígbà tí Terrell rí i pé ara ìsáǹsá náà kò balẹ̀, ó gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìròyìn nípa ìwà ọ̀daràn Palczynski nínú ìròyìn agogo mọ́kànlá lórí tẹlifíṣọ̀n, Palczynski gbá Terrell mọ́ra, ó sì yọ́ kọ́rọ́ wọ àárín ìlú Baltimore, kò sì rí i mọ́.

Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, wọ́n ká Palczynski mọ́ inú ilé kan tó kó àwọn tó jí gbé sí. Wọ́n ké sí Terrell, ìsáǹsá yìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúnàádúrà pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí, nígbà tó sì di March 22, àwọn ọlọ́pàá fipá wọ ilé náà, wọ́n sì yìnbọn pa Palczynski. Àmọ́, kò sí ẹlòmíràn tó fara pa.

Lẹ́yìn náà, Terrell gba nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ẹ̀dà Jí! tó sọ pé òun ló gba ẹ̀mí òun là. Ó ti pín ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Inú Terrell dùn pé ó ti jẹ́ àṣà òun láti máa ka àwọn ìsọfúnni wíwúlò tó wà nínú Jí!, a sì lérò pé ìwọ pẹ̀lú yóò ṣe bẹ́ẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

William Terrell

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́