Sísọ Igbó Amazon Dọ̀tun
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL
LÁÀÁRÍN ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1990, ayé pàdánù àràádọ́ta ọ̀kẹ́ hẹ́kítà igbó àìro lọ́dọọdún, ohun tí Ẹ̀ka Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ nìyẹn. Nínú igbó Amazon tó wà ní àgbègbè Brazil nìkan, igbó kìjikìji tó fẹ̀ ju ilẹ̀ Jámánì lọ ni wọ́n ṣá dànù, wọ́n sọ ọ́ di pápá ìjẹko lásán. Ó yẹ kí ibẹ̀ jẹ́ àgbègbè tí igbó ti pọ̀ lọ súà, ṣùgbọ́n ńṣe ni àwọn igi inú igbó náà wà gátagàta, tí àwọn èpò sì hù ṣúúrú-ṣúúrú sórí àwọn amọ̀ gbígbẹ, tí oòrùn sì pa àwọn gbòǹgbò igi gbẹ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìpagbórun tó ń lọ lọ́wọ́ yìí ń fa ìyọnu, ó jọ pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dára. Ètò kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ ti mú àwọn ìyọrísí kan wá. Wọ́n pè é ní gbígbin igi igbó, ìwé kan sì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ètò igi gbígbìn pa pọ̀ mọ́ gbígbin irúgbìn tàbí koríko kí wọ́n sì máa . . . dàgbà pa pọ̀.” Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ètò gbígbin igi igbó? Kí ni ètò náà ti ṣàṣeparí rẹ̀? Kí ni ó lè ní nípamọ́ fún ọjọ́ iwájú? Láti mọ èyí, Jí! ṣèbẹ̀wò sí Ibùdó Ìwádìí ti Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè ní Igbó Amazon (INPA) ní Manaus, tí í ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Amazonas ní Brazil.
Ojútùú Tó Jáni Kulẹ̀
Johannes van Leeuwen, ọmọ ilẹ̀ Netherlands, tí í ṣe onímọ̀ nípa irúgbìn àti àbójútó erùpẹ̀ ní ẹ̀ka Ìmọ̀ Nípa Ewéko ní àjọ INPA, ti ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbẹ̀ nínú igbó Amazon láti ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe jẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ fi dorí kọ igbó Amazon lákọ̀ọ́kọ́ ná? Àwọn àgbẹ̀ aládàá ńlá tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ní àárín gbùngbùn àti gúúsù ilẹ̀ Brazil bẹ̀rẹ̀ sí gba ìjẹ lẹ́nu àwọn àgbẹ̀ kéékèèké, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún ń gba ilẹ̀ wọn, èyí ló fà á tí wọ́n fi ń ṣí lọ. Àwọn àgbẹ̀ mìíràn, tí wọ́n ń gbin irúgbìn jute, tí wọ́n fi ń ṣe àpò ìdọ̀họ, rí i tí ìjẹ ń bọ́ lẹ́nu wọn nígbà tí àwọn àpò onírọ́bà bẹ̀rẹ̀ sí rọ́pò àpò ìdọ̀họ. Bákan náà ni ó di ọ̀ranyàn fún àwọn mìíràn tí wọ́n ń gbé àwọn àgbègbè tí ọ̀dá ti dá láti ṣí lọ nítorí wọ́n ń wá ilẹ̀ tó lọ́ràá. Ṣùgbọ́n ibo ni wọn ì bá lọ? Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ìlérí tí wọ́n ń ṣe fún wọn nípa ilẹ̀, ilé, àti ilẹ̀ tó lọ́ràá ní igbó Amazon, wọ́n gbéra, ó di inú igbó kìjikìji náà.
Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí àwọn àgbẹ̀ náà rí i pé ibi tí àwọn fìdí kalẹ̀ sí jẹ́ àgbègbè tí òjò ńlá ti máa ń rọ̀, tí ọ̀rinrin ti pọ̀, tí ooru ti pọ̀, tí ilẹ̀ ibẹ̀ kò sì lọ́ràá. Láàárín ọdún méjì sí mẹ́rin, wọ́n ti lo ilẹ̀ náà ṣá, ìṣòro kan náà sì tún dìde: àwọn òtòṣì èèyàn lórí ilẹ̀ tí kò lẹ́tù lójú. Àwọn àgbẹ̀ tí ojú ń pọ́n náà yanjú ìṣòro wọn nípa ṣíṣá àwọn àgbègbè kan sí i nínú igbó náà láti fi ṣọ̀gbìn.
Ká sọ tòótọ́, kì í ṣe àwọn àgbẹ̀ kéékèèké ló fa pípa igbó Amazon run ní pàtàkì. Àwọn oko màlúù ńláńlá, àwọn tí ń ṣe àgbẹ̀ aládàá ńlá, àwọn ilé iṣẹ́ ìwakùsà àti àwọn ilé iṣẹ́ igi gẹdú, àti àwọn ìsédò tí àwọn tó gba iṣẹ́ iná mànàmáná kọ́ ló pa èyí tó pọ̀ jù nínú igbó náà run. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, rírọ́ tí àwọn àgbẹ̀ kéékèèké rọ́ lọ síbẹ̀ àti àṣà ṣíṣá igbó, ká sì sun ún láti fi dáko dá kún pípa igbó náà run.
Bíbéèrè Ọ̀rọ̀ Lọ́wọ́ “Àwọn Tó Mọ Ìtàn Ibẹ̀”
Van Leeuwen sọ pé: “Láìka bí ipa tí àwọn àgbẹ̀ aláìní wọ̀nyí ní lórí igbó náà ṣe lágbára sí, wọ́n kò ní ibòmíràn tí wọ́n lè lọ. Nítorí náà, láti lè fawọ́ pípa igbó run sẹ́yìn, a ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá ọ̀nà tí wọ́n á fi lè máa rí nǹkan mú jáde láti inú ilẹ̀ wọn láìsí pé wọ́n ń ṣá igbó sí i mọ́.” Ibi tí ọ̀ràn gbígbin igi igbó ti wọ̀ ọ́ nìyẹn, èyí tó ń kọ́ni ní ọ̀nà iṣẹ́ àgbẹ̀ tó ń gbógun ti lílo ilẹ̀ ṣá, tó sì ń jẹ́ kí àwọn àgbẹ̀ lè máa lo ilẹ̀ kan náà tí wọ́n ti ṣá igbó rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Báwo ni àwọn olùwádìí ṣe pinnu kúlẹ̀kúlẹ̀ ètò náà?
Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu ìwádìí, àwọn ìwé àfiṣèwádìí, àti àwọn ohun ọ̀gbìn àti erùpẹ̀ àgbègbè tí wọ́n ṣèwádìí nípa rẹ̀ ló ṣáájú ìfilọ́lẹ̀ ètò gbígbin igi igbó tí àjọ INPA ṣe. Wọ́n rí àwọn ìsọfúnni tó ṣeyebíye gbà nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá “àwọn tó mọ ìtàn ibẹ̀” lẹ́nu wò, ìyẹn àwọn Àmẹ́ríńdíà àti àwọn ẹ̀yà caboclo, tí wọ́n jẹ́ àdàlù ìrandíran àwọn aláwọ̀ funfun, adúláwọ̀, àti àwọn Àmẹ́ríńdíà, tí àwọn baba ńlá wọn fi pẹ̀tẹ́lẹ̀ Amazon ṣe ibùjókòó.
Àwọn olùgbé Amazon yìí ní ìmọ̀ tó pọ̀. Wọ́n mọ bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí lágbègbè yẹn àti onírúurú erùpẹ̀ tó wà níbẹ̀—ìlẹ̀dú, ìlẹ̀pa, iyanrìn, ilẹ̀ pupa, àti àdàlú erùpẹ̀ òun amọ̀—àti onírúurú èso ibẹ̀, àwọn nǹkan amóúnjẹ ta sánsán, àti àwọn ewé tí a lè fi ṣe egbòogi tó wà nínú igbó náà. Nípa gbígbà nínú ìmọ̀ yìí, àwọn onímọ̀ nípa irúgbìn àti àbójútó erùpẹ̀, àti àwọn àgbẹ̀ wá di alájọṣiṣẹ́ nínú ṣíṣe ìwádìí—àjọṣe tó mú kí ètò náà túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí.
Igbó Náà Kì Í Ṣe Ibi Ìwakùsà
Wọ́n ṣe ètò gbígbìn igi igbó náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ohun tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ni láti yí àwọn àgbẹ̀ lérò padà kí wọ́n má ṣe máa wo igbó náà gẹ́gẹ́ bí ibi ìwakùsà—ibi tí wọ́n á kàn ti wá ṣiṣẹ́ tí wọ́n á sì pa tì—ṣùgbọ́n kí wọ́n wò ó bí ohun àmúṣọrọ̀ tí wọ́n lè sọ dọ̀tun. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbà wọ́n níyànjú láti má ṣe máa gbin kìkì pákí, ọ̀gẹ̀dẹ̀, erín (àgbàdo), ìrẹsì, ẹ̀wà, àti àwọn ohun ọ̀gbìn tí kì í kádún nìkan ṣùgbọ́n kí wọ́n máa gbin igi pẹ̀lú. Àwọn àgbẹ̀ náà béèrè pé: “Ká máa gbin igi kẹ̀, kí ló dé?”
Níwọ̀n bí àwọn àgbẹ̀ ti sábà máa ń wá láti àwọn àgbègbè tí igi kò ti ní nǹkan ṣe nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ àti pé níwọ̀n bí wọn kò ti mọ̀ nípa àwọn oríṣi igi inú igbó Amazon, àwọn olùwádìí ṣàlàyé fún wọn nípa àǹfààní tó wà nínú gbígbin igi. Wọ́n ṣàlàyé pé erùpẹ̀ inú igbó kìjikìji kò ní àwọn èròjà aṣaralóore tí àwọn irè oko tí a ń jẹ nílò. Fún àpẹẹrẹ, kí àwọn èròjà aṣaralóore tó lè dénú àwọn irè oko tí a ń jẹ bí àgbàdo, ọ̀gbàrá òjò á ti wọ́ wọn lọ. Ti àwọn igi kò rí bẹ́ẹ̀, igi máa ń rọ́nà fa àwọn èròjà wọ̀nyí sára, ó sì máa ń gbá wọn jọ sínú, yóò sì jẹ́ kí ọ̀rá inú ilẹ̀ máa wà bó ṣe wà. Ní àfikún sí i, igi ń pèsè oúnjẹ àti ibòji fún àwọn ẹranko. Àwọn àgbẹ̀ pẹ̀lú lè fi igi ṣe ọgbà yíká ààlà ilẹ̀ wọn. Bákan náà, àwọn igi tí ń so èso lè mówó wálé—kí wọ́n so èso, kí a sì fi igi wọn ṣe pákó.
Wọ́n tún rọ àwọn àgbẹ̀ náà láti gbin oríṣiríṣi igi. Èé ṣe? Kí wọ́n bàa lè kórè oríṣiríṣi èso, kí wọ́n sì lè rí oríṣiríṣi pákó gé. Lọ́nà yẹn, kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ pé kí àwọn àgbẹ̀ máa kórè oríṣi èso kan tàbí méjì péré jọ rẹpẹtẹ, kí wọ́n sì wá máa tà á ní owó pọ́ọ́kú nítorí pé gbogbo èèyàn ń ta irú irè oko kan náà lákòókò kan náà.
Ètò Igi Gbígbìn Méso Rere Wá
Irú àwọn igi wo ni wọ́n gbìn? Nígbà tí Van Leeuwen, tí í ṣe onímọ̀ nípa irúgbìn àti àbójútó erùpẹ̀, ń fún mi ní ìwé tó kọ àwọn àjèjì orúkọ igi márùndínláàádọ́rin sí, ó sọ pé: “Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a ń gbin nǹkan bí ọgbọ̀n sí ogójì lára àwọn igi èso tí a to orúkọ wọn sínú ìwé yìí.” Láti fi hàn pé ètò náà ń yọrí sí rere, Van Leeuwen kó àwọn fọ́tò mélòó kan jáde tó jẹ́ ti ilẹ̀ kan náà tí wọ́n ti ro nínú igbó náà ní àwọn àkókò tó yàtọ̀ síra.—Wo àpótí tó ní àkọlé náà, “Bí A Ṣe Lè Sọ Igbó Dọ̀tun.”
Ìbẹ̀wò tí a ṣe sí àwọn ọjà tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ ní Manaus fi hàn pé ètò gbígbin igi igbó náà ń méso rere wá. Ó lé ní ọgọ́ta onírúurú èso tí wọ́n ń gbìn lágbègbè náà tí wọ́n ń tà ní ọjà yìí. Nípa ti ọjọ́ iwájú, àwọn onímọ̀ nípa irúgbìn àti àbójútó erùpẹ̀ nírètí pé bí ètò gbígbin igi igbó náà bá ṣe fìdí múlẹ̀ tó ni àṣà pípa igbó run yóò ṣe máa dín kù sí i. Ó ṣe tán, nígbà tí àgbẹ̀ kan bá ti kọ́ bí ó ṣe lè máa lo oko tó ti ní tẹ́lẹ̀ ní àlòtúnlò, ó lè má ronú nípa ṣíṣá igbó mìíràn mọ́ láti fi dá oko tuntun.
Kò dájú pé àwọn iṣẹ́ takuntakun tó yẹ láti gbóríyìn fún yìí yóò fòpin sí ewu tó ń wu ayé àti àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n fi ohun tí a lè ṣe hàn nígbà tí wọ́n bá fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wa ṣíṣeyebíye.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọsàn àti Èso Acerola Ṣèbà
Ọsàn, ìyẹn èso tí a mọ̀ dáadáa pé ó máa ń fúnni ní fítámì C, kò já mọ́ nǹkan kan nígbà tí a fi í wé èso kan tí wọ́n ń gbóṣùbà fún pé òun ni “ọba èso tó ń fúnni ní fítámì C.” Kódà èso acerola, tí í ṣe olórí láàárín àwọn èso tó ní fítámì C gan-an, gbà á lọ́gàá. Ta wá ni ọ̀gá báyìí o? Èso kékeré kan báyìí ni ṣùgbọ́n ọba ni láàárín àwọn èso, ó láwọ̀ àlùkò, títóbi rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti ọsàn gíréèpù, inú igbó Amazon ni a sì ti ń rí i. Kí ni orúkọ rẹ̀? Camu-camu ni. Ṣé ipò náà tọ́ sí i? Ìwé ìròyìn kan ní ilẹ̀ Brazil sọ pé ọgọ́rùn-ún gíráàmù ọsàn ní mílígíráàmù mọ́kànlélógójì fítámì C nínú, nígbà tí ọgọ́rùn-ún gíráàmù èso acerola ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ó lé àádọ́rùn-ún [1,790] mílígíráàmù fítámì C nínú. Ṣùgbọ́n, ọgọ́rùn-ún gíráàmù èso camu-camu ní ẹgbẹ̀rìnlá ó lé ọgọ́rin [2,880] mílígíráàmù fítámì C nínú—ó jẹ́ ìlọ́po àádọ́rin iye tó wà nínú ọsàn!
[Credit Line]
Èso acerola àti èso camu-camu: Silvestre Silva/Reflexo
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Iṣẹ́ Gbígbin Igi Ní Ọ̀wọ́-Ọ̀wọ́
Lẹ́yìn tí àwọn àgbẹ̀ bá ti gbà láti tẹ̀ lé àwọn kan lára ètò gbígbin igi igbó, Johannes van Leeuwen tí í ṣe onímọ̀ nípa ohun ọ̀gbìn àti àbójútó erùpẹ̀ yóò fún wọn ní àwọn àbá tó túbọ̀ kún—àwòrán bí oko igi wọn ọjọ́ iwájú yóò ṣe rí. Dípò kí wọ́n kàn yan irú igi kan ṣá tàbí kí wọ́n wulẹ̀ pa àwọn igi kan pọ̀ láìronú jinlẹ̀, wọ́n wo àwòrán àwọn ohun ọ̀gbìn àti àyíká wọn lórí kọ̀ǹpútà láti pinnu irú ẹ̀yà tó yẹ kí wọ́n gbìn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n tò wọ́n. Ọ̀nà kan wà tí wọ́n máa ń gbà gbin àwọn ẹ̀yà igi, ìyẹn sí ọ̀wọ́ àwọn kéékèèké, ọ̀wọ́ àwọn tó tóbi lábọ́ọ́dé, àti ọ̀wọ́ àwọn ńláńlá.
Fún àpẹẹrẹ, ọ̀wọ́ àkọ́kọ́, tó jẹ́ àwọn igi góbà, guarana, àti cupuaçu, ni wọ́n máa ń gbìn sún mọ́ra. Àwọn igi wọ̀nyí tètè máa ń bẹ̀rẹ̀ sí so èso. Ọ̀wọ́ kejì, tó jẹ́ àwọn igi tó tóbi lábọ́ọ́dé bíi biribá, píà avocado, àti ọ̀pẹ murumuru, yóò ní láti jìnnà síra díẹ̀. Àwọn tó wà nínú ọ̀wọ́ yìí máa ń pẹ́ díẹ̀ ju ọ̀wọ́ ti àkọ́kọ́ kí wọn tó bẹ̀rẹ̀ sí so èso. Ọ̀wọ́ kẹta, tó jẹ́ àwọn igi ńláńlá bí igi ẹ̀pà Brazil, piquia, àti igi ọ̀ganwó, ní láti jìnnà síra gan-an. Àwọn kan lára àwọn igi tó wà nínú ọ̀wọ́ tó kẹ́yìn yìí máa ń so èso, a máa ń fi àwọn mìíràn ṣe gẹdú, a sì máa ń rí méjèèjì mú jáde láti ara àwọn mìíràn. Tí ọ̀wọ́ àwọn igi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà bá dàgbà pa pọ̀, ńṣe ni oko náà á dà bí igbó àìro.
[Àwọn àwòrán]
Johannes van Leeuwen, (níkangun apá ọ̀tún)
Ọjà kan ní Manaus tí wọ́n ti ń ta àwọn èso tí wọ́n gbìn níbẹ̀
[Credit Line]
J. van Leeuwen, INPA, Manaus, Brazil
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Bí A Ṣe Lè Sọ Igbó Dọ̀tun
1. February 1993—Oṣù September ọdún 1992 ni wọ́n ṣá igbó orí ilẹ̀ tó wà ní àárín gbùngbùn igbó Amazon yìí. Ní oṣù January ọdún 1993, wọ́n gbin ọ̀pẹ̀yìnbó sórí rẹ̀. Oṣù kan lẹ́yìn náà, wọ́n gbin àwọn igi eléso pẹ̀lú.
2. March 1994—Àwọn ọ̀pẹ̀yìnbó náà ti gbó, àwọn igi eléso tí wọ́n gbìn náà sì ti ń dàgbà gan-an. Wọ́n fi àwọn igi tí wọ́n wé rọ́bà aláwọ̀ oríṣiríṣi mọ́ sàmì sí wọn, èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àwọn igi náà láti fi mọ irú igi tí wọ́n jẹ́, àwọn bí ìgbá, ẹ̀pà Brazil, àti àwọn igi eléso peach, ká wulẹ̀ dárúkọ díẹ̀ lára wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ náà ṣe máa ń ro ìdí àwọn ọ̀gbìn náà ṣe àwọn igi náà láǹfààní pẹ̀lú. Bí ìgbà tí a bá sọ pé àwọn igi náà ń fi ìmoore hàn, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ilẹ̀ náà lọ́ràá.
3. April 1995—Wọ́n ti kórè àwọn ohun ọ̀gbìn tí kì í kádún, wọ́n jẹ wọ́n, tàbí kí ó jẹ́ pé wọ́n tà wọ́n, síbẹ̀síbẹ̀ onírúurú àwọn igi eléso ṣì ń dàgbà lọ.
[Credit Line]
Àwọn àwòrán 1 sí 3: J. van Leeuwen, INPA-CPCA, Manaus, Brazil