ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 12/8 ojú ìwé 30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdánwò Nípa Ọkọ̀ Wíwà Fa Ìrunú
  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Tí Ara Ń Ni
  • Túùkú Bẹ́ Sígboro
  • Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Ń Ṣègbéyàwó
  • Ìbàyíkájẹ́ Fa Àjàkálẹ̀ Kantíkantí
  • Àmujù Ọtí Lè Kó Bá Ìlera Rẹ
    Jí!—2005
  • Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Àmujù Ọtí Àkóbá Tó Ń Ṣe Fún Àwùjọ
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 12/8 ojú ìwé 30

Wíwo Ayé

Ìdánwò Nípa Ọkọ̀ Wíwà Fa Ìrunú

Ìwé ìròyìn ìlú Paris náà, International Herald Tribune, sọ pé: “Èébú àti lílù tí àwọn èèyàn ń lu ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ‘àwọn tó ń ṣèdánwò fúnni’ nípa ọkọ̀ wíwà ní ilẹ̀ Faransé ti wá pọ̀ sí i dé ìwọ̀n àádọ́jọ lórí ọgọ́rùn-ún láti ọdún 1994.” Àwọn tó yege nínú àyẹ̀wò ọkọ̀ wíwà tí wọ́n fi ogún ìṣẹ́jú ṣe náà, kò tó ìpín ọgọ́ta ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí kò tíì gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ọkọ̀ wíwà ló fìdí rẹmi. Àwọn tí wọ́n fìdí rẹmi túbọ̀ ń fi ìrunú wọn hàn sí àwọn tó ń ṣèdánwò fúnni náà nípa gbígbá wọn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ àti fífi irun fà wọ́n bọ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Ọkùnrin kan tiẹ̀ lé ẹni tó ṣèdánwò fún un kiri, ó fẹ́ gún un lábẹ́rẹ́ tó sọ pé ẹ̀jẹ̀ tó ní àrùn éèdì lòún fà sínú rẹ̀. Láìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tó fìdí rẹmi nínú ìdánwò tó ṣe yin ìbọn tí ọta onírọ́bà wà nínú rẹ̀ lu ẹni tó ṣèdánwò fún un. Láti mú kí gbogbo irú ìwà ipá báwọ̀nyí kásẹ̀ nílẹ̀, àwọn tó ń ṣèdánwò fúnni wá dábàá pé kí wọ́n máa fi èsì ìdánwò àwọn awakọ̀ tó wọn létí nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́ dípò kí wọ́n máa sọ ọ́ fún wọn lójúkojú.

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Tí Ara Ń Ni

Ìwé ìròyìn Asian Age ti Mumbai sọ pé àkókò ìdánwò ìparí ọdún nílé ìwé túbọ̀ máa ń ni púpọ̀ ọmọdé ilẹ̀ Íńdíà lára. Híhá nǹkan sórí kí ìdánwò tó bẹ̀rẹ̀ àti ìdààmú pé kí àwọn lè gba máàkì dáadáa ti pọ̀ ju ohun tí ẹ̀mí àwọn kan lè gbé lọ, iye àwọn tó sì ń lọ rí àwọn oníṣègùn ọpọlọ máa ń di ìlọ́po méjì lákòókò ìdánwò. Àwọn òbí kan, tí ọkàn wọn wà nínú pé kí àwọn ọmọ wọn ṣe dáadáa nínú ìdánwò, kì í jẹ́ kí wọ́n ṣe eré ìnàjú èyíkéyìí. V. K. Mundra, tí í ṣe oníṣègùn ọpọlọ, sọ pé: “Àwọn òbí ń fipá mú àwọn ọmọ gan-an. Bákan náà, ọ̀ràn ti fífigagbága pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tún wà níbẹ̀.” Ó tún sọ pé ọ̀pọ̀ òbí ni “kò mọ̀ pé ríran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti sinmẹ̀dọ̀ yóò jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ jí pépé, yóò sì ràn án lọ́wọ́ láti kàwé dáadáa.” Dókítà Harish Shetty sọ pé másùnmáwo ìgbà ìdánwò “ti ń yọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wà ní kíláàsì kìíní sí ìkeje lẹ́nu pẹ̀lú.”

Túùkú Bẹ́ Sígboro

Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilẹ̀ Jámánì náà, Die Woche, sọ pé àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ẹgàn, tí wọ́n máa ń sábà tijú, ti wá rí i pé àárín ìlú ni oúnjẹ pọ̀ sí àti pé ibẹ̀ ni àwọn ti lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọdẹ. Àwọn abo ẹlẹ́dẹ̀ ẹgàn tilẹ̀ ń bímọ sáàárín ìlú Berlin. Kì í ṣe inú igbó àti àwọn ọgbà ìṣiré ìlú nìkan làwọn ẹranko tí ebi ń pa náà ń jẹ̀ sí. Wọ́n tún ń jẹ̀ nínú àwọn oko etílé, wọ́n ń jẹ ìdí igi òdòdó. Àwọn túùkú náà, tí wọ́n lè wọ̀n tó àádọ́ta dín nírínwó kìlógíráàmù, ti dẹ́rù ba ọ̀pọ̀ ará ìlú, tí wọ́n máa ń ta mọ́ igi tàbí kí wọ́n sá sínú akóló tẹlifóònù. Àwọn ẹranko náà ti fa ọ̀pọ̀ jàǹbá mọ́tò. Ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú ló ti pàdé àwọn aṣíwọ̀lú onírun ṣágiṣàgi náà nígbà tí wọ́n dé sílé láti ibi iṣẹ́. Ẹnì kan béèrè pé: “Báwo ni mo ṣe lè wọlé nígbà tí ogún túùkú tò síwájú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi níbi tí mo máa ń gbà wọnú ilé?”

Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Ń Ṣègbéyàwó

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Asian Age ti Mumbai ti sọ, Ìwádìí Nípa Ìlera Ìdílé tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní Íńdíà fi hàn pé ó tó ìpín mẹ́rìndínlógójì lára àwọn ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bàlágà tí wọ́n ti ṣègbéyàwó tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́rìndínlógún lọ. Ìwádìí náà tún fi hàn pé ìpín mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lára àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́tàdínlógún sí mọ́kàndínlógún lọ ló ti bímọ kan tàbí ni wọ́n ti lóyún. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti sọ, ewu ikú tí oyún ń fà fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń bímọ ní ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlógún fi nǹkan bí ìlọ́po méjì ju ti àwọn tí wọ́n ti pé ogún ọdún sí ọdún mẹ́rìnlélógún. Síwájú sí i, àwọn àrùn abẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógún ń kó ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Àwọn ògbógi sọ pé àìní ìmọ̀, àti ìsọfúnni tó ń ṣini lọ́nà tí àwọn ojúgbà wọn àti àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ló ń mú kí ìṣòro náà pọ̀ sí i.

Ìbàyíkájẹ́ Fa Àjàkálẹ̀ Kantíkantí

Ó ti hàn gbangba pé sísọ omi di eléèérí ti dá kún ìṣòro àwọn kòkòrò tí ń tani ní tòsí Odò Chili, tó ń ṣàn kọjá ní Arequipa, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó tóbi jù lọ ní Peru. Àwọn olùgbé àdúgbò náà ti lo gbogbo oògùn apakòkòrò tó wà níbẹ̀ tán nígbà tí wọ́n ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àwọn kòkòrò kantíkantí kéékèèké. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn El Comercio ti Lima ti sọ, wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn kẹ́míkà tí wọ́n fi ba Odò Chili jẹ́ ló fa àjàkálẹ̀ náà. Ìwé ìròyìn náà wá fi kún un pé, ó jọ pé àwọn oró májèlé ti pa púpọ̀ lára àwọn ọ̀pọ̀lọ́ inú odò náà, àwọn tó jẹ́ pé “fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti ń gbógun ti àwọn kòkòrò ọ̀hún láti má ṣe di púpọ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́