ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 26-27
  • Ọ̀rẹ́ Tí Kò Ṣeé Yà ni Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rẹ́ Tí Kò Ṣeé Yà ni Wá
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Fọ́jú, Síbẹ̀ Mo Ń Ríran
  • A Yàn Án fún Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Àrà Ọ̀tọ̀
  • Ohun Tí Tracy Ń Ṣe fún Mi
  • Àìní fún Lílóye
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Bí Mo Ṣe Kojú Ìkólòlò
    Jí!—1998
  • Àwọn Ọmọdé Ha Wà Láìséwu Lọ́dọ̀ Ajá Rẹ bí?
    Jí!—1997
  • Kí Nìdí Tó FI Yẹ Kí N Máa Fàwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù?
    Jí!—2008
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 26-27

Ọ̀rẹ́ Tí Kò Ṣeé Yà ni Wá

TRACY, ajá ọdẹ dúdú ọlọ́dún mẹ́wàá kan, tí ó jẹ́ oríṣi tí a ń pè ní Labrador ni ajá afinimọ̀nà mi. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni mo fi lè máa rìn kiri bó ṣe yẹ. Ó sábà máa ń wà pẹ̀lú mi, ó sì ń tù mí nínú pẹ̀lú. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìyàlẹ́nu pé mo ti wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀, a sì ti di ọ̀rẹ́ tí kò ṣeé yà.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, láìmọ̀ọ́mọ̀, ẹ̀dá ènìyàn ń jáni kulẹ̀ lọ́nà kan tí Tracy kò ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, mo ti fi Tracy sílé, mo sì ń bá ọ̀rẹ́ kan kẹ́sẹ̀ rìn lọ. A ń sọ̀rọ̀ tayọ̀tayọ̀ nígbà tí mo ṣubú lulẹ̀ lójijì. Ọ̀rẹ́ mi ti gbàgbé pé ojú mi fọ́, kò sì kìlọ̀ fún mi nípa gegele oníkọnkéré tí wọ́n fi ṣe ọ̀nà àgbàrá. Ká ní Tracy ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi ni, irú èyí kì bá tí ṣẹlẹ̀.

Nígbà kan, Tracy gbà mí là gan-an ni. Mo ń kọjá lọ ní títì kan nígbà tí ọwọ́ ọkọ̀ akẹ́rù kan kò ṣeé ṣàkóso mọ́, tí ó sì dédé bẹ̀rẹ̀ sí í fì bọ̀ níhà ọ̀dọ̀ mi. Mo gbọ́ròó ẹ́ńjìnnì rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹ ti mọ̀, n kò lè rí ibi tí ó forí lé. Tracy rí i, ó mọ̀ pé ewu ń bọ̀, ó sì yára fà mí lọ síbi tí kò séwu.

Mo Fọ́jú, Síbẹ̀ Mo Ń Ríran

A bí mi ní 1944 ní ìhà gúúsù Sweden, mo sì ti fọ́jú láti ìgbà tí a ti bí mi. Wọ́n rán mi lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn afọ́jú kan tí ó ní ibùgbé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, níbi tí mo ti kọ́ láti ka ìwé àwọn afọ́jú kí n sì kọ ọ́. Orin di apá pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé mi, ní pàtàkì, títẹ dùùrù. Lẹ́yìn tí mo jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè àti orin nìṣó ní Yunifásítì Göteborg.

Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbésí ayé mi yí pa dà pátápátá nígbà tí méjì lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ẹnu ọ̀nà mi ní ọgbà yunifásítì náà. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ẹlòmíràn ṣàjọpín ohun tí mo ń kọ́. Ní 1977, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. Bí mo tilẹ̀ fọ́jú nípa ti ara, nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mo ti rí ohun kan tí ó túbọ̀ níye lórí gbà—ìríran tẹ̀mí.

Lónìí, mo ka ara mi sí ẹni tí ó sàn gidigidi ju àwọn tí wọ́n ríran nípa ti ara, ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú nípa tẹ̀mí lọ. (Fi wé Jòhánù 9:39-41.) Mo láyọ̀ láti ní ojú ìríran tinú nípa ayé tuntun ti Ọlọ́run, níbi tí ojú àwọn afọ́jú yóò ti ríran, gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣèlérí—bẹ́ẹ̀ ni, níbi tí a óò ti wo gbogbo àìlera ti ara sàn, àní tí a óò sì jí àwọn òkú pàápàá dìde!—Orin Dáfídì 146:8; Aísáyà 35:5, 6; Ìṣe 24:15.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lọ́kọ, tí mo sì fọ́jú ní ti ara, pẹ̀lú Tracy gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́ mi tí kò yẹsẹ̀, mo ń gbé ayé lọ́nà dídára. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí ó ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ti ara mi, kí n sì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Mátíù 24:14; Ìṣe 20:20; Hébérù 10:25) Ṣùgbọ́n ṣáájú, kí n kọ́kọ́ sọ díẹ̀ sí i nípa Tracy fúnra rẹ̀.

A Yàn Án fún Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Àrà Ọ̀tọ̀

Nígbà tí Tracy dàgbà tó oṣù mẹ́jọ péré, wọ́n dán an wò láti mọ̀ bóyá yóò lè wúlò bí ajá afinimọ̀nà. Ẹ̀rí wà pé ó baralẹ̀, ó dùn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ariwo òjijì kò sì ń bà á lẹ́rù. Nítorí náà, wọ́n mú un sọ́dọ̀ ìdílé kan fún àkókò díẹ̀, kí ó lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìgbésí ayé ìdílé ti sábà máà ń rí. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó dàgbà tó, wọ́n rán an lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn ajá afinimọ̀nà.

Nílé ẹ̀kọ́ yìí ni Tracy ti kẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣe àwọn ohun tí a retí pé kí ajá afinimọ̀nà kan máa ṣe, ìyẹn ni, láti máa ran ọ̀gá rẹ̀ ọjọ́ iwájú lọ́wọ́ láti mọ ibi tí ilẹ̀kùn, àtẹ̀gùn, géètì, àti ojú ọ̀nà bá wà. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ láti máa rìn ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí èrò gbé pọ̀, àti láti máa ré títì kọjá. Wọ́n tún kọ́ ọ láti máa dúró bí ó bá kan gegele oníkọnkéré tí wọ́n fi ṣe ọ̀nà àgbàrá, kí ó máa tẹ̀ lé àmì iná tí ń darí ọkọ̀, kí ó sì máa yẹ̀ fún àwọn ohun ìdènà líléwu. Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù márùn-ún tí ó fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, ó ti gbára dì láti ṣiṣẹ́. Nígbà yẹn ni wọ́n mú mi mọ Tracy.

Ohun Tí Tracy Ń Ṣe fún Mi

Láràárọ̀ ni Tracy ń jí mi kí n lè fún un lóúnjẹ. Lẹ́yìn náà, a ń múra fún iṣẹ́. Ọ́fíìsì mi jẹ́ ìrìn nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú láti ilé wa. Ní kedere, mo mọ ọ̀nà náà, ṣùgbọ́n iṣẹ́ Tracy ni láti mú mi débẹ̀ láìsí pé mo ta lu àwọn ọkọ̀, ènìyàn, òpó iná, tàbí ohun yòó wù kó jẹ́. Nígbà tí a bá débẹ̀, yóò dùbúlẹ̀ sábẹ́ tábìlì mi. Lẹ́yìn náà, nígbà ìṣíwọ́ oúnjẹ ọ̀sán, a máa ń nasẹ̀ lọ.

Nírọ̀lẹ́, lẹ́yìn tí a bá darí tibi iṣẹ́ dé, a máa ń bẹ̀rẹ̀ apá tí ó gbádùn mọ́ni jù lọ nínú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ìgbà yí ni Tracy máa ń tọ́ mi sọ́nà lọ sínú iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé, àti sí àwọn ilé tí mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn máa ń bá a ṣọ̀rẹ́, wọ́n ń fọwọ́ pa á lára, wọ́n sì ń gbá a mọ́ra, nígbà míràn pẹ̀lú, wọ́n sì ń kó àwọn oúnjẹ kan fún mi láti fún un jẹ. A tún máa ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn ìpàdé wọ̀nyí, àwọn ọmọdé máa ń fẹ́ láti kí Tracy, kí wọ́n sì gbá a mọ́ra, èyí sì ń mú inú rẹ̀ dùn gidigidi.

Mo mọ̀ pé Tracy wulẹ̀ jẹ́ ajá kan ni, yóò sì kú lọ́jọ́ kan. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, èmi yóò ní láti wá ajá afinimọ̀nà míràn. Ṣùgbọ́n, ní báyìí ná, agbo òṣìṣẹ́ kan la jọ jẹ́, a sì nílò ara wa. Nígbà tí Tracy kò bá sí nítòsí, n kì í dá ara mi lójú, òun náà sì máa ń wára pàpà, tí ara rẹ̀ kò sì máa ń balẹ̀, nígbà tí kò bá lè ṣamọ̀nà mi.

Àìní fún Lílóye

Ó yani lẹ́nu pé àwọn ènìyàn máa ń gbìyànjú láti yà wá nígbà míràn. Wọ́n ń fojú wo Tracy bí ajá lásán tàbí ohun ọ̀sìn lásán kan, wọn kò sì lóye ipò ìbátan jíjinlẹ̀ tí a ní. Ó yẹ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí mọ̀ pé, bí àga àwọn arọ ṣe jẹ́ sí arọ kan ni Tracy jẹ́ sí mi. Yíyà wá dà bíi mímú ojú mi kúrò.

Bí àwọn ẹlòmíràn bá ṣe lóye ipò ìbátan àárín èmi àti Tracy dáradára tó ni wàhálà yóò ṣe kéré tó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn sábà ń fara mọ́ kẹ̀kẹ́ arọ, ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé, wọn kì í sábà fara mọ́ ajá afinimọ̀nà. Ẹ̀rù ajá máa ń ba àwọn ènìyàn kan, tàbí wọn kò ṣáà fẹ́ràn wọn ni.

Ìsọfúnni tí a rí nínú ìwé pẹlẹbẹ kan, tí Ẹgbẹ́ Ilẹ̀ Sweden fún Àwọn Afọ́jú tẹ̀ jáde, nípa àwọn ajá afinimọ̀nà wúlò gan-an. Ó wí pé: “Ajá afinimọ̀nà ní ń ran àwọn afọ́jú lọ́wọ́ láti lè máa rìn kiri. Ní gidi, ó ju ìyẹn lọ. Ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà láàyè. . . . Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ kan tí kì yóò já ọ kulẹ̀ láé.”

Ní tòótọ́, Tracy ń ṣiṣẹ́ bí ojú mi nínú òkùnkùn, ó sì ń ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé yíyẹ bí ó ti ṣeé ṣe tó nísinsìnyí. Síbẹ̀, ó dá mi lójú pé, láìpẹ́, nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, yóò ṣeé ṣe fún mi láti rí gbogbo ohun ìyanu ìṣẹ̀dá tí ń múni ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, mo ti pinnu nísinsìnyí láti di ìríran tẹ̀mí mi mú ṣinṣin.

Nítorí náà, bí mo ti gbé orí Tracy lé itan mi, a ti ṣe tán báyìí láti fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí ó jáde kẹ́yìn tí a ti gbà sílẹ̀.—Bí Anne-Marie Evaldsson ṣe sọ ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́